ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 12/8 ojú ìwé 16-19
  • Béèyàn Ṣe Lè Sá fún Ewu Tó Wà Nínú Lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Béèyàn Ṣe Lè Sá fún Ewu Tó Wà Nínú Lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Ṣọ́ra
  • Ewu Tó Wà Nínú Jíjíròrò Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíì Lórí Kọ̀ǹpútà
  • Fífi Àwọn Ìlànà Bíbélì Sílò Lè Pa Ọ́ Mọ́
  • Ìsokọ́ra Alátagbà Internet—Èé Ṣe Tí O Ní Láti Ṣọ́ra?
    Jí!—1997
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Ewu Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
    Jí!—2000
  • Ṣé Bẹ́ẹ̀ Ni Ewu Pọ̀ Tó Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
    Jí!—2005
  • Fi Ọgbọ́n Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 12/8 ojú ìwé 16-19

Ojú Ìwòye Bíbélì

Béèyàn Ṣe Lè Sá fún Ewu Tó Wà Nínú Lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì

NÍ ABÚLÉ àdádó kan lórílẹ̀-èdè Íńdíà, àgbẹ̀ kan ń wo iye tí wọ́n ń ta ẹ̀wà sóyà ní ìlú Chicago, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, kó bàa lè mọ ìgbà tó máa dáa jù lọ fún òun láti ta èyí tóun ní sílé. Lákòókò kan náà, obìnrin kan tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ń rẹ́rìn-ín músẹ́ bó ṣe ń ka lẹ́tà tí ọmọ-ọmọ ẹ̀ fi ránṣẹ́ sí i látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ẹnì kan tó ràjò ń gbọ́ àsọbádé nípa ojú ọjọ́ níbi tó dé sí, ìyá kan sì rí ìsọfúnni tó wúlò tọ́mọ ẹ̀ á lò láti fi ṣe iṣẹ́ tí wọ́n ní kó ṣe wá nílé ìwé. Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni gbogbo wọn sì ti rí àwọn ìsọfúnni tá à ń sọ̀ yìí o. Lílò táwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀ta mílíọ̀nù káàkiri àgbáyé ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì ti wá mú kí ìyàtọ̀ dé bá ọ̀nà táráyé ń gbà bára wọn sọ̀rọ̀ àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bára wọn ṣòwò.

Àwọn tí lílò ẹ̀ tiẹ̀ wá gbádùn mọ́ jù làwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ pé ayé kọ̀ǹpútà làwọn lajú sí ní tiwọn. Ọ̀pọ̀ ọmọléèwé ló sì ti wá ń lò ó báyìí láti máa gbọ́ ìròyìn àti fún ṣíṣe ìwádìí. Deanna L. Tillisch, ẹni tó darí ìwádìí kan tó dá lórí àwọn tó ku ọdún kan kí wọ́n jáde ilé ẹ̀kọ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Lọ́rọ̀ kan, ohun tá à ń sọ ni pé orí Íńtánẹ́ẹ̀tì nìkan ló kù táwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí . . . ti ń kọ́ gbogbo nǹkan tí wọ́n bá fẹ́ kọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni o, kòṣeémánìí ni Íńtánẹ́ẹ̀tì jẹ́ láwùjọ wa lóde òní.

Àmọ́, bọ́ràn ṣe sábà máa ń rí ni pé bí irinṣẹ́ kan bá ṣe lágbára tó, bẹ́ẹ̀ lewu tó wà nínú lílò ó ṣe máa ń pọ̀ tó. Ayùn ìrẹ́gi tó ń lo gáàsì lè ṣiṣẹ́ fíìfíì ju ayùn ọlọ́wọ́ lọ; síbẹ̀, ìlò ẹ̀ gba ìṣọ́ra. Bí Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe lágbára tó àti bó ṣe wúlò yẹn, ìlò ẹ̀ gba ìṣọ́ra, nítorí pé ewu wà níbẹ̀. Àníyàn táwọn orílẹ̀-èdè tó ju ogójì lọ tó wà nínú Àjọ Ilẹ̀ Yúróòpù ń ṣe nípa àwọn ewu yìí ti mú kí wọ́n fọwọ́ sí ìwé àdéhùn pé àwọn á dáàbò bo àwọn tó wà láwùjọ lọ́wọ́ àwọn tó ń fi Íńtánẹ́ẹ̀tì hùwà ọ̀daràn.

Kí ló fà á tí àníyàn fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Kí ni díẹ̀ lára ewu táwọn Kristẹni ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ jù? Ṣé ewu náà pọ̀ débi pé kó o má lo Íńtánẹ́ẹ̀tì? Ìtọ́sọ́nà wo ni Bíbélì fúnni?

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Ṣọ́ra

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Bíbélì kì wá nílọ̀ nípa ewu látọ̀dọ̀ àwọn olubi tó pè ní ‘ọ̀gá nídìí àwọn èrò ibi’ tí wọ́n sì “ń pète-pèrò àtiṣe búburú.” (Òwe 24:8) Wòlíì Jeremáyà ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí “àwọn ènìyàn burúkú” tí “ilé wọn kún fún ẹ̀tàn.” Bí àwọn pẹyẹpẹyẹ, wọ́n a máa “dẹ [okùn] ìparun” kí wọ́n lè fi mú àwọn èèyàn kí wọ́n sì “jèrè ọrọ̀.” (Jeremáyà 5:26, 27) Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti mú káwọn “ènìyàn burúkú” tó ń dẹ irú okùn kan tó tún yàtọ̀ wà lóde òní. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ọgbọ́n ìtànjẹ díẹ̀ tó léwu gidigidi fáwọn Kristẹni.

Àwọn àwòrán oníhòhò táwọn èèyàn máa ń wò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń mówó gegere tó tó bílíọ̀nù méjì àbọ̀ dọ́là wọlé sápò àwọn tó ń gbé àwòrán náà jáde. Àwọn abala ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì téèyàn ti lè wo àwọn àwòrán oníhòhò ti yára fi ìlọ́po méjìdínlógún pọ̀ sí i ju bó ṣe rí ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn. Àwọn kan tiẹ̀ fojú bù ú pé ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, irú àwọn abala bẹ́ẹ̀ tó wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ju ọ̀tàlénígba mílíọ̀nù lọ, ńṣe ni iye náà sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ọ̀mọ̀wé Kimberly S. Young, olùdarí àgbà fún Ibùdó Tó Ń Rí sí Sísọ Lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì Di Bárakú sọ pé: “Àwòrán tó ń mú kéèyàn fẹ́ láti ṣèṣekúṣe ti wá ń pọ̀ sí i lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì báyìí débi pé ó ti ṣòroó yẹra fún, ìyẹn ló fi jẹ́ pé téèyàn ò bá ṣọ́ra ó lè mọ́ ọn lára láti máa wò wọ́n.”

Bíbélì sọ fún wa pé “olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀.” (Jákọ́bù 1:14) Èrò àwọn tó ń ṣagbátẹrù àwọn àwòrán ìṣekúṣe ni pé ẹni kẹ́ni tó bá ti lè fi kọ̀ǹpútà rẹ̀ wọnú Íńtánẹ́ẹ̀tì làwọn lè mú balẹ̀, nítorí náà, wọ́n máa ń ta oríṣiríṣi ọgbọ́n tí wọ́n á fi fa “ìfẹ́-ọkàn” olúkúlùkù mọ́ra. Ìyẹn ni àwọn ìfẹ́ ọkàn bí “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú.” (1 Jòhánù 2:16) Gbogbo ohun tí wọ́n ń fẹ́ ni pé kí wọ́n ṣáà ti fọgbọ́n tan àwọn tó bá gbàgbé ara wọn sídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì kí wọ́n sì “gbìyànjú láti sún” wọn “dẹ́ṣẹ̀.”—Òwe 1:10.

Bíi tàwọn olubi lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọgbọ́n ẹ̀tàn làwọn tó ń ta àwòrán àwọn tó ń bára wọn ṣèṣekúṣe sábà máa ń lò. Wọ́n fojú bù ú pé gẹ́gẹ́ bí ara ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tí wọ́n máa ń dá láti fa àwọn oníbàárà tuntun mọ́ra, lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tó tó bílíọ̀nù méjì tó sì ní àwọn àwòrán ìṣekúṣe nínú ni wọ́n máa ń fi ránṣẹ́ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì lójoojúmọ́. Àkọlé àwọn lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tí wọ́n bá ṣàdédé fi ránṣẹ́ sábà máa ń dà bí èyí tí kò léwu. Àmọ́, béèyàn bá ṣí ọ̀kan nínú wọn wò pẹ́nrẹ́n, ọ̀pọ̀ àwòrán ìṣekúṣe á kàn máa ṣí sójú kọ̀ǹpútà ni, á sì ṣòro láti dá wọn dúró. Bó o bá sì wá sọ pé o ò fẹ́ kí wọ́n máa firú àwòrán bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́ sí ẹ mọ́, ó lè jẹ́ ìyẹn gan-an lá á mú kí wọ́n kúkú fi ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìsọfúnni nípa ìṣekúṣe ránṣẹ́ sí ẹ.

Pẹyẹpẹyẹ máa ń fọ́n irúgbìn sójú ọ̀nà ni. Ẹyẹ tí ò fura á sì máa ṣa àwọn irúgbìn tó dùn náà jẹ níkọ̀ọ̀kan títí tá á fi kó sínú okùn. Àfi wọ̀n-ìn, okùn á bá mú un lẹ́sẹ̀! Bákan náà ló rí pẹ̀lú àwọn tí ojúmìító sún dé ìdí bíbẹjú wo àwọn àwòrán tó ń mú kéèyàn fẹ́ láti ṣèṣekúṣe. Wọ́n gbà pé ẹni kẹ́ni ò rí àwọn. Àmọ́ báwọn àwòrán náà bá ṣe ń mú kí ìṣekúṣe gbádùn mọ́ àwọn kan, á di pé kí wọ́n máa padà lọ wò ó láwòtúnwò. Kò ní pẹ́ tá a fi dojútì sí wọn lára, tí ọkàn wọn á sì máa dá wọn lẹ́bi. Nígbà tó bá sì yá, ohun tó ti ń ṣe wọ́n bákan tẹ́lẹ̀ ò ní tu irun kankan mọ́ lára wọn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, bí ajílẹ̀ ṣe máa ń mú kí irúgbìn dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni Íńtánẹ́ẹ̀tì ń mú ìfẹ́ ọkàn àwọn tí wọn ò lè ṣe kí wọ́n má wo àwòrán ìṣekúṣe lágbára sí i títí tí wọ́n á fi dẹ́ṣẹ̀. (Jákọ́bù 1:15) Ọ̀jọ̀gbọ́n Victor Cline, afìṣemọ̀rònú tó ti tọ́jú ọ̀pọ̀ àwọn tó ní ìṣòro nítorí wíwo àwòrán oníhòhò sọ pé, bó bá yá ńṣe nirú wọn á bẹ̀rẹ̀ sí “hùwà má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́, èyí tá á mú kí wọ́n máa fẹ́ láti bá tajá tẹran ní ìbálòpọ̀.”

Ewu Tó Wà Nínú Jíjíròrò Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíì Lórí Kọ̀ǹpútà

Jíjíròrò pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì lórí kọ̀ǹpútà máa ń fàkókò ṣòfò, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń da ilé onílé rú. Nígbà tí ọkùnrin kan ń kọ̀wé nípa bí àkókò púpọ̀ tí ìyàwó rẹ̀ ń lò nídìí kọ̀ǹpútà ṣe tojú sú u, ó sọ pé: “Bó bá ti dé látibi iṣẹ́, ìdí kọ̀ǹpútà lá á gbà lọ. Ó sì lè lò tó wákàtí márùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kó tó kúrò nídìí ẹ̀. Nǹkan ò lọ déédéé nínú ilé wa mọ́ nítorí ẹ̀.” Àkókò tó yẹ kéèyàn fi wà pẹ̀lú ìdílé àti aya tàbí ọkọ ẹ̀ lá á máa lò dà nù bó bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Angela Sibson, ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ Relate tí wọ́n ti ń gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn nípa ìgbéyàwó, sọ pé ńṣe ni Íńtánẹ́ẹ̀tì “máa ń báni wá àwọn ọ̀rẹ́ míì. Irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń nípa tó pọ̀ lórí ẹni wọ́n sì lè da àárín onítọ̀hún àtàwọn ẹlòmíì rú.” Ó lè máà pẹ́ tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ níbi àpérò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì á fi di nǹkan tó léwu. Nítorí pé àwọn ‘alálùmọ̀kọ́rọ́yí ọkàn-àyà’ máa ń wá ẹni bá hùwà pálapàla ní gbogbo ọ̀nà, wọ́n máa ń lo ‘ahọ́n dídùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in’ láti máa sọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n mọ̀ pé á dùn mọ́ àwọn tọ́wọ́ wọn bá ti bà. (Òwe 6:24; 7:10) Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tọ́wọ́ wọn ti bà rí, Nicola tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ṣàlàyé pé: “Nígbà gbogbo ṣáá ló ń sọ fún mi pé òun nífẹ̀ẹ́ mi. Kò yé sọ fún mi pé irú mi ṣọ̀wọ́n, ohun tó fi rí mi tàn nìyẹn o.” Ọ̀mọ̀wé Al Cooper, olóòtú ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, Sex and the Internet: A Guidebook for Clinicians, sọ pé ó yẹ ká “kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé bí bíbáni tage bá ti bẹ̀rẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìkọ̀sílẹ̀ ló sábà máa ń yọrí sí.”

Àwọn ọmọdé gan-an lọwọ́ “àwọn tó ń fi ìṣekúṣe ṣeré lórí kọ̀ǹpútà” tètè máa ń bà tí wọ́n sì máa ń pa lára jù. Nítorí pé àwọn abọ́mọdéṣèṣekúṣe máa ń lo “ọ̀rọ̀ wíwọ́” àti ‘ètè békebèke,’ àwọn ọmọ tí ò tíì gbọ́n ni wọ́n máa ń wá kiri. (Òwe 4:24; 7:7) Wọ́n kọ́kọ́ máa ń fa ojú ọmọdé mọ́ra náà, wọ́n á máa ṣe gbogbo ohun tó ń bá fẹ́ fún un, wọ́n á máa fi hàn ní gbogbo ọ̀nà pé àwọn fẹ́ràn ẹ̀, pé àwọn á fojúure hàn sí i, tọ́mọ náà á fi máa wò ó pé òun tóbi gan-an lọ́wọ́ wọn. Ó dà bí ẹni pé wọ́n máa ń mọ gbogbo nǹkan tọ́mọ kan ń fẹ́, tó fi mọ́ orin tó gbádùn mọ́ ọn àti eré ìtura tó fẹ́ràn láti máa ṣe. Wọ́n á máa bepo síná ìṣòro tí ò tó nǹkan tọ́mọ náà bá ní nínú ilé kí wọ́n bàa lè dá ọ̀tá sáàárín òun àtàwọn tó ń bá gbélé. Kí wọ́n bàa lè ṣiṣẹ́ ibi tó wà lọ́kàn wọn, àwọn ẹlẹ̀tàn wọ̀nyí tiẹ̀ le fi tíkẹ́ẹ̀tì ọkọ̀ ránṣẹ́ sí ẹni tí wọ́n dójú sọ náà pé kó fi najú lọ káàkiri orílẹ̀-èdè tó ń gbé. Ohun tó burú ló máa ń tìdí ẹ̀ yọ.

Fífi Àwọn Ìlànà Bíbélì Sílò Lè Pa Ọ́ Mọ́

Lẹ́yìn táwọn èèyàn kan ti rò ó síwá rò ó sẹ́yìn, wọ́n ti pinnu pé ó kúkú sàn káwọn má ṣe lo Íńtánẹ́ẹ̀tì rárá. Àmọ́ ṣá o, ohun tó yẹ ká mọ̀ ni pé díẹ̀ péré lára àwọn ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló léwu, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lò ó kò sì tíì ko ìṣòro tó lágbára.

A dúpẹ́ pé Ìwé Mímọ́ fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó lè “fi ìṣọ́ ṣọ́” wa ká má bàa kó sínú ewu. Ó gbà wá níyànjú pé ká ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n ká sì mọnúúrò. Irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ á ‘máa ṣọ́ wa’ láti lè ‘dá wa nídè kúrò ní ọ̀nà búburú.’ (Òwe 2:10-12) Jóòbù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan nígbàanì, béèrè pé: “Ṣùgbọ́n ọgbọ́n—ibo ni ó ti wá?” Ìdáhùn tó rí gbà sí ìbéèrè yẹn ni pé, “Ìbẹ̀rù Jèhófà—ìyẹn ni ọgbọ́n.”—Jóòbù 28:20, 28.

“Ìbẹ̀rù Jèhófà,” tó “túmọ̀ sí kíkórìíra ohun búburú,” ló lè ràn wá lọ́wọ́ ká bàa lè ní àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run fẹ́. (Òwe 1:7; 8:13; 9:10) Níní ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run, àti níní ọ̀wọ̀ tó ga fún agbára àti àṣẹ rẹ̀, á mú ká kórìíra àwọn nǹkan búburú tí Ọlọ́run kórìíra ká sì yẹra fún wọn. Mímọnúúrò àti lílóye àwọn ìlànà Ọlọ́run á ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ewu tó lè ba ọkàn wa, àyà wa àti ipò tẹ̀mí wa jẹ́. A óò wá kórìíra àwọn ìwà ìmọtara-ẹni nìkan àti ọ̀kánjúwà tó lè tú ìdílé wa ká àtèyí tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.

Nítorí náà, bó o bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, má ṣe gbà gbé pé ewu wà níbẹ̀ o. Pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé wà á pa òfin Ọlọ́run mọ́, wàá sì yẹra fún fífọwọ́ ara ẹ fa wàhálà. (1 Kíróníkà 28:7) Wàyí o, bó o bá bá ohun tó léwu pàdé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ohun tá á bọ́gbọ́n mu fún ẹ ni pé kó o sá fún irú ewu bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 6:18.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

SÁ FÁWỌN ÀWÒRÁN ONÍHÒHÒ TÓ Ń MÚNI ṢÈṢEKÚṢE!

“Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́.”—Éfésù 5:3.

“Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò.”—Kólósè 3:5.

“Èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, . . . pé kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá, kì í ṣe nínú ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo irúfẹ́ èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì pẹ̀lú tí kò mọ Ọlọ́run ní.”—1 Tẹsalóníkà 4:3-5.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

ṢỌ́RA, EWU Ń BẸ NÍBI ÌFỌ̀RỌ̀WÉRỌ̀ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ!

Obìnrin ọlọ́pàá inú kan tó máa ń ṣèwádìí nípa ìwà ọ̀daràn táwọn èèyàn ń hù lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ké sí aṣojú ìwé ìròyìn Jí! láti wá fojú ara ẹ̀ rí ewu tó wà nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó ṣí ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà, ó sì ṣe bíi pé ọmọbìnrin ẹni ọdún mẹ́rìnlá lòun. Níwọ̀nba ìṣẹ́jú àáyá díẹ̀ tó ṣí i síbẹ̀, àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé sí i lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì níbẹ̀. Àwọn èèyàn tí ò mọ̀ rí náà ń bí i láwọn ìbéèrè bíi: “Níbo lo ti wá?” “Ọkùnrin ni ẹ́ àbí obìnrin?” “Ṣé mo lè bá ẹ sọ̀rọ̀?” Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kọ̀wé ránṣẹ́ làwọn tí ọlọ́pàá ti fura sí pé wọ́n máa ń fi ìbálòpọ̀ ta àwọn èèyàn ní jàǹbá, ọ̀wọ́ ò kàn tíì tẹ̀ wọ́n ni. Tóò, bó ṣe rọrùn jẹ̀lẹ̀jẹlẹ fẹ́ni tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe láti wà níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan náà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kó sì máa bá ọmọ ẹ sọ̀rọ̀ nìyẹn o!

Àwọn òbí kan ronú pé kò séwu fáwọn ọmọdé bí wọ́n bá ń fọ̀rọ̀wérọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nítorí pé àwọn míì tí wọ́n jọ wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì á máa rí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń kọ́ ránṣẹ́ síra bí ìjíròrò náà ti ń lọ lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá o, gbàrà tí ìjíròrò náà bá ti bẹ̀rẹ̀, àwọn tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀ lè ní káwọn ṣe é tí ẹlòmíì ò fi ní mọ ohun tí wọ́n ń kọ ránṣẹ́ síra wọn. Nígbà tí àwọn Ẹ̀ṣọ́ Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń sọ nípa èyí, wọ́n kìlọ̀ pé: “Ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn jáde kúrò lágbo àríyá tó sì wọnú yára àdáni kan lọ tó wá ń bá àjèjì kan fọ̀rọ̀ wérọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́.”

Ó tún ṣe pàtàkì káwọn òbí mọ̀ pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe ò jẹ́ fọ̀rọ̀ mọ sórí fífọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú ọmọ kan. Ìwé kan tó wá látọ̀dọ̀ Ètò Jẹ́-N-Wí-Tèmi Nípa Ìwà Ọ̀daràn Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ròyìn pé: “Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó bá bẹ̀rẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tún lè máa bá a lọ láwọn ọ̀nà mìíràn, bíi nípa kíkọ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà síra ẹni tàbí bíbá ara ẹni sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù (alágbèéká).” Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí ẹní ṣeré ọwọ́ lásán ló rí fáwọn tó ń fi ìṣekúṣe ṣeré lórí kọ̀ǹpútà láti máa báwọn ọmọdé tó ti kó sí akóló wọn sọ̀rọ̀, wàhálà kékeré kọ́ ló ń dá sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ wọn á fẹ́ láti bá àwọn ọmọdé náà sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù. Wọ́n sábà máa ń bá àwọn ọmọ náà sọ ọ̀rọ̀ tá á mú kí wọ́n fẹ́ láti ṣe ìṣekúṣe lórí tẹlifóònù, wọ́n á sì fàdéhùn síbi tí wọ́n ti lè ní ìbálòpọ̀ gidi pẹ̀lú àwọn ọmọdé náà.”

Báwọn tó ń fi ìṣekúṣe ṣeré lórí kọ̀ǹpútà ṣe máa ń ṣe é ni pé wọ́n sábà máa ń fún àwọn ọmọdé náà ní nọ́ńbà tẹlifóònù wọn. Bí ọmọ ẹ bá sì pè wọ́n pẹ́nrẹ́n, wọ́n á rí nọ́ńbà tọmọ ẹ lórí tẹlifóònù wọn. Àwọn míì lára wọn ní àwọn nọ́ńbà téèyàn kì í sanwó fún tàbí kí wọ́n san owó tó bá fi pè wọ́n. Àwọn míì tí ẹ ti fi tẹlifóònù alágbèékà ránṣẹ́ sírú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ rí. Wọ́n tiẹ̀ lè fi lẹ́tà, fọ́tò, àtàwọn ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí i.

Kì í ṣàwọn ọmọdé nìkan ló ń kó sí páńpẹ́ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì yìí o. Láìpẹ́ yìí, ọkùnrin kan sọ ọ̀rọ̀ dídùn tó mọ̀ pé àwọn obìnrin á fẹ́ láti gbọ́, àwọn obìnrin mẹ́fà láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì gbà sọ́wọ́ kan náà pé àwọn á fẹ́ ẹ. Ọ̀kan lára wọn, Cheryl, arẹwà ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tó ń kàwé láti gboyè kejì ní yunifásítì sọ pé: “Mi ò tiẹ̀ mọ bí mi ò bá ṣe ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ọ̀hún. Ó mú mi lára gan-an ni.”

Jenny Madden, tó jẹ́ olóòtú ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan tó ń jẹ́ Àwọn Obìnrin Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, sọ pé: “Ó rọ àwọn obìnrin lọ́rùn láti máa báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, nítorí pé kò sẹ́ni tá á wo bí wọ́n ṣe rí kó tó pinnu bóyá òun máa fẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n ó tún lè rọrùn fáwọn èèyàn láti tàn wọ́n jẹ, nítorí pé ó ṣeé ṣe, pàápàá láwọn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kéèyàn yára sọ àṣírí púpọ̀ nípa ara ẹ̀.”

Nígbà táwọn tó ń ṣèwádìí fún ilé ìwé gíga University of Florida, tí Beatriz Avila Mileham jẹ́ aṣáájú wọn béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin kan, ó sọ pé: “Kí n kàn ṣáà ti ṣí kọ̀ǹpútà mi ni, kí n wá máa ṣà kí n sì máa rọ̀ lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún obìnrin.” Olóòtú náà sọ pé: “Íńtánẹ́ẹ̀tì máa tó di ibi tí àìṣòótọ́ máa pọ̀ sí jù lọ, ìyẹn bí ò bá tíì dà bẹ́ẹ̀.” Ọ̀mọ̀wé Al Cooper, olóòtú ìwé Sex and the Internet: A Guidebook for Clinicians, sọ pé: “À ń gbọ́ káàkiri orílẹ̀-èdè tí àwọn tó ń tọ́jú ara ń sọ pé bíbára ẹni fọ̀rọ̀ wérọ̀ nípa ìbálòpọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló ń fa ìṣòro tó pọ̀ jù fáwọn lọ́kọláya.”

Lójú ọ̀ràn ńlá tó délẹ̀ yìí, ó bọ́gbọ́n mu pé ká ṣọ́ra ṣe nígbà tá a bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, kó o sì kọ́ wọn bí wọn ò ṣe ní kó sínú ewu. Bí ọṣẹ́ tí Íńtánẹ́ẹ̀tì lè ṣe ò bá ṣàjèjì sí ọ, wà á lè kòòré ewu tó wà nínú lílò ó.—Oníwàásù 7:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́