ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 7/22 ojú ìwé 3-4
  • Kí Ni Ìsokọ́ra Alátagbà Internet?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ìsokọ́ra Alátagbà Internet?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ó Jẹ́?
  • Fi Ọgbọ́n Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìsokọ́ra Alátagbà Internet—Èé Ṣe Tí O Ní Láti Ṣọ́ra?
    Jí!—1997
  • Ṣé Bẹ́ẹ̀ Ni Ewu Pọ̀ Tó Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
    Jí!—2005
  • O Ha Nílò Ìsokọ́ra Alátagbà Internet Ní Gidi Bí?
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 7/22 ojú ìwé 3-4

Kí Ni Ìsokọ́ra Alátagbà Internet?

NÍ LÍLO ìsokọ́ra alátagbà Internet, David, olùkọ́ kan ní United States, ṣàkójọ àwọn ìsọfúnni nípa ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Bàbá kan láti Kánádà lò ó láti máa kàn sí ọmọbìnrin rẹ̀ ní Rọ́ṣíà. Loma, ìyàwó ilé kan, lò ó láti ṣàyẹ̀wò ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àgbáálá ayé. Àgbẹ̀ kan lò ó láti wá ìsọfúnni nípa àwọn ìlànà tuntun ti lílo sátẹ́láìtì láti gbin nǹkan. Ó fa àwọn àjọ ìṣòwò mọ́ra nítorí agbára rẹ̀ láti polówó ọjà àti iṣẹ́ wọn fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn oníbàárà tó lè yọjú. Àwọn ènìyàn jákèjádò òbìrìkìtì ayé ka àwọn ìròyìn tí ó dé kẹ́yìn nípa orílẹ̀-èdè tiwọn àti ti àwọn orílẹ̀-èdè jákèjádò ayé nípasẹ̀ ìròyìn tí ń gbé jáde lọ́nà gbígbòòrò àti iṣẹ́ ìgbésọfúnni-jáde rẹ̀.

Kí ni àrà mérìíyìírí orí kọ̀ǹpútà yí tí ń jẹ́ ìsokọ́ra alátagbà Internet, tàbí ìgbékalẹ̀ Net? Ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ha nílò rẹ̀ bí? Kí o tó pinnu láti bẹ̀rẹ̀ sí í “lo” ìsokọ́ra alátagbà Internet, o lè fẹ́ láti mọ ohun kan nípa rẹ̀. Lójú gbogbo ìpolówó gígọntiọ tí a ń fún un, àwọn ìdí wà tí a fi ní láti ṣọ́ra, ní pàtàkì, bí a bá ní àwọn ọmọdé nílé.

Kí Ni Ó Jẹ́?

Finú wòye iyàrá kan tí aláǹtakùn púpọ̀ kún inú rẹ̀, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń takùn tirẹ̀. Àwọn okùn náà so kọ́ra dáradára gan-an débi pé àwọn aláǹtakùn náà lè rìn fàlàlà láàárín ìsokọ́ra dídíjú yìí. Ní báyìí, o ti wá lóye lọ́nà rírọrùn nípa ìsokọ́ra alátagbà Internet—àkójọ onírúurú kọ̀ǹpútà àti ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra kọ̀ǹpútà tí a ta látagbà káàkiri ayé. Gan-an gẹ́gẹ́ bí tẹlifóònù kan ti ń jẹ́ kí o lè bá ẹnì kan ní apá ìhà kejì ayé tí òun pẹ̀lú ní tẹlifóònù sọ̀rọ̀, ìsokọ́ra alátagbà Internet ń jẹ́ kí ẹnì kan jókòó sídìí kọ̀ǹpútà rẹ̀, kí ó sì máa ṣe pàṣípààrọ̀ ìsọfúnni pẹ̀lú àwọn kọ̀ǹpútà míràn àti àwọn ẹlòmíràn tí ń lo kọ̀ǹpútà níbikíbi lágbàáyé.

Àwọn kan pe ìsokọ́ra alátagbà Internet ní ọ̀nà márosẹ̀ ìfìsọfúnni-ránṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan tí ń jẹ́ kí a lè rìnrìn àjò lọ sí apá ibi yíyàtọ̀síra ní orílẹ̀-èdè kan, bẹ́ẹ̀ ni ìsokọ́ra alátagbà Internet ń jẹ́ kí àwọn ìsọfúnni lọ káàkiri onírúurú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra alátagbà lórí kọ̀ǹpútà. Ibi ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra kọ̀ọ̀kan tí ìsọfúnni ń dé bí ó ti ń lọ káàkiri ní àwọn ìsọfúnni tí ń ṣèrànwọ́ láti tàtaré sọ́dọ̀ ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra tí ó wà nítòsí. Ibi tí ó ń lọ gangan lè wà ní ìlú ńlá tàbí orílẹ̀-èdè míràn.

Ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra kọ̀ọ̀kan lè bá ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra tí ó sún mọ́ ọn “sọ̀rọ̀” nípasẹ̀ àkójọ àwọn ìlànà àfilélẹ̀ àjùmọ̀ní kan tí àwọn tí wọ́n ṣàgbékalẹ̀ ìsokọ́ra alátagbà Internet ṣẹ̀dá. Ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra mélòó ni a ta látagbà jákèjádò ayé? Àwọn ìdíyelé kan sọ pé, ó lé ní 30,000. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ kan ti sọ, àwọn ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra wọ̀nyí tàtagbà àwọn kọ̀ǹpútà tí iye wọ́n lé ní 10,000,000, àti nǹkan bí 30,000,000 àwọn ẹni tí ń lò ó jákèjádò ayé. A fojú díwọ̀n pé iye àwọn kọ̀ǹpútà tí a ta látagbà mọ́ ọn ń wọ ìlọ́po méjì lọ́dọọdún.

Kí ni àwọn ènìyàn lè rí lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet? Ó ń pèsè àkójọ ìsọfúnni tí ń yára pọ̀ sí i, tí ó ní àwọn àkọlé tí ó wà láti orí ìmọ̀ ìṣègùn sí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ. Ó ń gbé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àkójọ ìsọfúnni jáde lórí iṣẹ́ ọnà, títí kan àwọn àkójọ ìwádìí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, ó sì kárí àwọn àǹfààní eré ìtura, ohun àṣenajú, eré ìdárayá, ìrajà, àti iṣẹ́. Ìsokọ́ra alátagbà Internet ń pèsè àǹfààní láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìtẹ̀jáde olónírúurú ìsọfúnni, àwọn ìwé atúmọ̀ èdè, àwọn ìwé gbédègbẹ́yọ̀, àti àwọn àwòrán ilẹ̀.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìhà tí ń yọni lẹ́nu kan wà láti ronú lé lórí. A ha lè ka gbogbo ohun tó wà lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet sí èyí tó gbámúṣé bí? Àwọn iṣẹ́ ìpèsè àti orísun ìsọfúnni wo ni ìsokọ́ra alátagbà Internet jẹ́ orísun rẹ̀? Àwọn ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ wo ló yẹ? Àwọn àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti Ìwéwèéṣètò Ìsokọ́ra Alátagbà Internet

Ẹ̀ka Ààbò United States ló bẹ̀rẹ̀ ìsokọ́ra alátagbà Internet ní àwọn ọdún 1960 bí àṣeyẹ̀wò kan láti ran àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àti àwọn olùṣèwádìí láti àwọn àgbègbè tí ó jìnnà síra lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ pa pọ̀ nípa ṣíṣàjọpín àwọn kọ̀ǹpútà àti àwọn àkójọ ìsọfúnni ṣíṣọ̀wọ́n, tí ó sì gbówó lórí nínú wọn. Góńgó yìí béèrè fún ṣíṣẹ̀dá ọ̀wọ́ àwùjọ ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra kan tí yóò ṣiṣẹ́ bí àkójọ alátagbà kan tí a ń ṣe kòkárí rẹ̀.

Ogun Tútù náà ru ìfẹ́ ọkàn sókè nínú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra “tí bọ́ǹbù kò ràn” kan. Bí apá kan ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra náà bá bà jẹ́, ìsọfúnni oníṣirò yóò ṣì lọ káàkiri sí ibi tí ó ń lọ gangan pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn apá tí ó ṣì wà. Nínú ìgbékalẹ̀ alátagbà Internet tí ó jẹ́ àbájáde àṣeyẹ̀wò náà, ẹrù iṣẹ́ ọ̀nà ìgbésọfúnni náà ni a tipa bẹ́ẹ̀ tàn kálẹ̀ káàkiri inú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra náà dípò kíkó o síbì kan ṣoṣo.

Dé àyè púpọ̀, ìsokọ́ra alátagbà Internet náà, tí ó ti wà ju ẹ̀wádún méjì lọ báyìí, ti gbajúmọ̀ gan-an nítorí lílo àwọn èlò ìsọfúnni àwògààràgà. Èlò ìsọfúnni àwògààràgà jẹ́ èlò ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà kan tí ń mú kí ìgbésẹ̀ “ìṣèbẹ̀wò” tí ẹnì kan tí ń lò ó ń ṣe sí ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet rọrùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́