Ìwọ́ Ha Rántí Bí?
O ha ti gbádùn kíka àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò rí i pé ó ń gbádùn mọ́ni láti rántí àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:
◻ Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, pa.rou.siʹa, tí a lò nínú Mátíù 24:3, 27, 37, 39?
Ìwé atúmọ̀ èdè náà, An Expository Dictionary of New Testament Words tí Vine ṣe sọ pé: “PAROUSIA . . . túmọ̀ sí, dídé àti wíwà níhìn-ín tí ó tẹ̀ lé e.” Nítorí náà, kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe àkókò dídé, ṣùgbọ́n wíwà níhìn-ín tí ó bẹ̀rẹ̀ láti àkókò dídé rẹ̀ síwájú.—8/15, ojú ìwé 11.
◻ Báwo ni a ṣe “ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú” kí a baà lè gba “ẹran ara” là ní ọ̀rúndún kìíní, báwo ni yóò sì ṣe ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó túbọ̀ gbòòrò? (Mátíù 24:22)
Ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, láìròtẹ́lẹ̀ àwọn ará Róòmù ké ìsàgatì wọn lórí Jerúsálẹ́mù kúrú, ní fífàyè gba àwọn “ẹran ara” Kristẹni láti sálà. Bákan náà, a fojú sọ́nà pé a óò ké ìkọlù tí ń bọ̀ wá sórí Bábílónì Ńlá kúrú lọ́nà kan ṣá. Nípa báyìí, a óò dáàbò bo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun tí ó lè ṣẹlẹ̀.—8/15, ojú ìwé 18 sí 20.
◻ Kí ni ó yẹ kí ó jẹ́ ìhùwàpadà wa bí ẹnì kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàjọpín nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí tàbí bí ó bá ṣíwọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀?
Kò sí ìdí fún àwọn Kristẹni yòó kù láti dààmú. Jésù wí pé: “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà, mo sì mọ àwọn àgùntàn mi.” Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti mú un dáni lójú, Jèhófà mọ àwọn tí ó ti yàn ní ti gidi gẹ́gẹ́ bí ọmọ tẹ̀mí. (Jòhánù 10:14; Róòmù 8:16, 17)—8/15, ojú ìwé 31.
◻ Kí ni olórí ète Òfin Mósè?
Ní pàtàkì, ó kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìjẹ́pàtàkì Mèsáyà náà, tí yóò rà wọ́n padà kúrò nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Gálátíà 3:24) Òfin náà tún kọ́ni ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìgbọràn, ó sì ran Ísírẹ́lì lọ́wọ́ láti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn àṣà dídíbàjẹ́ ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká. (Léfítíkù 18:24, 25)—9/1, ojú ìwé 9.
◻ Kí ni ète májẹ̀mú tuntun? (Jeremáyà 31:31-34)
Ó jẹ́ láti pèsè orílẹ̀-èdè àwọn ọba àti àlùfáà láti bù kún aráyé. (Ẹ́kísódù 19:6; Pétérù Kìíní 2:9; Ìṣípayá 5:10)—9/1, ojú ìwé 14, 15.
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a sọ títọrọ àforíjì dàṣà?
Ìtọrọ àforíjì lè dín ìrora tí àìpé ń mú wá kù, ó sì lè mú àjọṣe tí kò lọ déédéé mọ́ sunwọ̀n sí i. Àforíjì kọ̀ọ̀kan tí a bá tọrọ jẹ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń kọ́ wa láti túbọ̀ máa kíyè sí ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn.—9/15, ojú ìwé 24.
◻ Àkúnya kárí ayé tí ọjọ́ Nóà ha jẹ́ ìtàn tòótọ́ bí?
Bẹ́ẹ̀ ni. Káàkiri ayé, láti àwọn ilẹ̀ America títí dé Australia, a lè rí àwọn ìròyìn ìgbàanì tí ń sọ nípa ìkún omi kan tí ó kárí ilẹ̀ ayé. Ìtànkálẹ̀ ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí ti òkodoro òtítọ́ náà lẹ́yìn pé àkúnya kárí ayé ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti ròyìn nínú Bíbélì. (Jẹ́nẹ́sísì 7:11-20)—9/15, ojú ìwé 25.
◻ Kí ni jíjẹ́ aláájò àlejò ní nínú? (Róòmù 12:13)
“Aájò àlejò” ni a túmọ̀ láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tí ó ní ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ méjì tí ó túmọ̀ sí “ìfẹ́” àti “àlejò.” Nítorí náà, aájò àlejò ní pàtàkì túmọ̀ sí “ìfẹ́ àlejò.” Ṣùgbọ́n, ó ní nínú ju ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà, tí a ń fi hàn nítorí pé ó jẹ́ ọ̀ranyàn. A gbé e karí ojúlówó ìfẹ́, ìfẹ́ni, àti ìbádọ́rẹ̀ẹ́.—10/1, ojú ìwé 9.
◻ Kí ni ìjiyàn Pọ́ọ̀lù nípa ìgbéyàwó àti wíwà lápọ̀n-ọ́n nínú lẹ́tà rẹ̀ kìíní sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ní orí 7?
Ìgbéyàwó tọ́, ó sì yẹ fún àwọn kan, lábẹ́ àwọn àyíká ipò kan. Síbẹ̀, láìṣeéjá ní kooro, wíwà lápọ̀n-ọ́n ṣàǹfààní fún Kristẹni ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó bá fẹ́ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà pẹ̀lú ìpínyà ọkàn tí ó mọ níwọ̀nba.—10/15, ojú ìwé 13.
◻ Báwo ni alàgbà kan yóò ṣe “pèsè fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀”? (Tímótì Kìíní 5:8)
Alàgbà kan ní láti ‘pèsè fún tirẹ̀’—aya rẹ̀ títí kan àwọn ọmọ rẹ̀—nípa ti ara, nípa tẹ̀mí, àti ní ti èrò ìmọ̀lára.—10/15, ojú ìwé 22.
◻ Báwo ni Jèhófà ṣe ń pèsè ìtùnú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “olùtùnú.” (Jòhánù 14:16, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW) Ọ̀nà míràn tí Ọlọ́run ń gbà pèsè ìtùnú jẹ́ nípasẹ̀ Bíbélì. (Róòmù 15:4) Ọlọ́run mọ àìní olúkúlùkù wa, ó sì lè lò wá láti tu ẹnì kíní kejì wa nínú, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe jèrè ìtùnú nípasẹ̀ ìròyìn Títù nípa àwọn ará Kọ́ríńtì. (Kọ́ríńtì Kejì 7:11-13)—11/1, ojú ìwé 10, 12.
◻ Kí ni ṣíṣàpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “Bàbá àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́,” tí a rí nínú Kọ́ríńtì Kejì 1:3 dọ́gbọ́n túmọ̀ sí?
Ọ̀rọ̀ orúkọ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí “àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” wá láti inú ọ̀rọ̀ kan tí a ń lò láti fi ìbànújẹ́ hàn nígbà tí ẹlòmíràn bá ń jìyà. Nípa báyìí, Pọ́ọ̀lù ń ṣàpèjúwe ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọ́run fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ olùṣòtítọ́ tí ń jìyà ìpọ́njú.—11/1, ojú ìwé 13.
◻ Kí ni gbígbààwẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbààwẹ̀ ní Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún ṣàṣeparí rẹ̀? (Léfítíkù 16:29-31; 23:27)
Gbígbààwẹ̀ ń sún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti túbọ̀ mọ̀ pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àti pé, wọ́n nílò ìràpadà. Nípasẹ̀ rẹ̀, wọ́n fi ìbànújẹ́ hàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì fi ìrònúpìwàdà hàn níwájú Ọlọ́run.—11/15, ojú ìwé 5.
◻ Kí ni àṣẹ náà fún àwọn ọ̀dọ́ pé: “Rántí [Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá, NW] rẹ nísinsìnyí” dọ́gbọ́n túmọ̀ sí? (Oníwàásù 12:1)
Orísun kan sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí a túmọ̀ sí “rántí” sábà máa ń dọ́gbọ́n túmọ̀ sí “ìfẹ́ni ti èrò inú àti ìgbésẹ̀ tí ń bá rírántí rìn.” Nítorí náà, kíkọbi ara sí àṣẹ yìí túmọ̀ sí ju wíwulẹ̀ ronú nípa Jèhófà. Ó kan gbígbégbèésẹ̀, ṣíṣe ohun tí inú rẹ̀ dùn sí.—12/1, ojú ìwé 16.