Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 23
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 23
Orin 175
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
lv orí 13 ìpínrọ̀ 1 sí 4, àpótí tó wà lójú ìwé 148 sí 149, àti 158 sí 159
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 28-31
No. 1: Diutarónómì 30:1-14
No. 2: Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣiṣẹ́ (lr orí 42)
No. 3: Ìdí Tí Amágẹ́dọ́nì Fi Jẹ́ Ẹ̀rí Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa (td 4B)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 206
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
5 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́, kó o sì dábàá àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ṣe àṣefihàn kan tó dá lórí bí akéde ògbóṣáṣá kan ṣe ń kọ́ akéde tuntun kan bó ṣe lè múra sílẹ̀ láti fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn.
25 min: “Bá A Ṣe Lè Wàásù fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 4, ní kí akéde kan ṣàṣefihàn àbá tó wà níbẹ̀.
Orin 165