MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Láti Wàásù Láwọn Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Onírúurú Èdè
Àwọn èèyàn sábà máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wa tá a bá wàásù fún wọn ní èdè ìbílẹ̀ wọn. Nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí ìdí yẹn ni Jèhófà fi jẹ́ kí àwọn Júù “tí ó ní ìfọkànsìn” tó wá láti “gbogbo orílẹ̀-èdè” gbọ́ ìhìn rere ní “èdè tirẹ̀,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn náà máa sọ èdè Hébérù tàbí Gíríìkì tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbọ́. (Iṣe 2:5, 8) Lónìí, láwọn àdúgbò tí wọ́n ti ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn ìjọ tó ń ṣe ìpàdé lédè tó yàtọ̀ síra lè máa wàásù ní ìpínlẹ̀ kan náà. Báwo làwọn akéde tó wà ní irú ìjọ yìí ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti jẹ́rìí kúnnákúnná, tí wọn ò sì ní máa wàásù láwọn ibi tí ìjọ kan ti ṣẹ̀ṣẹ̀ wàásù tán, èyí tó ṣeé ṣe kó múnú bí àwọn onílé?
Ẹ Fikùnlukùn (Owe 15:22): Kí àwọn alábòójútó iṣẹ́ ìsìn jọ fikùnlukùn, kí wọ́n sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ṣe ètò tó máa ṣe gbogbo ìjọ láǹfààní láti wàásù ìhìn rere náà. Àwọn ìjọ tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiyín lè má fi bẹ́ẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù, torí náà wọ́n lè sọ pé kẹ́ ẹ má ṣe wàásù ní ilé àwọn tó ń sọ èdè tí ìjọ wọn fi ń ṣe ìpàdé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìpínlẹ̀ ìwàásù yín làwọn ilé yẹn wà. Àmọ́, tí ìpínlẹ̀ wọn bá tóbi, tí wọn ò sì lè máa ṣe é déédéé, wọ́n lè ní kẹ́ ẹ máa wàásù ní gbogbo ilé tó wà ní ìpínlẹ̀ àwọn, àmọ́ tẹ́ ẹ bá rí ẹni tó fìfẹ́ hàn, kẹ́ ẹ jẹ́ kí àwọn mọ̀. (od 93 ¶37) Wọ́n sì lè sọ pé kí ìjọ yín bá àwọn wá àwọn tó ń sọ èdè tí ìjọ wọn ń lò, kí wọ́n lè máa lọ wàásù fún wọn. (km 7/12 5, àpótí) Ẹ fi sọ́kàn pé láwọn ìgbà míì, àwọn tó ń gbé inú ilé kan lè máa sọ ju èdè kan lọ. Gbogbo ètò tẹ́ ẹ bá ṣe gbọ́dọ̀ bá òfin mu lórí ọ̀rọ̀ lílo ìsọfúnni ẹlòmíì.
Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ (Ef 4:16): Fara balẹ̀ tẹ̀ lé ìtọ́ni èyíkéyìí tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bá fún yín. Tó o bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ tó jẹ́ pé èdè tẹ́ ẹ fi ń ṣe ìpàdé kì í ṣe èdè tí ẹni náà fẹ́. Ó ṣeé ṣe kí ẹni náà tẹ̀ síwájú kíákíá tó o bá fa ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lé ẹlòmíì lọ́wọ́, ìyẹn ẹni tó wà ní ìjọ tàbí àwùjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè tí ẹni náà gbọ́ dáadáa.
Múra Sílẹ̀ (Owe 15:28; 16:1): Tó o bá pàdé ẹnì kan tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tìẹ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti wàásù fún un. O lè ronú nípa irú èdè tí àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín ń sọ, kó o sì wa Bíbélì àti àwọn fídíò àwọn èdè yẹn sórí fóònù rẹ. O tún lè lo ètò ìṣiṣẹ́ JW Language láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń kí èèyàn láwọn èdè kan.