Ẹ̀KỌ́ 10
Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ìsìn Tòótọ́?
1. Ṣé ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà?
“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké.”—MÁTÍÙ 7:15.
Ìsìn kan ṣoṣo ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn sì ni ìsìn tòótọ́. Ó dà bí ọ̀nà téèyàn lè gbà kó lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. Jésù sọ pé: ‘Àwọn díẹ̀ ló ń rí’ ọ̀nà náà. (Mátíù 7:14) Ìjọsìn tó bá Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu nìkan ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Bó ṣe jẹ́ pé ohun kan náà ni gbogbo àwọn olùjọsìn tòótọ́ gbà gbọ́, èyí mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan.—Ka Jòhánù 4:23, 24; 14:6; Éfésù 4:4, 5.
Wo Fídíò náà Ṣé Gbogbo Ẹ̀sìn Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?
2. Kí ni Jésù sọ nípa àwọn èké Kristẹni?
“Wọ́n sọ ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run, àmọ́ iṣẹ́ wọn fi hàn pé wọ́n kọ̀ ọ́.”—TÍTÙ 1:16.
Jésù kìlọ̀ pé àwọn wòlíì èké máa sọ ẹ̀sìn Kristẹni dìbàjẹ́. Wọ́n máa ń fara hàn bíi pé olùjọsìn tòótọ́ ni wọ́n. Àwọn ọmọ ìjọ wọn máa ń sọ pé Kristẹni ni àwọn. Àmọ́, o lè mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an. Lọ́nà wo? Ìjọsìn tòótọ́ nìkan ló máa ń mú kéèyàn jẹ́ Kristẹni tòótọ́ tí á sì hàn nínú ìwà àti ìṣe ẹni.—Ka Mátíù 7:13-23.
3. Báwo lo ṣe lè dá àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ mọ̀?
Wo ohun márùn-ún téèyàn lè fi dá wọn mọ̀:
Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Wọ́n máa ń sapá kí wọ́n lè fi àwọn ìlànà inú rẹ̀ sílò. Torí náà, ìsìn tòótọ́ yàtọ̀ sí àwọn ìsìn tó jẹ́ pé ọgbọ́n orí èèyàn ni wọ́n ń tẹ̀ lé. (Mátíù 15:7-9) Àwọn olùjọsìn tòótọ́ kì í sọ ohun kan kí wọ́n wá máa ṣe ohun míì.—Ka Jòhánù 17:17; 2 Tímótì 3:16, 17.
Àwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Jèhófà. Jésù bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run bó ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ náà. Ó jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ Ọlọ́run, ó sì kọ́ wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. (Mátíù 6:9) Ní àdúgbò rẹ, ẹ̀sìn wo ló ń jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run?—Ka Jòhánù 17:26; Róòmù 10:13, 14.
Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ọlọ́run rán Jésù pé kó wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba Ọlọ́run nìkan ni ọ̀nà àbáyọ fún aráyé. Títí dé ojú ikú ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 4:43; 8:1; 23:42, 43) Ó sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa wàásù Ìjọba yìí. Tí ẹnì kan bá wá bá ọ, tó sì ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ẹ̀sìn wo ni wàá sọ pé onítọ̀hún ń ṣe?—Ka Mátíù 24:14.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kì í ṣe apá kan ayé búburú yìí. Ara ohun tó o lè fi dá wọn mọ̀ ni pé wọn kì í dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú tàbí rúkèrúdò tó ń lọ láwùjọ. (Jòhánù 17:16; 18:36) Bákan náà, wọn kì í lọ́wọ́ sí àwọn àṣàkaṣà àti ìwàkiwà tó kún inú ayé.—Ka Jémíìsì 4:4.
Àwọn Kristẹni tòótọ́ ní ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún ara wọn. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo èèyàn láìka ẹ̀yà tí wọ́n ti wá sí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ara ni àwọn ẹ̀sìn èké fi ń ti àwọn orílẹ̀-èdè tó ń jagun lẹ́yìn, àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ní tiwọn. (Míkà 4:1-3) Kàkà bẹ́ẹ̀, tinútinú ni àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń lo àkókò wọn àti ohun tí wọ́n ní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kí wọ́n sì fún wọn lókun.—Ka Jòhánù 13:34, 35; 1 Jòhánù 4:20.
4. Ṣé o lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀?
Ẹ̀sìn wo ló jẹ́ pé inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni gbogbo ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni ti wá? Ẹ̀sìn wo ló ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run, tó sì ń kéde pé Ìjọba Ọlọ́run ni ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tí aráyé ní? Àwọn onísìn wo ló nífẹ̀ẹ́ ara wọn tí wọn kì í sì í lọ́wọ́ nínú ogun? Kí ni ìdáhùn rẹ?—Ka 1 Jòhánù 3:10-12.