Lati Ori Yèyé Ayé Si Awọn Abo-Ọlọrun Ọlọ́mọyọyọ
IWỌ HA dá aworan abo-ọlọrun tí ó wà lẹhin iwe-irohin yi mọ bi? Oun ni Isis, yèyé abo-ọlọrun igbaani ti Ijibiti. Bi iwọ ba ti ṣebẹwo si ile akojọ ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tabi ṣayẹwo iwe kan lori itan igbaani, ó ṣeeṣe ki o ti ri awọn oriṣa ti wọn farajọ eyi. Ṣugbọn gbé eyi yẹwo: Iwọ yoo ha fori balẹ fun ki o si jọsin abo-ọlọrun naa Isis bi?
Bi iwọ ba jẹ́ mẹmba ọkan lara awọn isin Kristẹndọm, iyẹn le dabi ibeere yiyanilẹnu kan. O ṣeeṣe ki iwọ rinkinkin pe iwọ njọsin Ẹlẹdaa naa, Ẹni naa ti a ndari ọrọ naa si pe, “Baba wa ti nbẹ ni ọrun.” (Matiu 6:9) Ero ti fifori balẹ fun yèyé abo-ọlọrun le dabi eyi ti o ṣajeji, ani ki o tilẹ kóní ní ìríra. Laika eyiini si, iru ijọsin abo-ọlọrun ti tankalẹ jalẹjalẹ itan, a si le ya ọ lẹnu gidigidi lati mọ awọn ẹni naa gan an ti njọsin yèyé abo-ọlọrun nla naa lonii.
Bi o ti wu ki o ri, ṣaaju ki a tó jiroro iyẹn, ẹ jẹ ki a ní isọfunni ipilẹ diẹ nipa ṣiṣe agbeyẹwo ibi ti ijọsin yèyé abo-ọlọrun ni igba atijọ gbooro dé. Iru ijọsin yii farahan lati jẹ ẹ̀yà isin eke akọkọbẹrẹ kan. Awọn ere iranti kekeke ati ere awọn yèyé abo-ọlọrun ti wọn wà ní ìhòhò ni awọn awalẹpitan ti hú jade ni awọn ibi ilẹ igbaani jakejado Europe ati lati awọn ilẹ Mediterranean si India.
Yèyé Aye ni a kasi orisun ti kii yẹ̀ fun gbogbo oniruuru iwalaaye, ti nfunni ni iye ti o si ngba a pada sọdọ araarẹ nigba iku wọn. Gẹgẹ bii bẹẹ, oun ni a jọsin ti a si bẹru nigba kan naa. Lakọọkọ ná, awọn eniyan gbà á gbọ́ ni ipilẹṣẹ pe, awọn agbara ibimọ rẹ jẹ eyi ti ko ni ibalopọ takọtabo ninu. Lẹhin naa, gẹgẹ bi ẹkọ arosọ atọwọdọwọ ti wí, ó bi Baba Oju-ọrun ti o jẹ akọ ó sì di aya rẹ. Tọkọtaya yii mu àìlóǹkà awọn ọlọrun ati abo-ọlọrun miiran jade.
Àwòṣe Babiloni Naa
Ninu awọn ọlọrun ti a mọ dunju ni Babiloni, Ishtar jẹ abo-ọlọrun pataki, ti o baramu pẹlu Innanna abo-ọlọrun ọlọ́mọyọyọ ti Sumeria. Lọna ti o takora, oun jẹ abo-ọlọrun ogun ati abo-ọlọrun ifẹ ati ibalopọ takọtabo onífàájì. Ninu iwe rẹ Les Religions de Babylonie et d’Assyrie (Awọn Isin Babiloni ati ti Asiria), ọmọwe ara Faranse Édouard Dhorme wi nipa Ishtar pe: “Ó jẹ́ abo-ọlọrun naa, iyalode naa, iya aanu naa ti nfetisilẹ si adura ti o si nṣipẹ niwaju awọn ọlọrun ti nbinu ti o si ńrọ̀ wọn. . . . Oun ni a gbega bori gbogbo awọn ọlọrun, o di abo-ọlọrun awọn abo-ọlọrun, ayaba gbogbo awọn ọlọrun, ọba alaṣẹ awọn ọlọrun ni ọrun ati ni ilẹ-aye.”
Awọn olujọsin Ishtar pè é ni “Wundia naa,” “Wundia Mimọ,” ati “Iya Wundia.” “Adura Ìpohùnréré si Ishtar” ti awọn ara Sumeria ati Akkadia wipe: “Mo gbadura si ọ, óò ìyálóde awọn ìyálóde, abo-ọlọrun awọn abo-ọlọrun. Óò Ishtar, ọbabinrin gbogbo awujọ eniyan. . . . Iwọ ti o ni gbogbo agbara atọrunwa, ti o dé ade agbara ijọba. . . . Awọn ile ijọsin kekeke, awọn ibi mimọ, awọn ibi ilẹ mimọ, ati awọn ojubọ nfun ọ ni afiyesi. . . . Nibo ni a kò ti ṣafarawe irisi rẹ? . . . Wò mi óò ìyálóde mi; gbọ́ awọn adura mi.”a
Ijọsin Yèyé Abo-Ọlọrun Tànkálẹ̀
Ọjọgbọn nipa awọn eniyan ara Gabasi Édouard Dhorme sọrọ nipa “imugbooro ijọsin Ishtar.” Ó tankalẹ jakejado Mesopotamia, ati yala Ishtar funraarẹ tabi awọn abo-ọlọrun ti wọn ni orukọ ọtọọtọ ṣugbọn ti wọn ni awọn iwa ẹyẹ ti o farajọra ni a nsin ni Ijibiti, Phoenicia, ati Canaan, ati pẹlu ni Anatolia (Asia Kekere), Greece, ati Italy.
Olori yèyé abo-ọlọrun ti a njọsin ni Ijibiti ni Isis. Opitan H. G. Wells kọwe pe: “Isis fa ọpọlọpọ awọn olufọkansin mọra, ti wọn fi ẹmi wọn jẹ́jẹ̀ẹ́ fun. Awọn ere rẹ ni a gbékalẹ̀ ninu tẹmpili, ti a fi ade dé gẹgẹ bi Ọbabinrin Ọrun ti o si gbé ọmọ kekere jòjòló naa Horus sọwọ rẹ. Awọn àbẹ́là njo bùlàbùlà ti atẹgun si nfẹ ẹ niwaju rẹ, awọn ẹbọ ẹ̀jẹ́ ti a fi ìda ṣe ni a sì gbé kọ ojubọ naa.” (The Outline of History) Ijọsin Isis gbajumọ gidigidi ni Ijibiti. O tun tànkálẹ̀ jakejado agbegbe Mediterranean, ni pataki de Greece ati Roomu, o tilẹ de iha iwọ-oorun ati iha ariwa Europe paapaa.
Ni Phoenicia ati Canaan, ijọsin yèyé abo-ọlọrun kó afiyesi jọ sori Aṣtorẹti, tabi Asitate, ti a sọ pe o jẹ aya Baali. Bi Ishtar, alabaadọgba rẹ ti Babiloni, oun jẹ abo-ọlọrun ọlọ́mọyọyọ ati ti ogun papọ. Ni Ijibiti, awọn ikọwe igbaani ni a ti ri ninu eyi ti a ti pe Asitate ni iyalode ọrun ati ọbabinrin awọn ọrun. Awọn ọmọ Isirẹli nilati ja lemọlemọ lodisi agbara idari arẹniwalẹ ti ijọsin abo-ọlọrun ọlọ́mọyọyọ yii.
Si iha ariwa iwọ-oorun ni Anatolia, eyi ti o ṣe rẹgi pẹlu Ishtar ni Cybele, ti a mọ si Iya Nla awọn ọlọrun. A tun npe e ni Ẹni ti o bí gbogbo eniyan, Ẹni ti Nfun Gbogbo Eniyan Lounjẹ, Iya gbogbo awọn ti a Bukun. Lati Anatolia ẹgbẹ awo Cybele tànkálẹ̀ lakọọkọ lọ si Greece ati lẹhin naa lọ si Roomu, nibi ti o ti nbaa lọ lati wà titi wọnu Sanmani Tiwa. Ijọsin abo-ọlọrun ọlọ́mọyọyọ yii ni ijó asinwin ninu, yiya ara ẹni pátipàti lati ọwọ awọn alufaa, ìtẹ ara ẹni lọ́dàá ti awọn olunaga fun ipo alufaa, ati itolọwọọwọ ninu eyi ti a ti gbé ere iranti abo-ọlọrun ninu ọpọrẹpẹtẹ ogo ẹwa.b
Awọn Giriiki ipilẹṣẹ jọsin abo-ọlọrun Yèyé Ayé kan ti a npe ni Gaea. Ṣugbọn ọlọrun amọdunju wọn wá ní awọn abo-ọlọrun iru ti Ishtar ninu, iru bii Aphrodite, abo-ọlọrun ọlọ́mọyọyọ ati ifẹ; Athena, abo-ọlọrun ogun; ati Demeter, abo-ọlọrun ohun ọ̀gbìn.
Ni Roomu, Venus ni abo-ọlọrun ifẹ ati gẹgẹ bii bẹẹ, ó ṣe rẹgi pẹlu Aphrodite ti Giriiki ati Ishtar ti Babiloni. Bi o ti wu ki o ri, awọn ara Roomu, tun jọsin awọn abo-ọlọrun Isis, Cybele, ati Minerva (Athena Giriiki), gbogbo awọn ti wọn fi awoṣe Ishtar Babiloni han ni ọna kan tabi omiran.
Ni kedere, fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun, ijọsin yèyé abo-ọlọrun jẹ́ orogún ijọsin mimọgaara ti Ẹlẹdaa nla naa, Jehofa. Njẹ ijọsin yèyé abo-ọlọrun nla ha ti parẹ kuro bi? Tabi o ha ti là á já titi di ọjọ oni bi? Jọwọ maa ba kika lọ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ancient Near Eastern Texts, ti a tunṣe fun titẹ lati ọwọ James B. Pritchard, Princeton University Press, oju-iwe 383-4.
b Abo-ọlorun ọlọ́mọyọyọ miiran ti a nsin ni Asia Kekere ni Atẹmisi ti Efesu, eyi ti a o gbéyẹwo ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
ISHTAR ti Babiloni ti a fihan gẹgẹ bii irawọ
[Credit Line]
Courtesy of The British Museum
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
ISIS ti Ijibiti pẹlu ọlọrun ọmọ kekere jòjòló Horus
[Credit Line]
Musée du Louvre, Paris