ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 4/8 ojú ìwé 20-22
  • Wọ́n Ti Gbà Báyìí Pé Àwọn Ò Gba Ẹ̀sìn Míì Láyè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Ti Gbà Báyìí Pé Àwọn Ò Gba Ẹ̀sìn Míì Láyè
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì Bẹ̀rẹ̀ sí Fìtínà Ìjọ Àgùdà
  • Ìjọ Àgùdà Bẹ̀rẹ̀ sí Fìtínà Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì
  • Fífìyà Jẹ Àwọn Aládàámọ̀
  • Ohun Tí Mary Fi Sílẹ̀ Lọ
  • Ẹ̀rí Ọkàn Tí Wọ́n Mú Kó Ṣiṣẹ́ Gbòdì
  • Ó Ṣe Wá Jẹ́ Ìsinyìí Ni Wọ́n Ń Bẹ̀bẹ̀?
  • “Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Àwọn Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Màríà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ṣé Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 4/8 ojú ìwé 20-22

Wọ́n Ti Gbà Báyìí Pé Àwọn Ò Gba Ẹ̀sìn Míì Láyè

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ

“ÀWỌN Bíṣọ́ọ̀bù Kẹ́dùn Nítorí ‘Ìwà Ọ̀daràn Tó Bùáyà’ Tí Ọbabìnrin Mary Hù,” ni àkọlé iwájú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, Catholic Herald, tó jáde ní December 11, 1998. Àwọn bíṣọ́ọ̀bù Ìjọ Àgùdà ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti àgbègbè Wales ti gbà pé “àwọn èèyàn ti hùwà ibi tó bùáyà lórúkọ Ìjọ Àgùdà, fún àpẹẹrẹ, wọ́n hùwà ìkà sí àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì nígbà Àtúnṣe ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.” Ta ni Ọbabìnrin Mary? Àwọn nǹkan burúkú wo ló dán wò tó wá fa ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ báyìí? Kí ló fà á tó fi wá jẹ́ àkókò yìí làwọn bíṣọ́ọ̀bù ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti àgbègbè Wales yàn láti sọ̀rọ̀?

Ọdún 1516, nígbà tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣì wà lábẹ́ agbára Ìjọ Àgùdà ni wọ́n bí Mary Tudor. Òun nìkan ló wà láyé nínú gbogbo ọmọ tí Catherine ti Aragon bí, ẹni tí í ṣe olorì àkọ́kọ́ tí Ọba Henry Kẹjọ fẹ́, ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Ìjọ Àgùdà ni ìyá Mary fi tọ́ ọ dàgbà. Ọmọkùnrin ni bàbá rẹ̀ fẹ́ kó jọba lẹ́yìn òun, ṣùgbọ́n Catherine ò bí ọkùnrin fún un. Níwọ̀n bí póòpù sì ti kọ̀ láti tú ìgbéyàwó Henry àti Catherine ká, ọkùnrin náà ṣe tinú ẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ tún ọ̀nà ṣe fún Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe ti Pùròtẹ́sítáǹtì láti rọ́wọ́ mú ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ní ọdún 1533, ó gbé Anne Boleyn níyàwó, lóṣù mẹ́rin ṣáájú kí Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ti Canterbury, Thomas Cranmer, tó tú ìgbéyàwó àkọ́kọ́ Henry ká.

Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Henry ṣàyà gbàǹgbà, ó fòpin sí gbogbo àjọṣe tó wà láàárín òun àti Róòmù, wọ́n sì fi í jẹ olórí pátápátá nínú Ìjọ Áńgílíkàn. Mary, tí wọ́n wá kà sí ọmọ àlè, kò tún fojú kan ìyá rẹ̀ mọ́, nítorí pé wọ́n ṣe é ní kàn-ńpá fún Catherine láti máà jáde mọ́ ní àwọn ọdún tó kẹ́yìn ayé rẹ̀.

Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì Bẹ̀rẹ̀ sí Fìtínà Ìjọ Àgùdà

Láàárín ọdún mẹ́tàlá tó tẹ̀ lé e, pípa ni wọ́n ń pa àwọn kan tí wọn ò tẹ́wọ́ gba Henry gẹ́gẹ́ bí olórí ìjọ náà àtàwọn tí wọ́n ṣì fara mọ́ àṣẹ póòpù. Henry kú ní ọdún 1547, Edward, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, tí í ṣe ọmọ olorì kẹta lára àwọn mẹ́fà tó fẹ́, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Edward àti àwọn alábàárò rẹ̀ gbìyànjú láti sọ àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì di ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ Ìjọ Àgùdà nítorí ẹ̀sìn wọn, wọ́n sì palẹ̀ àwọn ère àti pẹpẹ mọ́ kúrò nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì.

Láìpẹ́, wọ́n kásẹ̀ òfin tí wọ́n fi de títẹ Bíbélì àti kíkà á lédè Gẹ̀ẹ́sì nílẹ̀, wọ́n ní ìsìn tí wọ́n bá fẹ́ ṣe tó máa ní kíka Bíbélì nínú gbọ́dọ̀ jẹ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì dípò èdè Látìn. Àmọ́, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré ni Edward nígbà tí àrùn ikọ́ ẹ̀gbẹ pa á lọ́dún 1553. Ni wọ́n bá ní Mary loyè tọ́ sí o, bó ṣe di ọbabìnrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nìyẹn o.

Ìjọ Àgùdà Bẹ̀rẹ̀ sí Fìtínà Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì

Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn èèyàn fìfẹ́ gba Mary tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì wọlé, ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí fojú burúkú wò ó. Ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ti mọ́ àwọn tó ń jọba lé lórí lára, ṣùgbọ́n Mary ti pinnu wàyí láti tún sọ gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè náà di ọmọ Ìjọ Àgùdà. Kíá, wọ́n ti ka gbogbo ère ìsìn tí Edward ń lò léèwọ̀. Mary lọ tọrọ àforíjì fún orílẹ̀-èdè náà lọ́dọ̀ póòpù. Bí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe tún padà di ẹlẹ́sìn Ìjọ Àgùdà nìyẹn.

Nísinsìnyí tí wọ́n ti bá Róòmù rẹ́ padà, ńṣe ni inúnibíni tún bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun sí àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì. Wọ́n fi wọ́n wé eéwo tí ń fòòró ẹ̀mí tó yẹ kéèyàn tẹ ọyún inú rẹ̀ dà nù kó tó ran gbogbo ara. Ọ̀pọ̀ àwọn tó kọ̀ tí wọn ò fara mọ́ ohun tí Ìjọ Àgùdà fi ń kọ́ni ni wọ́n so mọ́gi, tí wọ́n sì dáná sun.

Fífìyà Jẹ Àwọn Aládàámọ̀

Ẹni tí wọ́n kọ́kọ́ pa lákòókò tí Mary ń jọba ni John Rogers. Ó ṣàkójọ ìwé tí a mọ̀ sí Bíbélì ti Matthew, tí wọ́n lò láti túmọ̀ ẹ̀dà King James Version. Lẹ́yìn tó wàásù lòdì sí Ìjọ Àgùdà, tó sì kìlọ̀ fún àwọn èèyàn nípa “Ìjọ Àgùdà aṣekúpani, ìbọ̀rìṣà, àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán,” wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n ọdún kan, nígbà tó sì di February 1555, wọ́n dáná sun ún lórí ẹ̀sùn àdámọ̀.

Wọ́n tún sọ pé aládàámọ̀ ni John Hooper, tí í ṣe bíṣọ́ọ̀bù ìlú Gloucester àti Worcester. Ó kéde pé ó bófin mu kí àlùfáà gbéyàwó àti pé àwọ́n gbà kí àwọn èèyàn kọ ara wọn sílẹ̀ lórí ẹ̀sùn panṣágà. Ó tún sọ pé Kristi kì í sí níbi ìsìn Máàsì nínú ara. Ńṣe ni wọ́n sun Hooper láàyè, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta kí ẹ̀mí rẹ̀ tó bọ́, ikú oró gbáà ni. Nígbà tí wọ́n fẹ́ pa Hugh Latimer, oníwàásù ẹni àádọ́rin ọdún, tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, ó fún Nicholas Ridley, tí wọ́n jọ jẹ́ Alátùn-únṣe, tí wọ́n sì jọ so mọ́gi láti dáná sun níṣìírí pé: “Ọ̀gbẹ́ni Ridley, ṣe ọkàn gírí, ṣe bí ọkùnrin. Nípa oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, wọ́n á fi wá tan iná kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lónìí, ó sì dá mi lójú pé iná náà ò ní kú láé.”

Wọ́n ṣẹjọ́ Thomas Cranmer, tí í ṣe Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà àkọ́kọ́ ti ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì ní ìlú Canterbury nígbà tí Henry àti Edward ń jọba, wọ́n ní aládàámọ̀ ni, wọ́n sì dájọ́ ikú fún òun náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó sẹ́ pé òun jẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, àmọ́ ní ìṣẹ́jú tó kẹ́yìn, lẹ́ẹ̀kan náà ló yí èrò rẹ̀ padà ní gbangba, tó bẹ̀rẹ̀ sí fi póòpù bú, tó ní ọ̀tá Kristi ni, ó wá ki ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún bọná kó lè kọ́kọ́ jóná, nítorí pé ọwọ́ ọ̀hún ló jẹ̀bi bíbuwọ́ lu ìwé tó fi sẹ́ ìgbàgbọ́.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọlọ́rọ̀ tí wọ́n jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n sá lọ sókè òkun nítorí ẹ̀mí wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rin, láàárín ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́sàn-án tó tẹ̀ lé e títí dìgbà tí Mary kú, ó kéré tán àádọ́talérúgba ó lé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [277] ènìyàn ni wọ́n so mọ́gi tí wọ́n sì dáná sun ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn èèyàn gbáàtúù pọ̀ lára àwọn tí wọ́n pa, àwọn tí ọ̀ràn náà ti sú, tí wọn ò tiẹ̀ mọ ohun tí wọn ì bá gbà gbọ́ mọ́. Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ pé láti kékeré ni wọ́n ti ń gbọ́ tí wọ́n ń bẹnu àtẹ́ lu póòpù ló wá di pé ńṣe ni wọ́n ń fìyà jẹ wọ́n nítorí pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ sí i. Àwọn mìíràn ti kọ́ láti máa ka Bíbélì fúnra wọn, wọ́n sì ti ní èrò tiwọn nípa ìsìn.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò dùn mọ́ nínú bí àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé tí wọ́n ń sun lórí igi ṣe ń kú ikú oró. Òpìtàn Carolly Erickson ṣàpèjúwe bí wọ́n ṣe ń sun wọ́n, ó wí pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, igi tútù ni wọ́n fi máa ń dá iná náà, tàbí kí wọ́n lo koríko tútù tí kò ní tètè jó. Iná kì í ran àwọn àpò ẹ̀tù ìbọn tí wọ́n so kọ́ ara àwọn tí wọ́n ń sun náà kó bàa lè dín jíjà ràpà wọn kù, tàbí kó tiẹ̀ sọ wọ́n di aláàbọ̀ ara láìpa wọ́n.” Wọn kì í di ẹnu àwọn tí wọ́n ń sun náà, nítorí “gbogbo bí wọ́n ṣe ń ké rara, tí wọ́n sì ń gbàdúrà làwọn èèyàn máa ń gbọ́ títí wọ́n fi máa gbẹ́mìí mì.”

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn wá bẹ̀rẹ̀ sí kọminú sí irú ìsìn tó jẹ́ pé sísun ló ń sun àwọn èèyàn lórí òpó káwọn èèyàn lè tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ rẹ̀. Àánú àwọn tí wọ́n ń sun náà wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn onírárà, ni wọ́n bá ń kọrin fún àwọn ajẹ́rìíkú ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì. John Foxe bẹ̀rẹ̀ sí kọ ìwé rẹ̀ Book of Martyrs, tó wá lágbára lórí àwọn Alátùn-únṣe Inú Ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì débi pé Bíbélì nìkan ló lágbára jù ú lọ. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó di ọmọ Ìjọ Àgùdà nígbà tí Mary bẹ̀rẹ̀ sí jọba ló wá padà di Pùròtẹ́sítáǹtì nígbà tí ìjọba rẹ̀ fi máa dópin.

Ohun Tí Mary Fi Sílẹ̀ Lọ

Lẹ́yìn tí Mary jọba, ó sọ pé òun á fẹ́ Philip, tí í ṣe ìbátan rẹ̀, tó tún jẹ́ àrólé ọba ilẹ̀ Sípéènì. Ọkùnrin yìí ń jọba láti ilẹ̀ òkèèrè, ọmọ Ìjọ Àgùdà hán-únhán-ún sì ni, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ò sì fẹ́ bẹ́ẹ̀. Ọ̀tẹ̀ kan táwọn Pùròtẹ́sítáǹtì sì dì láti fi ẹ̀hónú wọn hàn nípa ìgbéyàwó náà forí ṣánpọ́n, wọ́n sì rí ọgọ́rùn-ún ọlọ̀tẹ̀ pa. Philip àti Mary ṣègbéyàwó ní July 25, 1554, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Philip ò gbadé. Síbẹ̀, wọn ò bímọ, èyí ló sì fa wàhálà fún Mary, tó ń wá kí òun bí ọmọ tó máa jọba lẹ́yìn òun, táá sì jẹ́ ọmọ Ìjọ Àgùdà.

Mary di olókùnrùn, lẹ́yìn tó sì jọba fún ọdún márùn-ún péré, ó kú ní ẹni ọdún méjìlélógójì. Ìbànújẹ́ bá a dénú sàréè ni. Ọ̀rọ̀ ẹ̀ ti sú ọkọ ẹ̀, èyí tó sì pọ̀ jù lára àwọn tóbìnrin yìí jọba lé lórí ló kórìíra ẹ̀. Púpọ̀ àwọn ará ìlú London ni inú wọ́n dùn nígbà tó kú, wọ́n sì ṣe àríyá lójú pópó. Dípò kó tún Ìjọ Àgùdà ṣe, ńṣe ló mú kí ìtara òdì tó ní gbé ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ga síwájú. Ohun tó fi sílẹ̀ lọ hàn nínú orúkọ tí wọ́n mọ̀ ọ́n sí, ìyẹn ni Mary Apààyàn.

Ẹ̀rí Ọkàn Tí Wọ́n Mú Kó Ṣiṣẹ́ Gbòdì

Kí ló dé tí Mary fi pàṣẹ pé kí wọ́n finá sun àwọn èèyàn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọ́n fi kọ́ ọ pé ọ̀dàlẹ̀ làwọn aládàámọ̀ jẹ́ sí Ọlọ́run, ó sì ronú pé ó jẹ́ ojúṣe òun láti dènà ipa tí wọ́n lè ní lórí àwọn èèyàn kí wọ́n tó sọ gbogbo orílẹ̀-èdè dà bíi wọn. Ó ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ní kó ṣe, àmọ́ kò ka ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn sí, àwọn tí ẹ̀rí-ọkàn wọ́n darí wọn gba ibòmíì.

Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì pẹ̀lú ò gba ẹ̀sìn míì láyè. Lábẹ́ ìjọba Henry àti Edward, wọ́n dáná sun àwọn èèyàn nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Elizabeth Kìíní, tó jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì, tó jọba lẹ́yìn Mary sọ pé ẹní bá jẹ́ ọmọ Ìjọ Àgùdà, ọ̀dàlẹ̀ ni, ó sì lé ní ọgọ́sàn-án ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ ọmọ Ìjọ Àgùdà tí wọn pa nígbà tó ń jọba. Láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún tó tẹ̀ lé e, ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ni wọ́n tún pa nítorí ìgbàgbọ́ wọn.

Ó Ṣe Wá Jẹ́ Ìsinyìí Ni Wọ́n Ń Bẹ̀bẹ̀?

December 10, 1998, ló pé àádọ́ta ọdún tí wọ́n ṣe Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé ní Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Ẹ̀ka òfin kejìdínlógún gbà pé èèyàn “lẹ́tọ̀ọ́ sí òmìnira ìrònú, ẹ̀rí-ọkàn àti ẹ̀sìn,” ẹ̀tọ́ yìí sì kan òmìnira láti yí ẹ̀sìn ẹni padà, kéèyàn fi í kọ́ àwọn míì, kó sì máa ṣe é lọ. Àwọn bíṣọ́ọ̀bù Ìjọ Àgùdà ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti àgbègbè Wales yan àyájọ́ àádọ́ta ọdún náà bí “àkókò tó wọ̀ fún àwọn ọmọ Ìjọ Àgùdà láti yẹ ẹ̀rí-ọkàn wọn wò lórí ọ̀ràn wọ̀nyí,” kí wọ́n sì jẹ́wọ́ “ìwà ìkà tó bùáyà” tí wọ́n hù, pàápàá nígbà ayé Mary Tudor.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsinyìí ni wọ́n wá ń kẹ́dùn nítorí àwọn ìwà àìgba ẹ̀sìn míì láyè tí wọ́n hù ní nǹkan bí àádọ́talénírínwó ọdún sẹ́yìn, ṣé nǹkan tiẹ̀ ti yí padà ni? Wọn kì í sun àwọn èèyàn lórí òpó mọ́, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni ṣì ń fipá kó àwọn ẹlẹ́sìn míì, wọ́n sì máa ń pa wọ́n. Irú ìwà àìgba ẹ̀sìn míì láyè bẹ́ẹ̀ kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Àní, Jésù Kristi, tó gbé ànímọ́ Ọlọ́run yọ lọ́nà pípé, sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ọbabìnrin Mary

[Credit Line]

Láti inú ìwé A Short History of the English People

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Wọ́n dáná sun Latimer àti Ridley lórí òpó

[Credit Line]

Láti inú ìwé Foxe’s Book of Martyrs

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Cranmer rí i dájú pé ọwọ́ ọ̀tún òun ló kọ́kọ́ jóná

[Credit Line]

Láti inú ìwé The History of England (Ìwé Kìíní)

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]

Ìgbátí ìwé: 200 Decorative Title-Pages/Alexander Nesbitt/Dover Publications, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́