ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 8/15 ojú ìwé 9-14
  • Wíwá Jésù Tàbí Wíwà Níhìn-ín Jésù—Èwo Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwá Jésù Tàbí Wíwà Níhìn-ín Jésù—Èwo Ni?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Wọ́n Ń Béèrè?
  • Ohun Tí Mátíù Kọ —Ní Èdè Gíríìkì
  • Ibá Ìṣẹ̀lẹ̀ Nínú Èdè Hébérù
  • Dídúró De Òtéńté Wíwà Níhìn-ín Rẹ̀
  • Títan Ìmọ́lẹ̀ Sori Wíwàníhìn-ín Kristi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Wíwàníhìn-ín Messia naa ati Iṣakoso Rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Wíwàníhìn-ín Kristi—Báwo Ló Ṣe Yé ọ sí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Yóò Dé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 8/15 ojú ìwé 9-14

Wíwá Jésù Tàbí Wíwà Níhìn-ín Jésù—Èwo Ni?

‘Kí ni yóò jẹ́ àmì wíwà níhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan?’—MÁTÍÙ 24:3.

1. Ipa wo ni ìbéèrè kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù?

Ọ̀NÀ jíjáfáfá tí Jésù gbà lo ìbéèrè mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ronú, àní wọ́n gbé àwọn nǹkan yẹ̀ wò pẹ̀lú ojú ìwòye tuntun pàápàá. (Máàkù 12:35-37; Lúùkù 6:9; 9:20; 20:3, 4) A lè dúpẹ́ pé ó tún dáhùn àwọn ìbéèrè. Àwọn ìdáhùn rẹ̀ tànmọ́lẹ̀ sí àwọn òtítọ́ tí àwa fúnra wa ì bá má mọ̀ tàbí lóye.—Máàkù 7:17-23; 9:11-13; 10:10-12; 12:18-27.

2. Ìbéèrè wo ni ó yẹ kí a fún ní àfiyèsí nísinsìnyí?

2 Ní Mátíù 24:3, a rí ọ̀kan nínú àwọn ìbéèrè pàtàkì jù lọ tí Jésù tí ì dáhùn rí. Níwọ̀n bí òpin ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ti ń sún mọ́ tòsí, Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ kìlọ̀ pé a óò pa tẹ́ḿpìlì Jerúsálẹ́mù run ni, ní sísàmì sí òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn Júù. Àkọsílẹ̀ Mátíù fi kún un pé: “Bí ó ti jókòó lórí Òkè Ńlá Ólífì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tọ̀ ọ́ wá ní ìdákọ́ńkọ́, wọ́n wí pé: ‘Sọ fún wa, Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwà níhìn-ín [“wíwá,” King James Version] rẹ àti ti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan?’”—Mátíù 24:3.

3, 4. Ìyàtọ̀ pàtàkì wo ni ó wà nínú bí Bíbélì ṣe lo lájorí ọ̀rọ̀ kan nínú Mátíù 24:3?

3 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí ń ka Bíbélì ti ṣe kàyéfì pé, ‘Èé ṣe tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn fi béèrè ìbéèrè yẹn, báwo sì ni ìdáhùn Jésù ṣe yẹ kí ó nípa lórí mi?’ Nínú ìdáhùn rẹ̀, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ìrísí ewé tí ń fi hàn pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn “sún mọ́lé.” (Mátíù 24:32, 33) Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ń fi kọ́ni pé àwọn àpọ́sítélì ń béèrè fún àmì “wíwá” Jésù, àmì tí ń fi hàn pé dídé rẹ̀ ti kù sí dẹ̀dẹ̀. Wọ́n gbà gbọ́ pé “wíwá” náà yóò jẹ́ àkókò náà gan-an tí yóò mú àwọn Kristẹni lọ sí ọ̀run, tí yóò sì mú òpin ayé wá. Ìwọ́ ha gbà gbọ́ pé èyí tọ̀nà bí?

4 Dípò ìtumọ̀ náà “wíwá,” àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan, títí kan ti New World Translation of the Holy Scriptures, lo ọ̀rọ̀ náà “wíwà níhìn-ín.” Ṣe kì í ṣe pé ohun tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn béèrè àti ohun tí Jésù fèsì yàtọ̀ sí ohun tí a fi ń kọ́ni nínú ṣọ́ọ̀ṣì? Kí ni wọ́n béèrè gan-an? Kí sì ni ìdáhùn tí Jésù fún wọn?

Kí Ni Wọ́n Ń Béèrè?

5, 6. Ìparí èrò wo ni a lè dé nípa èrò àwọn àpọ́sítélì nígbà tí wọ́n béèrè ìbéèrè tí a kà ní Mátíù 24:3?

5 Bí a bá gbé ohun tí Jésù sọ nípa tẹ́ḿpìlì yẹ̀ wò, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ti máa ronú nípa ìṣètò àwọn Júù nígbà tí wọ́n béèrè fún ‘àmì wíwà níhìn-ín [tàbí, “wíwá”] rẹ̀ àti ti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan [ní òwuuru, “sànmánì”].’—Fi wé “ayé” ní Kọ́ríńtì Kìíní 10:11 àti Gálátíà 1:4, KJ.

6 Níbi tí ọ̀ràn dé yìí, òye díẹ̀ ni àwọn àpọ́sítélì ní nípa ẹ̀kọ́ Jésù. Wọ́n ti lérò tẹ́lẹ̀ pé “ìjọba Ọlọ́run yóò fi ara rẹ̀ hàn sóde ní ìṣẹ́jú akàn.” (Lúùkù 19:11; Mátíù 16:21-23; Máàkù 10:35-40) Àní lẹ́yìn ìjíròrò lórí Òke Ólífì pàápàá, ṣùgbọ́n ṣáájú kí a tó fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n, wọ́n béèrè bí Jésù yóò bá dá Ìjọba padà fún Ísírẹ́lì nígbà náà lọ́hùn-ún.—Ìṣe 1:6.

7. Èé ṣe tí àwọn àpọ́sítélì fi lè béèrè nípa ipa iṣẹ́ Jésù ní ọjọ́ ọ̀la?

7 Síbẹ̀, wọ́n mọ̀ pé yóò lọ, nítorí kò tí ì pẹ́ tí ó wí pé: “Ìmọ́lẹ̀ yóò wà láàárín yín fún ìgbà díẹ̀ sí i. Ẹ rìn nígbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀ náà.” (Jòhánù 12:35; Lúùkù 19:12-27) Nítorí náà, wọ́n ti lè máa ṣe kàyéfì ní tòótọ́ pé, ‘Bí Jésù yóò bá lọ, báwo ni a óò ṣe mọ ìpadàbọ̀ rẹ̀?’ Nígbà tí ó fara hàn bíi Mèsáyà, ọ̀pọ̀ jù lọ kò mọ̀ ọ́n. Ní èyí tí ó lé ní ọdún kan lẹ́yìn náà, a ṣì ń béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa bóyá òun yóò ṣe gbogbo ohun tí Mèsáyà náà ní láti ṣe. (Mátíù 11:2, 3) Nítorí náà, àwọn àpọ́sítélì ní ìdí láti wádìí nípa ọjọ́ ọ̀la. Ṣùgbọ́n, lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n ha ń béèrè fún àmì kan pé òun yóò dé láìpẹ́ tàbí fún ohun mìíràn tí ó yàtọ̀ bí?

8. Èdè wo ni ó ṣeé ṣe kí àwọn àpọ́sítélì máa bá Jésù sọ?

8 Rò ó wò ná pé o jẹ́ ẹyẹ kan tí ń gbọ́ ìjíròrò náà tí ń lọ lọ́wọ́ lórí Òke Ólífì. (Fi wé Oníwàásù 10:20.) Bóyá ìwọ ì bá ti gbọ́ tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù. (Máàkù 14:70; Jòhánù 5:2; 19:17, 20; Ìṣe 21:40) Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n tún lè sọ èdè Gíríìkì.

Ohun Tí Mátíù Kọ —Ní Èdè Gíríìkì

9. Orí kí ni a gbé ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ òde òní ti Mátíù kà?

9 Àwọn àkọsílẹ̀ tí a kọ ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa fi hàn pé èdè Hébérù ni Mátíù kọ́kọ́ fi kọ Ìhìn Rere rẹ̀. Ó hàn gbangba pé ó kọ ọ́ ní èdè Gíríìkì lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ọ̀pọ̀ ìwé àfọwọ́kọ ní èdè Gíríìkì ṣì wà títí di ọjọ́ wa, wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún títúmọ̀ Ìhìn Rere rẹ̀ sí àwọn èdè òde òní. Kí ni Mátíù kọ ní èdè Gíríìkì nípa ìjíròrò yẹn lórí Òke Ólífì? Kí ni ó kọ nípa “wíwá” tàbí “wíwà níhìn-ín” tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn béèrè, tí Jésù sì sọ̀rọ̀ lé lórí?

10. (a) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì wo fún “wá” ní Mátíù lò lọ́pọ̀ ìgbà, ìtumọ̀ wo sì ni ó lè ní? (b) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì mìíràn wo ni ó fà wá lọ́kàn mọ́ra?

10 Nínú orí 23 àkọ́kọ́ nínú Mátíù, ó lé ní ìgbà 80 tí a rí ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Gíríìkì náà tí a sábà máa ń lò fún “wá,” èyí tí í ṣe erʹkho·mai. Ó sábà máa ń ní ìtumọ̀ sísún mọ́lé tàbí kíkù sí dẹ̀dẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú Jòhánù 1:47 pé: “Jésù rí tí Nàtáníẹ́lì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.” Ó sinmi lórí bí a bá ṣe lò ó, ọ̀rọ̀ ìṣe náà erʹkho·mai lè túmọ̀ sí “dé,” “lọ,” “dé ibì kan” “gúnlẹ̀ sí ibì kan” tàbí “kí ẹnì kan máa bọ̀ lọ́nà.” (Mátíù 2:8, 11; 8:28; Jòhánù 4:25, 27, 45; 20:4, 8; Ìṣe 8:40; 13:51) Ṣùgbọ́n nínú Mátíù 24:3, 27, 37, 39, Mátíù lo ọ̀rọ̀ tí ó yàtọ̀, ọ̀rọ̀ orúkọ kan tí a kò rí níbò míràn nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere: pa·rou·siʹa. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ni ó mí sí kíkọ Bíbélì, èé ṣe tí ó fi sún Mátíù láti yan ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, nígbà tí ó ń kọ Ìhìn Rere rẹ̀ sílẹ̀ ní èdè Gíríìkì? Kí ni ó túmọ̀ sí, èé sì ti ṣe tí ó fi yẹ kí a mọ̀ ọ́n?

11. (a) Kì ni ìtumọ̀ tí pa·rou·siʹa ní? (b) Báwo ni àwọn àpẹẹrẹ láti inú ìwé Josephus ṣe bá òye wa nípa pa·rou·siʹa mu? (Wo àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé.)

11 Ní ṣàkó, pa·rou·siʹa túmọ̀ sí “wíwà níhìn-ín.” Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Expository Dictionary of New Testament Words tí Vine ṣe, sọ pé: “PAROUSIA, . . . ní [òwuuru] túmọ̀ sí, wíwà níhìn-ín, para, pẹ̀lú, ousia, tí ó wà (láti inú eimi, láti wà), túmọ̀ sí dídé àti wíwà níhìn-ín tí ó tẹ̀ lé e. Fún àpẹẹrẹ, nínú lẹ́tà pápírọ́sì kan, ọmọbìnrin kan sọ nípa ìjẹ́pàtàkì parousia rẹ̀ ní ọ̀gangan ibì kan, kí ó baà lè yanjú àwọn ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ dúkìá rẹ̀.” Àwọn ìwé atúmọ̀ èdè míràn ṣàlàyé pé pa·rou·siʹa túmọ̀ sí ‘ìbẹ̀wò olùṣàkóso kan.’ Nítorí náà, kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe àkókò dídé, ṣùgbọ́n wíwà níhìn-ín tí ó bẹ̀rẹ̀ láti àkókò dídé rẹ̀ síwájú. Ó dùn mọ́ni pé, bí Júù òpìtàn nì, Josephus, tí ó jẹ́ alájọgbáyé pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì, ṣe lo pa·rou·siʹa nìyẹn.a

12. Báwo ni Bíbélì gan-an ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́rìí sí ìtumọ̀ pa·rou·siʹa?

12 Ìlànà ìwé kíkọ ìgbàanì jẹ́rìí sí ìtumọ̀ náà “wíwà níhìn-ín,” síbẹ̀, àwọn Kristẹni ní pàtàkì ní ọkàn ìfẹ́ nínú bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lo pa·rou·siʹa. Ìdáhùn náà ṣì jẹ́ bákan náà—wíwà níhìn-ín. A rí ìyẹn nínú àwọn àpẹẹrẹ tí ń bẹ nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù. Fún àpẹẹrẹ, ó kọ̀wé sí àwọn ará Fílípì pé: “Ní ọ̀nà tí ẹ ń gbà ṣègbọràn nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n nísinsìnyí pẹ̀lú ìmúratán púpọ̀ sí i nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà tiyín yọrí.” Ó tún sọ̀rọ̀ nípa bíbá gbogbo wọn gbé kí wọ́n baà lè yọ ayọ̀ àṣeyọrí “nípasẹ̀ wíwà [pa·rou·siʹa] [rẹ̀] lẹ́ẹ̀kan sí i pẹ̀lú [wọn].” (Fílípì 1:25, 26; 2:12) Àwọn ìtumọ̀ míràn kà pé “wíwà mi pẹ̀lú yín lẹ́ẹ̀kan sí i” (Weymouth; New International Version); “nígbà tí mo bá wà pẹ̀lú yín lẹ́ẹ̀kan sí i” (Jerusalem Bible; New English Bible); àti “nígbà tí ẹ bá tún rí mi láàárín yín lẹ́ẹ̀kan sí i.” (Twentieth Century New Testament) Nínú Kọ́ríńtì Kejì 10:10, 11, Pọ́ọ̀lù fi “wíwà níhìn-ín òun alára” wéra pẹ̀lú ‘àìkò sí lọ́dọ̀ wọn.’ Nínú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí, ó ṣe kedere pé, òun kò sọ̀rọ̀ nípa bí àkókò tí yóò dé ṣe sún mọ́lé tó tàbí dídé rẹ̀; ó lo pa·rou·siʹa lọ́nà tí ó túmọ̀ sí wíwà láàárín wọn.b (Fi wé Kọ́ríńtì Kìíní 16:17.) Ṣùgbọ́n, àwọn ìtọ́ka sí pa·rou·siʹa Jésù ńkọ́? Wọ́n ha túmọ̀ sí “wíwá” rẹ̀, tàbí wọ́n ha tọ́ka sí wíwà níhìn-ín tí ń bá a nìṣó bí?

13, 14. (a) Èé ṣe tí a fi gbọ́dọ̀ parí èrò sí pé pa·rou·siʹa gba àkókò? (b) Kí ni a gbọ́dọ̀ sọ nípa bí pa·rou·siʹa Jésù ti gùn tó?

13 Àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró ní ọjọ́ Pọ́ọ̀lù ní ọkàn-ìfẹ́ nínú pa·rou·siʹa Jésù. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún wọn, kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ‘a tètè mì wọ́n kúrò nínú ìmọnúúrò wọn.’ Lákọ̀ọ́kọ́ “ọkùnrin ìwà àìlófin” yóò kọ́kọ́ dé, èyí tí ó wá jẹ́ àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé “wíwà níhìn-ín aláìlófin náà jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ Sátánì pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ agbára àti àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn àpẹẹrẹ ìyanu irọ́.” (Tẹsalóníkà Kejì 2:2, 3, 9) Ó ṣe kedere pé, pa·rou·siʹa, tàbí wíwà níhìn-ín, “ọkùnrin ìwà àìlófin” kì í wulẹ̀ ṣe dídé ní àkókò kan pàtó; yóò gba àkókò, nígbà tí àwọn àmì irọ́ yóò fi fara hàn. Èé ṣe tí èyí fi ṣe pàtàkì?

14 Gbé ẹsẹ tí ó ṣáájú ìyẹn gan-an yẹ̀ wò: “A óò ṣí aláìlófin náà payá, ẹni tí Jésù Olúwa yóò fi ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ pa tí yóò sì sọ di asán nípasẹ̀ ìfarahàn kedere wíwà níhìn-ín rẹ̀.” Gan-an gẹ́gẹ́ bí wíwà níhìn-ín “ọkùnrin ìwà àìlófin” yóò ti jẹ́ fún sáà àkókò kan, wíwà níhìn-ín Jésù yóò wà fún àkókò kan, tí yóò sì dé òtéńté rẹ̀ nínú ìparun “ọmọ ìparun” oníwà àìlófin yẹn.—Tẹsalóníkà Kejì 2:8.

Ibá Ìṣẹ̀lẹ̀ Nínú Èdè Hébérù

15, 16. (a) Ọ̀rọ̀ wo gan-an ni a lò nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ ti Mátíù sí èdè Hébérù? (b) Báwo ni a ṣe lo bohʼ nínú Ìwé Mímọ́?

15 Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkíyèsí, ó hàn gbangba pé èdè Hébérù ni Mátíù kọ́kọ́ fi kọ Ìhìn Rere rẹ̀. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Hébérù wo ni ó lò nínú Mátíù 24:3, 27, 37, 39? Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Mátíù tí a túmọ̀ sí èdè Hébérù ti òde òní ní irú ọ̀rọ̀ ìṣe bíi bohʼ, nínú ìbéèrè àwọn àpọ́sítélì àti nínú èsì Jésù. Èyí lè yọrí sí kíkà á lọ́nà yìí: “Kí ni yóò jẹ́ àmì [bohʼ] rẹ àti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan?” àti, “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni [bohʼ] Ọmọkùnrin ènìyàn yóò rí.” Kí ni bohʼ túmọ̀ sí?

16 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní onírúurú ìtumọ̀, ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù náà bohʼ ní ti gidi túmọ̀ sí “wá.” Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Theological Dictionary of the Old Testament, sọ pé: ‘Bohʼ tí ó fara hàn nígbà tí ó lé ní 2,532, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe tí a lò léraléra jù lọ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, òun sì ni olórí àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe tí ń sọ ìṣípòpadà.’ (Jẹ́nẹ́sísì 7:1, 13; Ẹ́kísódù 12:25; 28:35; Sámúẹ́lì Kejì 19:30; Àwọn Ọba Kejì 10:21; Orin Dáfídì 65:2; Aísáyà 1:23; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 11:16; Dáníẹ́lì 9:13; Ámósì 8:11) Ká ní Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti lo ọ̀rọ̀ tí ó ní ọ̀wọ́ ìtumọ̀ bẹ́ẹ̀, ìtumọ̀ rẹ̀ ì bá fa ìjiyàn. Ṣùgbọ́n wọ́n ha lò ó bí?

17. (a) Èé ṣe tí ó fi ṣeé ṣe pé àwọn ìtumọ̀ òde òní ti Mátíù sí èdè Hébérù lè má fi ohun tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ hàn? (b) Níbo ni a tún ti lè rí ojútùú sí ọ̀rọ̀ tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì ti lè lò, ìdí mìíràn wo sì ni orísun yìí fi fà wá lọ́kàn mọ́ra? (Wo àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé.)

17 Rántí pé àwọn ẹ̀dà Hébérù òde òní jẹ́ ìtumọ̀ tí ó lè máà gbé ohun tí Mátíù kọ ní èdè Hébérù kalẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí. Òkodoro òtítọ́ náà ni pé, ó ṣeé ṣe fún Jésù láti lo ọ̀rọ̀ míràn yàtọ̀ sí bohʼ, ọ̀kan tí ó bá ìtumọ̀ pa·rou·siʹa mu. A rí èyí nínú ìwé náà, Hebrew Gospel of Matthew, tí Ọ̀jọ̀gbọ́n George Howard ṣe ní 1995. Ìwé náà darí àfiyèsí sórí àtakò gbígbóná janjan ti ọ̀rúndún kẹrìnlá sí ìsìn Kristẹni láti ọwọ́ Júù oníṣègùn náà, Shem-Tob ben Isaac Ibn Shaprut. Àkọsílẹ̀ yẹn gbé ẹsẹ ìwé mímọ́ lédè Hébérù ti Ìhìn Rere Mátíù kalẹ̀. Ẹ̀rí wà pé, dípò kí ó jẹ́ pé a túmọ̀ rẹ̀ láti inú èdè Látínì tàbí Gíríìkì ní àkókò Shem-Tob, ẹsẹ ìwé mímọ́ ti Mátíù yìí ti pẹ́, a sì ṣàkójọ rẹ̀ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní èdè Hébérù.c Ó lè tipa báyìí túbọ̀ mú wa sún mọ́ ohun tí a sọ ní Òkè Ólífì.

18. Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù fífani mọ́ra wo ni Shem-Tob lò, kí sì ni ó túmọ̀ sí?

18 Nínú Mátíù 24:3, 27, 39, Mátíù ti Shem-Tob kò lo ọ̀rọ̀ ìṣe náà bohʼ. Dípò èyí, ó lo ọ̀rọ̀ orúkọ tí ó fara jọ ọ́ bi·ʼahʹ. Ọ̀rọ̀ orúkọ yẹ́n fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù kìkì nínú Ìsíkẹ́ẹ̀lì 8:5, níbi tí ó ti túmọ̀ sí “ọ̀nà.” Dípò níní ìtumọ̀ ìgbésẹ̀ wíwá, bi·ʼahʹ níhìn-ín túmọ̀ sí ẹnu ọ̀nà ilé kan; nígbà tí o bá wà lẹ́nu ọ̀nà tàbí níbi àbáwọlé, o ti wà nínú ilé náà. Bákan náà, àwọn àkọsílẹ̀ tí kì í ṣe apá kan Bíbélì àmọ́ tí ó jẹ́ ti ìsìn, lára Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, sábà ń lo bi·ʼahʹ ní sísọ̀rọ̀ nípa dídé tàbí ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àlùfáà. (Wo Kíróníkà Kìíní 24:3-19; Lúùkù 1:5, 8, 23.) Ìtumọ̀ tí a ṣe sí èdè Hébérù ti Síríákì (tàbí, Árámáíkì) ìgbàanì ní ọdún 1986, Peshitta, lo bi·ʼahʹ nínú Mátíù 24:3, 27, 37, 39. Nítorí náà, ẹ̀rí wà pé ní àkókò ìgbàanì ọ̀rọ̀ orúkọ náà bi·ʼahʹ ti lè ní ìtumọ̀ tí ó yàtọ̀ sí ohun tí ọ̀rọ̀ ìṣe náà, bohʼ, tí a lò nínú Bíbélì túmọ̀ sí. Èé ṣe tí èyí fi fà wá lọ́kàn mọ́ra?

19. Bí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì bá lo bi·ʼah,ʹ ìparí èrò wo ni a lè dé?

19 Nínú ìbéèrè àwọn àpọ́sítélì àti nínú èsì Jésù, wọ́n ti lè lo ọ̀rọ̀ orúkọ náà bi·ʼah.ʹ Àní bí àwọn àpọ́sítélì náà tilẹ̀ ní kìkì èrò nípa dídé Jésù ní ọjọ́ ọ̀la lọ́kàn, Kristi ti lè lo bi·ʼahʹ láti yọ̀ọ̀da fún ohun tí ó ré kọjá ohun tí wọ́n ń ronú rẹ̀. Jésù ti lè máa tọ́ka sí dídé rẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ onípò tuntun kan; dídé rẹ̀ yóò jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ipa iṣẹ́ rẹ̀ tuntun. Èyí yóò bá ìtumọ̀ pa·rou·siʹa mu, èyí tí Mátíù lò lẹ́yìn ìgbà náà. Lọ́nà tí a lè lóye, lílo bi·ʼahʹ lọ́nà bẹ́ẹ̀ yóò ní láti ti ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fi kọ́ni láti ìgbà pípẹ́ lẹ́yìn, pé “àmì” alápá púpọ̀ tí Jésù fúnni jẹ́ láti fi hàn pé òún ti wà níhìn-ín.

Dídúró De Òtéńté Wíwà Níhìn-ín Rẹ̀

20, 21. Kí ni a lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ Jésù nípa àwọn ọjọ́ Nóà?

20 Ìkẹ́kọ̀ọ́ wa nípa wíwà níhìn-ín Jésù yẹ kí ó ní agbára ìdarí tààràtà lórí ìgbésí ayé wa àti ìfojúsọ́nà wa. Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti wà lójúfò. Ó pèsè àmì kan, kí wọ́n baà lè mọ̀ pé òún ti wà níhìn-ín, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ kì yóò fiyè sí i: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwà níhìn-ín Ọmọkùnrin ènìyàn yóò rí. Nítorí bí wọ́n ti wà ní àwọn ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ náà tí Nóà wọ inú ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwà níhìn-ín Ọmọkùnrin ènìyàn yóò rí.”—Mátíù 24:37-39.

21 Ní ọjọ́ Nóà, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn ìran yẹ́n wulẹ̀ ń bá àlámọ̀rí ojoojúmọ́ wọn lọ. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò rí pẹ̀lú “wíwà níhìn-ín Ọmọkùnrin ènìyàn.” Àwọn ènìyàn tí wọ́n yí Nóà ká ti lè rò pé kò sí ohunkóhun tí yóò ṣẹlẹ̀. O mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ti gidi. Àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn, tí ó jẹ́ fún sáà kan, yọrí sí òtéńté kan, “ìkún omi . . . dé ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” Lúùkù gbé irú àkọsílẹ̀ kan náà kalẹ̀ nínú èyí tí Jésù ti fi “àwọn ọjọ́ Nóà” wéra pẹ̀lú “àwọn ọjọ́ Ọmọkùnrin ènìyàn.” Jésù ṣíni létí pé: “Bákan náà ni yóò rí ní ọjọ́ náà nígbà tí a óò ṣí Ọmọkùnrin ènìyàn payá.”—Lúùkù 17:26-30.

22. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a lọ́kàn ìfẹ́ pàtàkì nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nínú Mátíù orí 24?

22 Gbogbo èyí ní ìtumọ̀ àrà ọ̀tọ̀ fún wa nítorí pé, a ń gbé ní àkókò kan tí àwa mọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀—ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, àìtó oúnjẹ, àti ṣíṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀. (Mátíù 24:7-9; Lúùkù 21:10-12) Àwọn ipò wọ̀nyẹn ti wà láti ìgbà ìforígbárí tí ó yí ìtàn padà, ní pàtàkì, tí a sọ lórúkọ náà Ogun Àgbáyé Kìíní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ka èyí sí apá kan ìtàn lásán. Ṣùgbọ́n, àwọn Kristẹni tòótọ́ lóye ìtumọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé yìí, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí ó wà lójúfò ṣe ń lóye pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ń sún mọ́lé nígbà tí igi ọ̀pọ̀tọ́ bá ń rudi. Jésù gbani nímọ̀ràn pé: “Ní ọ̀nà yìí ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.”—Lúùkù 21:31.

23. Àwọn wo ni ọ̀rọ̀ Jésù nínú Mátíù orí 24 ní ìtumọ̀ àrà ọ̀tọ̀ fún, èé sì ti ṣe?

23 Jésù darí ọ̀pọ̀ nínú èsì rẹ̀ lórí Òke Ólífì sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ni yóò nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà náà, ti wíwàásù ìhìn rere ní gbogbo ilẹ̀ ayé kí òpin tó dé. Àwọn ni yóò fòye mọ “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́.” Àwọn ni yóò dáhùn padà nípa “sísá” kí ìpọ́njú ńlá tó dé. Àwọn ní pàtàkì sì ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó fi kún un náà yóò nípa lé lórí pé: “Láìjẹ́ pé a ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là; ṣùgbọ́n ní tìtorí àwọn àyànfẹ́ a óò ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú.” (Mátíù 24:9, 14-22) Ṣùgbọ́n kí ni àwọn ọ̀rọ̀ amúnironújinlẹ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀ sí, èé sì ti ṣe tí a fi lè sọ pé wọ́n pèsè ìdí fún wa láti ní ayọ̀, ìgbọ́kànlé, àti ìtara púpọ̀ sí i lónìí? Ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó tẹ̀ lé e nípa Mátíù 24:22 yóò pèsè àwọn ìdáhùn náà.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn àpẹẹrẹ láti ọwọ́ Josephus: Ní Òke Sínáì mànàmáná àti àrá “fi hàn pé Ọlọ́run wà [pa·rou·siʹa] níbẹ̀.” Ìfarahàn lọ́nà ìyanu nínú àgọ́ àjọ “fi wíwà níhìn-ín [pa·rou·siʹa] Ọlọ́run hàn.” Nípa fífi àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí ó pagbo yí wọn ká han ìránṣẹ́ Èlíṣà, Ọlọ́run “fi agbára àti wíwà níhìn-ín [pa·rou·siʹa] rẹ̀ hàn fún ìránṣẹ́ rẹ̀.” Nígbà tí ìjòyè òṣìṣẹ́ Róòmù Petronius gbìyànjú láti tu àwọn Júù lójú, Josephus sọ pé ‘Ọlọ́run fi wíwà níhìn-ín [pa·rou·siʹa] rẹ̀ hàn fún Petronius, nípa rírọ̀jò. Josephus kò lo pa·rou·siʹa fún sísún mọ́lé lásán tàbí dídé ní àkókò pàtó. Ó túmọ̀ sí wíwà níhìn-ín tí ń bá a nìṣó, àní tí a kò lè fojú rí. (Ẹ́kísódù 20:18-21; 25:22; Léfítíkù 16:2; Àwọn Ọba Kejì 6:15-17)—Fi wé Antiquities of the Jews, Ìwé 3, orí 5, ìpínrọ̀ 2 [80]; orí 8, ìpínrọ̀ 5 [202]; Ìwé 9, orí 4, ìpínrọ̀ 3 [55]; Ìwé 18, orí 8, ìpínrọ̀ 6 [284].

b Nínú ìwé atúmọ̀ èdè náà, A Critical Lexicon and Concordance to the English and Greek New Testament, E. W. Bullinger ṣàlàyé pé, pa·rou·siʹa túmọ̀ sí ‘wíwà tàbí dídi ẹni tí ó wà níhìn-ín, nítorí náà, wíwà níhìn-ín, dídé; wíwá tí ó ní èrò bíbáni gbé fún ìgbà pípẹ́ láti àkókò dídé yẹn síwájú.’

c Ẹ̀rí kan ni pé ó ní gbólóhùn èdè Hébérù náà, “Orúkọ Náà,” ní ìgbà 19, tí a kọ tán tàbí tí a ké kúrú. Ọ̀jọ̀gbọ́n Howard kọ̀wé pé: “Kíka Orúkọ Àtọ̀runwá náà nínú àkọsílẹ̀ Kristẹni tí Júù alátakò gbígbóná janjan kán ṣàdàkọ rẹ̀ jẹ́ ohun pípẹtẹrí. Bí èyí bá jẹ́ ìtumọ̀ èdè Hébérù ti àkọsílẹ̀ Kristẹni lédè Gíríìkì tàbí Látìnì, ẹnì kan yóò retí láti rí adonai [Olúwa] nínú ẹsẹ ìwé mímọ́ náà, kì í ṣe ohun tí yóò dúró fún orúkọ àtọ̀runwá tí a kò gbọdọ̀ pè náà YHWH. . . . Ìdí tí ó ṣe fi orúkọ tí a kò gbọdọ̀ pé náà kún un ni a kò lè ṣàlàyé. Ẹ̀rí náà fi hàn ní kedere pé, Shem-Tob rí Mátíù tirẹ̀ gbà pẹ̀lú Orúkọ Àtọ̀runwá náà tí ó ti wà nínú ẹsẹ ìwé mímọ́ náà tẹ́lẹ̀, tí ó sì ṣeé ṣe kí ó ti pa á mọ́, kàkà tí ì bá fi fara rẹ̀ wewu jíjẹ̀bi yíyọ ọ́ kúrò.” Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures—With References lo Mátíù (J2) ti Shem-Tob gẹ́gẹ́ bí ìtìlẹ́yìn fún lílo orúkọ àtọ̀runwá náà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti rí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín bí àwọn Bíbélì ṣe lo Mátíù 24:3?

◻ Kí ni ìtumọ̀ pa·rou·siʹa, èé sì ti ṣe tí a fi lọ́kàn ìfẹ́ nínú rẹ̀?

◻ Ìjọra wo ni ó ṣeé ṣe kí ó wà nínú Mátíù 24:3 ní èdè Gíríìkì àti ní èdè Hébérù?

◻ Kókó abájọ wo nípa àkókò ni ó yẹ kí a mọ̀ tí a bá lóye Mátíù 24?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Òkè Ólífì, tí a lè máa tibẹ̀ wo Jerúsálẹ́mù nísàlẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́