ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 7/1 ojú ìwé 5-7
  • Ijọsin Yèyé Abo-Ọlọrun Ha Ṣì Wà Sibẹ Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ijọsin Yèyé Abo-Ọlọrun Ha Ṣì Wà Sibẹ Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Atẹmisi Ti Efesu
  • Lati ori Yèyé Abo-Ọlọrun si “Iya Ọlọrun”
  • Ijọsin Yèyé Abo-Ọlọrun Ṣì Wà Sibẹ
  • Ìlú Tí Ìjọsìn Tòótọ́ àti Ìbọ̀rìṣà Ti Forí Gbárí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ẹ̀kọ́ Èké Karùn-ún: Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ṣé Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Lati Ori Yèyé Ayé Si Awọn Abo-Ọlọrun Ọlọ́mọyọyọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 7/1 ojú ìwé 5-7

Ijọsin Yèyé Abo-Ọlọrun Ha Ṣì Wà Sibẹ Bi?

IJỌSIN yèyé abo-ọlọrun ni a ṣì nṣe sibẹ lakooko ọjọ awọn Kristian ijimiji. Apọsteli Pọọlu pade rẹ ni Efesu ni Asia Kekere. Gẹgẹ bi o ti ri ni Atẹni, ilu miiran ti a ti njọsin abo-ọlọrun, oun ti jẹrii si “Ọlọrun naa ti o dá aye,” Ẹlẹdaa alaaye, ẹni ti ko “dabi wura, tabi fadaka, tabi okuta, ti a fi ọgbọn ati imọ eniyan ṣe ni ọnà.” Eyi ti pọ ju fun awọn ara Efesu lati mu mọra, ọpọjulọ awọn ti njọsin yèyé abo-ọlọrun naa Atẹmisi. Awọn wọnni ti wọn wá ọna atijẹ nipa ṣiṣe awọn ojubọ onifadaka ti abo-ọlọrun naa ru irukerudo soke. Fun nǹkan bi wakati meji, ogunlọgọ naa nkigbe pe: “Titobi ni Atẹmisi ti awọn ara Efesu!”—Iṣe 17:24, 29; 19:26, 34, New World Translation.

Atẹmisi Ti Efesu

Awọn Giriiki pẹlu njọsin Atẹmisi kan, ṣugbọn Atẹmisi ti a njosin ni Efesu ni ko fi bẹẹ bá a tan. Atẹmisi Giriiki jẹ wundia abo-ọlọrun ọdẹ ṣiṣe ati ọmọ bíbí. Atẹmisi Efesu jẹ abo-ọlọrun ọlọ́mọyọyọ. Tẹmpili gàgàrà rẹ ni Efesu ni a ka si ọkan lara awọn ohun iyanu meje ni aye. Ere iranti rẹ, ti a ronu pe o jábọ́ lati ọrun, fi i han gẹgẹ bi apẹẹrẹ pipe ọlọ́mọyọyọ, àyà rẹ ni o kun fun itotẹlera awọn ọmú ti o ni irisi ẹyin. Aworan ti o ṣajeji niti awọn ọmú wọnyi ti gbe oniruuru awọn alaye dide, iru gẹgẹ bi pe wọn duro fun awọn iṣupọ ẹyin tabi hórópọ̀n awọn akọ maluu paapaa. Ohun yoowu ki o jẹ alaye naa, ami ọlọ́mọyọyọ ṣekedere.

Lọna ti o gbani lafiyesi, gẹgẹ bi The New Encyclopædia Britannica ti wi, ere iranti ipilẹṣẹ abo-ọlọrun yii “ni a fi wura, ehin erin, fadaka, ati okuta dudu ṣe.” Ere iranti Atẹmisi ti Efesu ti a mọ daradara, ti o pẹ sẹhin to ọrundun keji, fi i han pẹlu oju, awọn ọwọ, ati ẹsẹ dudu.

Ere Atẹmisi ni a gbe kiri la aarin awọn opopona já. Ọmọwe akẹkọọ Bibeli jinlẹ R. B. Rackham kọwe pe: “Laaarin tẹmpili [Atẹmisi naa ni a] tọju . . . awọn ere, ojubọ, ati awọn ohun eelo mimọ rẹ si, wura ati fadaka, eyi ti a gbe lọ sinu ilu ti a si gbé pada ni itolọwọọwọ oniyẹbẹyẹbẹ nigba awọn ajọdun nla.” Awọn ajọdun wọnyi fa ọgọrọọrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun awọn arinrin-ajo isin lati gbogbo Asia Kekere mọra. Wọn ra awọn ojubọ kekere ti abo-ọlọrun naa wọn si yin in gẹgẹ bi ẹni titobi, iyalode wọn, ọbabinrin naa, wundia naa, “ẹni ti nfetisi ti o si ngbọ awọn adura.” Ni iru awọn ayika bẹẹ, o gba igboya fun Pọọlu ati awọn Kristian ijimiji lati gbe “Ọlọrun naa ti o da aye,” ga dipo awọn ọlọrun ati abo-ọlọrun ti a fi “wura tabi fadaka, tabi okuta,” ṣe.

Lati ori Yèyé Abo-Ọlọrun si “Iya Ọlọrun”

Awọn alagba ijọ Kristian ti Efesu ni apọsteli Pọọlu sọ asọtẹlẹ ipẹhinda fun. O kilọ fun wọn pe awọn apẹhinda yoo dide wọn yoo si sọ ‘ọrọ odi.’ (Iṣe 20:17, 28-30) Laaarin awọn ewu ti wọn nlugọ ṣáá ni Efesu ni ipada si ijọsin yèyé abo-ọlọrun. Eyi ha ṣẹlẹ niti gidi bi?

A ka ninu New Catholic Encyclopedia pe: “Gẹgẹ bi ibi irin ajo isin kan, Efesu ni a ka si ọgangan iboji [apọsteli] Johanu. . . . Igbagbọ atọwọdọwọ miiran, ti Igbimọ Efesu (431) jẹrii si, so Maria Wundia Olubukun pọ pẹlu Johanu Mimọ. Basilica ninu eyi ti Igbimọ yii ti jokoo ni a pe ni Ṣọọṣi Maria.” Iṣẹ Katoliki miiran (Théo—Nouvelle encyclopédie catholique) sọ nipa “ẹkọ atọwọdọwọ ti o jọ otitọ” kan pe Maria tẹle Johanu lọ si Efesu, nibi ti o ti lo iyoku igbesi-aye rẹ. Eeṣe ti ohun ti wọn ro pe o jẹ isopọ laaarin Efesu ati Maria yii fi ṣe pataki fun wa lonii?

Jẹ ki The New Encyclopædia Britannica dahun: “Ibọwọ jijinlẹ fun iya Ọlọrun gba ifunlokun rẹ nigba ti Ṣọọṣi Kristian di ṣọọṣi ọba labẹ Constantine awọn gbáàtúù eniyan ti wọn jẹ keferi si wọ́ lọ sinu ṣọọṣi naa. . . . Ẹmi isin ati imọlara onisin wọn ni wọn ti mu dagba fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun nipasẹ ẹgbẹ awo ti yèyé abo-ọlọrun ‘iyan nla’ ati ‘wundia atọrunwa,’ imudagba kan ti o ti pẹ́ sẹhin lati igba awọn isin olokiki atijọ ti Babiloni ati Asiria.” Nibo ni o tun le dara fun ‘sisọ ijọsin yèyé abo-ọlọrun di isin Kristian’ ju Efesu lọ?

Nipa bayii, ni Efesu, ni 431 C.E., ni awọn ti a npe ni igbimọ kẹta ti iṣọkan isin Kristian kari aye pe Maria ni “Theotokos,” ọrọ Giriiki kan ti o tumọ si “Ẹni ti o bí Ọlọrun,” tabi “Iya Ọlọrun.” New Catholic Encyclopedia wipe: “Ilo orukọ oye yii nipasẹ ṣọọṣi ni o pinnu idagba ẹkọ igbagbọ ati ifọkansin Maria ni awọn ọrundun ti o tẹle e laisi iyemeji.”

Awoku “Ṣọọṣi Maria Wundia,” nibi ti igbimọ yii ti pade pọ, ni a ṣi le ri lonii ni ibi ilẹ Efesu igbaani. A tun le ṣebẹwo si ile isin kekere kan ti o jẹ, gẹgẹ bi ẹkọ atọwọdọwọ kan ti wi, ibi ti Maria gbé ti o si kú si. Pope Paul Kẹfa ṣebẹwo si awọn ojubọ Maria wọnyi ni Efesu ni 1967.

Bẹẹni, Efesu ni ọgangan apafiyesi fun iyipada ijọsin yèyé abo-ọlọrun oloriṣa, iru eyi ti Pọọlu ba pade ni ọgọrun un ọdun kìn-ínní, si ifọkansin onigboonara fun Maria gẹgẹ bi “Iya Ọlọrun.” O jẹ ni pataki nipasẹ ifọkansin si Maria ni ijọsin yèyé abo-ọlọrun fi la a já ninu awọn ilẹ Kristẹndọm.

Ijọsin Yèyé Abo-Ọlọrun Ṣì Wà Sibẹ

Encyclopædia of Religion and Ethics tọka si ọmọwe akẹkọọ Bibeli jinlẹ W. M. Ramsay gẹgẹ bi ẹni ti nṣalaye pe ni “ọrundun karun un ọla ti a bu fun Maria Wundia ni Efesu jẹ iru [imudọtun] ti ijọsin Iya Wundia oloriṣa atijọ ti Anatolia.” The New International Dictionary of New Testament Theology wipe: “Awọn igbagbọ Katoliki nipa ‘iya ọlọrun’ ati nipa ‘ọbabinrin ọrun,’ bi o tilẹ jẹ pe o pẹ ju M[ajẹmu] T[itun], tọka si awọn ipilẹṣẹ isin ati itan ti o pẹ sẹhin daradara ni Ila-oorun. . . . Ninu ibọwọ jijinlẹ fun Maria lẹhin naa ọpọlọpọ itọsẹ awo oloriṣa ti yèyé ọrun ni wọn wa.”

Awọn itọsẹ wọnyi ti pọ ju wọn si ti mu kulẹkulẹ lọwọ ju lati jẹ èèṣì. Ifarajọra laarin awọn ere iranti tọmọtiya ti o jẹ ti Maria Wundia ati ti awọn ere iranti abo-ọlọrun oloriṣa, iru bii Isis, ni a ko le ṣai kiyesi. Ọgọrọọrun awọn ere iranti ati ere isin ti Madonna Dudu ninu awọn ṣọọṣi jakejado aye ko le kuna lati mu ere iranti Atẹmisi wa sọkan. Iṣẹ naa Théo—Nouvelle encyclopédie catholique sọ nipa awọn Wundia Dudu wọnyi pe: “Wọn farahan lati jẹ ọna gbigbe ohun ti o ṣẹku ninu ifọkansin olokiki si Diana [Atẹmisi] . . . tabi Cybele fun Maria.” Awọn itolọwọọwọ Ọjọ Igbasoke ti Maria Wundia tun ri àwòṣe wọn ninu awọn itolọwọọwọ ni ibọla fun Cybele ati Atẹmisi.

Awọn orukọ oye gan an ti a fi fun Maria ran wa leti awọn yèyé abo-ọlọrun oloriṣa. Ishtar ni a yin gẹgẹ bi “Wundia Mimọ,” “Iyalode mi,” ati “iya alaaanu ti nfetisilẹ si adura.” Isis ati Asitate ni a pe ni “Ọbabinrin Ọrun.” Cybele ni a pe ni “Iya gbogbo awọn Olubukun.” Gbogbo awọn orukọ oye wọnyi, pẹlu awọn iyatọ fẹẹrẹfẹ ni a lò fun Maria.

Vatican Keji fun awo “Wundia Olubunkun” niṣiiri. Pope John Paul Keji ni a mọ daradara fun ifọkansin onigboona ọkan fun Maria. Lakooko awọn irin ajo gbigbooro rẹ, ohun ko tii tase anfaani kan lati bẹ awọn ojubọ Maria wo, papọ pẹlu ti Madonna Dudu ti Czestochowa, ni Poland. O fi gbogbo aye le Maria lọwọ. Nitori naa, ko yanilẹnu pe labẹ “Yèyé Abo-Ọlọrun,” The New Encyclopædia Britannica kọwe pe: “Ede isọrọ naa ni a tun ti lo fun awọn irisi ẹda oniruuru bii awọn ti a npe ni awọn Venus Ọdun Gbánhan ati Maria Wundia.”

Ṣugbọn ibọwọ jijinlẹ fun Maria ni iha ọdọ awọn Roman Katoliki kii ṣe ọna kanṣoṣo ti ijọsin yèyé abo-ọlọrun ti wa titi di ọjọ wa. O runi lọkan soke pe, awọn alatilẹhin ajọ ominira awọn obinrin ti pese ọpọ awọn iwe ikẹkọọ lori ijọsin awọn yèyé abo-ọlọrun. Wọn gbagbọ pe awọn obinrin ni a ti nilara kikankikan ninu aye ti awọn okunrin ti nfipa jẹ gàba lé awọn obinrin lori yii ati pe ijọsin ti a dari si obinrin fi iyanhanhan araye han fun aye kan ti o ṣe pẹlẹ. Wọn tun farahan lati gbagbọ pe lonii aye yoo dara ju yoo si jẹ alalaafia bi o ba ni itẹsi ọkan fun abo.

Bi o ti wu ki o ri, ijọsin yèyé abo-ọlọrun ko mu alaafia wa ni aye igbaani, ko si ni mu un wa lonii. Siwaju sii, awọn eniyan pupọpupọ si lonii, nitootọ araadọta ọkẹ ti wọn ndarapọ mọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni idaniloju pe ilẹ-aye ni a ko ni gbala nipasẹ Maria, bi o ti wu ki wọn bọwọ fun un ki wọn si nifẹ rẹ tó gẹgẹ bi obinrin oluṣotitọ ọgọrun un ọdun kìn-ínní ti o ni anfaani agbayanu ti bibi ati titọ Jesu dagba. Bẹẹ si ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ko gbagbọ pe Ajọ Ẹgbẹ Ominira Obinrin le mu aye alalaafia wa, bi o tilẹ jẹ pe diẹ ninu awọn ohun ti wọn beere fun ni a le dá lare. Fun iyẹn wọn wo Ọlọrun naa ti Pọọlu polongo fun awọn ara Atẹni ati awọn ara Efesu, “Ọlọrun naa ti o dá aye ati ohun gbogbo ti nbẹ ninu rẹ.” (Iṣe 17:24; 19:11, 17, 20) Ọlọrun Olodumare yii, ẹni ti orukọ rẹ njẹ Jehofa, ti ṣeleri aye titun ologo kan ninu eyi ti “ododo ngbe,” awa si le fi igbọkanle gbarale ileri rẹ.—2 Peteru 3:13.

Niti oju-iwoye Bibeli lori ipo obinrin niwaju Ọlọrun ati eniyan, koko ẹkọ yii ni a o sọrọ le lori siwaju sii ninu iwe-irohin yii.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

AṢITORẸTI abo-ọlọrun ibalopọ takọtabo ati ogun ti Kenani

[Credit Line]

Musée du Louvre, Paris

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

ATẸMISI Abo-ọlọrun ọlọ́mọyọyọ ti Efesu

[Credit Line]

Musei dei Conservatori, Rome

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“IYA ỌLỌRUN” ti Kristẹndọm

[Credit Line]

Chartres Cathedral, France

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́