Iṣẹ́ Ìpèsè àti Orísun Ìsọfúnni Ìsokọ́ra Alátagbà Internet
ORÍSUN ìsọfúnni tí ó wọ́pọ̀ tí ìsokọ́ra alátagbà Internet ń pèsè ni ìgbékalẹ̀ tí ó wà jákèjádò ayé fún fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ àti gbígba ìsọfúnni lórí kọ̀ǹpútà, tí a mọ̀ sí E-mail. Ní gidi, ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà dúró fún apá títóbi lára gbogbo ohun tí ń lọ lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet, ó sì jẹ́ orísun ìsọfúnni ìsokọ́ra alátagbà Internet kan ṣoṣo tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lò. Báwo ni ó ṣe ń ṣiṣẹ́? Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ yẹ̀ ìgbékalẹ̀ ìfìsọfúnni lásán ránṣẹ́ wò.
Finú wòye pé o ń gbé Kánádà, o sì fẹ́ láti fi lẹ́tà kan ránṣẹ́ sí ọmọbìnrin rẹ tí ń gbé Moscow. Lẹ́yìn tí o bá ti kọ àdírẹ́sì tí ó yẹ sára àpòòwé náà, ìwọ yóò fi ránṣẹ́, ní mímú kí ìrìn àjò lẹ́tà náà bẹ̀rẹ̀. Nílé ìfìwéránṣẹ́ kan, wọn óò darí lẹ́tà náà sí ibi tí yóò lọ lẹ́yìn náà, bóyá ibùdó ìpínkiri ẹlẹ́kùnjẹkùn tàbí ti orílẹ̀-èdè, àti lẹ́yìn náà lọ sí ilé ìfìwéránṣẹ́ àdúgbò kan tí ó sún mọ́ ọmọbìnrin rẹ.
Ìgbésẹ̀ kan tí ó jọra ń ṣẹlẹ̀ ní ti ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà. Lẹ́yìn tí o bá ti kọ lẹ́tà rẹ tán lórí kọ̀ǹpútà rẹ, o gbọ́dọ̀ kọ àdírẹ́sì ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà tí ó ní orúkọ ọmọbìnrin rẹ nínú sí i. Gbàrà tí o bá ti fi lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà yí ránṣẹ́, yóò gbéra lọ láti orí kọ̀ǹpútà rẹ, lọ́pọ̀ ìgbà yóò gba inú ìhùmọ̀ kan tí ń jẹ́ aṣèyípadà àmì ìsọfúnni, tí ń tàtagbà kọ̀ǹpútà pẹ̀lú ìsokọ́ra alátagbà Internet láti inú ìsokọ́ra tẹlifóònù. Yóò gbéra lọ, ní fíforílé onírúurú kọ̀ǹpútà tí ń ṣiṣẹ́ bí ipa ọ̀nà ìfìwéránṣẹ́ àdúgbò àti orílẹ̀-èdè. Wọ́n ní ìsọfúnni tí ó pọ̀ tó láti gbé lẹ́tà náà dé orí kọ̀ǹpútà tí ó ń lọ, níbi tí ọmọbìnrin rẹ ti lè rí i, kí ó sì kà á.
Láìdàbí ìsọfúnni lásán, ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà sábà máa ń dé ibi tí ń lọ, kódà ní àwọn kọ́ńtínẹ́ǹtì míràn, láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan tàbí láìpẹ́ tó bẹ́ẹ̀ àyàfi bí àwọn apá kan lára ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra náà bá kún jù tàbí tí kò ṣiṣẹ́ fún àkókò díẹ̀. Nígbà tí ọmọbìnrin rẹ bá yẹ ibi tí àkójọ ìsọfúnni tí a fi ń ránṣẹ́ sí i wà wò, yóò rí ìsọfúnni tí o fi ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà. Ìyára ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà àti bí ó ṣe rọrùn láti fi ránṣẹ́ sí àwọn agbàsọfúnni púpọ̀ jákèjádò ayé pàápàá mú kí ó jẹ́ ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tí ó wọ́pọ̀.
Àwọn Àwùjọ Oníròyìn
Iṣẹ́ ìpèsè wíwọ́pọ̀ míràn ni a ń pè ní Usenet. Usenet ń fúnni ní àǹfààní láti dé ọ̀dọ̀ àwọn àwùjọ oníròyìn fún jíjíròrò pọ̀ bí àwùjọ lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ pàtó kan. Àwọn àwùjọ oníròyìn kan darí àfiyèsí sí rírà tàbí títa onírúurú àwọn ohun àràlò. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwùjọ oníròyìn ló wà, gbàrà tí ẹnì kan tí ń lò ó bá sì ti dé inú Usenet, a kò ní sàsansílẹ̀ owó kankan fún wọn.
Jẹ́ kí a finú wòye pé ẹnì kan ti dara pọ̀ mọ́ àwùjọ kan tí ń lọ́wọ́ nínú ṣíṣàkójọ sítáǹpù. Bí a ti ń fi àwọn ìsọfúnni tuntun nípa ìgbòkègbodò àfipawọ́ yìí ránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n sàsansílẹ̀ owó fún àwùjọ yìí, ìsọfúnni náà wá wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ẹni tuntun yìí. Kì í ṣe ohun tí ẹnì kan fi ránṣẹ́ sí àwùjọ oníròyìn náà nìkan ni ẹni yìí yóò ṣàtúnyẹ̀wò àmọ́ ohun tí àwọn ẹlòmíràn fèsì pa dà. Fún àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá béèrè fún ìsọfúnni nípa ọ̀wọ́ àwọn sítáǹpù kan, ní ìgbà díẹ̀ lẹ́yìn náà àwọn èsì púpọ̀ lè wá jákèjádò ayé, tí ó fúnni ní àwọn ìsọfúnni tí yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ fún gbogbo ẹni tó bá sàsanpọ̀ owó fún àwùjọ yìí.
Ìyàtọ̀ kan nínú èyí ni Ìgbékalẹ̀ Pátákó Àfiyèsí (BBS). Àwọn BBS fara jọ Usenet, yàtọ̀ sí pé gbogbo ibi tí a kó ìsọfúnni sí ló wà lórí kọ̀ǹpútà kan ṣoṣo, tí ẹnì kan tàbí àwùjọ kan sábà máa ń bójú tó. Ohun tí àwọn ẹgbẹ́ oníròyìn máa ń jíròrò ń fi onírúurú ọkàn ìfẹ́, ojú ìwòye, àti àwọn ìhùwàsí tí a kà sí pàtàkì nípa àwọn tí ń lò wọ́n hàn, nítorí náà, a nílò ọgbọ́n inú.
Ṣíṣàjọlò Ibi Ìkósọfúnnisí àti Wíwá Kókó Ọ̀rọ̀
Ọ̀kan lára àwọn góńgó tí ìsokọ́ra alátagbà Internet wà fún látètèkọ́ṣe jẹ́ ṣíṣèpínkiri ìsọfúnni kárí ayé. Olùkọ́ tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tí ó ṣáájú bá olùkọ́ mìíràn pàdé lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet tí ó nífẹ̀ẹ́ láti ṣàjọpín ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí àwọn àkójọ ìsọfúnni tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀. Láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan, a ti fi àwọn ibi ìkósọfúnnisí náà ránṣẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi 3,200 kìlómítà jìnnà.
Ìrànlọ́wọ́ wo ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó tí ẹnì kan kò bá mọ ibi tí ó ti lè rí kókó ọ̀rọ̀ kan nínú ìsokọ́ra alátagbà Internet? Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti rí nọ́ńbà tẹlifóònù kan nípa lílo atọ́nà tẹlifóònù, ẹnì kan tí ń lò ó lè rí àwọn ibi tí ó nífẹ̀ẹ́ sí lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet nípa kíkọ́kọ́ rí ọ̀nà dé ibi àkójọ ìsọfúnni tí a mọ̀ sí ibi ìwáǹkan. Ẹni tí ń lò ó náà yóò tẹ ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ kan sínú rẹ̀; ibi àkójọ ìsọfúnni náà yóò wá dáhùn pa dà pẹ̀lú àkọsílẹ̀ àwọn ibi tí ìsokọ́ra alátagbà Internet wà tí a ti lè rí ìsọfúnni. Ní gbogbogbòò, ọ̀fẹ́ ni ìwákiri náà, ó sì ń gba ìṣẹ́jú àáyá bíi mélòó kan péré!
Àgbẹ̀ tí a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ gbọ́ nípa ìlànà iṣẹ́ tuntun kan tí ń jẹ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ ìṣerẹ́gí, tí ń lo kọ̀ǹpútà àti fífi sátẹ́láìtì wo ilẹ̀. Nípa títẹ ọ̀rọ̀ yẹn sí àyíká ìgbékalẹ̀ ìṣèwákiri kan, ó rí orúkọ àwọn àgbẹ̀ tí ń lò ó àti àwọn ìsọfúnni kíkún nípa ìlànà náà.
Ìsokọ́ra Web Kárí Ayé
Ìhà ìsokọ́ra alátagbà Internet tí ń jẹ́ Ìsokọ́ra Web Kárí Ayé (tàbí, ìsokọ́ra Web) ń gba àwọn tí wọ́n ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ láyè láti lo èrò ògbólógbòó kan—lílo àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé—lọ́nà tuntun kan. Nígbà tí ẹnì kan tó ṣàgbékalẹ̀ àpilẹ̀kọ ìwé ìròyìn kan bá fi àmì àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé síbẹ̀, a óò wò kiri ìsàlẹ̀ ojú ìwé náà, ó sì ṣeé ṣe kí ó darí wa sí ojú ìwé mìíràn tàbí ìwé mìíràn. Ní pàtàkì jù lọ, àwọn tí wọ́n ṣàgbékalẹ̀ àwọn ìsọfúnni kọ̀ǹpútà inú ìsokọ́ra alátagbà Internet lè ṣe ohun kan náà ní lílo ìlànà kan tí yóò fa ilà sídìí ọ̀rọ̀ kan, àpólà ọ̀rọ̀ kan, tàbí àwòrán kan nínú àkọsílẹ̀ ìsọfúnni kan tàbí kí ó sàmì sí i.
Ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán tí a sàmì sí náà jẹ́ amọ̀nà fún ẹni tí ń kà á pé orísun ìsọfúnni ìsokọ́ra Internet kan tí ó tan mọ́ ọn, tí ó sábà máa ń jẹ́ àkọsílẹ̀ ìsọfúnni mìíràn, wà níbì kan. A lè ṣàwárí àkọsílẹ̀ ìsọfúnni Internet yí, kí a sì gbé e jáde fún ẹni tí ń kà á náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àkọsílẹ̀ ìsọfúnni náà tilẹ̀ lè wà lórí kọ̀ǹpútà míràn, kí ó sì wà ní orílẹ̀-èdè míràn. David Peal, ẹni tí ó kọ ìwé Access the Internet!, sọ pé, ìlànà yí “so ọ pọ̀ mọ́ àwọn àkọsílẹ̀ ìsọfúnni gidi, kì í ṣe àwọn atọ́ka wọn nìkan.”
Ìsokọ́ra Web tún ń mú kí ìtọ́júpamọ́ àti ìmúpadàbọ̀-sípò tàbí ìgbésáfẹ́fẹ́ àwọn fọ́tò, àwòrán, sinimá apanilẹ́rìn-ín, fídíò, àti ìró ohùn ṣeé ṣe. Loma, ìyàwó ilé tí a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ tí ó ṣáájú, gba sinimá aláwòrán mèremère kúkúrú kan nípa àwọn àbá èrò orí lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa àgbáálá ayé, ó sì gbé e sáfẹ́fẹ́. Ó gbọ́ ọ̀rọ̀ àlàyé rẹ̀ nínú ìgbékalẹ̀ gbohùngbohùn inú ìgbékalẹ̀ kọ̀ǹpútà rẹ̀.
Wíwòkiri Inú Ìgbékalẹ̀ Net
Nípa lílo ìgbékalẹ̀ ìwòkiri inú ìsokọ́ra Web kan, ẹnì kan lè fìrọrùn wo àwọn ìsọfúnni àti àwòrán aláwọ̀ mèremère tí a lè kó sínú àwọn kọ̀ǹpútà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, kí ó sì ṣe é kíákíá. Lílo ìgbékalẹ̀ ìwòkiri inú ìsokọ́ra Web lè jọra pẹ̀lú rírìnrìn àjò ní gidi ní àwọn ọ̀nà kan, kìkì pé ó túbọ̀ rọrùn. Ẹnì kan lè ṣèbẹ̀wò sí ibi ìpàtẹ Ìwé Kíká Òkun Òkú tàbí Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí fún Ìrántí Ìpakúpa lórí ìsokọ́ra Web. Agbára yìí láti máa lọ fìrìfìrì síwá-sẹ́yìn láti ibi Ìsọkọ́ra Web ti Ìsokọ́ra Alátagbà Internet kan sí òmíràn ni a sábà máa ń pè ní wíwòkiri inú ìgbékalẹ̀ Net.
Àwọn ètò òwò àti àwọn àjọ mìíràn ti wá nífẹ̀ẹ́ sí ìsokọ́ra Web náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìpolówó ọjà tàbí iṣẹ́ wọn àti ọ̀nà ìpèsè irú àwọn ìsọfúnni mìíràn. Wọ́n ń ṣẹ̀dá ojú ìwé ìsokọ́ra Web kan, irú ibi ìkósọfúnni orí kọ̀ǹpútà sí kan. Lẹ́yìn mímọ ojú ìwé tí àdírẹ́sì àjọ kan wà lórí ìsokọ́ra Web, àwọn tí wọ́n fẹ́ di oníbàárà lè lo ìgbékalẹ̀ ìwòkiri kan láti lọ “rajà,” tàbí láti wò kiri fún ìsọfúnni. Síbẹ̀síbẹ̀, bí ó ti máa ń rí ní ọjà èyíkéyìí, kì í ṣe gbogbo ọjà, iṣẹ́, tàbí ìsọfúnni tí a pèsè lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet ló gbámúṣé.
Àwọn olùṣèwádìí ń gbìyànjú láti mú kí ìsokọ́ra alátagbà Internet ní ààbò tó láti pa àṣírí mọ́, kí ó sì dáàbò bo káràkátà. (A óò túbọ̀ sọ nípa ààbò tó bá yá.) Ìsokọ́ra alátagbà Internet míràn kárí ayé—tí a pè ní ìsokọ́ra alátagbà Internet Kejì—ni a ṣe nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń lò ó, tí a fi ṣẹ̀dá ìgbòkègbodò ìṣòwò yí.
Kí Ni “Chat”?
Iṣẹ́ ìpèsè wíwọ́pọ̀ míràn tí ìsokọ́ra alátagbà Internet ń ṣe ni Internet Relay Chat (Ìtàtagbà Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Lórí Ìsokọ́ra Alátagbà Internet), tàbí Chat (Ìfọ̀rọ̀wérọ̀). Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ń jẹ́ kí ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn ènìyàn kan, tí ń lo orúkọ ìnagijẹ, lè fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí ara wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsọ̀wọ́ onírúurú ènìyàn ní ń lò ó, ní pàtàkì, ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́. Gbàrà tí ẹni tí ń lò ó bá ti wà lára wọn, a ti mú un mọ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn mìíràn tí ń lò ó káàkiri ayé.
A ṣẹ̀dá àwọn ibi tí a pè ní iyàrá ìfọ̀rọ̀wérọ̀, tàbí ìkànnì ìfọ̀rọ̀wérọ̀, tí ń gbé kókó ọ̀rọ̀ pàtó kan jáde, bí àròsọ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, àwọn sinimá, eré ìdíje, tàbí ọ̀ràn ìfẹ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ẹ̀ẹ̀kan náà ni gbogbo àwọn ìsọfúnni tí a tẹ̀ nínú iyàrá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan ń yọ lójú kọ̀ǹpútà gbogbo àwọn olùkópa tí ń lo iyàrá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn.
Iyàrá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan dà bí ibì kan tí àwọn ènìyàn kan kóra jọ sí, tí wọ́n jùmọ̀ ń kẹ́gbẹ́ pọ̀, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ní àkókò kan náà, àyàfi ti pé gbogbo wọn ń tẹ àwọn ìsọfúnni kéékèèké. Àwọn iyàrá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ sábà máa ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí 24 lóòjọ́. Dájúdájú, àwọn Kristẹni mọ̀ pé àwọn ìlànà Bíbélì nípa ìbákẹ́gbẹ́, irú èyí tí a rí nínú Kọ́ríńtì Kíní 15:33, kan kíkópa nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn àwùjọ kan bí wọ́n ṣe kan gbogbo apá ìgbésí ayé.a
Ta Ló Ń Sanwó Ìsokọ́ra Alátagbà Internet?
O lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ló ń san owó tí a dá léni fún ọ̀nà jíjìn tí ẹnì kan lè dé lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet?’ Àwọn tí ń lò ó, àwọn àjọ àti ẹnì kọ̀ọ̀kan, ní ń pín owó náà san. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò pọn dandan pé kí a fún ẹni tí ń lò ó ní ìwé owó tẹlifóònù fún pípe ọ̀nà jíjìn, kódà bí ó bá ṣàyẹ̀wò ọ̀pọ̀ ibi-ìkósọfúnni-sí ti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ń lò ó ní àkáǹtì lọ́dọ̀ ẹnì kan tí ń ṣòwò ìpèsè iṣẹ́ ìsokọ́ra alátagbà Internet ládùúgbò, nínú ọ̀ràn púpọ̀, ẹni náà máa ń ṣàkọsílẹ̀ iye owó pàtó kan tí ẹni tí ń lò ó yóò máa san lóṣooṣù. Ní gbogbogbòò, àwọn tí ń ṣe ìpèsè náà máa ń fúnni ní nọ́ńbà kan tí ó jẹ́ ti àdúgbò láti yẹra fún èlé owó tẹlifóònù. Àfiṣàpẹẹrẹ owó lílò ó tí a ń béèrè lóṣooṣù jẹ́ nǹkan bí 20 dọ́là (ti U.S.).
Bí ẹ ti lè rí i, ohun tí ìsokọ́ra alátagbà Internet lè ṣe kàmàmà. Ṣùgbọ́n ó ha yẹ kí o bọ́ sojú ọ̀nà mároṣẹ̀ ìfisọfúnni-ránṣẹ́ yìí bí?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó bá yá, a óò jíròrò àìní fún lílo ìṣọ́ra nípa àwọn iyàrá ìfọ̀rọ̀wérọ̀.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Àdírẹ́sì Ìsokọ́ra Alátagbà Internet—Kí Ni Wọ́n Jẹ́?
Àdírẹ́sì ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà ló ń jẹ́ kí a lè mọ àwọn ènìyàn tí a so mọ́ ìsokọ́ra alátagbà Internet. Finú wòye pé o fẹ́ láti fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà sí ọ̀rẹ́ kan tí àdírẹ́sì ìgbàsọfúnni rẹ̀ lórí kọ̀ǹpútà jẹ́ drg@tekwriting.com.b Nínú àpẹẹrẹ yìí, ìdánimọ̀ ẹni náà, tàbí àmì tí ó fi ń dénú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra náà, ni “drg.” Àwọn ènìyàn sábà máa ń lo lẹ́tà ìbẹ̀rẹ̀ orúkọ wọn tàbí orúkọ wọn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí àmì wíwọnú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra náà. Ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé àmì “@” lè jẹ́ agbanisíṣẹ́ wọn, ibi iṣẹ́ wọn, tàbí ẹni tí ń pèsè ìtàtagbà ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà wọn. Nínú àpẹẹrẹ yìí, “tekwriting” fi irú ẹni tí ń pèsè ìtàtagbà náà hàn. Apá tí ó kẹ́yìn nínú àdírẹ́sì náà ń fi irú àjọ tí ọ̀rẹ́ rẹ ń lò láti wọnú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra hàn. Nínú àpẹẹrẹ yìí, “com” tọ́ka sí àjọ olówò kan. Àwọn àjọ elétò ẹ̀kọ́ ní irú ọ̀nà ìkọrúkọ bẹ́ẹ̀ àmọ́ tiwọn máa ń parí pẹ̀lú “edu,” ti àwọn àjọ tí kì í ṣe fún ìṣòwò sì parí pẹ̀lú “org.” Ìlànà míràn fún fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà parí pẹ̀lú àmì orúkọ orílẹ̀-èdè ẹni náà. Fún àpẹẹrẹ, àdírẹ́sì náà, lvg@spicyfoods.ar, fi hàn pé ilé iṣẹ́ kan tí a pè ní “spicyfoods” ní Ajẹntínà ni ẹni náà tí orúkọ wíwọnú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra rẹ̀ ń jẹ́ “lvg” ń bá ṣiṣẹ́.
Irú àdírẹ́sì míràn máa ń ṣàwárí àwọn àkọsílẹ̀ ìsọfúnni ìsokọ́ra Web lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet. Ká ní a lè rí ìsọfúnni lórí ìṣèwádìí nípa igbó kìjikìji nínú àkọsílẹ̀ ìsọfúnni ìsokọ́ra Web tí ó wà ní http://www.ecosystems.com/research/forests/rf. Àwọn lẹ́tà náà, “http” (Hypertext Transfer Protocol [Ìgbésẹ̀ Fífi Àkọsílẹ̀ Púpọ̀ Ránṣẹ́]) tọ́ka sí ọ̀nà tí a ń gbà lo irú àkọsílẹ̀ ìsọfúnni orí ìsokọ́ra Web, tí “www.ecosystems.com” sí tọ́ka sí orúkọ orísun ìsọfúnni ìsokọ́ra Web náà, kọ̀ǹpútà kan—nínú àpẹẹrẹ yìí, a tọ́ka sí ilé iṣẹ́ olówò kan bí “ecosystems.” Àkọsílẹ̀ ìsọfúnni ìsokọ́ra Web náà ní gidi ni apá tí ó kẹ́yìn àdírẹ́sì náà—“/research/forests/rf.” Àwọn àdírẹ́sì ìsokọ́ra Web ni a sábà máa ń pè ní Uniform Resource Locators (Aṣàwárí Orísun Ìsọfúnni Bíbáramu), tàbí ní kúkúrú, àwọn URL.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b Àwọn àdírẹ́sì ìsokọ́ra alátagbà Internet tí a tọ́ka sí jẹ́ àfinúrò.