Ìwọ Ha Ní Ojú Ìwòye Ọlọ́run Nípa Ọtí Líle Bí?
NǸKAN bí 20 ọdún sẹ́yìn, àwọn awalẹ̀pìtàn wú ilé àtijọ́ kan tí a fi bíríkì alámọ̀ kọ́ jáde lẹ́bàá ìlú Urmia, Iran. Wọ́n rí ládugbó alámọ̀ kan, tí ó ti wà fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, láti ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ àwọn ìlú ìjímìjí tí ènìyàn ń gbé dó, gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti sọ. Láìpẹ́ yìí, a lo ọgbọ́n ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tuntun láti ṣàyẹ̀wò ládugbó náà. Ẹnu ya àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti rí ẹ̀rí kẹ́míkà ọlọ́jọ́ pípẹ́ jù lọ tí a fi ń ṣe wáìnì nínú rẹ̀.
Bíbélì pẹ̀lú fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní kedere pé láti ìgbà àtijọ́ ni a ti ń mu wáìní, bíà, àti àwọn ọtí líle mìíràn. (Jẹ́nẹ́sísì 27:25; Oníwàásù 9:7; Náhúmù 1:10) Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn oúnjẹ mìíràn, Jèhófà ń fún wa ní àǹfààní gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan láti yàn—láti mu ọtí líle tàbí láti má ṣe mú un. Jésù sábà máa ń mu wáìnì lẹ́yìn oúnjẹ rẹ̀. Jòhánù Oníbatisí kò mu ọtí líle.—Mátíù 11:18, 19.
Bíbélì ka fífi ọtí kẹ́ra bàjẹ́ léèwọ̀. Ìmutípara jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. (Kọ́ríńtì Kìíní 6:9-11) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í yọ̀ǹda kí ẹnikẹ́ni tí ó bá di ọ̀mùtí aláìronúpìwàdà wà nínú ìjọ Kristẹni. Àwọn tí wọ́n wà nínú ìjọ tí wọ́n yàn láti máa mu ọtí líle gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.—Títù 2:2, 3.
Ojú Ìwòye Tí Kò Bá Ti Ọlọ́run Mu
Ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí kò ní ojú ìwòye Ọlọ́run nípa ọtí líle. Ó rọrùn láti rí i pé Sátánì ń gbé ìmukúmu ohun àtayébáyé yìí lárugẹ. Fún àpẹẹrẹ, ní àwọn erékùṣù kan ní Gúúsù Pacific, ó jẹ́ àṣà àwọn ọkùnrin láti kóra jọ láti mu ọtí rẹpẹtẹ, tí a fi àwọn ohun mímu tí ó ti bà ṣe lábẹ́lé. Àkókò ìjókòó yìí lè wà fún ọ̀pọ̀ wákàtí, ó sì máa ń jẹ́ léraléra—ọ̀pọ̀ ọkùnrin ń lọ́wọ́ nínú àṣà náà lójoojúmọ́. Àwọn kan wulẹ̀ kà á sí apá kan àṣà ìbílẹ̀ wọn. Nígbà míràn, wọ́n máa ń mu bíà àti ògógóró dípò—tàbí ní àfikún sí—ohun mímu ìbílẹ̀ tí a ṣe lábẹ́lé. Ó sábà máa ń yọrí sí ìmutípara.
Ní ilẹ̀ Pacific mìíràn, a kì í sábà gbọ́ pé àwọn ọkùnrin mutí ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Gẹ́gẹ́ bí ìlànà gbogbogbòò, tí wọ́n bá mutí, wọ́n mú un láti mu àmupara ni. Fún àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ ìgbowó-oṣù, àwọn ọkùnrin díẹ̀ yóò kóra jọ, wọn yóò ra ọ̀pọ̀ páálí bíà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n ní ìgò 24 nínú. Ó di ìgbà tí bíà náà bá tán kí wọ́n tó ṣíwọ́ ọtí mímu. Ní ìyọrísí rẹ̀, ìmutípara ní gbangba jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àṣà, a máa ń mu àwọn ohun mímu tí ó ti bà, irú bí ẹmu àti ọtí ìbílẹ̀ míràn ní àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà. Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ní àwọn àwùjọ kan béèrè pé kí a gbé ọtí kalẹ̀ nígbà tí a bá ń ṣàlejò. Gẹ́gẹ́ bí àṣà ìbílẹ̀, olùgbàlejò náà tí ó lẹ́mìí aájò àlejò ní láti pèsè ju ohun tí àlejò rẹ̀ lè mu lọ. Ní agbègbè kan, àṣà náà ni láti gbé ìgò bíà 12 kalẹ̀ síwájú àlejò kọ̀ọ̀kan.
Ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ àwọn ará Japan máa ń ṣètò ìrìn àjò inú bọ́ọ̀sì fún àwọn òṣìṣẹ́ wọn. Wọn yóò kó ọ̀pọ̀ ọtí lílé dání, wọ́n sì fàyè gba ìmutípara. Díẹ̀ nínú àwọn fàájì ilé iṣẹ́ wọ̀nyí máa ń gbà tó ọjọ́ méjì sí mẹ́ta. Gégẹ́ bí ìwé ìròyìn náà, Asiaweek, ní Japan ti sọ, “láti orí àgbẹ̀ agbìnrẹsì títí dórí ọlọ́rọ̀ olóṣèlú, gẹ́gẹ́ bí àṣà, ohun tí a fi ń mọ bí ọkùnrin kan ṣe tọ́kùnrin tó ni bí ó ṣe lè mú ọtí líle tó.” A ti ṣàkíyèsí irú ìtẹ̀sí kan náà ni àwọn orílẹ̀-èdè Éṣíà. Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé: “Àwọn ará Gúúsù Korea ń mu ọtí líle nísinsìnyí ju ọ̀mùtí èyíkéyìí lọ níbikíbi lágbàáyé.”
Ọtí àmujù ti di àṣà ti ó ti tàn kálẹ̀ ní àwọn ọgbà kọ́lẹ́ẹ̀jì ní United States. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde náà, The Journal of the American Medical Association, ti sọ, “ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ń mu ọtí àmujù kò rí ara wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ní ìṣòro ọtí mímu.”a Kò yẹ kí èyí yani lẹ́nu nítorí pé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ilé iṣẹ́ ìròyìn ń gbé ọtí mímu lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ìgbòkègbodò amóríyá, aláfẹ́, àti olóye. Lọ́pọ̀ ìgbà, èrò títàn kálẹ̀ yìí máa ń fojú sun àwọn ọ̀dọ́ ní pàtàkì.
Ní Britain, iye bíà tí a ń mu ti di ìlọ́po méjì láàárín 20 ọdún, iye ọtí líle tí a ń mu sì ti di ìlọ́po mẹ́ta. Àwọn tí ń mu ọtí ti ń tètè bẹ̀rẹ̀ nígbà ọ̀dọ́, àwọn obìnrin tí ń mu ọtí sì ń pọ̀ sí i. A kíyè sí irú ìtẹ̀sí kan náà ni àwọn orílẹ̀-èdè Ìlà Oòrùn Europe àti Latin America. Ìlọsókè ìmukúmu àti jàm̀bá ojú pópó tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọtí líle fi èyí hàn kedere. Ó ṣe kedere pé, ìlọsókè híhàn gbangba wà nínú ìmukúmu ọtí líle káàkiri ayé.
Mélòó Ni A Lè Mu Tí A Lè Sọ Pé Àṣejù Ti Wọ̀ Ọ́?
Ojú ìwòye Bíbélì nípa ọtí líle wà déédéé. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Ìwé Mímọ́ sọ pé, wáìnì jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run “tí í mú inú ènìyàn dùn.” (Orin Dáfídì 104:1, 15) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ní dídẹ́bi fún ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́, Bíbélì lo àwọn gbólóhùn náà “ìmutíyó kẹ́ri,” “àṣejù nídìí ọtí wáìnì, àwọn àríyá aláriwo, ìfagagbága ọtí mímu,” ‘fífi ara ẹni fún ọ̀pọ̀ ọtí wáìnì,’ àti dídi “ẹrú fún ọ̀pọ̀ ọtí wáìnì.” (Lúùkù 21:34; Pétérù Kìíní 4:3; Tímótì Kìíní 3:8; Títù 2:3) Ṣùgbọ́n ọtí mélòó ni a lè pé ní “ọ̀pọ̀ ọtí wáìnì”? Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè pinnu ohun tí ó jẹ́ ojú ìwòye Ọlọ́run ní ti ọtí líle?
Kò ṣòro láti mọ ìmutípara. A fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣàpèjúwe àwọn àbájáde rẹ̀ nínú Bíbélì: “Ta ni ó ni òṣì? ta ni ó ni ìbìnújẹ́? ta ni ó ni ìjà? ta ni ó ni asọ̀? ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí, ta ni ó ni ojú pípọn. Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí wáìnì; àwọn tí ń lọ dán ọtí wáìnì àdàlù wò. . . . Ojú rẹ yóò wo àjèjì obìnrin, àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ̀ àyídáyidà.”—Òwe 23:29-33.
Àpọ̀jù ọtí líle lè dá ìdàrúdàpọ̀, iyè ríra, àìmọramọ́, àti àwọn ìgbégbòdì míràn nínú èrò inú àti ara sílẹ̀. Nígbà tí ọtí bá ń pani, ẹnì kan lè má lè ṣàkóso ìhùwàsí rẹ̀ mọ́, ní pípa ara rẹ̀ àti àwọn ẹlòmíràn lára. A mọ àwọn ọ̀mùtí sí àwọn tí ń lọ́wọ́ nínú ìwà ẹ̀sín, ìwà tí ń kóni nírìíra, tàbí ìwà pálapàla.
Mímu ọtí dórí ìmutípara, pẹ̀lú àwọn àbájáde rẹ̀ tí a mẹ́nu kàn lókè yìí, ní ti gidi jẹ́ ọtí àmujù. Ṣùgbọ́n, ẹnì kan lè fi àìjẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì hàn láìfi gbogbo àmì àpẹẹrẹ ti ìmutípara hàn. Nítorí náà, ọ̀ràn bóyá ẹnì kan ti mu àmujù sábà máa ń fa àríyànjiyàn. Kí ni ìyàtọ̀ nínú ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ìfọtíkẹ́rabàjẹ́?
Dáàbò Bo Agbára Ìrònú Rẹ
Bíbélì kò fi ààlà lélẹ̀ nípa sísọ iye ọtí tí ó gbọ́dọ̀ wà nínú ẹ̀jẹ̀ tàbí àwọn ọ̀nà ìfidíwọ̀n míràn. Iye ọtí tí ara ẹnì kan lè gbà yàtọ̀ láti ara ẹnì kan sí èkejì. Síbẹ̀, àwọn ìlànà Bíbélì kan gbogbo Kristẹni, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú ojú ìwòye Ọlọ́run ní ti ọtí líle dàgbà.
Jésù wí pé, òfin àkọ́kọ́ ni láti “nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37, 38) Ọtí líle ń ní ipa tààràtà lórí èrò inú, ìfọtíkẹ́rabàjẹ́ yóò sì forí gbárí pẹ̀lú ìgbọràn rẹ̀ sí òfin títóbi jù lọ yìí. Ó lè nípa gidigidi lórí ríronú lọ́nà yíyè kooro, agbára láti yanjú ìṣòro, lílo ìkóra-ẹni-níjàánu, àti àwọn iṣẹ́ pàtàkì míràn tí èrò inú ń ṣe. Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé: “Pa ọgbọ́n tí ó yè, àti ìmòye mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni wọn óò máa jẹ́ ìyè sí ọkàn rẹ, àti oore ọ̀fẹ́ sí ọrùn rẹ.”—Òwe 3:21, 22.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàrọwà fún àwọn Kristẹni pé: “[Ẹ] fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.” (Róòmù 12:1) Kristẹni kan yóò ha ‘ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run’ bí ó bá ń mu ọtí líle dórí àìlèṣàkóso “agbára ìmọnúúrò” rẹ̀ mọ́ bí? Lọ́pọ̀ ìgbà, díẹ̀ díẹ̀ ni ọ̀mùtí kan tí ó jẹ́ aláìmọ̀wọ̀ntúnwọ̀nsì fi máa ń di ẹni tí ó ń rí ara gba ọtí sí. Ó lè nímọ̀lára pé ọ̀pọ̀ ọtí tí òún ń mu—lójú tòun—kì í ṣe ìmutípara. Síbẹ̀, ó lè di ẹni tí ọtí ń wọ̀ lẹ́wù lọ́nà tí ó léwu. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ha lè gbé ara rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ẹbọ ààyè, mímọ́” bí?
Iye ọtí lílé èyíkéyìí tí ó bá lè nípa lórí “ọgbọ́n tí ó yè, àti ìmòye” gẹ́gẹ́ bí Kristẹni ti di ọtí tí ó pọ̀ jù fún ọ.
Kí Ní Ń Darí Ojú Ìwòye Rẹ̀ Nípa Ọtí Líle?
Kristẹni kan ní láti ṣàyẹ̀wò bóyá ìtẹ̀sí tí ó gbòde tàbí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ni ó ń dárí ọ̀nà tí ó gbà ń mu ọtí. Nígbà tí ó bá di ọ̀ràn ọtí líle, ó dájú pé, ìwọ kò ní fẹ́ kí o ṣe yíyàn tí a gbé karí ìtẹ̀sí tí ó gbòde tàbí ètò tí ilé iṣẹ́ ìròyìn ń tàn kálẹ̀. Ní gbígbé ìṣarasíhùwà tìrẹ yẹ̀ wò, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Ohun tí ó jẹ́ àṣà ní àwùjọ ni ó ha ń nípa lórí ọ̀nà tí mo gbà ń mu ọtí bí? Àbí àwọn ìlànà Bíbélì ni ó ha ń darí bí mo ṣe ń mu ọtí?’
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe àwọn abáṣàyodì, wọ́n mọ̀ pé Jèhófà kórìíra ọ̀pọ̀ àṣà tí a tẹ́wọ́ gbà níbi gbogbo lónìí. Àwọn àwùjọ kan fàyè gba ìṣẹ́yún, ìfàjẹ̀sínilára, ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀, tàbí ìkóbìnrinjọ. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Kristẹni ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ojú ìwòye Ọlọ́run nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí. Bẹ́ẹ̀ ni, ojú ìwòye Ọlọ́run yóò sún Kristẹni kan láti kórìíra irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ láìka bóyá àṣà ìbílẹ̀ tẹ́wọ́ gbà wọ́n sí tàbí kò tẹ́wọ́ gbà wọ́n.—Orin Dáfídì 97:10.
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “ìfẹ́ inú àwọn orílẹ̀-èdè,” tí ó ní nínú “àṣejù nídìí ọtí wáìnì” àti “ìfagagbága ọtí mímu.” Ọ̀rọ̀ náà “ìfagagbága ọtí mímu” ní ìtumọ̀ èrò àpèjẹ kan tí a ṣètò pẹ̀lú ète kan pàtó, ti mímu ọtí líle rẹpẹtẹ. Ó dà bíi pé ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, àwọn kan tí wọ́n ń fi agbára wọn láti lè mu ọtí púpọ̀ yangàn máa ń gbìyànjú láti mutí ju àwọn yòó kù lọ, tàbí kí wọ́n gbìyànjú láti wo ẹni tí ó lè mu ọtí tí ó pọ̀ jù. Àpọ́sítélì Pétérù tọ́ka sí irú ìwà yìí gẹ́gẹ́ bí “kòtò ẹ̀gbin jíjìn wọlẹ̀” kan tí àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ronú pìwà dà kó gbọ́dọ̀ kó wọ̀ mọ́.—Pétérù Kìíní 4:3, 4.
Yóò ha ba bọ́gbọ́n mu fún Kristẹni kan láti mú ojú ìwòye náà dàgbà pé, tí òun kò bá ṣáà ti mu àmupara, kò sí ohun tí ó burú nípa ibi tí òún ti mu ọtí, ìgbà tí òún mu ún, tàbí iye tí òun mu? A lè béèrè pé, Ojú ìwòye Ọlọ́run ha nìyẹn bí? Bíbélì sọ pé: “Yálà ẹ̀ ń jẹ tàbí ẹ̀ ń mu tàbí ẹ̀ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” (Kọ́ríńtì Kìíní 10:31) Gbogbo àwọn ọkùnrin díẹ̀ tí wọ́n kóra jọ láti mu ọtí rẹpẹtẹ ní gbangba lè má mu àmupara, ṣùgbọ́n ìwà wọn yóò ha mú ògo wá fún Jèhófà bí? Bíbélì ṣíni létí pé: “Ẹ . . . jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ̀yín lè fún ara yín ní ẹ̀rí ìdánilójú ìfẹ́ inú Ọlọ́run tí ó dára tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà tí ó sì pé.”—Róòmù 12:2.
Yẹra fún Mímú Àwọn Ẹlòmíràn Kọsẹ̀
Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, lọ́pọ̀ ìgbà, àṣà ìbílẹ̀ náà tí ó fàyè gba fífi ọtí kẹ́ra bà jẹ́ kì í fọwọ́ sì i nígbà tí ọ̀mùtí paraku kan bá sọ pé òun jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run. Ní àwùjọ kékeré kan ní Gúúsù Pacific, olùṣàkíyèsí kan wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn yìí wú mi lórí púpọ̀. Òtítọ́ ni ohun tí ẹ ń wàásù. Ṣùgbọ́n ìṣòro tí a rí ni pé àwọn ènìyàn yín ń mu ọtí púpọ̀.” Ìròyìn fi tóni létí pé, àwọn ẹni náà kò mu àmupara, síbẹ̀ òkodoro òtítọ́ yẹn kò hàn sí ọ̀pọ̀ tí ó wà ní àwùjọ náà. Àwọn olùṣàkíyèsí lè tètè parí èrò sí pé, bíi ti àwọn ọkùnrin mìíràn tí ń jókòó sídìí ọtí fún ìgbà pípẹ́, àwọn Ẹlẹ́rìí pẹ̀lú ń mu àmupara. Kristẹni òjíṣẹ́ kan tí ń jókòó sídìí ọtí fún ìgbà pípẹ́ ha lè ní orúkọ rere, kí ó sì ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní gbangba pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ bí?—Ìṣe 28:31.
Ìròyìn kan láti orílẹ̀-èdè Europe kan fi hàn pé, nígbà míràn, àwọn arákùnrin kan àti àwọn arábìnrin kan máa ń dé sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tí òórùn ọtí yóò sì máa bì tì ì lẹ́nu wọn. Èyí ti da ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn láàmú. Bíbélì ṣíni létí pé: “Ó dáa láti má ṣe jẹ ẹran tàbí mu ọtí wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin rẹ kọsẹ̀.” (Róòmù 14:21) Ojú ìwòye Ọlọ́run nípa ọtí líle yóò sún Kristẹni kan tí ó dàgbà dénú láti bìkítà nípa ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn, kódà bí o bá túmọ̀ sí títa kété sí ọtí líle lábẹ́ àwọn àyíká ipò kan.
Àwọn Kristẹni Yàtọ̀ Lọ́nà Ṣíṣe Kedere
Ó bani nínú jẹ́ pé, ayé yìí ti ṣẹ Jèhófà lọ́pọ̀ ọ̀nà nípa ṣíṣi àwọn ohun rere tí ó fún aráyé lò, títi kan ọtí líle. Kristẹni kọ̀ọ̀kan tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ ní láti làkàkà láti yẹra fún ojú ìwòye tí kò bá ti Ọlọ́run mu, tí ó gbòde kan. Nípa báyìí, àwọn ènìyàn yóò lè rí “ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni búburú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run, àti ẹni tí kò sìn ín.”—Málákì 3:18.
Nígbà tí ọ̀ràn bá di ti ọtí líle, “ìyàtọ̀” tí ó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ayé yẹ kí ó ṣe kedere. Mímu ọtí líle kì í ṣe ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé àwọn Kristẹni tòótọ́. Wọ́n kì í fi bí wọ́n ti lè mu ọtí tó dáran wò, tí wọn yóò fi fẹ́rẹ̀ẹ́ mu àmupara; bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í yọ̀ǹda kí ọtí líle dí ṣíṣiṣẹ́ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn àti èrò inú mímọ́ tónítóní lọ́wọ́ tàbí kí ó forí gbárí pẹ̀lú rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ojú ìwòye tí ó bá ti Ọlọ́run mu nípa ọtí líle. Ìwọ ńkọ́? Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìbùkún Jèhófà bí a ti ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Bíbélì “láti kọ àìṣefẹ́ Ọlọ́run jù sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́ ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti ìfọkànsin Ọlọ́run nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”—Títù 2:12.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “A túmọ̀ ọtí àmujù gẹ́gẹ́ bíi mímu ọtí márùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan fún àwọn ọkùnrin àti ọtí mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan fún àwọn obìnrin.”—The Journal of the American Medical Association.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Fetí Sí Àwọn Tí Ó Nífẹ̀ẹ́ Rẹ
Ẹnì kan tí ń mutí láìní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì kò lè mọ̀ pé òún ní ìṣòro láé láé. Àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́, àti àwọn Kristẹni alàgbà kò ní láti lọ́ tìkọ̀ láti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́, tí wọ́n jẹ́ aláìníwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, bí àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ bá sọ pé inú àwọn kò dùn sí ọ̀nà tí o gbà ń mu ọtí, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ní ìdí fún un. Gbé ohun tí wọ́n ń sọ yẹ̀ wò.—Òwe 19:20; 27:6.