ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 12/15 ojú ìwé 30
  • Ǹjẹ́ O Rántí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Rántí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìwọ Ha Ní Ojú Ìwòye Ọlọ́run Nípa Ọtí Líle Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ṣọ́ra Fún Ọtí Àmujù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 12/15 ojú ìwé 30

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ o ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Ṣé o gbádùn wọn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

• Kí ni Kristẹni kan lè ṣe nígbà tí gbogbo nǹkan bá tojú sú u tó sì rẹ̀ ẹ́ nípa tẹ̀mí?

Ó yẹ ká mọ ohun tó máa ń jẹ́ kó rẹ̀ wá. Ohun kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká yẹ àwọn ohun tá a máa ń ṣe àtàwọn ohun ìní wa wò, ká sì pa gbogbo àwọn ohun tí kò pọn dandan tì. A lè ṣe àwọn ìwéwèé tí agbára wa gbé. Ó ṣe pàtàkì gan-an láti bójú tó ìlera wa nípa tẹ̀mí, ìyẹn sì kan pé ká máa gbàdúrà déédéé ká sì máa ṣe àṣàrò.—8/15, ojú ìwé 23 sí 26.

• Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbà pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] jẹ́ iye gidi kan?

Lẹ́yìn tá a sọ nípa àwọn tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yìí fún àpọ́sítélì Jòhánù, ó tún rí “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà.” (Ìṣípayá 7:4, 9) Tí ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì bá jẹ́ iye ìṣàpẹẹrẹ kan, a jẹ́ pé kò ní sí ìyàtọ̀ kankan láàárín ẹsẹ méjèèjì nìyẹn. Jésù pe àwọn tí yóò bá a ṣàkóso ní “agbo kékeré.” (Lúùkù 12:32)—9/1, ojú ìwé 30.

• Kí nìdí tí ọmọ Ísírẹ́lì kan fi lè ta ẹran tí wọn ò dúńbú fún ọmọ ilẹ̀ òkèèrè?

Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tàbí àtìpó tí kò di aláwọ̀ṣe kò sí lábẹ́ Òfin. Nítorí náà, Jèhófà fàyè gba ọmọ Ísírẹ́lì láti fún un ní irú ẹran bẹ́ẹ̀ tàbí kó tà á fún un. (Diutarónómì 14:21) Àmọ́ Òfin de ẹni tó jẹ́ aláwọ̀ṣe ní tirẹ̀, kò sì lè jẹ irú ẹran bẹ́ẹ̀. (Léfítíkù 17:10)—9/15, ojú ìwé 26.

• Àwọn àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká mọ báwọn èèyàn ṣe ń wo ohun tí Ọlọ́run dá láti fi ṣe ohun tó jọ ọ́?

Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn ọmọkùnrin Wright ṣe ọkọ̀ òfuurufú kan lẹ́yìn tí wọ́n wo àwọn ẹyẹ ńlá kan tó ń fò. Onímọ̀ ẹ̀rọ ọmọ ilẹ̀ Faransé kan ya àwòrán tí wọ́n wò kọ́ ilé gogoro kan tí wọ́n fi orúkọ rẹ̀ pè nílùú Paris. Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ṣe eegun inú itan tó ń gbé èèyàn dúró ni onímọ̀ ẹ̀rọ yìí tẹ̀ lé.—10/1, ojú ìwé 9.

• Ta ni 2 Kọ́ríńtì 12:2-4 sọ pé a gbà lọ sínú párádísè?

Àyọkà yẹn ló tẹ̀ lé àwọn ẹsẹ tí Pọ́ọ̀lù ti gbèjà iṣẹ́ àpọ́sítélì rẹ̀. Nígbà tí Bíbélì ò sì sọ nípa ẹlòmíràn tó rí irú ìran yẹn, tó sì jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ló sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wa, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù tó rí ìran yìí ni.—10/15, ojú ìwé 8.

• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ tí Jésù ní tó mú kó tóótun láti jẹ́ Aṣáájú tí Ọlọ́run yàn?

Jésù pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ láìkù síbì kankan, ìwà rẹ̀ dára, kò sì ní àríwísí kankan. Ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ pátápátá fún Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ Jésù lọ́kàn gan-an, kì í sì í fiṣẹ́ ṣeré.—11/1, ojú ìwé 6 àti 7.

• Ibo làwọn ẹ̀mí èṣù máa wà nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi?

Ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé jíjù la máa jù wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ pẹ̀lú Sátánì nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi. (Ìṣípayá 20:1-3) Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé a óò fọ́ ejò náà ní orí, èyí sì kan jíjù Sátánì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà. Àwọn áńgẹ́lì búburú tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù sì wà lára irú ọmọ rẹ̀. Ẹ̀rù ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ tó ń ba àwọn ẹ̀mí èṣù gidigidi fi hàn pé wọ́n mọ̀ pé ibẹ̀ làwọn ń lọ tó bá yá. (Lúùkù 8:31)—11/15, ojú ìwé 30 àti 31.

• Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn ṣọ́ra fún ọtí mímu, bó tilẹ̀ jẹ́ pé onítọ̀hún kì í mú un débi táá fi máa ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́?

Àwọn kan wà tó jẹ́ pé bí wọ́n tilẹ̀ mú odidi àgbá pàápàá, kò ní hàn lójú wọn. Àmọ́, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọtí á di bárakú sí wọn lára, wọ́n á sì di “ẹrú fún ọ̀pọ̀ wáìnì.” (Títù 2:3) Jésù kìlọ̀ pé ká ṣọ́ra ká máa di ẹni tí “a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri.” (Lúùkù 21:34, 35) Kò dìgbà tẹ́nì kan bá mutí yó pàápàá kí ọtí tó sọ onítọ̀hún di ọ̀lẹ àti ẹni tó ń tòògbé nípa tara àti nípa tẹ̀mí.—12/1, ojú ìwé 19 sí 21.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́