O Ha Nílò Ìsokọ́ra Alátagbà Internet Ní Gidi Bí?
O HA gbọ́dọ̀ lo ìsokọ́ra alátagbà Internet bí? A gbà pé èyí jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni, èyí tí o ní láti gbé yẹ̀ wò tìṣọ́ratìṣọ́ra. Àwọn kókó abájọ wo ló lè nípa lórí ìpinnu rẹ?
Ohun Tí O Nílò—O Ha Ti Ṣírò Ohun Tí Yóò Ná Ọ Bí?
Ọ̀pọ̀ lára ìmúgbòòrò tí ìsokọ́ra alátagbà Internet ń ní láìpẹ́ yìí, ló jẹ́ nítorí àwọn ìsapá ọ̀nà ìtajà lílágbára láwùjọ àwọn oníṣòwò. Ní kedere, ète wọn jẹ́ láti ṣẹ̀dá èrò inú pé a nílò wọn. Níwọ̀n bí a bá ti ní èrò àìní yìí, àwọn ẹgbẹ́ kan yóò wá béèrè fún owó àsansílẹ̀ bí ọmọ ẹgbẹ́ tàbí owó àsansílẹ̀ ọlọ́dọọdún fún àwọn ìsọfúnni tàbí ìpèsè tí o ti ń lò tẹ́lẹ̀ rí láìsanwó. Owó yìí jẹ́ àfikún sí owó lílo ìsokọ́ra alátagbà Internet rẹ lóṣooṣù. Àwọn ilé iṣẹ́ ìwé agbéròyìnjáde kan jẹ́ àpẹẹrẹ wíwọ́pọ̀ lára àwọn tí ń ṣe èyí.
Ṣé o ti ṣírò iye tí ohun ẹ̀rọ àti ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà náà yóò ná ọ ní ìfiwéra pẹ̀lú àìní rẹ ní gidi bí? (Fi wé Lúùkù 14:28.) Àwọn ibi ìkówèésí tàbí ilé ẹ̀kọ́ gbogbogbòò tí ń lo ìsokọ́ra alátagbà Internet ha wà bí? Lílo ìpèsè yí lákọ̀ọ́kọ́ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti díye lé àìní rẹ láìsí kíkọ́kọ́ kówó tí ó pọ̀ kan lé kọ̀ǹpútà àdáni kan àti àwọn ohun èlò tí ó tan mọ́ ọn. Ó lè jẹ́ pé a lè lo orísun ìsọfúnni ìsokọ́ra alátagbà Internet ti gbogbogbòò tí ó yẹ, bí a bá ṣe nílò rẹ̀ sí, títí di ìgbà tí bí a ṣe ń béèrè fún irú ọgbọ́n ojútùú bẹ́ẹ̀ tó ní ti gidi yóò yéni yékéyéké. Rántí pé ìsokọ́ra alátagbà Internet náà ti wà fún ohun tí ó lé ní ẹ̀wádún méjì kí àwọn ènìyàn níbi gbogbo tilẹ̀ tó mọ̀ nípa rẹ̀, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ nípa ìgbà tí àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé àwọn nílò rẹ̀!
Ààbò —Ibi Àṣírí Rẹ Ha Láàbò Bí?
Kókó àníyàn pàtàkì míràn ni ọ̀ràn àṣírí. Fún àpẹẹrẹ, ẹni tí o fẹ́ kí ó gba àwọn ìsọfúnni tí o ń fi ránṣẹ́ nìkan ló yẹ kí ó rí i. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí lẹ́tà náà ṣì wà lójú ọ̀nà, ẹnì kan tàbí àwùjọ àwọn kan tí wọ́n gbọ́n féfé, tí wọ́n lè jẹ́ aláìtẹ̀lé-lànà lè dá a dúró tàbí kí wọ́n tọpa orísun ìsọfúnni rẹ. Láti dáàbò bo ìsọfúnni náà, àwọn ènìyàn kan ń lo àwọn ìmújáde ìfìsọfúnni-ráńṣẹ́ ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà láti da ohun tí ó jẹ́ àṣírí nínú lẹ́tà wọn rú kí wọ́n tó fi ránṣẹ́. Ní ìhà kejì lọ́hùn-ún, ẹni tí ń gbà á lè nílò irú ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà tí ó jọra láti tún ìsọfúnni náà tò.
Láìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ ìjíròrò ti dá lórí ṣíṣe pàṣípààrọ̀ káàdì ìrajà àwìn àti àwọn ìsọfúnni mìíràn tí ó jẹ́ àṣírí fún ìṣòwò lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a retí pé kí àwọn ìhùmọ̀ gidi fún ààbò lókun, gbajúmọ̀ alálàyé lórí ààbò kọ̀ǹpútà náà, Dorothy Denning, sọ pé: “A kò lè rí ìgbékalẹ̀ tí ó láàbò pátápátá, àmọ́ a lè dín ewu rẹ̀ kù dé àyè kan, bóyá dé ìpele kan tí ó dọ́gba pẹ̀lú ìdíyelé àwọn ìsọfúnni tí a kó sínú ìgbékalẹ̀ náà àti ewu tí olùṣètò ìgbékalẹ̀ ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà àti ẹni tí ń yẹ àṣírí ẹlòmíràn wò gbé dìde.” A kò lè rí ààbò pátápátá nínú ìgbékalẹ̀ kọ̀ǹpútà èyíkéyìí, yálà a tàtagbà rẹ̀ pẹ̀lú ìsokọ́ra alátagbà Internet tàbí a kò ṣe bẹ́ẹ̀.
Ṣé O Lè Rí Àkókò fún Un?
Kókó pàtàkì míràn ni àkókò rẹ. Yóò ti pẹ́ ọ tó láti ṣàgbékalẹ̀ ìsokọ́ra alátagbà Internet, kí o sì kọ́ nípa lílo àwọn èlò rẹ̀ láti wò káàkiri inú rẹ̀? Bákan náà, olùkọ́ni onírìírí kan nípa lílo ìsokọ́ra alátagbà Internet, tọ́ka pé, wíwòkiri inú ìsokọ́ra alátagbà Internet “lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbòkègbodò tí ń di bárakú, tí ó sì ń jẹ àkókò jù lọ fún ẹnì kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìsokọ́ra alátagbà Internet.” Èé ṣe tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀?
Àwọn kókó gbígbádùnmọ́ni rẹpẹtẹ àti àìlóǹkà àwọn ohun tuntun láti ṣàwárí pọ̀ níbẹ̀. Ní pàtàkì, ìsokọ́ra alátagbà Internet jẹ́ àkójọ àwọn ibi ìkósọfúnnisí gbígbòòrò tí ó ní àwọn ìsọfúnni tí ń fani mọ́ra nínú. Wíwòkáàkiri apá kan péré nínú rẹ̀ lè gba èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára ìrọ̀lẹ́ rẹ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, kí o tilẹ̀ tó ronú kan oorun. (Wo àpótí náà, “Báwo Ni Àkókò Rẹ Ṣe Ṣeyebíye Tó?” ní ojú ìwé 13.) Dájúdájú, èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tí ń dé inú ìsokọ́ra Web náà kò ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Bí ó ti wù kí ó rí, yóò bọ́gbọ́n mu láti pààlà sí iye àkókò àti irú ìsọfúnni tí a óò wá kiri nínú ìsokọ́ra Web—ní pàtàkì fún àwọn ọmọdé. Ọ̀pọ̀ ìdílé ń ṣe ohun kan náà ní ti tẹlifíṣọ̀n.a Èyí yóò pa àkókò tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ìgbòkègbodò ìdílé àti tẹ̀mí mọ́.—Diutarónómì 6:6, 7; Mátíù 5:3.
O Ha Ń Pàdánù Bí?
Bí àkókò ti ń lọ, a óò máa ṣàmúlò ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ìsokọ́ra alátagbà Internet lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ sí i ní àwọn àgbègbè tí wọn kò tí ì gòkè àgbà lágbàáyé. Bí ó ti wù kí ó rí, rántí àwọn ẹni tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́. Wọ́n ti lè rí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìsọfúnni tí wọ́n rí gbà nípa lílo àwọn ibi ìkówèésí, tẹlifóònù, ọ̀nà ìfìwéránṣẹ́ wíwọ́pọ̀, tàbí nípasẹ̀ àwọn ìwé agbéròyìnjáde. Dájúdájú, díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà wọ̀nyí lè gba àkókò àti ìnáwó púpọ̀. Síbẹ̀, fún ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn jákèjádò ayé, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọ̀nà tí ó túbọ̀ jẹ́ àṣà gbogbogbòò wọ̀nyí máa bá a lọ ní jíjẹ́ lájorí ọ̀nà ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ fún àkókò kan.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Wíwo Tẹlifíṣọ̀n Jù?” nínú Jí! (Gẹ̀ẹ́sì), ìtẹ̀jáde February 22, 1985.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Wíwòkiri inú ìgbékalẹ̀ Net lè di ìdẹkùn bí kò bá sí ìkóra-ẹni-níjàánu