ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 10/1 ojú ìwé 14-19
  • Wíwàníhìn-ín Messia naa ati Iṣakoso Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwàníhìn-ín Messia naa ati Iṣakoso Rẹ̀
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀nà Ipadabọ Kristi
  • Nigba wo ni ó Bẹrẹ?
  • Eeṣe Ti O Fi Jẹ́ Akoko Oniwahala?
  • Nigba Ti Messia Ba Ń Ṣakoso Ayé
  • Bi Iṣakoso Rẹ̀ Ṣe Kàn Ọ́
  • Títan Ìmọ́lẹ̀ Sori Wíwàníhìn-ín Kristi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Yóò Dé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Wíwá Jésù Tàbí Wíwà Níhìn-ín Jésù—Èwo Ni?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Mèsáyà! Ọ̀nà Ìgbàlà Tí Ọlọ́run Pèsè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 10/1 ojú ìwé 14-19

Wíwàníhìn-ín Messia naa ati Iṣakoso Rẹ̀

“Jesu yii ti a gbà soke kuro lọdọ yin sí ojú-ọ̀run yoo wá bayii ni iru ọ̀nà kan-naa bi ẹ ti rí i ti ń lọ si ojú-ọ̀run.”—IṢE 1:11, NW.

1, 2. (a) Bawo ni awọn angẹli meji ṣe tu awọn aposteli Jesu ninu nigba ti ó goke re ọrun? (b) Awọn ibeere wo ni a gbé dide nipa ifojusọna fun ipadabọ Kristi?

AWỌN ọkunrin 11 duro lori gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìhà    ila-oorun Òkè Olifi, ni wíwo ojú-ọ̀run    toto. Iwọnba iṣẹju diẹ sẹhin gan-an ni Jesu Kristi ti gberasoke laaarin wọn, irisi rẹ̀ bẹrẹ sii di fírífírí titi di ìgbà ti awọsanma fi mú un pòórá. Ninu awọn ọdun ti wọn lò pẹlu rẹ̀, awọn ọkunrin wọnyi ti rí i ti Jesu funni ní ẹ̀rí ti ó pọ yanturu pe oun ni Messia naa; wọn tilẹ ti walaaye la ọkàn gbígbọgbẹ́ ti ikú rẹ̀ fà ati ìbúrẹ́kẹ́ ayọ ajinde rẹ̀ já. Nisinsinyi oun ti lọ.

2 Awọn angẹli meji farahan lojiji wọn sì sọ awọn ọ̀rọ̀ onitunu wọnyi: “Ẹyin eniyan Galili, eeṣe ti ẹ fi duro ń wo ojú-ọ̀run? Jesu yii ti a gbà soke kuro lọdọ yin si ojú-ọ̀run yoo wá bayii ni iru ọ̀nà kan-naa bi ẹ ti rí i ti ń lọ si ojú-ọ̀run.” (Iṣe 1:11, NW) Ẹ wo bi o ti finilọkanbalẹ tó—igoke re ọ̀run Jesu kò tumọsi pe oun ti pari pẹlu ilẹ̀-ayé ati araye! Ni idakeji, Jesu yoo pada wá. Kò sí iyemeji pe awọn ọ̀rọ̀ wọnyi yoo mu ki awọn aposteli naa kún fun ireti. Araadọta-ọkẹ awọn eniyan lonii pẹlu so ijẹpataki giga mọ ileri ipadabọ Kristi. Awọn kan sọrọ nipa rẹ̀ gẹgẹ bi “Ìpadàwá Ẹlẹẹkeji” tabi “Bíbọ̀wá.” Bi o ti wu ki o ri, ọpọ julọ, ni ó jọbii pe a ń rú loju nipa ohun ti ipadabọ Kristi tumọsi niti gidi. Ni ọ̀nà wo ni Kristi gbà padabọ? Nigba wo? Bawo sì ni eyi ṣe nipa lori igbesi-aye wa lonii?

Ọ̀nà Ipadabọ Kristi

3. Kí ni ọpọ eniyan gbagbọ nipa ipadabọ Kristi?

3 Gẹgẹ bi iwe naa An Evangelical Christology ti wi, “ìpadàwá ẹlẹẹkeji tabi ipadabọ Kristi (parousia) fidii ijọba Ọlọrun mulẹ, nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín, ni gbangba, ati fun gbogbo ayeraye.” Igbagbọ ti gbogbo eniyan dimu ni pe ipadabọ Kristi yoo ṣee fojuri ni gbangba wálíà, tí gbogbo eniyan ti ń gbé planẹti yii yoo rí i niti gidi. Lati ti èrò yii lẹhin, ọpọlọpọ ń tọka si Ìfihàn 1:7 (NW), eyi ti ó kà pe: “Wò ó! Ó ń bọ̀ pẹlu awọsanma, gbogbo ojú ni yoo sì rí i, ati awọn wọnni ti wọn gún un ní ọ̀kọ̀.” Ṣugbọn ó ha tumọsi pe ẹsẹ yii ni a nilati loye ni olówuuru bi?

4, 5. (a) Bawo ni a ṣe mọ̀ pe Ìfihàn 1:7 ni a kò nilati tumọ ni èrò olowuuru? (b) Bawo ni awọn ọ̀rọ̀ Jesu funraarẹ ṣe fi ẹ̀rí òye yii hàn?

4 Ranti, iwe Ìfihàn ni a gbekalẹ “nipa awọn àmì.” (Ìfihàn 1:1, NW) Nigba naa, àyọkà-ọ̀rọ̀ yii, gbọdọ jẹ́ afiṣapẹẹrẹ; ó ṣetan, bawo ni “awọn wọnni ti wọn gún un ní ọ̀kọ̀” ṣe lè rí ipadabọ Kristi? Wọn ti kú ni ohun tí ó fẹrẹẹ tó ọrundun lọna 20! Siwaju sii, awọn angẹli sọ pe Kristi yoo padabọ “ni iru ọ̀nà kan-naa” bi o ti lọ. Ó dara, ọ̀nà wo ni ó gbà lọ? Pẹlu araadọta-ọkẹ tí ń wò ó ni bi? Bẹẹkọ, iwọnba awọn oluṣotitọ diẹ pere ni wọn rí iṣẹlẹ naa. Nigba ti angẹli naa sì bá wọn sọrọ, awọn aposteli naa ha ń wo Kristi tí ń rinrin-ajo taarata lọ si ọrun niti gidi bi? Bẹẹkọ, bíbò ti awọsanma bo Jesu mú ki o pòórá mọ́ wọn loju. Ni akoko kan lẹhin ìgbà naa, oun ti nilati wọnu awọn ọrun tẹmi lọ gẹgẹ bi ẹ̀dá ẹmi kan, ti kò ṣee fojuri fun eniyan. (1 Korinti 15:50) Nitori naa, patapata, awọn aposteli naa rí kìkì ibẹrẹ irin-ajo Jesu; wọn kò lè rí opin rẹ̀, ipadabọ rẹ̀ si iwaju Baba rẹ̀ lọrun, Jehofa. Eyi ni wọn lè foye mọ̀ kìkì pẹlu oju igbagbọ wọn.—Johannu 20:17.

5 Bibeli kọni pe Jesu ń padabọ ni ọ̀nà ti ó rí bakan-naa gan-an. Jesu funraarẹ sọ ni kété ṣaaju ikú rẹ̀ pe: “Nigba diẹ sii, ayé kì ó sì rí mi mọ́.” (Johannu 14:19) Ó tun sọ pe “ijọba Ọlọrun kò ní wá pẹlu ṣíṣeékíyèsí tí ń pàfiyèsí.” (Luku 17:20, NW) Ni èrò itumọ wo, nigba naa, ni ‘gbogbo oju yoo rí i’? Lati dahun, a kọ́kọ́ nilo òye kedere nipa ọ̀rọ̀ ti Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lò ni isopọ pẹlu ipadabọ rẹ̀.

6. (a) Eeṣe ti awọn ọ̀rọ̀ bii “ipadabọ,” “dídé,” “bíbọ̀wá,” ati “ìpadàwá” kìí fií ṣe itumọ kikunrẹrẹ ti o bá ọ̀rọ̀ Griki naa pa·rou·siʹa mu? (b) Kí ni o fihàn pe pa·rou·siʹa, tabi “wíwàníhìn-ín,” pẹ́ pupọ ju iṣẹlẹ onigba kukuru gan-an lasan lọ?

6 Otitọ naa ni pe, Kristi ṣe pupọ pupọ ju wiwulẹ “padabọ.” Ọ̀rọ̀ yẹn, bii “ìpadàwá,” “dídé,” tabi “bíbọ̀wá,” dọgbọn tumọsi iṣẹlẹ kanṣoṣo ni ìgbà kukuru gan-an. Ṣugbọn ọ̀rọ̀ Griki naa ti Jesu ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lò tumọsi ohun ti ó pọ̀ jù bẹẹ lọ. Ọ̀rọ̀ naa ni pa·rou·siʹa, ti o tumọ ní olówuuru si “wíwà ni ìhà-ẹ̀gbẹ́” tabi “wíwàníhìn-ín.” Ọpọ julọ ninu awọn ọmọwe fohunṣọkan pe ọ̀rọ̀ yii ni ninu kìí ṣe kìkì dídé nikan bikoṣe wíwàníhìn-ín tí ó tẹle e pẹlu—gẹgẹ bii ti ibẹwo ọlọla-ọba Orilẹ-ede kan. Wíwàníhìn-ín yii kìí ṣe iṣẹlẹ onigba kukuru gan-an; sanmani akanṣe kan ni, sáà akoko kan ti a sàmì sí ni. Ni Matteu 24:37-39 (NW), Jesu sọ pe “wíwàníhìn-ín [pa·rou·siʹa] Ọmọkunrin eniyan” yoo dabi “awọn ọjọ Noa” eyi ti ó pari sí Ikun-omi. Noa ń kan ọkọ̀ áàkì ó sì ń kilọ fun awọn eniyan buburu fun ọpọ ẹwadun ṣaaju ki Ikun-omi naa tó dé ti ó sì gbá eto igbekalẹ ayé oniwa-palapala yẹn lọ. Bẹẹ gẹgẹ, nigba naa, wíwàníhìn-ín alaiṣeefojuri ti Kristi wà fun ohun ti o ju sáà ọpọ ẹwadun lọ ṣaaju ki ó tó pari sí iparun ńláǹlà pẹlu.

7. (a) Kí ni fihàn pe pa·rou·siʹa naa ni eniyan kò le fojuri? (b) Bawo ati nigba wo ni imuṣẹ yoo deba awọn ẹsẹ iwe mimọ ti o ṣapejuwe ipadabọ Kristi gẹgẹ bi eyi ti “gbogbo oju” yoo rí?

7 Laiṣiyemeji, pa·rou·siʹa naa kò ṣeefojuri niti gidi fun oju eniyan. Bi ó bá rí bẹẹ ni, eeṣe ti Jesu yoo fi lo akoko pupọ tobẹẹ, gẹgẹ bi awa yoo ṣe rí i, ní fifun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni àmì lati ràn wọ́n lọwọ lati foyemọ wíwàníhìn-ín yii?a Bi o ti wu ki o ri, nigba ti Kristi bá wá lati pa eto igbekalẹ ayé Satani run, otitọ wíwàníhìn-ín rẹ̀ ni yoo farahan fun gbogbo eniyan lọna ti o pabambari. Nigba naa ni “gbogbo oju yoo rí i.” Àní awọn alatako Jesu paapaa yoo lè foyemọ, si ìdààmú araawọn, pe iṣakoso Kristi jẹ́ otitọ gidi.—Wo Matteu 24:30; 2 Tessalonika 2:8; Ìfihàn 1:5, 6.

Nigba wo ni ó Bẹrẹ?

8. Awọn iṣẹlẹ wo ni wọn sàmì sí ibẹrẹ wíwàníhìn-ín Kristi, nibo sì ni eyi ti ṣẹlẹ?

8 Wíwàníhìn-ín Messia bẹrẹ pẹlu iṣẹlẹ kan ti ó mú ẹsin-ọrọ awọn asọtẹlẹ tí ń farahan leralera ṣẹ nipa Messia. Oun ni a dé ládé gẹgẹ bi Ọba ni ọrun. (2 Samueli 7:12-16; Isaiah 9:6, 7; Esekieli 21:26, 27) Jesu fúnraarẹ̀ fihàn pe wíwàníhìn-ín oun ni a o so pọ mọ́ ipo ọba rẹ̀. Ninu awọn àkàwé melookan, o fi araarẹ̀ wé ọ̀gá kan ti ó fi agbo-ile ati awọn ẹrú rẹ̀ silẹ sẹhin, ni ririnrin-ajo fun akoko gigun lọ si “ilu okeere” kan nibi ti o ti gba “ijọba.” Ó funni ni iru àkàwé kan bayii gẹgẹ bi apakan idahun rẹ̀ si ibeere awọn aposteli rẹ̀ nipa igba ti pa·rou·siʹa rẹ̀ yoo bẹrẹ; omiran ni oun sọ nitori ti “wọn ń rò pe, ijọba Ọlọrun yoo farahàn nisinsinyi.” (Luku 19:11, 12, 15; Matteu 24:3; 25:14, 19) Nitori naa ní ìgbà ayé rẹ̀ gẹgẹ bi ọkunrin kan, ìgbà ìfinijoyè rẹ̀ ṣì jẹ akoko jíjìnnà kan, lati ṣẹlẹ ni “ilu okeere” ti ọrun. Nigba wo ni yoo ṣẹlẹ?

9, 10. Idaniloju wo ni o wà pe Kristi ń ṣakoso lọwọlọwọ ni ọrun, nigba wo sì ni ó bẹrẹ iṣakoso rẹ̀?

9 Nigba ti awọn ọmọ-ẹhin Jesu bi í leere pe: “Kí ni yoo ṣe àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀, ati ti opin ayé?” Jesu dahunpada nipa fifun wọn ni kulẹkulẹ apejuwe kan nipa akoko ọjọ iwaju yẹn. (Matteu, ori 24, NW; Marku, ori 13; Luku, ori 21; tun wo 2 Timoteu 3:1-5; Ìfihàn, ori 6.) Àmì yii parapọ jẹ́ kulẹkulẹ aworan sanmani oniwahala kan. Ó jẹ akoko kan tí ogun jakejado awọn orilẹ-ede, iwa-ipa ti ń gasoke, igbesi-aye idile ti ń jorẹhin, ajakalẹ awọn àrùn, ìyàn, ati awọn iṣẹlẹ ń sàmì sí—kìí ṣe bii awọn iṣoro ti a fimọ si adugbo kan ṣugbọn gẹgẹ bi akoko lilekoko ti o bo gbogbo agbaye. Eyi ha dabi ohun ti a mọ̀ dunjú bi? Ọjọ kọọkan tí ń kọja lọ jẹrii sii pe ọrundun lọna 20 yii bá apejuwe Jesu mu rẹ́gí.

10 Awọn opitan fohunṣọkan pe 1914 jẹ́ ikorita iyipada kan ninu ìtàn ẹdá, ọdun ṣiṣepataki kan lẹhin eyi ti ọpọ awọn iṣoro wọnyii bẹrẹ sii kọja akoso, ti ó ń ga sii ni iye jakejado agbaye. Bẹẹni, awọn iṣẹlẹ ayé ti a lè fojuri ni imuṣẹ asọtẹlẹ Bibeli lapapọ ń tọka si 1914 gẹgẹ bi ọdun naa nigba ti Jesu bẹrẹ sii ṣakoso gẹgẹ bi Ọba ni ọrun. Siwaju sii, asọtẹlẹ kan ní Danieli ori 4 pese ẹ̀rí niti iṣeto akoko iṣẹlẹ ti o ṣamọna wa si ọdun kan-naa—1914—gẹgẹ bi akoko naa ti Ọba Jehofa ti a yàn yoo bẹrẹ iṣakoso rẹ̀.b

Eeṣe Ti O Fi Jẹ́ Akoko Oniwahala?

11, 12. (a) Eeṣe ti o fi ṣoro fun awọn kan lati gbagbọ pe Kristi ń ṣakoso ni ọrun ni lọwọlọwọ bayii? (b) Bawo ni a ṣe lè ṣakawe ohun ti o sẹlẹ lẹhin ti a dé Jesu ládé bi Ọba?

11 Bi o ti wu ki o ri, awọn kan ṣe kayeefi pe, ‘Eeṣe ti a fi ń daamu ayé tobẹẹ bi Messia ba ń ṣakoso ni ọrun? Iṣakoso rẹ̀ ha jẹ́ eyi ti kò gbeṣẹ ni bi?’ Àkàwé kan le ṣeranwọ. Aarẹ buburu kan ń ṣakoso orilẹ-ede kan. Ó ti gbé iṣeto oniwa ibajẹ kan kalẹ pẹlu awọn agbara idari ti ó nasẹ̀ dé origun mẹrẹẹrin ilẹ naa. Ṣugbọn a ṣe ìdìbò kan; ọkunrin rere kan bori. Ni bayii kí ni yoo ṣẹlẹ? Bi ọran ti jẹ́ ni awọn ilẹ onijọba dẹmọ kan, akoko ìpààrọ̀ ijọba oloṣu diẹ kan yoo wà ki a tó fi aarẹ titun naa sori oye. Bawo ni awọn ọkunrin meji wọnyi yoo ṣe huwa laaarin iru akoko bayii? Ǹjẹ́ ọkunrin rere naa yoo ha gbejako ki o si wó gbogbo aburú ti aṣiwaju rẹ̀ ti ṣe ni gbogbo orilẹ-ede naa palẹ lẹsẹkẹsẹ bi? Kaka bẹẹ, oun kì yoo ha pọkanpọ sori ilu tii ṣe olu-ilu naa lakọọkọ, ni ṣiṣagbekalẹ igbimọ awọn olùdámọ̀ràn ijọba titun kan ki o si maa fawọ ajọṣepọ sẹhin kuro lọdọ awọn alábàákẹ́gbẹ́ ati awọn alatilẹhin oníwà-wíwọ́ ti aarẹ iṣaaju naa bi? Ni ọ̀nà yẹn, nigba ti o ba wọnu iṣakoso lẹkun-unrẹrẹ, oun lè ṣiṣẹ lati ori àlééfà agbara mimọtonitoni, ti o sì gbeṣẹ. Nipa ti aarẹ oniwa-ibajẹ naa, oun kò ha ni lo anfaani akoko kukuru ti o ṣẹ́kù lati kó gbogbo awọn èrè ti o lè fèrú kojọ́ ṣaaju ki o tó padanu gbogbo agbara bi?

12 Niti gasikiya, ó jọra pẹlu pa·rou·siʹa Kristi. Ìfihàn 12:7-12 fihàn pe nigba ti a fi Kristi jẹ Ọba ni ọrun, ó kọ́kọ́ fi Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ sọko kuro ni ọrun, ni titipa bayii fọ ibi-ààyè ijọba Rẹ̀ mọ́. Lẹhin jijiya iṣẹgun ti a ti ń reti tipẹtipẹ yii, bawo ni Satani ṣe huwa laaarin “akoko kukuru” naa ṣaaju ki Kristi tó lo agbara rẹ̀ ni kikun nihin-in lori ilẹ̀-ayé? Gẹgẹ bii ti aarẹ oniwa-ibajẹ yẹn, ó ń gbiyanju lati kó ohun gbogbo ti o bá lè ri ninu eto ogbologbo yii jọ. Oun kò lepa owó; kaka bẹẹ ó ń lepa ẹmi awọn eniyan. Ó ń fẹ́ lati sọ ọpọ awọn eniyan bi ó bá ti le ṣeeṣe tó di àjèjì Jehofa ati Ọba Rẹ̀ ti ń ṣakoso.

13. Bawo ni Iwe Mimọ ṣe fihàn pe ibẹrẹ iṣakoso Kristi yoo jẹ́ akoko oniwahala nihin-in lori ilẹ̀-ayé?

13 Abajọ, nigba naa, ti o fi jẹ́ pe ibẹrẹ iṣakoso Messia tumọsi akoko “ègbé . . . fun ayé.” (Ìfihàn 12:12) Bakan-naa, Orin Dafidi 110:1, 2, 6 fihàn pe Messia naa bẹrẹ iṣakoso rẹ̀ ‘laaarin awọn ọ̀tá rẹ̀.’ Kiki lẹhin naa ni yoo fọ́ ‘awọn orilẹ-ede,’ túútú papọ pẹlu olukuluku apa eto igbekalẹ oniwa-ibajẹ ti Satani, sinu òkun ìgbàgbé!

Nigba Ti Messia Ba Ń Ṣakoso Ayé

14. Kí ni Messia naa yoo le ṣe lẹhin ti o ba ti pa eto igbekalẹ awọn nǹkan buburu ti Satani run?

14 Lẹhin ti o bá ti pa eto igbekalẹ Satani ati gbogbo awọn ti wọn kọwọ tì í run, Messia Ọba naa, Jesu Kristi, ni paripari rẹ̀ yoo wà ni ipo lati mú awọn asọtẹlẹ Bibeli agbayanu ti o ṣapejuwe Iṣakoso Ẹgbẹrundun Ijọba rẹ̀ ṣẹ. Isaiah 11:1-10 ràn wá lọwọ lati rí iru alakoso ti Messia yoo jẹ́ gan-an. Ẹsẹ 2 sọ fun wa pe oun yoo ní “ẹmi Oluwa . . . , ẹmi ọgbọ́n ati òye, ẹmi igbimọ ati agbara.”

15. Kí ni ‘ẹmi agbara’ yoo tumọsi ninu iṣakoso Messia naa?

15 Ṣagbeyẹwo ohun ti ‘ẹmi agbara’ yoo tumọsi ninu iṣakoso Jesu. Nigba ti o wà lori ilẹ̀-ayé, oun ni ìwọ̀n agbara pàtó kan lati ọdọ Jehofa, eyi ti ó mú ki o ṣeeṣe fun un lati ṣe awọn iṣẹ́ iyanu. Oun sì fi ìfẹ́-ọkàn atinuwa hàn lati ṣeranlọwọ fun awọn eniyan, ni wiwi pe, “Mo fẹ́.” (Matteu 8:3) Ṣugbọn iṣẹ iyanu rẹ̀ ní awọn ọjọ wọnni wulẹ jẹ́ òfìrí aṣetẹlẹ ohun ti oun yoo ṣe nigba ti o bá ń ṣakoso lati ọrun ni. Jesu yoo ṣe awọn iṣẹ iyanu ti o wà jakejado agbaye! Awọn alaisan, afọju, odi, alábùkù-ara, ati arọ ni a o mu larada fun gbogbo akoko. (Isaiah 35:5, 6) Ọpọ ounjẹ, ti a fi ododo pin, yoo fopin si ebi titilae. (Orin Dafidi 72:16) Kí ni nipa ti awọn ọkẹ aimọye ti wọn wà ninu sàréè ti o dunmọ Ọlọrun ninu lati ranti? “Agbara” Jesu yoo ni ninu agbara naa lati jí wọn dide, ni fífún olukuluku ni anfaani naa lati gbé titilae ninu Paradise! (Johannu 5:28, 29) Sibẹ, ani pẹlu gbogbo agbara yii, Messia Ọba naa yoo maa jẹ́ onirẹlẹ lọna jijinlẹ nigba gbogbo. “Òórùn-dídùn rẹ̀ sì wà ni ibẹru Oluwa.”—Isaiah 11:3.

16. Iru Onidaajọ wo ni Messia Ọba naa yoo jẹ́, bawo ni iyẹn yoo sì ṣe yatọ si akọsilẹ tí awọn eniyan ti wọn jẹ́ onidaajọ ní?

16 Ọba yii yoo tun jẹ́ Onidaajọ pípé. “Oun kì yoo si dajọ nipa ìrí ojú rẹ̀, bẹẹ ni kì yoo dajọ nipa gbígbọ́ etí rẹ̀.” Eniyan ti o jẹ́ onidaajọ wo, ni atijọ ati ni isinsinyi, ni a lè ṣapejuwe ni ọ̀nà yẹn? Àní ọkunrin onidaajọ yiyekooro kan paapaa le ṣedajọ kìkì nipa ohun ti oun rí ti o si gbọ́, ni lilo ọgbọ́n ati òye eyikeyii ti oun lè ni. Nipa bayii, awọn onidaajọ ati awọn ẹgbẹ́ igbimọ onidaajọ ti ayé ogbologbo yii ni awọn ọgbọ́n àrékérekè jíjáfáfá, awọn iṣe apanilẹrin-in ninu kootu, tabi ẹ̀rí ti ń takora lè darí tabi ṣì lọna. Ni ọpọ ìgbà kìkì awọn ọlọ́rọ̀ ati awọn alagbara ni ipá wọn lè ká ṣíṣe igbeja ara-ẹni ti o gbeṣẹ, ní ríra idajọ niti gidi. Kò ri bẹẹ labẹ Messia Onidaajọ naa! Oun mọ ohun tí ó wà ninu ọkan-aya. Ohunkohun kì yoo kọja afiyesi rẹ̀. Idajọ òdodo ti a fi ifẹ ati aanu ṣe, kì yoo jẹ fun títà. Yoo maa figba gbogbo borí.—Isaiah 11:3-5.

Bi Iṣakoso Rẹ̀ Ṣe Kàn Ọ́

17, 18. (a) Aworan ti ń tàn yòò nipa ọjọ-ọla araye wo ni a yà ninu Isaiah 11:6-9? (b) Ta ni asọtẹlẹ yii ni imuṣẹ lé lori ni pataki, eeṣe ti o fi rí bẹẹ? (c) Bawo ni asọtẹlẹ yii yoo ṣe ní imuṣẹ gidi kan?

17 Lọna ti o yéni, iṣakoso Messia ní idari jijinlẹ lori awọn ọmọ abẹ́ rẹ̀. Ó ń yí awọn eniyan pada. Isaiah 11:6-9 fi bi iru awọn iyipada bẹẹ ti gbooro tó gan-an hàn. Asọtẹlẹ yii ya aworan kan ti ń jẹnilọkan nipa awọn ẹranko elewu, apanijẹ—awọn beari, ìkookò, amọtẹkun, kinniun, ejò ọká—ni aarin awọn ẹran-ọsin alailepanilara ati awọn ọmọde paapaa. Ṣugbọn awọn ẹranko apanijẹ wọnyii kò fa ijamba kankan! Eeṣe? Ẹsẹ 9 dahun pe: “Wọn kì yoo panilara, bẹẹ ni wọn kì yoo panirun ni gbogbo oke mimọ mi: nitori ayé yoo kún fun imọ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bo òkun.”

18 Niti tootọ, “imọ Oluwa” kò ni ipa kankan lori awọn ẹranko niti gidi; nipa bayii awọn ẹsẹ wọnyi gbọdọ ni imuṣẹ taarata lori awọn eniyan. Iṣakoso Messia naa ń ṣagbatẹru itolẹsẹẹsẹ idanilẹkọọ kárí-ayé kan, ni kíkọ́ awọn eniyan nipa Jehofa ati awọn ọ̀nà rẹ̀, ni kíkọ́ gbogbo wọn lati bá awọn eniyan bii tiwọn lò pẹlu ifẹ, ọ̀wọ̀, ati ọlá. Ninu Paradise ti ń bọ̀, Messia naa yoo gbé araye dide lọna iyanu si ijẹpipe niti ara ìyára ati iwa-rere. Awọn ìwia apanijẹ, bii ti ẹranko ti o dá àbàwọ́n si ìwà ẹ̀dá alaipe yoo ti lọ. Ni èrò itumọ gidi, pẹlu, araye yoo wà ni alaaafia pẹlu awọn ẹranko—nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín!—Fiwe Genesisi 1:28.

19. Bawo ni iṣakoso Messia naa ṣe ni ipa lori igbesi-aye awọn eniyan ni awọn ikẹhin ọjọ wọnyi?

19 Bi o ti wu ki o ri, ranti, Messia naa ń ṣakoso nisinsinyi. Ani nisinsinyi, awọn ọmọ abẹ́ Ijọba rẹ̀ ń kẹkọọ lati gbé papọ ni alaaafia, ni mimu Isaiah 11:6-9 ṣẹ ni ọ̀nà kan. Ju bẹẹ lọ, fun eyi ti o fẹrẹẹ to 80 ọdun, Jesu ti ń mú Isaiah 11:10 ṣẹ: “Ati ni ọjọ naa kùkùté Jesse kan yoo wà, ti yoo duro fun ọ̀págun awọn eniyan; oun ni awọn keferi yoo wá rí: isinmi rẹ̀ yoo si ni ògo.” Awọn eniyan lati orilẹ-ede gbogbo ń yipada si Messia naa. Eeṣe? Nitori pe lati ìgbà ti o ti bẹrẹ sii ṣakoso, oun ti “duro fun ọ̀págun.” Óun ti ń sọ wíwàníhìn-ín rẹ̀ di mímọ̀ jakejado ayé nipasẹ itolẹsẹẹsẹ ikọnilẹkọọ ńláǹlà ti a ṣapejuwe loke. Niti tootọ, Jesu sọtẹlẹ pe iṣẹ iwaasu kan jakejado gbogbo ayé yoo jẹ́ àmì titayọ julọ ti wíwàníhìn-ín rẹ̀ ki opin eto igbekalẹ ogbologbo yii tó dé.—Matteu 24:14.

20. Iṣarasihuwa wo ni gbogbo awọn ọmọ abẹ́ iṣakoso Messia naa nilati yẹra fun, eesitiṣe?

20 Nitori naa wíwàníhìn-ín Kristi ninu agbara Ijọba kìí ṣe ọ̀ràn ti o díjú, ti o jẹ́ ti imọ-ero-ori lasan kan, kókó ariyanjiyan ti ọgbọn-ori laaarin awọn ẹlẹkọọ isin. Iṣakoso rẹ̀ ní ipá ó sì ń yí igbesi-aye pada lori ilẹ̀-ayé nihin-in, gan-an gẹgẹ bi Isaiah ti sọtẹlẹ pe yoo ri. Jesu ti fa araadọta-ọkẹ awọn ọmọ abẹ́ Ijọba rẹ̀ jade kuro ninu eto igbekalẹ ayé onibajẹ yii. Iwọ ha jẹ́ iru ọmọ abẹ́ bẹẹ bi? Nigba naa ṣiṣẹsin pẹlu gbogbo ìtara ati ayọ ti ó yẹ Alakoso wa! Bẹẹni ó rọrun daradara lati ṣaarẹ, lati darapọ mọ́ igbe ìbẹ̀tẹ́luni ti ayé naa pe: “Nibo ni ileri yii ti wíwàníhìn-ín rẹ̀ gbé wà?” (2 Peteru 3:4, NW) Ṣugbọn gẹgẹ bi Jesu funraarẹ ti sọ, “ẹni ti o bá foriti i titi de opin, oun naa ni a o gbàlà.”—Matteu 24:13.

21. Bawo ni gbogbo wa ṣe le mu imọriri wa fun ireti ti Messia naa pọ̀ sii?

21 Ọjọ kọọkan tí ń kọja lọ ń mú wa sunmọ ọjọ ńlá naa nigba ti Jehofa yoo dari Ọmọkunrin Rẹ̀ lati sọ wíwàníhìn-ín rẹ̀ di mímọ̀ fun gbogbo ayé. Maṣe jẹ́ ki ireti rẹ ninu ọjọ́ yẹn di bàìbàì lae. Ṣaṣaro lori ipo Messia Jesu ati lori awọn akòpọ animọ rẹ̀ gẹgẹ bii Ọba ti ń ṣakoso. Ronu jinlẹ, pẹlu, nipa Jehofa Ọlọrun, oluṣẹda ati alatilẹhin ireti ńlá ti Messia naa ti a lasilẹ ninu Bibeli. Bi iwọ ti ń ṣe bẹẹ, laisi iyemeji iwọ yoo nimọlara pupọpupọ sii gẹgẹ bi aposteli Paulu ti ṣe nigba ti o kọwe pe: “Áà! ijinlẹ ọrọ̀ ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ Ọlọrun!”—Romu 11:33.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Pada sẹhin ni 1864 R. Govett ẹlẹkọọ-isin sọ ọ́ ni ọ̀nà yii: “Lójú temi eyi dabii ohun ti o ṣe pàtó gan-an. Fifunni ni àmì Wíwàníhìn-ín fihàn pe aṣiri ni. A kò nilo àmì ìtọ́ka kankan lati sọ wíwàníhìn-ín ohun ti a rí di mímọ̀ fun wa.”

b Fun kulẹkulẹ, wo iwe naa “Let Your Kingdom Come” [Gẹẹsi], oju-iwe 133 si 139.

Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Ni ọna wo ni Kristi gbà padabọ?

◻ Bawo ni a ṣe mọ̀ pe pa·rou·siʹa Kristi jẹ alaiṣeefojuri ti o sì wà fun sáà akoko gigun kan?

◻ Nigba wo ni wíwàníhìn-ín Kristi bẹrẹ, bawo ni awa si ṣe mọ eyi?

◻ Iru Alakoso ọrun wo ni Messia naa jẹ́?

◻ Ni awọn ọ̀nà wo ni iṣakoso Kristi fi nipa lori igbesi-aye awọn ọmọ abẹ rẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ireti naa pe Jesu yoo padabọ tumọsi ohun pupọ fun awọn aposteli rẹ̀ oloootọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ni ṣiṣakoso lati ọrun wá, Jesu yoo ṣe awọn iṣẹ́ iyanu ní ìwọ̀n ti ó jẹ́ kárí-ayé

[Credit Line]

Ilẹ̀-ayé: A gbé e kari fọto NASA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́