ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 12/15 ojú ìwé 26-29
  • Ìlú Tí Ìjọsìn Tòótọ́ àti Ìbọ̀rìṣà Ti Forí Gbárí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìlú Tí Ìjọsìn Tòótọ́ àti Ìbọ̀rìṣà Ti Forí Gbárí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àgbègbè Tó Wọ Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lójú
  • Ìjọsìn Tòótọ́ àti Ìbọ̀rìṣà Forí Gbárí
  • Ìparun Tẹ́ńpìlì Átẹ́mísì Kù sí Dẹ̀dẹ̀
  • “Ìyá Ọlọ́run” Lọ̀rọ̀ Tún Kàn
  • Ìjọsìn Átẹ́mísì Dohun Ìgbàgbé
  • A Rìn Yíká Àwókù Ìlú Éfésù
  • Ijọsin Yèyé Abo-Ọlọrun Ha Ṣì Wà Sibẹ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Gbilẹ̀ Nìṣó, Ó sì Ń Borí” Lójú Àtakò
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ẹ̀kọ́ Èké Karùn-ún: Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 12/15 ojú ìwé 26-29

Ìlú Tí Ìjọsìn Tòótọ́ àti Ìbọ̀rìṣà Ti Forí Gbárí

ÓTI lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún táwọn awalẹ̀pìtàn ti ń ṣèwádìí àṣekára lórí àwókù ìlú Éfésù ayé ọjọ́un. Ìlú yìí wà ní ìwọ̀ oòrùn etíkun ilẹ̀ Turkey. Wọ́n ti tún àwọn ilé bíi mélòó kan kọ́ ní ìlú náà, ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ṣàwárí níbẹ̀ làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sì ń yẹ̀ wò fínnífínní tí wọ́n sì ń ṣàlàyé ohun tí wọ́n dúró fún. Èyí ló mú kí ìlú Éfésù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi tó gbajúmọ̀ jù lọ táwọn èèyàn ń ṣèbẹ̀wò sí lórílẹ̀-èdè Turkey.

Àwọn nǹkan wo ló ti wá di mímọ̀ báyìí nípa ìlú Éfésù? Báwo ni ìlú tó fani mọ́ra láyé ọjọ́un yẹn ṣe wá rí lónìí? Àbẹ̀wò sí ìlú tó ti di àwókù yìí àti síbi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé ibẹ̀ sí ní Vienna lórílẹ̀-èdè Austria yóò jẹ́ kó o rí bí ìjọsìn tòótọ́ àti ìbọ̀rìṣà ṣe forí gbárí ní ìlú Éfésù. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká mọ díẹ̀ nípa ìtàn ìlú náà.

Àgbègbè Tó Wọ Ọ̀pọ̀ Èèyàn Lójú

Ní ọ̀rúndún kọkànlá ṣáájú Sànmánì Tiwa, rúkèrúdò àti káwọn èèyàn máa ṣí kiri wọ́pọ̀ gan-an láwọn àgbègbè Yúróòpù àti Éṣíà. Àkókò yìí làwọn Gíríìkì láti àgbègbè Ayóníà lọ tẹ̀dó sí apá ìwọ oòrùn etíkun Éṣíà Kékeré. Abo ọlọ́run kan, ìyẹn òrìṣà tí wọ́n wá mọ̀ lẹ́yìn náà sí Átẹ́mísì ti ìlú Éfésù làwọn èèyàn tí wọ́n bá níbẹ̀ ń jọ́sìn.

Ní ìdajì ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Tiwa, àwọn Sìméríà tí wọ́n máa ń ṣí kiri ti apá àríwá Òkun Dúdú wá sí Éṣíà Kékeré, wọ́n sì jí ẹrù àwọn èèyàn kó lọ yán-ányán-án. Lẹ́yìn náà, ní nǹkan bí ọdún 550 ṣáájú Sànmánì Tiwa, Ọba Croesus ti ilẹ̀ Lydia gorí ìtẹ́, ọba yìí lágbára gan-an, ó sì lọ́rọ̀ rẹpẹtẹ. Bí Ilẹ̀ Ọba Páṣíà ti ń gbòòrò sí i, Ọba Kírúsì gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìlú tó wà lágbègbè Ayóníà, Éfésù sì wà lára wọn.

Lọ́dún 334 ṣáájú Sànmánì Tiwa, Alẹkisáńdà ara Makedóníà bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti ilẹ̀ Páṣíà, ó sì wá di alákòóso tuntun fún ìlú Éfésù. Lẹ́yìn tí Alẹkisáńdà kú lójijì lọ́dún 323 ṣáájú Sànmánì Tiwa, àwọn ọ̀gágun abẹ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí jà lé Éfésù. Lọ́dún133 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ọba Págámù tí kò bímọ, ìyẹn Attalus Kẹta, fún àwọn ará Róòmù ní ìlú Éfésù gẹ́gẹ́ bí ogún, bí Éfésù sì ṣe di ara àgbègbè tí ilẹ̀ Róòmù ń ṣàkóso ní Éṣíà nìyẹn.

Ìjọsìn Tòótọ́ àti Ìbọ̀rìṣà Forí Gbárí

Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá sílùú Éfésù lópin ìrìn-àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì ní ọ̀rúndún kìíní ṣáájú Sànmánì Tiwa, àwọn èèyàn inú ìlú náà tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún. (Ìṣe 18:19-21) Nígbà tó ń rírìn-àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta, ó tún padà lọ sí ìlú Éfésù, ó sì fi ìgboyà tó ju tàtẹ̀yìnwá lọ sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run nínú sínágọ́gù wọn. Àmọ́, lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, àtakò àwọn Júù le koko sí i, ni Pọ́ọ̀lù bá pinnu láti lọ máa sọ àsọyé tó ń sọ lójoojúmọ́ nínú gbọ̀ngàn ilé ìwé Tíránù. (Ìṣe 19:1, 8, 9) Ọdún méjì gbáko ló fi wàásù níbẹ̀, ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu bíi wíwo àwọn èèyàn sàn àti lílé ẹ̀mí èṣù jáde. (Ìṣe 19:10-17) Abájọ tí ọ̀pọ̀ fi di onígbàgbọ́! Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì gbilẹ̀ débi pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ awo tẹ́lẹ̀ ló fínnúfíndọ̀ dáná sun àwọn ìwé olówó iyebíye tí wọ́n ń lò.—Ìṣe 19:19, 20.

Iṣẹ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù kẹ́sẹ járí nítorí pé ọ̀pọ̀ ló jáwọ́ nínú ìjọsìn abo ọlọ́run Átẹ́mísì. Àmọ́ èyí tún jẹ́ kó rí ìbínú àwọn tó fẹ́ kí ìjọsìn náà máa bá a lọ. Owó rẹpẹtẹ làwọn tó ń kọ́ ojúbọ Átẹ́mísì tí wọ́n fi fàdákà ṣe máa ń rí. Bó ṣe wá dà bíi pé Pọ́ọ̀lù fẹ́ gba ìjẹ lẹ́nu wọn yìí ló mú kí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Dímẹ́tíríù ké sáwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà yòókù pé káwọn bá Pọ́ọ̀lù fàjọ̀gbọ̀n.—Ìṣe 19:23-32.

Gbọ́nmi-sí-i omi-ò-to yìí le débi pé, wákàtí méjì gbáko làwọn èrò fi ń kígbe láìdánudúró pé: “Títóbi ni Átẹ́mísì ti àwọn ará Éfésù!” (Ìṣe 19:34) Lẹ́yìn tí rúkèrúdò yìí rọlẹ̀, Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níṣìírí ó sì ń bá ìrìn-àjò rẹ̀ nìṣó. (Ìṣe 20:1) Àmọ́, kíkúrò tó kúrò nílùú Éfésù lọ sí Makedóníà kò ní kí ìjọsìn Átẹ́mísì má pa run o.

Ìparun Tẹ́ńpìlì Átẹ́mísì Kù sí Dẹ̀dẹ̀

Ìjọsìn òrìṣà Átẹ́mísì fẹsẹ̀ rinlẹ̀ gan-an nílùú Éfésù. Kí Croesus tó di ọba, abo ọlọ́run kan tó ń jẹ́ Síbílì lọ̀pọ̀ àwọn ará ibẹ̀ máa ń jọ́sìn. Àmọ́ káwọn Gíríìkì àtàwọn tí kì í ṣe Gíríìkì lè máa jọ́sìn òrìṣà kan náà, Croesus fi yé wọn pé abo ọlọ́run Síbílì bá àwọn òrìṣà ilẹ̀ Gíríìkì tan. Pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Croesus, nígbà tó di ìdajì ọ̀rúndún kẹfà ṣáájú Sànmánì Tiwa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ tẹ́ńpìlì òrìṣà Átẹ́mísì tí wọ́n fi rọ́pò Síbílì.

Tá a bá ń sọ nípa ọ̀nà ìkọ́lé àwọn Gíríìkì, ìtẹ̀síwájú gbáà ni bí wọ́n ṣe kọ́ tẹ́ńpìlì yìí jẹ́. Kò tíì sí irú ilé yẹn tí wọ́n fi mábìlì tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ kọ́ rí. Lọ́dún 356 ṣáájú Sànmánì Tiwa, iná jó tẹ́ńpìlì yìí kanlẹ̀. Àmọ́ ilé ọba tó jó ẹwà ló bù si ni èyí tí wọ́n tún kọ́, torí pé fàkìàfakia ló rí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ríṣẹ́ ṣe nígbà tí wọ́n ń kọ́ ọ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ló tún di ibi táwọn èèyàn ń rìnrìn-àjò ìjọsìn lọ. Orí pèpéle kan tó fẹ̀ gan-an ni wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì náà sí. Fífẹ̀ pèpéle náà tó mítà mẹ́tàléláàádọ́rin [73] nígbà tí gígùn rẹ̀ tó mítà mẹ́tàdínláàádóje [127]. Fífẹ̀ tẹ́ńpìlì tí wọ́n tún kọ́ yìí fúnra rẹ̀ tó àádọ́ta [50] mítà, ó sì gùn ní mítà márùnlélọ́gọ́rùn-ún [105]. Wọ́n ní ọ̀kan ló jẹ́ lára àwọn ohun méje tó jẹ́ àgbàyanu jù lọ láyé ọjọ́un. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ni inú wọn dùn sí tẹ́ńpìlì yìí. Heracleitus tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí tó sì jẹ́ ọmọ ìlú Éfésù, fi àwọn tó ń fojú bàbàrà wo pẹpẹ yìí wé àwọn ẹni ibi tó wà nínú òkùnkùn, ó sì ní ìwàkiwà tí wọ́n ń hù nínú tẹ́ńpìlì náà burú ju ti ẹranko lọ. Síbẹ̀, bí ìgbà tí mìmì kan ò lè mi ilé ìjọsìn Átẹ́mísì tó wà ní Éfésù yìí ló rí lójú ọ̀pọ̀ èèyàn. Àmọ́ ìtàn fi hàn pé ibi tí wọ́n fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀. Ìwé kan tí wọ́n pè ní Ephesus—The New Guide sọ pé: “Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, ńṣe ni ìjọsìn Átẹ́mísì àtàwọn ọlọ́run míì tí wọ́n gbé kalẹ̀ ṣàdédé dohun tí ò já mọ́ nǹkan kan mọ́.”

Ní ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa, ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó fakíki gbo ìlú Éfésù jìgìjìgì. Ìyẹn nìkan kọ́, àwọn ẹ̀ya Goth tí wọ́n jẹ́ arìnrìn-àjò lórí òkun ya wọ ìlú Éfésù láti Òkun Dúdú, wọ́n kó ọrọ̀ rẹpẹtẹ inú tẹ́ńpìlì Átẹ́mísì, wọ́n sì sọ iná sí i. Ìwé tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dárúkọ rẹ̀ sọ pé: “Níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti rẹ́yìn Átẹ́mísì, tóun alára ò sì lè dáàbò bo ibùgbé rẹ̀, báwo làwọn èèyàn ṣe wá tún fẹ́ kà á sẹ́ni tó ń dáàbò bo ìlú náà?”—Sáàmù 135:15-18.

Paríparí rẹ̀ ni pé, lópin ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa, Olú Ọba Theodosius Kìíní, kéde pé “ìsìn Kristẹni” ni gbogbo ìlú gbọ́dọ̀ máa ṣe. Kò pẹ́ kò jìnnà, tẹ́ńpìlì Átẹ́mísì tó ti rí mìrìngìndìn tẹ́lẹ̀ wá dohun táwọn èèyàn ń fi òkúta rẹ̀ kọ́ àwọn ilé mìíràn. Bó ṣe di pé ìjọsìn Átẹ́mísì kò gbérí mọ́ nìyẹn o. Nígbà tí ọkùnrin alákìíyèsí kan ń sọ̀rọ̀ nípa ewì kan tí wọ́n fi ṣàpọ́nlé tẹ́ńpìlì náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ohun àgbàyanu ayé ọjọ́un, ó ní: “Tẹ́ńpìlì ọ̀hún ló ti wá dahoro pátápátá yìí tí kò sì bójú mu rárá àti rárá mọ́.”

“Ìyá Ọlọ́run” Lọ̀rọ̀ Tún Kàn

Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn àgbà ọkùnrin tó wà nínú ìjọ Éfésù pé, lẹ́yìn tóun bá lọ tán, “àwọn aninilára ìkookò” yóò wọlé wá, àwọn kan yóò sì dìde láàárín wọn tí wọn yóò máa sọ “àwọn ohun àyídáyidà.” (Ìṣe 20:17, 29, 30) Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Ìtàn fi hàn pé ìsìn àwọn Kristẹni apẹ̀yìndà ló wá di ìsìn èké tó gbilẹ̀ nílùú Éfésù.

Ìlú Éfésù ni àpérò gbogbo gbòò kẹta tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ṣe lọ́dún 431 Sànmánì Tiwa ti wáyé, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti jíròrò ẹni tí Kristi jẹ́. Ìwé Ephesus—The New Guide ṣàlàyé pé: “Ìgbàgbọ́ àwọn ará Alẹkisáńdíríà pé Kristi ni Ọlọ́run . . . ló borí.” Ohun tó tìdí ìpinnu náà jáde sì lágbára gan-an. “Kì í ṣe pé ìpinnu tí wọ́n fẹnu kò sí nílùú Éfésù yìí gbé Màríà ga láti ìyá Kristi di ìyá Ọlọ́run nìkan ni, èyí tó wá sọ Màríà dòrìṣà-àkúnlẹ̀bọ, àmọ́ ìpinnu yìí ló tún fa ìpínyà ńlá tó kọ́kọ́ wáyé nínú ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. . . . Títí dòní olónìí làríyànjiyàn ń lọ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Bí ìjọsìn Màríà tí wọ́n sọ di “ìyá Ọlọ́run” ṣe rọ́pò ìjọsìn abo ọlọ́run Síbílì àti Átẹ́mísì nìyẹn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà ṣe sọ, “sísọ tí wọ́n sọ Màríà dòrìṣà àkúnlẹ̀bọ ní Éfésù . . . ló wá di ìgbàgbọ́ tí kò pa rẹ́ mọ́ títí dòní. Kò sì sẹ́ni tó lè ṣàlàyé rẹ̀ láìmẹ́nu ba ìjọsìn òrìṣà Átẹ́mísì.”

Ìjọsìn Átẹ́mísì Dohun Ìgbàgbé

Lẹ́yìn tí ìjọsìn Átẹ́mísì kógbá sílé, Éfésù alára ò gbérí mọ́. Ìmìtìtì ilẹ̀, àìsàn ibà, àti líle tí ilẹ̀ etíkun rẹ̀ ń le gbagidi mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ nira gan-an níbẹ̀.

Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún keje Sànmánì Tiwa, ẹ̀sìn Ìsìláàmù ti bẹ̀rẹ̀ sí í tàn kálẹ̀. Kì í ṣe pé ẹ̀sìn yìí so àwọn Lárúbáwá tó tẹ́wọ́ gba ìlànà ẹ̀sìn náà pọ̀ nìkan ni, àmọ́ jálẹ̀ ọ̀rúndún keje àti ìkẹjọ ni ọkọ̀ ogun ojú omi àwọn Lárúbáwá yìí fi ń gbógun ti ìlú Éfésù. Ìgbà tí ilẹ̀ etíkun ìlú Éfésù tiẹ̀ wá le gbagidi pátápátá ló hàn gbangba pé ó ti tán fún ìlú náà, òkìtì àlàpà ló sì dà kẹ́yìn. Bí ìlú yìí ṣe gbayì tó nígbà kan, abúlé kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Aya Soluk (tó ti di Selçuk báyìí) nìkan ló ṣẹ́ kù níbẹ̀.

A Rìn Yíká Àwókù Ìlú Éfésù

Bó o bá fẹ́ mọ bí ọlá ńlá ìlú Éfésù ṣe tó nígbà kan, kó o ṣèbẹ̀wò sí àwókù rẹ̀. Bó o bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn rẹ láti ibi àbáwọlé apá òkè, kedere báyìí ni wàá máa wo Òpópónà Curete tó lọ já sí Ibi Ìkówèésí Celsus lọ́ọ̀ọ́kán. Lápá ọ̀tún òpópónà náà, wàá rí gbọ̀ngàn kékeré kan tí wọ́n kọ́ ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa, gbọ̀ngàn yìí á fà ọ́ mọ́ra gan-an. Yàtọ̀ sípàdé àwọn aṣòfin tí wọ́n máa ń ṣe níbẹ̀, bóyá ni wọ́n ò tún ń lò ó fún dídá àwọn èèyàn lára yá nítorí pé ó lè gbà tó ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ èèyàn. Ńṣe ni ilé tò lọ gẹ̀ẹ̀rẹ̀gẹ̀ lápá ọ̀tún àti lápá òsì Òpópónà Curete yìí. Lára wọn ni gbọ̀ngàn tí wọ́n ti ń jíròrò ọ̀rọ̀ ìlú, tẹ́ńpìlì Hadrian, àwọn ìsun omi, àtàwọn ilé tí wọ́n kọ́ sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ òkè táwọn sàràkí èèyàn ìlú Éfésù ń gbé látijọ́.

Ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa ni wọ́n kọ́ àrímáleèlọ Ibi Ìkówèésí ti Ọba Celsus, ẹ̀wà rẹ̀ ò sì ní ṣàì mórí rẹ wú. Àwọn ibi tí wọ́n ń ki ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àkájọ ìwé sí wà nínú yàrá ńlá kan níbẹ̀. Àwọn ère mẹ́rin kan wà ní gbàgede rẹ̀ tó jojú ní gbèsè. Àwọn ère náà dúró fún ànímọ́ mẹ́rin tí wọ́n retí látọ̀dọ̀ òṣìṣẹ́ ìjọba ilẹ̀ Róòmù tó wà nípò gíga, irú bí ọba Celsus. Orúkọ àwọn ère náà àtàwọn ànímọ́ tí wọ́n dúró fún nìyí: Sophi (ọgbọ́n), Arete (ìwà rere), Ennoia (ìbẹ̀rù Ọlọ́run) àti Episteme (ìmọ̀ tàbí òye). Èèyàn lè rí àwọn ère tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe pàá níbi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé ìlú Éfésù sí nílùú Vienna. Ilẹ̀kùn fàkìàfakia kan wà nítòsí àgbàlá ọwọ́ iwájú ibi ìkówèésí yìí tí wàá gbà já sí ọjà Tetragonos. Inú gbàgede tó fẹ̀ gan-an yìí, tí wọ́n ṣe òrùlé sórí ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ tó yí i ká, làwọn èèyàn ti ń ṣe káràkátà wọn ojoojúmọ́.

Bó o ti ń kúrò níbẹ̀, ojú Ọ̀nà Mábìlì tó lọ sí ibi ìṣeré ńlá ni wàá bọ́ sí. Ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n olùwòran ni gbọ̀ngàn yìí ń gbà nígbà tí ìjọba Róòmù túbọ̀ wá sọ ọ́ di ńlá. Wọ́n fi òpó àti oríṣiríṣi ère ẹlẹ́wà ṣe gbàgede rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ gan-an. O tiẹ̀ lè fojú inú wo yánpọnyánrin tí Dímẹ́tíríù alágbẹ̀dẹ fàdákà dá sílẹ̀ láàárín àwọn èrò tó kóra jọ sí gbàgede náà láyé ọjọ́un.

Òpópónà tó lọ láti gbọ̀ngàn ńlá yìí tó lọ já sí etíkun ìlú náà ti lọ wà jù. Gígùn rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] mítà nígbà tí fífẹ̀ rẹ̀ tó mítà mọ́kànlá. Ńṣe ni òpó tò lọ gẹ̀ẹ̀rẹ̀gẹ̀ lápá ọ̀tún àti lápá òsì. Ọ̀nà yìí náà ni wọ́n kọ́ àwọn ibi ìṣeré ìmárale méjì sí, àwọn tó ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí eré ìdárayá ló sì máa ń lò wọ́n. Ẹnubodè gbàràmùgbaramu tó wà lópin ọ̀nà náà ló jáde sẹ́yìn ìlú, ibẹ̀ la sì parí ìrìn-àjò kúkúrú tá a ṣe sí ọ̀kan lára àwọn àwókù ìlú tó fani mọ́ra jù lọ láyé sí. O lè rí àwòrán ìlú ńlá ayé ọjọ́un yìí tí wọ́n fi igi gbẹ́ àti ọ̀pọ̀ nǹkan ìrántí mìíràn nílùú Vienna, níbi tí wọ́n kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé ìlú Éfésù sí.

Téèyàn bá rìn yíká ibi tí wọ́n kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé wọ̀nyí sí, tó sì rí ère òrìṣà Átẹ́mísì ìlú Éfésù, èèyàn ò ní ṣàìronú nípa ìfaradà àwọn Kristẹni ìjímìjí ní ìlú Éfésù. Ìlú tó kún fún ìbẹ́mìílò tí ẹ̀tanú ìsìn sì ti ra àwọn èèyàn ibẹ̀ níyè ni wọ́n gbé. Àwọn olùjọsìn Átẹ́mísì ṣàtakò ìṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà gan-an. (Ìṣe 19:19; Éfésù 6:12; Ìṣípayá 2:1-3) Síbẹ̀, ìsìn tòótọ́ fìdí múlẹ̀ ní àyíká tí kò bára dé yìí. Bẹ́ẹ̀ ni ìsìn tòótọ́ náà yóò ṣe gbilẹ̀ nígbà tí ìsìn èkè òde òní bá pa rún, bí ìjọsìn abo ọlọ́run Átẹ́mísì ọjọ́un ṣe pa run.—Ìṣípayá 18:4-8.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

MAKEDÓNÍÀ

Òkun Dúdú

ÉṢÍÀ KÉKERÉ

Éfésù

Òkun Mẹditaréníà

ÍJÍBÍTÌ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwókù tẹ́ńpìlì Átẹ́mísì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]

1. Ibi Ìkówèésí Ọba Celsus

2. Ère Arete téèyàn bá sún mọ́ ọn dáadáa

3. Ojú Ọ̀nà Mábìlì tó lọ sí ibi ìṣeré ńlá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́