Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ó Tọ̀nà Láti Máa Jọ́sìn Jésù?
LÁTI ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tó ti kọjá ni ọ̀pọ̀ àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì ti ń jọ́sìn Jésù Kristi bí ẹni pé Ọlọ́run Olódùmarè ni. Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run nìkan ni Jésù tìkára rẹ̀ yíjú sí, tó sì jọ́sìn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Èṣù ní kí Jésù jọ́sìn òun, ohun tó fi dá a lóhùn ni pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.” (Mátíù 4:10) Lẹ́yìn ìgbà náà, Jésù pa á láṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni ti ọ̀run.”—Mátíù 23:9.
Nígbà tó ń bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀, Jésù ṣàlàyé irú ìjọsìn tí olúkúlùkù gbọ́dọ̀ fún Ọlọ́run. Ìjọsìn wọn gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí wọ́n ń fi ẹ̀mí àti òtítọ́ ṣe. Àní sẹ́, “irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:23, 24) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run nìkan ló yẹ ní jíjọ́sìn. Láti jọ́sìn ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun yàtọ̀ sí Ọlọ́run jẹ́ ìbọ̀rìṣà, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Lédè Gíríìkì sì ka èyí léèwọ̀.—Ẹ́kísódù 20:4, 5; Gálátíà 5:19, 20.
Àwọn kan lè fèsì pé: ‘Ṣùgbọ́n Bíbélì kò ha sọ pé a tún gbọ́dọ̀ jọ́sìn Jésù bí? Pọ́ọ̀lù kò ha sọ nínú Hébérù 1:6 pé: “Kí gbogbo àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run máa jọ́sìn rẹ̀ [Jésù]”?’ (King James Version) Báwo la ṣe lè lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí lójú ìwòye ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbọ̀rìṣà?
Ọ̀ràn Ìjọsìn Nínú Bíbélì
Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ lóye ohun tí ìjọsìn tí Pọ́ọ̀lù lò níhìn-ín túmọ̀ sí. Ó lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà pro·sky·neʹo. Ìwé náà, Unger’s Bible Dictionary sọ pé ní ṣáńgílítí, ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ‘fífẹnu ko ọwọ́ ẹnì kan gẹ́gẹ́ bí àmì ìbọláfúnni tàbí àyẹ́sí.’ Ìwé náà, An Expository Dictionary of New Testament Words, látọwọ́ W. E. Vine, sọ pé ọ̀rọ̀ yìí “ní ìtumọ̀ bíbọlá fún ènìyàn . . . tàbí fún Ọlọ́run.” Ní àkókò kíkọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà pro·sky·neʹo sábà máa ń jẹ mọ́ títẹríba fún ẹnì kan tó wà nípò gíga.
Ronú ná nípa àkàwé tí Jésù ṣe nípa ẹrú tí kò lè san gbèsè rẹpẹtẹ tó jẹ ọ̀gá rẹ̀. Irú ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí fara hàn nínú àkàwé yìí, nígbà tí King James Version sì ń túmọ̀ rẹ̀, ó sọ pé, “nítorí náà ọmọ ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀, ó sì jọ́sìn [irú ọ̀rọ̀ náà pro·sky·neʹo] rẹ̀ [ọba], ó ń wí pé, Olúwa, mú sùúrù fún mi, èmi ó sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.” (Mátíù 18:26; ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) A ha lè fi ẹ̀sùn ìbọ̀rìṣà kan ọkùnrin yìí bí? Rárá o! Ó kàn ń bu ọlá àti ọ̀wọ̀ tó yẹ ọba, tó tún jẹ́ ọ̀gá rẹ̀ fún un ni.
Wíwárí, tàbí bíbọ̀wọ̀ fúnni lọ́nà bẹ́ẹ̀, máa ń wáyé dáadáa ní Ìlà Oòrùn lọ́hùn-ún nígbà ayé àwọn tó kọ Bíbélì. Jékọ́bù tẹrí ba lẹ́ẹ̀méje nígbà tó pàdé Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 33:3) Àwọn arákùnrin Jósẹ́fù dọ̀bálẹ̀, tàbí wọ́n wárí fún un nítorí ipò tó wà láàfin Íjíbítì. (Jẹ́nẹ́sísì 42:6) Lójú ìwòye nǹkan wọ̀nyí, yóò rọrùn fún wa láti lóye ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn awòràwọ̀ rí ọmọ jòjòló náà, Jésù, tí wọ́n pè ní “ẹni tí a bí ní ọba àwọn Júù.” Gẹ́gẹ́ bí King James Version ti tú u, àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé wọ́n “wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn [ pro·sky·neʹo] rẹ̀.”—Mátíù 2:2, 11.
Torí náà, ó ṣe kedere pé ìlò ọ̀rọ̀ náà, pro·sky·neʹo, táwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan tú sí “jọ́sìn,” kò mọ sórí kìkì irú ìbọláfúnni táa yà sọ́tọ̀ gedegbe fún Jèhófà Ọlọ́run nìkan. Ó tún lè tọ́ka sí ọ̀wọ̀ àti ọlá táa fi fún ènìyàn mìíràn. Kí àwọn èèyàn má bàa ṣi ọ̀rọ̀ yìí lóye, àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan tú ọ̀rọ̀ náà, pro·sky·neʹo, ní Hébérù 1:6 sí “júbà rẹ̀” (New Jerusalem Bible), “bọlá fún un” (The Complete Bible in Modern English), “tẹrí bá níwájú rẹ̀” (Twentieth Century New Testament), tàbí “wárí fún un” (Ìtumọ̀ Ayé Tuntun).
Jésù Tóó Wárí Fún
Ǹjẹ́ Jésù tó ẹni à ń wárí fún? Ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ! Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù, ó ṣàlàyé pé gẹ́gẹ́ bí “ajogún ohun gbogbo,” Jésù ti “jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọba Ọlọ́lá ní àwọn ibi gíga fíofío.” (Hébérù 1:2-4) Fún ìdí yìí, “orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.”—Fílípì 2:10, 11.
Lọ́nà tó pẹtẹrí, láìpẹ́ Kristi yóò lo ipò gíga rẹ̀ àti agbára tó ju agbára lọ, tí ipò yìí fún un, láti fi sọ gbogbo ilẹ̀ ayé yìí di párádísè. Lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run, àti nípasẹ̀ agbára ẹbọ ìràpadà Jésù, yóò mú ìbànújẹ́, ìrora, àti àròdùn kúrò pátápátá, fún àǹfààní àwọn tó bá tẹrí ba fún ìṣàkóso òdodo rẹ̀. Nítorí náà, kò ha yẹ ní ẹni tí à ń bọlá fún, tí à ń bọ̀wọ̀ fún, tí a sì ń ṣègbọràn sí bí?—Sáàmù 2:12; Aísáyà 9:6; Lúùkù 23:43; Ìṣípayá 21:3, 4.
“Ọlọ́run Tí Ń Béèrè Ìfọkànsìn Tí A Yà Sọ́tọ̀ Gedegbe”
Àmọ́ o, Bíbélì fi hàn kedere pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni a gbọ́dọ̀ fún ní ìjọsìn—èyíinì ni ìfọkànsìn àti ìbọláfúnni tó la ti ẹ̀sìn lọ. Mósè pè é ní “Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” Bíbélì sì gbà wá níyànjú pé ká máa “jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.”—Diutarónómì 4:24; Ìṣípayá 14:7.
Ipa tí Jésù kó nínú ìjọsìn tòótọ́ ò kéré rárá, atóóbọláfún àti atóóbọ̀wọ̀fún ni. (2 Kọ́ríńtì 1:20, 21; 1 Tímótì 2:5) Òun nìkan ṣoṣo ni ọ̀nà táa lè gbà dé ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run. (Jòhánù 14:6) Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, nìkan ṣoṣo ló yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ máa jọ́sìn.