ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/97 ojú ìwé 3
  • Ìhìn Rere Lórí Ìsokọ́ra Alátagbà Internet

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìhìn Rere Lórí Ìsokọ́ra Alátagbà Internet
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iṣẹ́ Ìpèsè àti Orísun Ìsọfúnni Ìsokọ́ra Alátagbà Internet
    Jí!—1997
  • Lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì—Ẹ Ṣọ́ra fún Ewu Tó Wà Níbẹ̀!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Fi Ọgbọ́n Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ohun Tó Lè Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 11/97 ojú ìwé 3

Ìhìn Rere Lórí Ìsokọ́ra Alátagbà Internet

Ní àkókò wa tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti gòkè àgbà, àwọn ènìyàn kan ń rí ìsọfúnni gbà nípasẹ̀ àwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́, títí kan nípasẹ̀ Ìsokọ́ra Alátagbà Internet. Nítorí náà, Society ti fi ìsọfúnni mélòó kan tí ó péye nípa àwọn ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ àti ìgbòkègbodò wọn sínú Ìsokọ́ra Alátagbà Internet.

Ibi Ìsokọ́ra Web ti Ìsokọ́ra Alátagbà Internet tiwa ní àdírẹ́sì náà, http://www.watchtower.org tí ó sì ní àṣàyàn àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé pẹlẹbẹ, àti àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, Chinese (Tí A Mú Rọrùn), Germany, Rọ́ṣíà, àti Sípéènì, títí kan àwọn èdè míràn. Àwọn ìtẹ̀jáde tí ó wà lórí ibi Ìsokọ́ra Web yí ti wà nínú àwọn ìjọ, a sì ń lò wọ́n nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ète ibi Ìsokọ́ra Web wa kì í ṣe láti mú àwọn ìtẹ̀jáde tuntun jáde, ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti mú kí ìsọfúnni wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn nípasẹ̀ ìṣètò kọ̀ǹpútà. Kò sí ìdí fún ẹnikẹ́ni láti kọ ìsọfúnni nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ìgbòkègbodò wa, tàbí àwọn ohun tí a gbà gbọ́, fún lílò lórí Ìsokọ́ra Alátagbà Internet. Ibi Ìsokọ́ra tí a fàṣẹ sí pèsè ìsọfúnni tí ó péye fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ẹ.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi Ìsokọ́ra wa kò ní ìpèsè fún àwọn ìsọfúnni kọ̀ǹpútà (fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà), ó ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àdírẹ́sì ìfìwéránṣẹ́ àwọn ẹ̀ka Society kárí ayé. Nípa báyìí, àwọn ènìyàn lè kọ̀wé láti gba ìsọfúnni sí i tàbí láti gba ìrànwọ́ ara ẹni láti ọ̀dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí ládùúgbò. Má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti ṣàjọpín àdírẹ́sì Ìsokọ́ra Alátagbà Internet tí ó wà lókè yí pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì láti inú ìṣètò yí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́