Bí Onílé Bá Ń Sọ Èdè Tó Yàtọ̀
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nígbà tá a bá ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?
1 Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé máa ń bá àwọn tó fìfẹ́ hàn pàdé, àmọ́ tí èdè tí wọ́n ń sọ kò bá èyí táwọn akéde wọ̀nyẹn fi ń ṣèpàdé ìjọ mu. Káwọn ará bàa lè ran àwọn tó fìfẹ́ hàn wọ̀nyí lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì ló ti rí i pé ó pọn dandan káwọn dá àwọn àwùjọ àti ìjọ tó ń sọ irú èdè bẹ́ẹ̀ sílẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé oríṣiríṣi èdè ni wọ́n lè máa sọ ládùúgbò kan, àwọn ìjọ tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ síra lè máa wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kan náà. Báwo làwọn ìjọ tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ síra ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n bàa lè rí i pé wọ́n ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà létòletò?—1 Kọ́r. 14:33.
2. Tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, báwo la ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn àwùjọ tàbí ìjọ tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ ládùúgbò wa?
2 Ẹ Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀: Kí àwọn akéde má ṣe lọ́ra láti bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ní òpópónà tàbí tí wọ́n bá ń wàásù láìjẹ́-bí-àṣà, kódà wọ́n lè wàásù fẹ́ni tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwọn, wọ́n sì lè fún onítọ̀hún ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní èdè tó bá yàn láàyò. Àmọ́, tẹ́ ẹ bá ń wàásù láti ilé dé ilé ládùúgbò kan tí ìjọ yín àti àwọn àwùjọ tàbí ìjọ tó ń sọ èdè míì ti máa ń wàásù, káwọn akéde gbìyànjú láti wàásù ní kìkì àwọn ilé tí wọ́n ti ń sọ èdè tó bá ti ìjọ akéde yẹn mu. Àkọsílẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an nígbà tí ìpínlẹ̀ ìwàásù bá da ìjọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pọ̀. Káwọn alábòójútó iṣẹ́ ìsìn àwọn ìjọ tọ́rọ̀ náà bá kàn jọ ṣètò tó mọ́yán lórí, kí wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan lórí ọ̀nà tí wọ́n á gbà máa bójú tó ìpínlẹ̀ náà. (Òwe 11:14) Àmọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ bá ẹni tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ pàdé nígbà tẹ́ ẹ̀ ń wàásù láti ilé dé ilé, tí kò sì sí ìjọ tó ń sọ èdè náà nítòsí, kí akéde tó bá onítọ̀hún pàdé gbìyànjú láti wàásù fún un kó sì ràn án lọ́wọ́.
3. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá báwọn àwùjọ tàbí ìjọ tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa pàdé ládùúgbò tá a ti ń wàásù?
3 Iṣẹ́ Kan Náà Là Ń Ṣe: Kí ló yẹ ká ṣe táwọn akéde ìjọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ bá ń wàásù láti ilé dé ilé ládùúgbò kan náà lọ́jọ́ kan náà? Ó dájú pé ìfẹ́ ará máa borí ìpínyà tí èdè wa tó yàtọ̀ lè fà, á sì jẹ́ kí gbogbo àwọn ará pọkàn pọ̀ sórí ohun tó máa ṣàwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn láǹfààní. (Jòh. 13:34, 35) Nítorí náà, káwọn tó ń múpò iwájú lo ìfòyemọ̀, kí wọ́n sì fi ìfẹ́ gba tàwọn ẹlòmíì rò nípa pípinnu bóyá kí àwùjọ kan lọ sí àdúgbò míì fúngbà díẹ̀.—Ják. 3:17, 18.
4. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ló ń nímùúṣẹ lákòókò tá a wà yìí?
4 Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé onírúurú èèyàn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ síra ló máa gbọ́ ìhìn rere náà. (Ìṣí. 14:6, 7) Bí gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kàn bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, kò ní sí pé àwọn akéde látinú ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń bá ẹnì kan náà kẹ́kọ̀ọ́, èyí á sì jẹ́ kí wọ́n lè mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tuntun púpọ̀ sí i, títí kan àwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ séyìí tí wọ́n ń sọ nínú ìjọ wọn.—Éfé. 4:16.