Ìsokọ́ra Alátagbà Internet—Èé Ṣe Tí O Ní Láti Ṣọ́ra?
Ó DÁJÚ pé ìsokọ́ra alátagbà Internet lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, kí ó sì ran ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ojoojúmọ́ lọ́wọ́. Síbẹ̀, yàtọ̀ sí ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga rẹ̀ tí ó jọ pé ó fani mọ́ra, ìsokọ́ra alátagbà Internet ní díẹ̀ lára irú àwọn ìṣòro kan náà tí tẹlifíṣọ̀n, tẹlifóònù, ìwé agbéròyìnjáde, àti àwọn ibi ìkówèésí ti ní láti ìgbà pípẹ́ wá. Nípa bẹ́ẹ̀, ìbéèrè kan tí ó yẹ láti béèrè lè jẹ́, Àwọn àkójọ ìsọfúnni tí ìsokọ́ra alátagbà Internet ní nínú ha dára fún èmi àti ìdílé mi bí?
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìròyìn ti sọ nípa àwọn àkójọ ìsọfúnni arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè tí ó wà lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èyí ha fi hàn pé ìsokọ́ra alátagbà Internet jẹ́ kòtò ẹ̀gbin tí ó kún fún àwọn atàpásílànà oníwà-pálapàla lásán kan bí? Àwọn kan jiyàn pé, àsọdùn bíburú lékenkà gbáà ni èyí jẹ́. Wọ́n jiyàn pé, ẹnì kan gbọ́dọ̀ lo ìsapá tí ó gbàrònú tí ó sì jẹ́ àmọ̀ọ́mọ̀ṣe láti lè rí àwọn àkójọ ìsọfúnni tí a kò nífẹ̀ẹ́ sí.
Òtítọ́ ni pé, ẹnì kan gbọ́dọ̀ lo ìsapá àmọ̀ọ́mọ̀ṣe láti wá àwọn àkójọ ìsọfúnni tí kò bójú mu rí, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn jiyàn pé, a lè fìrọ̀rùn gan-an rí i lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet ju ibikíbi mìíràn lọ. Ní títẹ bọ́tìnì bí i mélòó kan, ẹnì kan tí ń lò ó lè ṣàwárí àwọn àkójọ ìsọfúnni arùfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè, bí àwọn fọ́tò ìbálòpọ̀ bíburú lékenkà tí ó ní àwọn àsomọ́ ohùn àti ègé fídíò.
Ọ̀ran ti bí ohun arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè tí ó wà lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet ti pọ̀ tó jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ tí àríyànjiyàn gbígbóná ń lọ lórí rẹ̀ ní lọ́wọ́lọ́wọ́. Àwọn kan lérò pé a lè sọ àsọdùn nípa àwọn ìròyìn tí ń fi ìṣòro gbígbalẹ̀kan hàn. Síbẹ̀, bí o bá gbọ́ pé ìwọ̀nba ejò bíi mélòó kan, àmọ́ tí kò tó 100, wa lẹ́yìnkùlé rẹ, ìyẹn yóò ha dín àníyàn rẹ nípa ààbò ìdílé rẹ kù bí? Yóò jẹ́ ìwà ọlọgbọ́n kí àwọn tí ń lo ìsokọ́ra alátagbà Internet ṣọ́ra.
Ṣọ́ra fún Àwọn Tí Ń Kó Àwọn Ọmọdé Nífà!
Ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tí a kó jọ ti fi hàn pé, àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọdé nínú ìjíròrò aláwàdà lórí ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra. Ní dídíbọ́n bí ọmọdé, àwọn àgbàlagbà wọ̀nyí ti fọgbọ́n àrékérekè mú orúkọ àti àdírẹ́sì lọ́dọ́ àwọn ọmọdé tí kò fura.
Ibùdó Àbójútó Ọ̀ràn Àwọn Ọmọ Tí Ó Sọnù àti Àwọn Tí A Kó Nífà ní Orílẹ̀-Èdè (NCMEC) ti ṣàkọsílẹ̀ díẹ̀ lára ìgbòkègbodò yí. Fún àpẹẹrẹ, ní 1996, àwọn ọlọ́pàá wá àwọn ọmọdébìnrin méjì láti South Carolina, U.S.A., tí ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún 13, tí èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún 15, tí wọ́n ti di àwátì fún ọ̀sẹ̀ kan rí. Wọ́n bá ọmọkùnrin ọlọ́dún 18 kan tí wọ́n bá pàdé lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet lọ sí ìpínlẹ̀ míràn. A fẹ̀sùn ìfẹ̀tàn fa ọmọdékùnrin ọlọ́dún 14 kan wọnú ìbálòpọ̀ aláìbófinmu, nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ kò sí nílé, kan ọkùnrin ọlọ́dún 35 kan. Àwọn ọ̀ràn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìjíròrò nínú iyàrá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet. Ní 1995, àgbàlagbà míràn bá ọmọkùnrin ọlọ́dún 15 kan pàdé lórí ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra, ó sì gbójúgbóyà lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ọmọkùnrin náà láti lọ pàdé rẹ̀. Àgbàlagbà míràn jẹ́wọ́ pé òun bá ọmọdébìnrin ọlọ́dún 14 kan lò pọ̀. Ọmọbìnrin náà lo kọ̀ǹpútà bàbá rẹ̀ láti bá àwọn ọ̀dọ́langba sọ̀rọ̀ gba orí àwọn pátákó àfiyèsí orí ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra. Òun pẹ̀lú bá àgbàlagbà yí pàdé lórí ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra. Wọ́n ti tan gbogbo àwọn èwe wọ̀nyí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti sọ orúkọ wọn.
Àìní fún Ìtọ́sọ́nà Àwọn Òbí
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀ràn bí èyí tí ó wà lókè yí kì í ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo, síbẹ̀síbẹ̀, àwọn òbí gbọ́dọ̀ gbé ọ̀ràn yí yẹ̀ wò tìṣọ́ratìṣọ́ra. Àwọn ohun èlò wo ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn òbí láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ dídi ẹni tí a fi ìwà ọ̀daràn ṣe léṣe, tí a sì fi ṣèfà jẹ?
Àwọn ilé iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí í pèsè àwọn ohun èlò tí ó lọ láti orí ìgbékalẹ̀ ìdíwọ̀n tí ó bá irú àwọn tí a ń lò fún sinimá dọ́gba, dé orí àwọn ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà atúrọ̀fó tí ń dínà àwọn ohun tí a kò nífẹ̀ẹ́, dé orí ìgbékalẹ̀ tí ń gbé ọjọ́ orí yẹ̀ wò. Àwọn kan lára àwọn ìgbékalẹ̀ wọ̀nyí máa ń dínà ìsọfúnni kí ó tó dé inú kọ̀ǹpútà ìdílé pàápàá. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìgbékalẹ̀ wọ̀nyí ṣì lábùkù, a sì lè lo oríṣiríṣi ọgbọ́n láti dọwọ́ wọn délẹ̀. Rántí pé ẹ̀yà ìsokọ́ra alátagbà Internet tí a ṣe látètèkọ́ṣe jẹ́ láti mú kí ó dènà àwọn ìdíwọ́ ìṣiṣẹ́ rẹ̀, nítorí náà ṣíṣàyẹ̀wò rẹ̀ ṣòro.
Nínú ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò kan pẹ̀lú Jí!, sájẹ́ǹtì ọlọ́pàá kan tí ń bójú tó àwùjọ kan tí ń ṣèwádìí kíkó ọmọdé nífà ní California fúnni ní ìmọ̀ràn yí pé: “Kò sí àfirọ́pò fún ìtọ́sọ́nà òbí. Èmi alára ní ọmọ ọlọ́dún 12 kan. Èmi àti ìyàwó mi ń jẹ́ kí ó lo ìsokọ́ra alátagbà Internet, àmọ́ a máa ń ṣe é pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, a sì máa ń fìṣọ́ra pa ìwọ̀n àkókò tí a ń lò mọ́.” Bàbá yìí ń lo ìṣọ́ra ní pàtàkì nípa àwọn iyàrá ìfọ̀rọ̀wérọ̀, ó sì gbé ìkálọ́wọ́kò dan-indan-in lórí lílò wọ́n. Ó fi kún un pé: “Kọ̀ǹpútà àdáni náà kò sí nínú iyàrá ọmọkùnrin mi àmọ́ ó wà ní ibi tí gbogbo wa ti ń rí i nínú ilé.”
Àwọn òbí ní láti lọ́kàn ìfẹ́ gidigidi nínú pípinnu ohun tí wọn óò gba àwọn ọmọ wọn láyè láti máa lò nínú ìsokọ́ra alátagbà Internet bí wọn óò bá gbà wọ́n láyè láti lo èyíkéyìí. Àwọn ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ tí ó gbéṣẹ́, tí ó sì bọ́gbọ́n mu wo ni a gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò?
Òṣìṣẹ́ òǹkọ̀wé nínú ìwé agbéròyìnjáde San Jose Mercury News náà, David Plotnikoff, fún àwọn òbí tí wọ́n pinnu láti máa lo ìsokọ́ra alátagbà Internet nílé ní àwọn ìmọ̀ràn wíwúlò díẹ̀.
• Ìrírí àwọn ọmọ rẹ yóò dára jù lọ bí wọ́n bá mọrírì èrò rẹ àti ìtọ́sọ́nà rẹ nígbà tí ẹ bá jùmọ̀ ń lò ó. Ó kìlọ̀ pé, láìsí ìdarísọ́nà rẹ, “gbogbo ìsọfúnni tí ó wà lórí ìgbékalẹ̀ Net wulẹ̀ dà bí omi tí kò sí nínú ife ni.” Àwọn ìlànà tí o rinkinkin mọ́ jẹ́ “àfikún ohun bíbọ́gbọ́nmu tí o ti ń fi kọ́ ọmọ rẹ tẹ́lẹ̀.” Àpẹẹrẹ kan yóò jẹ́ àwọn ìlànà nípa bíbá àwọn àjèjì sọ̀rọ̀.
• Ìsokọ́ra alátagbà Internet jẹ́ ibi tí gbogbogbòò ń lò, a kò sì gbọ́dọ̀ lò ó bí iṣẹ́ ìbánigbọ́mọ. “Ó ṣe tán, o kò wulẹ̀ ní gbé ọmọ rẹ ọlọ́dún 10 sọ sáàárín ìlú ńlá kan, kí o sì wí fún un pé kí ó jayé orí rẹ̀ fún wákàtí díẹ̀, àbí ìwọ yóò ṣe bẹ́ẹ̀?”
• Kọ́ láti mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ibi tí àwọn eré àṣedárayá orí ìsokọ́ra alátagbà Internet wà tàbí ibi tí a ti ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ àti àwọn ibi tí a ti lè rí ìrànlọ́wọ́ fún iṣẹ́ àṣetiléwá.
Ìwé ìléwọ́ kékeré tí ibùdó NCMEC ṣe náà, Child Safety on the Information Highway, pèsè àwọn ìlànà bíi mélòó kan fún àwọn ọ̀dọ́ pé:
• Má ṣe sọ àwọn ìsọfúnni nípa ara rẹ bí àdírẹ́sì rẹ, nọ́ńbà tẹlifóònù ilé rẹ, tàbí orúkọ àti ibi tí ilé ẹ̀kọ́ rẹ wà. Má ṣe fi fọ́tò ránṣẹ́ láìjẹ́ pé àwọn òbí rẹ fọwọ́ sí i.
• Wí fún àwọn òbí rẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ bí o bá rí ìsọfúnni kan gbà tí kò mú kí ara rẹ balẹ̀. Má ṣe dáhùn àwọn ìsọfúnni tí kò bára dé tàbí tí ó jẹ́ ti ìfínràn. Wí fún àwọn òbí rẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kí wọ́n baà lè kàn sí àwọn ilé iṣẹ́ tí ń bójú tó lílo ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra.
• Fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ ní gbígbé àwọn ìlànà kalẹ̀ fún lílo ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra náà, títí kan àkókò tí yóò jẹ́ àti bí ẹ óò ti máa pẹ́ tó ní lílò ó lójoojúmọ́ àti àwọn àyíká ibi tí ó bá a mu wẹ́kú láti ṣí wò; rọ̀ mọ́ àwọn ìpinnu wọn.
Fi sọ́kàn pé àwọn ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ ṣàǹfààní fún àwọn àgbàlagbà pẹ̀lú. Àwọn ìpò ìbátan tí a kò nífẹ̀ẹ́ sí àti àwọn ìṣòro lílekoko ti dẹkùn mú àwọn àgbàlagbà kan nítorí àìbìkítà. Ìṣarasíhùwà àràmàǹdà tí ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn iyàrá ìfọ̀rọ̀wérọ̀—àìsí ìfojúkanra àti àìdá àwọn tí ń lo orúkọ ìnagijẹ mọ̀—ti dín kíká àwọn kan lọ́wọ́ kò kù, ó sì ti ṣẹ̀dá èrò ààbò èké. Ẹyin àgbàlagbà, ẹ ṣọ́ra!
Níní Ojú Ìwòye Wíwàdéédéé
Àwọn kan lára àwọn àkójọ ìsọfúnni àti ọ̀pọ̀ lára àwọn ìpèsè tí a rí lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet ní àǹfààní ẹ̀kọ́ nínú, wọ́n sì lè ṣiṣẹ́ fún ète tí ó wúlò. Àwọn ilé iṣẹ́ tí ń pọ̀ sí i ń ṣàkójọ àwọn àkọsílẹ̀ tí kò hàn síta lórí àwọn ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra kọ̀ǹpútà wọn tí kò hàn síta, tàbí nínú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra ti abẹ́lé. Fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ gba orí ìsokọ́ra alátagbà Internet pẹ̀lú ẹnì kan tàbí àwọn púpọ̀ tí ń lò ó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti lè jùmọ̀ sọ̀rọ̀ lápapọ̀ níbi tí gbogbo àwọn olùkópa tí lè gbọ́ tàbí kí wọ́n tilẹ̀ rí ara wọn, ní agbára láti máa yí rírìnrìn àjò wa àti àwọn bátànì ìpàdé ìṣòwò wa pa dà títí lọ. Àwọn ilé iṣẹ́ ń lo ìsokọ́ra alátagbà Internet láti ṣe ìpínkiri ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà wọn, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ dín ìnáwó kù. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìpèsè tí ń lo àwọn òṣìṣẹ́ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ òwò rẹ̀, bí ìrìn àjò àti dídókòwò ìpèsè àfidúró, ni ó ṣeé ṣe kí ó kàn níwọ̀n bí a ti fún àwọn ẹni tí ń lo ìsokọ́ra alátagbà Internet lágbára láti ṣe àwọn kan tàbí gbogbo àwọn ètò náà fúnra wọn. Bẹ́ẹ̀ ni, ipa ìsokọ́ra alátagbà Internet jinlẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kí ó máa bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà pàtàkì kan fún ṣíṣàjọpín ìsọfúnni, fún ṣíṣe òwò, àti fífi ìsọfúnni ránṣẹ́.
Bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ohun èlò, ìsokọ́ra alátagbà Internet ní àwọn ọ̀nà ìlò tí ó ṣàǹfààní. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí a ṣì í lò. Àwọn kan lè yàn láti ṣàyẹ̀wò àwọn apá wíwàdéédéé inú ìsokọ́ra alátagbà Internet síwájú sí i, nígbà tí àwọn mìíràn lè má ṣe bẹ́ẹ̀. Kristẹni kan kò láṣẹ láti ṣèdájọ́ ìpinnu ẹlòmíràn lórí àwọn ọ̀ràn ara ẹni.—Róòmù 14:4.
Lílo ìsokọ́ra alátagbà Internet lè dà bíi rírìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè tuntun kan, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ohun tuntun tí a ní láti rí, kí a sì gbọ́. Ìrìn àjò béèrè pé kí o mọ̀wàáhù, kí o sì lo ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ tí ó bọ́gbọ́n mu. Ohun kan náà ni a ń béèrè bí o bá ní láti pinnu láti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìsokọ́ra alátagbà Internet—ọ̀nà márosẹ̀ ìfìsọfúnni-ránṣẹ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
“Kọ̀ǹpútà àdáni náà kò sí nínú iyàrá ọmọkùnrin mi, àmọ́ ó wà ní ibi tí gbogbo wa ti ń rí i nínú ilé”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]
Ìsokọ́ra alátagbà Internet jẹ́ ibi tí gbogbogbòò ń lò, a kò sì gbọ́dọ̀ lò ó bí iṣẹ́ ìbánigbọ́mọ
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Àìní fún Ìwà Rere àti Ìṣọ́ra
Ìwà rere
Kọ́ àwọn ìlànà ìwà rere àti ìmọ̀wàáhù. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ìpèsè ìsokọ́ra alátagbà Internet tẹ àwọn ìtọ́sọ́nà tí ó gba ìrònújinlẹ̀, tí ó sì ṣètẹ́wọ́gbà fún ìhùwà jáde. Àwọn mìíràn tí ń lò ó yóò mọrírì mímọ̀ tí ìwọ mọ̀ ìlànà wọ̀nyí, tí o sì ń lò wọ́n àti ìmọ̀wàáhù rẹ.
Ìṣọ́ra
Àwùjọ àwọn olùjíròrò kan ń jiyàn lórí ọ̀ràn ìsìn tàbí ọ̀ràn tí ń fa awuyewuye. Ṣọ́ra fún lílóhùn sí irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀; ó ṣeé ṣe kí a gbé àdírẹ́sì ìgbékalẹ̀ ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà rẹ sáfẹ́fẹ́ fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú àwùjọ náà. Èyí sábà máa ń yọrí sí ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ tí ń gba àkókò, tí a kò sì nífẹ̀ẹ́ sí. Ní tòótọ́, àwọn ẹgbẹ́ oníròyìn kan wà tí kò yẹ láti máa ka ọ̀rọ̀ wọn, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ dídara pọ̀ mọ́ wọn.
Ti dídá àwùjọ ìjíròrò kan, tàbí ẹgbẹ́ oníròyìn sílẹ̀ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni ń kọ́? Èyí lè dá àwọn ìṣòro àti ewu tí ó túbọ̀ pọ̀ ju èyí tí a retí níbẹ̀rẹ̀ lọ sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ẹni tí wọ́n ní èrò ìkọ̀kọ̀ ni a ti mọ̀ sí pé wọ́n ń purọ́ ẹni tí wọ́n jẹ́ lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ìsokọ́ra alátagbà Internet fúnra rẹ̀ kò fàyè gba ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ń lò ó láti fẹ̀rí ẹni ti òun jẹ́ hàn. Síwájú sí i, lọ́nà kan, a lè fi irú àwọn ẹgbẹ́ bẹ́ẹ̀ wé ìkórajọ-ṣefàájì ńlá kan tí ń lọ lọ́wọ́, tí ń gba àkókò àti agbára ìṣeǹkan olùgbàlejò rẹ̀ láti pèsè àbójútó tí ó pọn dandan, tí ó sì ní láárí.—Fi wé Òwe 27:12.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Báwo Ni Àkókò Rẹ Ṣe Ṣeyebíye Tó?
Ní ọ̀rúndún ogún yìí, ìgbésí ayé túbọ̀ ń díjú gan-an ni. Àwọn ìhùmọ̀ tí ó ti ṣàǹfààní fún àwọn ènìyàn kan sábà máa ń yọrí sí ohun afàkókòṣòfò fún àwọn púpọ̀. Síwájú sí i, àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ oníwà pálapàla àti oníwà ipá lórí tẹlifíṣọ̀n, àwọn ìwé arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè, àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù orin ìbàjẹ́, àti èyí tí ó fara jọ ọ́ jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn iṣẹ́ ẹ̀rọ tí a ti ṣì lò. Kì í ṣe pé wọ́n ń jẹ àkókò ṣíṣeyebíye nìkan ni àmọ́ wọ́n tún ń ṣèpalára fún ipò tẹ̀mí àwọn ènìyàn.
Kì í ṣe ohun tí a óò ṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sọ pé àwọn ohun àkọ́múṣe Kristẹni kan ni àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí, bíi kíkà Bíbélì lójoojúmọ́ àti dídi ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn òtítọ́ tí kò ṣeé díye lé tí ó wà nínú Ìwé Mímọ́ tí a jíròrò nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí Watch Tower Society ṣe. Kì í ṣe láti inú wíwò kiri inú ìsokọ́ra alátagbà Internet ni àwọn àǹfààní ayérayé ti ń wá, àmọ́ láti inú lílo àkókò rẹ láti gba ìmọ̀ Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà àti ti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi, sínú, àti mímú un lò tìtaratìtara.—Jòhánù 17:3; tún wo Éfésù 5:15-17.