Ẹ̀kọ́ 13
Báwo Ni O Ṣe Lè Rí Ìsìn Tòótọ́?
Gbogbo ìsìn ha ni ó dùn mọ́ Ọlọrun nínú bí, tàbí ẹyọ kan ṣoṣo ni? (1)
Èé ṣe tí ìsìn tí ń jẹ́wọ́ pé wọ́n jẹ́ Kristian fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? (2)
Báwo ni o ṣe lè mọ àwọn Kristian tòótọ́ yàtọ̀? (3-7)
1. Ìsìn Kristian tòótọ́ kan ṣoṣo ni Jesu dá sílẹ̀. Nítorí náà lónìí, ẹgbẹ́, tàbí àwùjọ, àwọn olùjọsìn Jehofa Ọlọrun kan ṣoṣo péré ni ó ní láti wà. (Johannu 4:23, 24; Efesu 4:4, 5) Bibeli kọ́ni pé àwọn ènìyàn díẹ̀ péré ni ó wà ní ojú ọ̀nà tóóró, tí ó lọ sí ìyè.—Matteu 7:13, 14.
2. Bibeli sọ tẹ́lẹ̀ pé, lẹ́yìn ikú àwọn aposteli, àwọn ẹ̀kọ́ èké àti àwọn àṣà tí kì í ṣe ti Kristian, yóò yọ́ wọnú ìjọ Kristian. Àwọn ènìyàn yóò fa àwọn onígbàgbọ́ lọ sẹ́yìn ara wọn dípò sẹ́yìn Kristi. (Matteu 7:15, 21-23; Ìṣe 20:29, 30) Ìdí nìyẹn tí a fi ń rí púpọ̀ ìsìn tí wọ́n ń jẹ́wọ́ pé àwọ́n jẹ́ Kristian. Báwo ní a ṣe lè mọ àwọn Kristian tòótọ́ yàtọ̀?
3. Àmì ìdánimọ̀ tí ó ṣe kedere jù lọ lára àwọn Kristian tòótọ́ ni pé, wọ́n ní ojúlówó ìfẹ́ láàárín ara wọn. (Johannu 13:34, 35) A kò kọ́ wọn láti ronú pé wọ́n sàn ju àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ti ẹ̀yà ìran tàbí àwọ̀ ara mìíràn. Bẹ́ẹ̀ sì ni a kò kọ́ wọn láti kórìíra àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè míràn. (Ìṣe 10:34, 35) Nítorí náà, wọn kì í lọ́wọ́ nínú ogun jíjà. Àwọn Kristian tòótọ́ máa ń bá ara wọn lò gẹ́gẹ́ bí arákùnrin àti arábìnrin.—1 Johannu 4:20, 21.
4. Àmì ìdánimọ̀ míràn lára ìsìn tòótọ́ ni pé, àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Bibeli. Wọn tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, wọ́n sì gbà ohun tí ó sọ gbọ́. (Johannu 17:17; 2 Timoteu 3:16, 17) Wọ́n ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sí ohun tí ó ṣe pàtàkì ju èrò tàbí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn lọ. (Matteu 15:1-3, 7-9) Wọ́n ń gbìyànjú láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú Bibeli nínú ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́. Nítorí náà, wọn kì í wàásù ohun kan, kí wọ́n sì ṣe òmíràn.—Titu 1:15, 16.
5. Ìsìn tòótọ́ tún gbọ́dọ̀ bọlá fún orúkọ Ọlọrun. (Matteu 6:9) Jesu sọ orúkọ Ọlọrun, Jehofa, di mímọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Àwọn Kristian tòótọ́ gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan náà. (Johannu 17:6, 26; Romu 10:13, 14) Àwọn wo ní àgbègbè rẹ ní ń sọ nípa orúkọ Ọlọrun fún àwọn ẹlòmíràn?
6. Àwọn Kristian tòótọ́ gbọ́dọ̀ wàásù nípa Ìjọba Ọlọrun. Jesu ṣe bẹ́ẹ̀. Òún máa ń sọ nípa Ìjọba náà nígbà gbogbo. (Luku 8:1) Ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti wàásù ìhìn iṣẹ́ kan náà yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé. (Matteu 24:14; 28:19, 20) Àwọn Kristian tòótọ́ gbà gbọ́ pé Ìjọba Ọlọrun nìkan ṣoṣo ni yóò mú àlàáfíà àti ààbò tòótọ́ wá sí ayé yìí.—Orin Dafidi 146:3-5.
7. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu kò gbọdọ̀ jẹ́ apá kan ayé búburú yìí. (Johannu 17:16) Wọn kì í lọ́wọ́ nínú àlámọ̀rí ìṣèlú ayé àti àríyànjiyàn ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Wọ́n ń yẹra fún àwọn ìwà, àṣà, àti ìṣarasíhùwà, tí ń pani lára, tí ó wọ́pọ̀ nínú ayé. (Jakọbu 1:27; 4:4) O ha lè dá ẹgbẹ́ ìsìn tí ó ní àwọn àmì ìdánimọ̀ ìsìn Kristian tòótọ́ wọ̀nyí mọ̀ yàtọ̀ ní agbègbè rẹ bi?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Àwọn Kristian tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n bọ̀wọ̀ fún Bibeli, wọ́n sì ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọrun