Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Ewu Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
FOJÚ inú wò ó pé o bá ara rẹ níbi ìkówèésí tó tóbi jù lọ láyé. Nígbà tóo wò yíká, o rí i pé oríṣiríṣi ìwé, àtìwé ìròyìn, àtìwé ọjà títà, àti fọ́tò ló kún ibẹ̀ rẹpẹtẹ, ṣàṣà sì ni àwo orin tí ò sí níbẹ̀—àní kò sóhun téèyàn ń wá láyé yìí tí ò sí níbẹ̀. Gbogbo ìsọfúnni tuntun àti ọ̀pọ̀ jáǹrẹrẹ ìwé àtayébáyé rèé lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ.
Ká pa teré tì, Íńtánẹ́ẹ̀tì lè mú kí gbogbo irú ìsọfúnni wọ̀nyẹn wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ. Béèyàn bá jókòó ti kọ̀ǹpútà rẹ̀, Íńtánẹ́ẹ̀tì á jẹ́ kónítọ̀hún lè tàtagbà ìsọfúnni lórí kọ̀ǹpútà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì tó ń lo kọ̀ǹpútà níbikíbi lágbàáyé.a Ó ń jẹ́ káwọn tó ń lò ó lè ṣe kárà-kátà, kí wọ́n lè dúnàádúrà pẹ̀lú báńkì, kí wọ́n lè tàkúrọ̀sọ, kí wọ́n lè gbọ́ orin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dóde—inú kọ̀rọ̀ yàrá wọn ni wọ́n wà tí wọ́n sì ti ń gbádùn gbogbo eléyìí o.
Abájọ, táwọn ògbógi kan fi sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn táá máa lo Íńtánẹ́ẹ̀tì nígbà tọ́dún yìí bá fi máa parí á ti lé ní okòó lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún [320] mílíọ̀nù èèyàn. Òótọ́ ni, Íńtánẹ́ẹ̀tì ti ń di kárí ilé níbi púpọ̀ lágbàáyé. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọ̀dọ́ ló ń rí i lò nítorí pé àwọn iléèwé àtàwọn ibi ìkówèésí ń fi taratara ṣonígbọ̀wọ́ fún lílò ó. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín márùndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ọdún méjìlá sí mọ́kàndínlógún tó ti lo Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí tó tilẹ̀ ti forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀.
Béèyàn bá lo Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́nà rere, ó lè pèsè ìsọfúnni tí ń ranni lọ́wọ́ nípa ojú ọjọ́, nípa ìrìn àjò, àtàwọn nǹkan míì. O lè tipasẹ̀ rẹ̀ ra àwọn ìwé rẹ, àti àwọn ẹ̀yà ara ọkọ rẹ, àtàwọn nǹkan míì. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń lò ó láti fi ṣe iṣẹ́ iléèwé.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Íńtánẹ́ẹ̀tì wúlò, a tún lè fi í wé ibi ìkówèésí tí kò ní alábòójútó tàbí táwọn èèyàn kì í yà sí. Èèyàn lè máa ronú pé kò sẹ́lòmíì nítòsí bó ti ń tibì kan dé ibòmíràn nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n, èyí jẹ́ ọ̀kan lára ewu tó ga jù lọ nínú ọ̀ràn lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Èé ṣe? Nítorí pé àìmọye ibi tí a ń kó ìsọfúnni sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì làwọn èèyàn ti kó ìsọfúnni pálapàla sí tó lè pani run nípa tẹ̀mí. Nítorí náà, Íńtánẹ́ẹ̀tì lè fa àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ sínú ìdẹwò. Ó ṣe tán, kò séèyàn tí kì í fẹ́ ṣe ojú-mìí-tó, ó sì ti pẹ́ ti Sátánì Èṣù ti ń fi ìfẹ́ yìí kó aráyé sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Ṣíṣe tí Éfà ṣe ojú-mìí-tó ló jẹ́ kí Sátánì rí i mú, ó sì “sún Éfà dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀.”—2 Kọ́ríńtì 11:3.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó rọrùn kí ìsọfúnni tí kò dáa sún ọ̀dọ́ Kristẹni dẹ́ṣẹ̀ bí kò bá múra gírí láti dáàbò bo ipò tẹ̀mí rẹ̀. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé náà, Better Homes and Gardens, ṣàlàyé pé: “Íńtánẹ́ẹ̀tì ni ọjà táráyé ń ná báyìí o, ibẹ̀ sì làwọn àgbà amòye ti ń polówó ìsọfúnni tuntun; àmọ́ àwọn tí ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe, àwọn gbájú-ẹ̀, àwọn kìígbọ́kìígbà, àtàwọn kàràǹbàní ẹ̀dá míì ti bẹ̀rẹ̀ sí lò ó pẹ̀lú.”
Ọ̀dọ́ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Javierb sọ pé: “Àwọn ibì kan wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó jẹ́ pé ìsọfúnni tó wà nínú wọn ò ṣeé gbọ́ sétí. Wọ́n sì lè ṣí sílẹ̀ láìjẹ́ pé a ṣí wọn.” Ó tún sọ pé: “Ṣe ni wọ́n ń dẹ páńpẹ́ fáwọn èèyàn. Wọ́n fẹ́ tàn wọ́n gba owó ọwọ́ wọn ni.” Kristẹni ọ̀dọ́ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John jẹ́wọ́ pé: “Tóo bá ti bẹ̀rẹ̀ sí wòwòkuwò, àtijáwọ́ máa ń nira—kì í pẹ́ di bára kú.” Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ kan ti lọ ń yọjú wòwòkuwò nínú Íńtánẹ́ẹ̀tì, èyí sì ti kó wọn sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Àwọn kan tiẹ̀ ti ba ìbátan wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Báwo la ṣe lè yẹra fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀?
‘Wíwo Ìwòkuwò’
Nígbà míì, orúkọ tẹ́nì kan pe ibi tó ń kó ìsọfúnni sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń fi hàn kedere pé nǹkan-kí-nǹkan lèèyàn máa bá níbẹ̀.c Ìwé Òwe 22:3 sì kìlọ̀ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”
Àmọ́, ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé ńṣe làwọn èèyàn máa ń ṣàdédé kan irú ibi tí wọ́n kó ìkókúkòó sí bẹ́ẹ̀ kuu. Ojú ìwé àkọ́kàn lè kún fún àwòrán mèremère tó jẹ́ àrímáleèlọ, wọ́n sì fẹ́ kó jẹ́ pé, ẹ̀ẹ̀kan tóo bá wò ó báyìí, o ò ní lè gbójú kúrò—tó bá sì yá, àwòtúnwò ni wàá lọ máa wò ó!d
Kevin sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan, ó ní: “Ọwọ́ rẹ̀ ti dilẹ̀ jù, ó sì máa ń fẹ́ ṣe ojú-mìí-tó. Kò pẹ́ tó fi jẹ́ pé wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ló lọ ń wo àwọn àwòrán tó ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè.” Ọpẹ́lọpẹ́ pé Kristẹni ọ̀dọ́ yìí lọ bá alàgbà kan, alàgbà yìí ló ràn án lọ́wọ́.
Ǹjẹ́ o mọ nǹkan tí wàá ṣe dájú, bóo bá ṣèèṣì kan irú ibi ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ kuu? Ohun tó yẹ kí Kristẹni kan ṣe ò láṣìmọ̀: Ńṣe ló yẹ kó fi ibẹ̀ sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀—tàbí kó tilẹ̀ pa wíwonú Íńtánẹ́ẹ̀tì náà tì! Fìwà jọ onísáàmù náà, tó sọ pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.” (Sáàmù 119:37; fi wé Jóòbù 31:1.) Má gbàgbé pé béèyàn ò tiẹ̀ rí nǹkan táà ń ṣe, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò sẹ́ni tó ń wò wá. Bíbélì rán wa létí pé ohun gbogbo ló wà “ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.”—Hébérù 4:13.
Bíbá àwọn òbí rẹ tàbí àwọn Kristẹni míì tó dàgbà dénú sọ̀rọ̀ lè fún ẹ lókun láti pinnu pé o ò ní padà lọ sírú àwọn ibi ìsọfúnni burúkú bẹ́ẹ̀ mọ́. Tiẹ̀ gbọ́ ná, ká sọ pé o ṣubú sínú pọ̀tọ̀pọ́tọ̀, ṣé wàá máa jàgùdù nínú rẹ̀ títí yóò fi mù ẹ́ dé ọrùn, kóo tó figbe ta pé káwọn èèyàn ó gbà ẹ́?
Àwọn Ọ̀rẹ́ Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì Ńkọ́?
Ètò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì nígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé láti fèrò wérò lákòókò kan náà. Àwọn iléeṣẹ́ okòwò máa ń fi ètò yìí ṣe àpérò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wọ́n sì máa ń fi mọ èrò àwọn oníbàárà wọn. Àwọn ibùdó ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan ń jẹ́ káwọn èèyàn lè fi ìsọfúnni nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ ṣọwọ́ sáwọn ẹlòmíì, àwọn ìsọfúnni nípa báa ṣe lè tún ẹ̀rọ ṣe tàbí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa kọ̀ǹpútà. Àwọn ètò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan máa ń jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ẹbí lè fi ìsọfúnni ránṣẹ́ síra ní ìdákọ́ńkọ́, láìjẹ gbèsè rẹpẹtẹ owó tẹlifóònù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì wúlò láyè ara ẹ̀, ǹjẹ́ ewu ń bẹ níbẹ̀?
Lílo ètò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ń béèrè ìṣọ́ra gidigidi, nítorí pé àwọn ewu kan ń bẹ nídìí lílò ó. Òǹkọ̀wé náà, Leah Rozen, sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́langba tó mọ̀ nípa kọ̀ǹpútà ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí ní ibùdó ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wọ́n ń fèrò wérò pẹ̀lú àwọn àjèjì tí wọn ò morúkọ wọn, láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin orílẹ̀-èdè yìí, kódà láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé. Ó mà ṣe o, pé àwọn àgbààyà tó ń wá àwọn ọmọ tí wọ́n máa bá ṣèṣekúṣe làwọn kan lára àwọn àjèjì táwọn ọ̀dọ́langba ń bá sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.” Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé Popular Mechanics, kìlọ̀ pé “o gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gidigidi” nígbà tóo bá ń lo àwọn ibùdó ìfọ̀rọ̀wérọ̀ gbogbo gbòò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kíkọ orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ fún àjèjì lè jẹ́ ọ̀nà àtifa wàhálà ńlá síra ẹni lọ́rùn! Kí ló dé tóo fẹ́ fọwọ́ ara ẹ ṣera ẹ?
Ṣùgbọ́n o, ewu ńlá míì tó fara sin ni kíkó wọnú àjọṣe tí kò tọ́ pẹ̀lú àwọn àjèjì tí kò náání àwọn ìlànà Bíbélì.e Àwọn olùwádìí sọ pé ọ̀ràn ìbálòpọ̀ ló pọ̀ jù lára nǹkan táwọn ọ̀dọ́langba ń sọ ní ibùdó ìfọ̀rọ̀wérọ̀. Fún ìdí yìí, ìmọ̀ràn Bíbélì nínú 1 Kọ́ríńtì 15:33 bá a mu wẹ́kú, ó wí pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” Kíkó ẹgbẹ́ búburú lórí kọ̀ǹpútà léwu gan-an. Ǹjẹ́ ó yẹ kí ọ̀dọ́ tó níbẹ̀rù Ọlọ́run dẹra nù lójú irú ewu bẹ́ẹ̀?
Ojú Lalákàn Fi Ń Ṣọ́rí O
Nítorí àwọn ewu tó wà nínú lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì, èèyàn ní láti ṣọ́ra gan-an. Fún àpẹẹrẹ, ojútáyé làwọn ìdílé kan gbé kọ̀ǹpútà wọn sí, ó tilẹ̀ lè jẹ́ ní pálọ̀. Wọ́n sì lè ṣòfin pé ìgbà táwọn ẹlòmíì bá wà nílé nìkan làwọn ó máa lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Báwọn òbí rẹ bá ṣe irú òfin bẹ́ẹ̀, á dáa kóo máa tẹ̀ lé e. (Òwe 1:8) Àwọn ìtọ́ni tó ṣe tààrà jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ.
Bí iṣẹ́ iléèwé bá béèrè pé kí o lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, o ò ṣe máa ṣọ́ iye àkókò tóò ń lò lórí rẹ̀? Kọ́kọ́ gbìyànjú láti pinnu iye àkókò tóo fẹ́ lò, o lè gbé aago kan tira, tó máa dún nígbà tí àkókò náà bá pé. Tom dá a lábàá pé: “Wéwèé rẹ̀ ṣáájú, mọ ohun tóo ń wá lọ gan-an, má sì yà síhìn-ín sọ́hùn-ún—bó ti wù káwọn nǹkan míì máa ṣẹ́jú sí ẹ tó.”
Ó tún yẹ kéèyàn ṣọ́ra nídìí ọ̀ràn lẹ́tà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún jíjẹ́ kí kíka ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ lẹ́tà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì mọ́ wọn lára, àgàgà bí ohun tó wà nínú lẹ́tà wọnnì kò bá gbéni ró, tí kò sì lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Jíjókòó ti àwọn lẹ́tà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń jẹ àkókò gidi gan-an, àkókò téèyàn ì bá lò fún iṣẹ́ iléèwé àtàwọn nǹkan tẹ̀mí.
Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Nínú ṣíṣe ìwé púpọ̀, òpin kò sí, fífi ara ẹni fún wọn lápọ̀jù sì ń mú ẹran ara ṣàárẹ̀.” (Oníwàásù 12:12) Ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kan Íńtánẹ́ẹ̀tì o. Máà jẹ́ kí wíwádìí òkodoro àti wíwá fìn-ín ìdí kókò gbà ẹ́ lọ́kàn débi pé o ò ní ráyè ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni mọ́. (Mátíù 24:14; Jòhánù 17:3; Éfésù 5:15, 16) Pẹ̀lúpẹ̀lù, rántí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé títa àtaré ìsọfúnni nípasẹ̀ kọ̀ǹpútà wúlò láyè ara ẹ̀, kò lè rọ́pò wíwà pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa lójúkojú. Nítorí náà, tó bá pọndandan pé kí o lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, ṣọ́ ọ lò o. Má ṣí àwọn ibi tó léwu wò nínú ẹ̀, má sì pẹ́ jù lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. “Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ,” má sì sọ ara rẹ di ẹrú Íńtánẹ́ẹ̀tì.—Òwe 4:23.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Ìsokọ́ra Alátagbà Internet—Ó Ha Wà fún Ọ Bí?” tó jáde nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti July 22, 1997.
b A ti yí orúkọ àwọn kan padà.
c Orúkọ wọ̀nyí lè jẹ́ àwọn lẹ́tà tẹ́nì kan ṣà jọ, tó fi ń dé ibi tó ń kó ìsọfúnni sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Nígbà míì, àwọn ọ̀rọ̀ tó para pọ̀ jẹ́ orúkọ wọ̀nyí lè sọ nǹkan kan nípa ohun tí ìsọfúnni tó kó jọ dá lé lórí.
d Ohun tí wọ́n ń pè ní ojú ìwé àkọ́kàn nínú Íńtánẹ́ẹ̀tì ni a lè fi wé fèrèsé tó kọjú sí títì. A lè tètè tibẹ̀ rí ìsọfúnni nípa ohun téèyàn lè bá nínú ibùdó yẹn, àti ẹni tó ni ibẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
e Irú ewu bẹ́ẹ̀ lè wà nínú ibùdó ìfọ̀rọ̀wérọ̀ gbogbo gbòò táwọn Kristẹni kan tí kò ní èrò búburú lọ́kàn dá sílẹ̀ fún jíjíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí. Nígbà míì, àwọn aláìṣòótọ́ àtàwọn apẹ̀yìndà ti lọ́wọ́ sírú ìjíròrò bẹ́ẹ̀, wọ́n sì ti dọ́gbọ́n gbìyànjú láti mú kí àwọn yòókù tẹ́wọ́ gba èrò wọn tó tako Ìwé Mímọ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]
“Awọn ibì kan wà nínú Íńtánẹ́ẹ̀tì tó jẹ́ pé ìsọfúnni tó wà nínú wọn ò ṣeé gbọ́ sétí. Wọ́n sì lè ṣí sílẹ̀ láìjẹ́ pé a ṣí wọn”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ojútáyé làwọn ìdílé kan gbé kọ̀ǹpútà wọn sí