ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 11/1 ojú ìwé 8
  • Ẹ̀kọ́ Èké Karùn-ún: Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Èké Karùn-ún: Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ijọsin Yèyé Abo-Ọlọrun Ha Ṣì Wà Sibẹ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ṣé “Ìyá Ọlọrun” Ni Maria?
    Jí!—1996
  • Ìwọ́ Ha Ti Ṣe Kàyéfì Rí Bí?
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 11/1 ojú ìwé 8

Ẹ̀kọ́ Èké Karùn-ún: Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run

Báwo ni ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? “Jíjọ́sìn ìyá Ọlọ́run di ohun tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nígbà tí . . . àwọn kèfèrí sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ wá sínú ṣọ́ọ̀ṣì. . . . Ẹ̀mí ìtara ìsìn àti ìfẹ́ [tí àwọn kèfèrí tó wá sínú ẹ̀sìn Kristẹni] ní fún ìsìn ti wà fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún látinú ẹgbẹ́ awo òrìṣà ńlá kan tó jẹ́ abo àti ‘wúńdíá àtọ̀runwá.’”—Ìwé The New Encyclopædia Britannica (1988), Ìdìpọ̀ 16, ojú ìwé 326 àti 327.

Kí ni Bíbélì sọ? ‘Ìwọ ó lóyún ní inú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní JÉSÙ. Òun ó pọ̀, Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ ni a ó sì máa pè é: . . . Nítorí náà, ohun mímọ́ tí á ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é.’—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa; Lúùkù 1:31-35, Bibeli Ajuwe.

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ ní kedere pé Màríà jẹ́ ìyá “Ọmọ Ọlọ́run,” kì í ṣe ìyá Ọlọ́run. Ṣé Màríà lè ní oyún Ẹni tí “àwọn ọ̀run kò lè gbà”? (1 Àwọn Ọba 8:27) Màríà kò fìgbà kankan sọ pé òun ni ìyá Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ni kò jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ irú ẹni tí Màríà jẹ́. Ibi Àpérò tó wáyé nílùú Éfésù lọ́dún 431 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ti pe Màríà ní Theotokos, (ìyẹn, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “Ẹni tí ó bí Ọlọrun”), tàbí “Ìyá Ọlọ́run,” ìyẹn ló sì jẹ́ kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Màríà. Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn èèyàn ti máa ń pàdé pọ̀ láti bọ̀rìṣà ní ìlú Éfésù níbi tí àpérò àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yìí ti wáyé, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń jọ́sìn Átẹ́mísì, abo òrìṣà ọlọ́mọyọyọ.

Torí náà, onírúurú ààtò ìjọsìn tí wọ́n máa ń ṣe fún ère Átẹ́mísì tí wọ́n gbà pé “ó jábọ́ láti ọ̀run,” irú bí ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ rìn ni wọ́n mú wọnú ìjọsìn Màríà. (Ìṣe 19:35) Àṣà míì tí wọ́n tún dọ́gbọ́n mú wọnú ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni ni lílo ère Màríà àtàwọn ère míì nínú ìjọsìn.

Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wéra: Mátíù 13:53-56; Máàkù 3:31-35; Lúùkù 11:27, 28

ÒKODORO ÒTÍTỌ́:

Màríà jẹ́ ìyá Ọmọ Ọlọ́run, kì í ṣe ìyá Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ èké nípa Mẹ́talọ́kan ló jẹ́ kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Màríà gẹ́gẹ́ bí Ìyá Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́