ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bhs orí 15 ojú ìwé 154-163
  • Ọ̀nà Tó Tọ́ Láti Jọ́sìn Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Tó Tọ́ Láti Jọ́sìn Ọlọ́run
  • Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ká à ní Bíbélì Fi Kọ́ni
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀NÀ TÓ TỌ́ LÁTI JỌ́SÌN ỌLỌ́RUN
  • KÍ LO MÁA ṢE?
  • Ìjọsìn Ta Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́gbà?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Nípa Ìjọsìn Tòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ìsìn Tòótọ́?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Ìwọ Ha Ti Rí Ìsì Tí Ó Tọ̀nà Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
bhs orí 15 ojú ìwé 154-163

ORÍ KẸẸ̀Ẹ́DÓGÚN

Ọ̀nà Tó Tọ́ Láti Jọ́sìn Ọlọ́run

1. Ta ló yẹ́ kó sọ ọ̀nà tó tọ́ fún wa láti jọ́sìn Ọlọ́run?

Ọ̀PỌ̀ ẹ̀sìn ló sọ pé àwọn ń kọ́ni ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀, torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó yàtọ̀ síra làwọn ẹ̀sìn fi ń kọ́ni pé Ọlọ́run jẹ́, wọ́n tún sọ pé a lè jọ́sìn rẹ̀ ní ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Báwo la ṣe lè mọ ọ̀nà tó tọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run? Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè sọ ọ̀nà tá a lè gbà jọ́sìn òun.

2. Kí ni wàá ṣe kó o lè mọ ọ̀nà tó tọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run?

2 Jèhófà ti fún wa ní Bíbélì ká lè mọ ọ̀nà tó tọ́ láti jọ́sìn rẹ̀. Torí náà, máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Jèhófà á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jàǹfààní nínú ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ torí pé ó ń fìfẹ́ bójú tó ẹ.​—Àìsáyà 48:17.

3. Kí ni Ọlọ́run fẹ́ ká mọ̀, kí a sì ṣe?

3 Àwọn kan sọ pé gbogbo ẹ̀sìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà, àmọ́ ìyẹn kì í ṣe ohun tí Jésù kọ́ wa. Ó sọ pé: “Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ló máa wọ Ìjọba ọ̀run, àmọ́ ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Baba mi.” Torí náà, ó pọn dandan pé ka mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, ká sì máa ṣe é. Ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì o, torí pé Jésù fi àwọn èèyàn tí kò ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run wé àwọn ọ̀daràn, ìyẹn àwọn “arúfin.”​—Mátíù 7:21-23.

4. Kí ni Jésù sọ lórí ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?

4 Jésù sọ pé tá a bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, a máa dojú kọ àwọn ìṣòro. Ó sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé, torí ẹnubodè tó lọ sí ìparun fẹ̀, ọ̀nà ibẹ̀ gbòòrò, àwọn tó ń gba ibẹ̀ wọlé sì pọ̀; nígbà tó jẹ́ pé, ẹnubodè tó lọ sí ìyè rí tóóró, ọ̀nà ibẹ̀ há, àwọn díẹ̀ ló sì ń rí i.” (Mátíù 7:13, 14) Ẹnubodè tóóró yẹn, tàbí ọ̀nà tó tọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run, ló lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́ ọ̀nà tó gbòòrò tàbí ọ̀nà tí kò tọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run, ló lọ sí ìparun. Ṣùgbọ́n, Jèhófà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kú. Ó fún gbogbo èèyàn láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun.​—2 Pétérù 3:9.

Ọ̀NÀ TÓ TỌ́ LÁTI JỌ́SÌN ỌLỌ́RUN

5. Kí la lè ṣe láti mọ àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́?

5 Jésù sọ pé a lè mọ àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́. A lè mọ̀ wọ́n tá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ìwà wọn. Ó sọ pé: “Àwọn èso wọn lẹ máa fi dá wọn mọ̀.” Ó tún fi kún un pé: “Gbogbo igi rere máa ń so èso rere.” (Mátíù 7:16, 17) Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run jẹ́ ẹni pípé. Àmọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń sapá láti ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo. Ní báyìí, a máa wo ohun tó máa jẹ́ ká mọ àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́.

6, 7. Kí nìdí tí ìjọsìn tòótọ́ fi ní láti dá lórí Bíbélì? Kí ni àpẹẹrẹ Jésù kọ́ wa?

6 Ìjọsìn wa gbọ́dọ̀ dá lórí Bíbélì. Bibélì sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì wúlò fún kíkọ́ni, fún bíbáni wí, fún mímú nǹkan tọ́, fún títọ́nisọ́nà nínú òdodo, kí èèyàn Ọlọ́run lè kúnjú ìwọ̀n dáadáa, kó sì lè gbára dì pátápátá fún gbogbo iṣẹ́ rere.” (2 Tímótì 3:16, 17) Àpọ̀sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni pé: “Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ lọ́dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ èèyàn, àmọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ lóòótọ́, bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (1 Tẹsalóníkà 2:13) Ìjọsìn tòótọ́ dá lórí kìkì Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kò dá lórí èrò àwọn èèyàn àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò dá lórí àwọn ohun míì.

7 Gbogbo ohun tí Jésù fi kọ́ni dá lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ka Jòhánù 17:17.) Ó sábà máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́. (Mátíù 4:4, 7, 10) Àwọn iránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, gbogbo ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni sì máa ń dá lórí Bíbélì.

8. Àwọn nǹkan wo ni Jésù kọ́ wa nípa bá a ṣe lè jọ́sìn Jèhófà?

8 Jèhófà nìkan la gbọ́dọ̀ jọ́sìn. Sáàmù 83:18 sọ pé: “Kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.” Jésù fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ẹni tí Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́ gan-an, ó sì fi orúkọ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn. (Ka Jòhánù 17:6.) Jésù sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.” (Mátíù 4:10) Torí náà, àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. À ń jọ́sìn Jèhófà nìkan, à ń lo orúkọ rẹ̀, à ń fi orúkọ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn, a sì tún ń kọ́ wọn ní ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé.

9, 10. Báwo la ṣe máa ń fi ìfẹ́ hàn sí ara wa?

9 A ní láti nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénúdénú. Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Ka Jòhánù 13:35.) Ibi tá a ti wa, àṣà ìbílẹ̀ wa àti bóyá a jẹ́ olówó tàbí tálákà kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ yìí. Ìfẹ́ tá a ní sí ara wa ló so wa pọ̀ di arákùnrin àti arábìnrin. (Kólósè 3:14) Torí náà, a kì í jagun, a kì í sì í pààyàn. Bíbélì sọ pé: “Ohun tí a máa fi dá àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Èṣù mọ̀ nìyí: Ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe òdodo kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Ká nífẹ̀ẹ́ ara wa; kì í ṣe bíi Kéènì, tó jẹ́ ti ẹni burúkú náà, tó sì pa àbúrò rẹ̀.”​—1 Jòhánù 3:10-12; 4:20, 21.

10 A máa ń lo àkókò wa, okun wa àti àwọn ohun ìní wa láti ran ara wa lọ́wọ́ ká sì fún ara wa níṣìírí. (Hébérù 10:24, 25) A ‘máa ń ṣe rere fún gbogbo èèyàn.’​—Gálátíà 6:10.

11. Kí nìdí tá a fi gbà pé Jésù ni ọ̀nà tó lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run?

11 A ní láti ṣègbọràn sí Jésù torí òun ni ọ̀nà tó lọ̀ sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Kò sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíì, nítorí kò sí orúkọ míì lábẹ́ ọ̀run tí a fún àwọn èèyàn tí a lè tipasẹ̀ rẹ̀ rí ìgbàlà.” (Ìṣe 4:12) Ní Orí 5 ìwé yìí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà rán Jésù wá sáyé láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún àwọn èèyàn tó bá ń ṣègbọràn. (Mátíù 20:28) Jèhófà ti yan Jésù láti jẹ́ Ọba tó máa ṣàkóso lé ayé lórí. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Jésù tí a bá fẹ́ wà láàyè títí láé.​—Ka Jòhánù 3:36.

12. Kí nìdí tí a kì í fi í lọ́wọ́ sí ìṣèlú?

12 A kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìṣèlú. Jésù kò lọ́wọ́ sí ìṣèlú. Nígbà tó ń jẹ́jọ́, ó sọ fún Pílátù tó jẹ́ alákòóso Róòmù pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Ka Jòhánù 18:36.) Bíi ti Jésù, Ìjọba Ọlọ́run tó wà lọ́run là ń tì lẹ́yìn, ìdí nìyẹn tí a kì i fi lọ́wọ́ sí ìṣèlú láìka ibi tá à ń gbé sí. Àmọ́, Bíbélì pàṣẹ fún wa pé ka ṣègbọràn sí “àwọn aláṣẹ onípò gíga,” ìyẹn àwọn ìjọba ayé. (Róòmù 13:1) À máa ń ṣègbọràn sí òfin orílẹ̀-èdè tí à ń gbé. Àmọ́ tí òfin kan bá ta ko òfin Ọlọ́run, a máa ń fara wé àwọn àpọ́sítélì, tí wọ́n sọ pé: “A gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.”​—Ìṣe 5:29; Máàkù 12:17.

13. Kí là ń wàásù pé Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe?

13 A gbà gbọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú àwọn ìṣòro ayé yìí. Jésù sọ pé, a ó wàásù “ìhìn rere Ìjọba yìí” kárí ayé. (Ka Mátíù 24:14.) Kò sí ìjọba èèyàn tó lè ṣe ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún wa. (Sáàmù 146:3) Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà nípa Ìjọba Ọlọ́run nígbà tó sọ pé: “Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.” (Mátíù 6:10) Bíbélì sọ pé Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba èèyàn run, “òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.”​—Dáníẹ́lì 2:44.

14. Àwọn wo lo gbà pé wọ́n ń sin Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́?

14 Ní bàyìí tó o ti mọ àwọn kókó yìí, bi ara rẹ pé: ‘Àwọn wo ni ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni dá lórí Bíbélì? Àwọn wo ló ń sọ fún àwọn èèyàn nípa orúkọ Ọlọ́run? Àwọn wo ló ń fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn sí ara wọn tí wọ́n sì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run rán Jésù wá sáyé láti gbà wá là? Àwọn wo ni kì í lọ́wọ́ sí ìṣèlú? Àwọn wo ló ń wàásù pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú àwọn ìṣòro wa?’ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni.​—Àìsáyà 43:10-12.

KÍ LO MÁA ṢE?

15. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa?

15 A ò kàn ní gbà pé Ọlọ́run wà, torí ìyẹn nìkan ò tó. Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ wọn kì í gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu. (Jémíìsì 2:19) Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, a ò ní gbà pé Ọlọ́run wà nìkan, àá tún máa ṣe àwọn ohun tó bá fẹ́ ká ṣe.

16. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ yẹra pátápátá fún ẹ̀sìn èké?

16 Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, a gbọ́dọ̀ yẹra pátápátá fún ẹ̀sìn èké. Wòlíì Àìsáyà sọ pé: “Ẹ jáde kúrò ní àárín rẹ̀, ẹ wà ní mímọ́.” (Àìsáyà 52:11; 2 Kọ́ríńtì 6:17) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká yẹra pátápátá fún ohunkóhun tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn èké.

17, 18. Kí ni “Bábílónì Ńlá,” kí sì nìdí tó fi yẹ kó o tètè yẹra fún un?

17 Kí ni ẹ̀sìn èké? Ẹ̀sìn èké ni ẹ̀sìn èyíkéyìí tó bá ń kọ́ni láti jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tí kò bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. Bíbélì pe gbogbo ẹ̀sìn èké ní “Bábílónì Ńlá.” (Ìfihàn 17:5) Kí nìdí? Ìdí ni pé lẹ́yìn Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn èké bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Bábílónì. Àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn èké yẹn sì tàn kárí ayé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn tó ń gbé Bábílónì ń jọ́sìn oríṣiríṣi ọlọ́run mẹ́talọ́kan. Lónìí náà, ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló ń kọ́ni pé mẹ́talọ́kan ni Ọlọ́run, àmọ́ Bíbélì kọ́ni lọ́nà tó ṣe kedere pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà, ìyẹn Jèhófà, àti pé Jésù ni Ọmọ rẹ̀. (Jòhánù 17:3) Àwọn ará Bábílónì náà tún gbà gbọ́ pé téèyàn bá ti kú ohun kan wà nínú èèyàn tó máa ń wà láàyè nìṣó àti pé ohun náà lè lọ sí ọ̀run àpáàdì láti máa joró. Àmọ́, ìyẹn kì í ṣòótọ́.​—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 14, 17, àti 18.

18 Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pe gbogbo ẹ̀sìn èké pátá ló máa pa run láìpẹ́. (Ìfihàn 18:8) Ṣé o mọ ìdí tó fi yẹ kó o tètè fi ẹ̀sìn èké sílẹ̀? Ìdí ni pé Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kó o ṣe bẹ́ẹ̀ kó tó pẹ́ jù.​—Ìfihàn 18:4.

Wọ́n ń kí ọkùnrin kan káàbọ̀ sínú ẹgbẹ́ ará àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ aláyọ̀

Tó o ba dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà láti jọ́sìn rẹ̀, wàá di ara ìdílé kan tó kárí ayé

19. Tó o bá pinnu láti sin Jèhófà, báwo ló ṣe máa bójú tó ẹ?

19 Tó o bá pinnu láti fi ẹ̀sìn èké sílẹ̀, tó o sì wá sin Jèhófà, àwọn kan lára ọ̀rẹ́ rẹ tàbí ìdílé rẹ lè má mọ ìdí tó o fi ṣe ìpinnu yẹn, wọ́n sì lè mú kí ayé níra fún ẹ. Àmọ́, Jèhófà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀. Wàá dara pọ̀ mọ́ ìdílé àìmọye èèyàn tó wà kárí ayé tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, wàá sì ní ìrètí láti wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. (Máàkù 10:28-30) Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí ìdílé rẹ tó ta ko ìpinnu rẹ láti sin Jèhófà wá pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó bá yá.

20. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́?

20 Láìpẹ́, Ọlọ́run máa fi òpin sí gbogbo ìwà ibi, Ìjọba rẹ̀ sì máa ṣàkóso lé ayé lórí. (2 Pétérù 3:9, 13) Àkókò alárinrin nìyẹn sì máa jẹ́! Gbogbo èèyàn á máa jọ́sìn Jèhófà bó ṣe fẹ́ ká jọ́sìn òun. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé kó o gbé ìgbésẹ̀ báyìí, kó o sì jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́.

ÀWỌN TÓ Ń JỌ́SÌN ỌLỌ́RUN

Àwọn èèyàn tí àwọ̀ wọn, ọjọ́ orí wọn àti ipò wọ́n yàtọ̀ síra ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́
  • máa ń kọ́ni ní ohun tó dá lórí Bíbélì

  • máa ń jọ́sìn Jèhófà nìkan, wọ́n sì ń fi orúkọ rẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn

  • máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn

  • gbà gbọ́ pé Ọlọ́run rán Jésù láti gbà wá là

  • kì í lọ́wọ́ sí ìṣèlú

  • máa ń wàásù pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú àwọn ìṣòro ayé yìí

KÓKÓ PÀTÀKÌ

ÒTÍTỌ́ 1: BÍ O ṢE LÈ MỌ ÌJỌSÌN TÒÓTỌ́

“Ẹnubodè tó lọ sí ìyè rí tóóró, ọ̀nà ibẹ̀ há, àwọn díẹ̀ ló sì ń rí i.”​—Mátíù 7:14

Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìjọsìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà?

  • Mátíù 7:21-23

    Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gba gbogbo ẹ̀sìn. Kì í ṣe gbogbo ẹ̀sìn ló ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.

  • Mátíù 7:13, 14

    Ìjọsìn tòótọ́ máa yọrí sí ìyè ayérayé. Ẹ̀sìn èké máa yọrí sí ìparun ayérayé.

  • Mátíù 7:16, 17

    O lè mọ ìjọsìn tòótọ́ nípa àwọn iṣẹ́ rẹ̀. Kò dìgbà tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa gbogbo ẹ̀sìn; ṣáà ti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ.

ÒTÍTỌ́ 2: Ọ̀NÀ TÓ TỌ́ LÁTI JỌ́SÌN ỌLỌ́RUN

  • 1 Tẹsalóníkà 2:13; 2 Tímótì 3:16, 17

    Ohun tó wà nínú Bíbélì nìkan ni kó o gbà gbọ́, òun nìkan ni kó o sì máa fi kọ́ni.

  • Mátíù 4:10; Jòhánù 17:6

    Jọ́sìn Jèhófà, kí o sì máa lo orúkọ rẹ̀.

  • Jòhánù 13:35

    Ẹ máa fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn sí ara yín.

  • Jòhánù 3:36; Ìṣe 4:12

    Ṣègbọràn sí Jésù. Ọlọ́run lo Jésù láti gbà wá là.

  • Jòhánù 18:36: Ìṣe 5:29

    Má ṣe lọ́wọ́ sí ìṣèlú.

  • Mátíù 24:14; 6:10

    Máa kọ́ àwọn èèyàn pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú àwọn ìṣòro wa.

ÒTÍTỌ́ 3: O NÍ LÁTI ṢIṢẸ́ LÓRÍ OHUN TÓ O GBÀ GBỌ́

Kí lo gbọ́dọ̀ ṣe tó o bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìjọsìn rẹ?

  • Jémíìsì 2:19

    Kò yẹ kó o kàn gbà pé Ọlọ́run wà, torí ìyẹn nìkan kò tó. Ó yẹ kó o máa ṣe ohun tó sọ nínú Bíbélì.

  • Àìsáyà 52:11; Ìfihàn 17:5

    Ẹ̀sìn èké tàbí “Bábílónì Ńlá” máa ń kọ́ àwọn èèyàn láti jọ́sìn Ọlọ́run ní ọ̀nà tí Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gbà. Àwọn kan lára ẹ̀kọ́ tí ẹ̀sìn èké fi ń kọ́ni ni Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn àti iná ọ̀run àpáàdì.

  • Ìfihàn 18:4, 8

    Jèhófà máa pa gbogbo ẹ̀sìn èké run láìpẹ́. O ní láti yẹra pátápátá fún ohunkóhun tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn èké.

  • Máàkù 10:28-30

    Àwọn èèyàn lè ta kò ẹ́, àmọ́ Jèhófà kò ní fi ẹ́ sílẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́