ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 136
  • Ṣé Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àwọn Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Màríà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ìwọ́ Ha Ti Ṣe Kàyéfì Rí Bí?
    Jí!—1996
  • Ẹ̀kọ́ Èké Karùn-ún: Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 136
Màríà pẹ̀lú Jésù nígbà tó ṣì wà ní ìkókó

Ṣé Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Rárá, Bíbélì kò sọ pé Màríà ni ìyá Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé kí àwa Kristẹni máa jọ́sìn Màríà tàbí ká máa júbà rẹ̀.a Ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé:

  • Màríà ò sọ pé òun ni ìyá Ọlọ́run. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé Màríà bí “Ọmọ Ọlọ́run,” kì í ṣe Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló bí.​—Máàkù 1:1; Lúùkù 1:32.

  • Jésù Kristi kò sọ pé Màríà ni ìyá Ọlọ́run tàbí pé ó yẹ ká máa júbà rẹ̀. Kódà, nígbà tí obìnrin kan pàfíyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí Màríà torí pé òun ló bí Jésù, ńṣe ni Jésù sọ pé: “Ó tì o, kàkà bẹ́ẹ̀, aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”​—Lúùkù 11:27, 28.

  • Àwọn ọ̀rọ̀ náà “Ìyá Ọlọ́run” àti “Theotokos” (Ẹni tó bí Ọlọ́run) kò sí nínú Bíbélì.

  • Kì í ṣe Màríà ni Bíbélì pè ní “Ọbabìnrin Ọ̀run,” òrìṣà kan táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti di apẹ̀yìndà ń jọ́sìn ni wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀. (Jeremáyà 44:15-19) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ishtar (Astarte) tó jẹ́ abo òrìṣà ilẹ̀ Bábílónì ni wọ́n ń pè ní “Ọbabìnrin Ọ̀run.”

  • Àwọn Kristẹni ayé àtijọ́ kò jọ́sìn Màríà, wọn ò sì bọlá fún un lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Òpìtàn kan sọ pé àwọn Kristẹni ayé àtijọ́ “kì í sí nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n máa bẹ̀rù pé táwọn bá bọlá fún Màríà lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, ìyẹn lè mú káwọn èèyàn máa rò pé ńṣe làwọn ń bọ̀rìṣà.”​—In Quest of the Jewish Mary.

  • Bíbélì sọ pé Ọlọ́run kò ní ìbẹ̀rẹ̀. (Sáàmù 90:1, 2; Aísáyà 40:28) Nígbà tó sì jẹ́ pé kò ní ìbẹ̀rẹ̀, a jẹ́ pé kò lè ní ìyá. Bákan náà, kò lè ṣeé ṣe fún Màríà láti lóyún Ọlọ́run sínú ikùn rẹ̀, torí Bíbélì sọ pé àwọn ọ̀run pàápàá kò lè gba Ọlọ́run.​—1 Ọba 8:27.

Ìyá Jésù ni Màríà jẹ́, kì í ṣe “Ìyá Olọ́run”

Júù ni Màríà, àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì sì ni. (Lúùkù 3:23-​31) Ọlọ́run ṣe ojú rere sí i lọ́nà gíga, torí pé ó nígbàgbọ́, ó sì ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn. (Lúùkù 1:28) Ọlọ́run ló yàn án pé kó jẹ́ ìyá Jésù. (Luke 1:31, 35) Màríà àti Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀ tún bí àwọn ọmọ mìíràn.​—Máàkù 6:3.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Màríà di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kò tún sọ nǹkan púpọ̀ mọ́ nípa rẹ̀.​—Ìṣe 1:14.

Kí nìdí táwọn kan fi ń pe Màríà ní ìyá Ọlọ́run?

Ìwádìí fi hàn pé láti apá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni làwọn èèyàn ti ń júbà Màríà torí pé ìgbà yẹn ni ẹ̀sìn Kátólíìkì di ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ abòrìṣà tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í pe ara wọn ní Kristẹni. Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yìí sì tún kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tí kò sí nínú Bíbélì.

Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan yìí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì gbà pé tó bá jẹ́ pé Jésù ni Ọlọ́run, a jẹ́ pé Màríà ni ìyá Ọlọ́run. Lọ́dún 431 Sànmánì Kristẹni, ìgbìmọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì kan nílùú Efésù kéde pé “Ìyá Ọlọ́run” ni Màríà. Lẹ́yìn ìkéde yìí, bó ṣe di pé ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara júbà Màríà nìyẹn. Báwọn tó jẹ́ abọ̀rìṣà tẹ́lẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n fi àwọn ère Màríà Wúńdíà rọ́pò abo òrìṣà ìbímọlémọ, bí Átẹ́mísì (ti àwọn ará Róòmù mọ̀ sí Diana) àti Isis.

Lọ́dún 432 Sànmánì Kristẹni, Póòpù Sixtus Kẹta pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kan sílùú Róòmù ní ìrántí “Ìyá Ọlọ́run.” Ìtòsí ilé òrìṣà Lucina, tó jẹ́ abo òrìṣà ìbímọlémọ àwọn ará Róòmù ni wọ́n kọ́ ọ sí. Nígbà tí òǹkọ̀wé kan sọ̀rọ̀ nípa ṣọ́ọ̀ṣì yìí, ó ní ó jẹ́ “ẹgbẹ́ awo Yèyé Òòṣà àwọn kèfèrí tí wọ́n sọ di ẹgbẹ́ awo Màríà lẹ́yìn táwọn ara Róòmù gba ẹ̀sìn Kristẹni.”​—Mary​—The Complete Resource.

a Àwọn ẹlẹ́sìn kan ń kọ́ni pé Màríà ni ìyá Ọlọ́run. Wọ́n tiẹ̀ máa ń pè é ní “Ọbabìnrin Ọ̀run” tàbí Theotokos, ìyẹn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “Ẹni tó bí Ọlọ́run.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́