ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 5/1 ojú ìwé 10-15
  • Títan Ìmọ́lẹ̀ Sori Wíwàníhìn-ín Kristi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Títan Ìmọ́lẹ̀ Sori Wíwàníhìn-ín Kristi
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Wíwàníhìn-ín Oluwa Wa”
  • Àmì Naa
  • Igbokegbodo Angẹli
  • Ajinde ti Ọ̀run
  • Iwaasu Kárí-Ayé
  • Wà ni Mímọ́ ati ni Ailaleebu
  • Wíwá Jésù Tàbí Wíwà Níhìn-ín Jésù—Èwo Ni?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Wíwàníhìn-ín Messia naa ati Iṣakoso Rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Wíwàníhìn-ín Kristi—Báwo Ló Ṣe Yé ọ sí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Yóò Dé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 5/1 ojú ìwé 10-15

Títan Ìmọ́lẹ̀ Sori Wíwàníhìn-ín Kristi

“Nigba ti Ọmọ eniyan yoo wá ninu ògo rẹ̀, . . . yoo si yà wọn si ọ̀tọ̀ kuro ninu araawọn.”—MATTEU 25:31, 32.

1. Ki ni awọn alufaa Kristẹndọm tumọ awọn ọ̀rọ̀ ti o wà ni Matteu 24:3 si?

NI ỌJỌ́ mẹta ṣaaju iku Jesu, mẹrin ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá wọn sì fi tọkantọkan beere pe: “Sọ fun wa, nigba wo ni nǹkan wọnyi yoo sẹ? Ki ni yoo si ṣe ami wíwá [Griki, pa·rou·siʹa] rẹ, ati ti opin ayé?” Fun ọpọ ọrundun awọn alufaa ati awọn onkọwe Kristẹndọm ti tumọ awọn ọ̀rọ̀ wọnyi ti a sọ si Jesu ninu Matteu 24:3 lati tumọsi pe oun yoo lẹẹkan sii ṣeefojuri ninu ara ki gbogbo ẹda araye lè wò ó. Nitori naa, wọn ti kọ́ni pe ipadabọ Kristi yoo jẹ́ pẹlu aṣehan nla ati afẹfẹyẹyẹ ti o ṣeefojuri. Wọn tọka si i gẹgẹ bi ipadabọ Kristi ẹlẹẹkeji. Ṣugbọn ero wọn ha tọna bi?

2, 3. (a) Ki ni iyatọ ti Idipọ 2 Studies in the Scriptures ṣe laaarin awọn ọ̀rọ̀ naa “bíbọ̀” ati “wíwàníhìn-ín”? (b) Ki ni awọn eniyan Jehofa wá loye nipa itumọ pa·rou·siʹa Kristi?

2 Ni ọdun 1889, awọn ẹni-ami-ororo Jehofa, gẹgẹ bi olutan ìmọ́lẹ̀ ọrundun kọkandinlogun, ti gba atunṣe ṣaaju akoko yii lori ọ̀ràn ipadabọ Kristi. Ninu Idipọ 2 Studies in the Scriptures, oju-iwe 158 si 161, Charles T. Russell, ààrẹ akọkọ ti Watch Tower Bible and Tract Society, kọwe pe: “Parousia . . . ṣapẹẹrẹ wíwàníhìn-ín, a kò sì gbọdọ tumọ rẹ̀ si bíbọ̀, gẹgẹ bi o ti rí ninu Bibeli Gẹẹsi ti o wọ́pọ̀ . . . Bibeli ‘Emphatic Diaglott,’ itumọ ti o niyelori gidi kan ti Majẹmu Titun, tumọ parousia lọna yíyẹ, wíwàníhìn-ín . . . , kìí ṣe ti bíbọ̀, bi ẹni pe o wà loju ọ̀nà, ṣugbọn wíwàníhìn-ín, gẹgẹ bii lẹhin dídé [Jesu] sọ pe, ‘Gẹgẹ bi ọjọ Noa, bẹẹ ni parousia [wíwàníhìn-ín] Ọmọkunrin eniyan yoo rí.’ Ṣakiyesi, pe ifiwera naa kìí ṣe laaarin bíbọ̀ Noa ati bíbọ̀ Oluwa wa . . . Iyatọ naa, nigba naa, jẹ laaarin akoko wíwàníbẹ̀ Noa laaarin awọn eniyan ‘ṣaaju ikun-omi,’ ati akoko wíwàníhìn-ín Kristi ninu ayé, nígbà dídé rẹ̀ ẹlẹẹkeji, ‘ṣaaju iná’—iṣoro lilekenka ti Ọjọ Oluwa [Jehofa] ninu eyi ti opin yoo gba débá iran yii.”—Matteu 24:37.

3 Nitori naa awọn eniyan Jehofa ti ọrundun kọkandinlogun fi ẹ̀tọ́ loye pe pa·rou·siʹa Kristi yoo jẹ́ ọ̀kan ti a kì yoo lè fojuri. Wọn tilẹ ti wá loye pẹlu pe opin Akoko Awọn Keferi yoo wáyé ni akoko ìkórè ni 1914. Bi ilaloye nipa tẹmi ti ń tẹsiwaju, wọn loye lẹhin naa pe Jesu Kristi ni a fi jọba ni ọrun gẹgẹ bi Ọba Ijọba ni ọdun yẹn kan naa, 1914.—Owe 4:18; Daniel 7:13, 14; Luku 21:24; Ìfihàn 11:15.

“Wíwàníhìn-ín Oluwa Wa”

4. “Wíwàníhìn-ín Oluwa wa Jesu Kristi” ń tọka si ki ni?

4 Nigba naa, ni ọjọ wa, ki ni ohun ti ọ̀rọ̀ Bibeli naa “wíwàníhìn-ín Oluwa wa Jesu Kristi” tumọsi? (1 Tessalonika 5:23, NW) Ọla-aṣẹ kan ṣalaye pe ede-isọrọ naa “wíwàníhìn-ín,” pa·rou·siʹa, “di ede-isọrọ ti a faṣẹ si fun ibẹwo ẹnikan ti o jẹ́ ọlọla nla, paapaa [julọ] awọn ọba ati awọn olu-ọba ti wọn ń bẹ igberiko kan wò.” Nitori naa ọ̀rọ̀ yii ń tọkasi wíwàhíhìn-ín ọba ti Oluwa Jesu Kristi gẹgẹ bi Ọba, lati 1914 wá ati lẹhin naa, tẹle ìgbégorí ìtẹ́ rẹ̀ ni ọrun. Oun wàníhìn-ín laiṣeefojuri lati ‘maa jọba laaarin awọn ọ̀tá rẹ̀,’ ni ṣiṣakoso taarata gẹgẹ bi Ọba lati mú àṣẹ alasọtẹlẹ yii ṣẹ. (Orin Dafidi 110:2) Fun awọn nǹkan bii ọdun 79, awọn eniyan lori ilẹ̀-ayé ti ń ni iriri ipa wíwàníhìn-ín alaiṣeefojuri ti Kristi bi ọba.

5. Awọn idagbasoke wo nigba pa·rou·siʹa ni a o jiroro ninu ọrọ-ẹkọ mẹta ninu iwe-irohin yii?

5 Ninu ọ̀wọ́ awọn ọrọ-ẹkọ mẹta yii, awa yoo gbe ẹ̀rí mimunadoko nipa awọn aṣepari Ijọba Kristi ni akoko yii yẹwo. Lakọọkọ, awa yoo gbe awọn asọtẹlẹ Bibeli melookan kalẹ ti ń sasọtẹlẹ nipa awọn iṣẹlẹ ti o ti ṣẹlẹ ṣaaju akoko yii tabi ti o ń ṣẹlẹ nisinsinyi paapaa. Lẹẹkeji, awa yoo ṣapejuwe iṣẹ bàǹtà-banta ti ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu ti Jesu ń lo ń ṣaṣepari rẹ̀ ni gbogbo akoko wíwàníhìn-ín rẹ̀ bi ọba. (Matteu 24:45-47) Ọrọ-ẹkọ kẹta yoo ṣapejuwe ipari titobilọla naa fun wa, akoko “ipọnju nla.” Iyẹn ni akoko ti Jesu wá gẹgẹ bi Olùfìyà-ikú-jẹni Jehofa lati pa awọn eniyan alaiṣododo run ki o sì gba awọn olódodo là. (Matteu 24:21, 29-31) Akoko iparun yẹn ni aposteli Paulu ṣapejuwe gẹgẹ bi mimu ‘isinmi pẹlu wa fun ẹyin ti a ń pọ́n loju, nigba ifarahan Jesu Oluwa lati ọrun wá ninu ọwọ́ iná pẹlu awọn angẹli alagbara rẹ̀, ẹni ti yoo san ẹsan fun awọn ti kò mọ Ọlọrun, ti wọn kò sì gba ihinrere Jesu Oluwa wa gbọ́.’—2 Tessalonika 1:7, 8.

Àmì Naa

6. Awọn àmì alapa pupọ wo ni a ṣapejuwe ninu Matteu ori 24 ati 25?

6 Ni ọrundun mọkandinlogun sẹhin, awọn olùtan ìmọ́lẹ̀ ọmọlẹhin Jesu beere fun àmì kan, tabi ẹ̀rí lọwọ rẹ̀ nipa wíwàníhìn-ín ọjọ-ọla rẹ̀ ninu agbara Ijọba. Èsì rẹ̀ ti a kọsilẹ ninu ori kẹrinlelogun ati ikẹẹdọgbọn iwe Matteu, pese ami alapa pupọ kan, eyi ti gbogbo apa rẹ̀ ń ni imuṣẹ nisinsinyi jakejado gbogbo agbaye. Imuṣẹ àmì yẹn sami si akoko idaamu ati idanwo nla. Jesu kilọ pe: “Ẹ kiyesara, ki ẹnikẹni ki o maṣe tan yin jẹ. Nitori ọpọlọpọ yoo wá ni orukọ mi, wi pe, Emi ni Kristi; wọn o sì tan ọpọlọpọ jẹ. Ẹyin ó sì gburoo ogun ati idagiri ogun: ẹ kiyesi i ki ẹyin ki o maṣe jáyà: nitori gbogbo nǹkan wọnyi kò lè ṣe ki o ma ṣẹ, ṣugbọn opin kìí ṣe isinsinyi.”—Matteu 24:4-6.

7. Awọn apa wo ninu àmì naa ni a ti ri ti o ni imuṣẹ lati 1914?

7 Jesu sọ asọtẹlẹ siwaju sii pe ogun yoo wà ni iwọn kan ti kò tii ṣẹlẹ ri. Ninu imuṣẹ rẹ̀, meji ninu iwọnyi ni a ti kàsí ogun agbaye, ọ̀kan lati 1914 si 1918 ati ekeji lati 1939 si 1945. Siwaju sii, o sọ pe aito ounjẹ ati iṣẹlẹ yoo wà ni ibikan si ibomiran. Awọn Kristian tootọ ni a o ṣe inunibini si kíkankíkan. Gan-an gẹgẹ bi asọtẹlẹ naa ti wí, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, awọn olùtan ìmọ́lẹ̀ ti ode-oni, ti jiya inunibini fun ẹwadun mẹjọ ti o kọja nigba ti wọn ń waasu ihinrere Ijọba Ọlọrun “ni gbogbo ayé lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede.” (Matteu 24:7-14) Iwe Yearbook of Jehovah’s Witnesses kọọkan fikun ẹ̀rí naa pe awọn apá iha wọnyi ni a ń muṣẹ ninu ami naa.

8, 9. (a) Ki ni wíwàníhìn-ín Jesu bi ọba ni ninu? (b) Ki ni asọtẹlẹ Jesu ti o niiṣe pẹlu awọn èké Kristi fihàn nipa ibi ti yoo dé si ati ọ̀nà ti yoo gbà wàníhìn-ín?

8 Niwọn bi ipo-ọba Jesu ti ni gbogbo ayé ninu, ijọsin tootọ ń gbooro ni gbogbo agbaye. Wíwàníhìn-ín rẹ̀ bi ọba (pa·rou·siʹa) jẹ́ akoko ayẹwo kaakiri agbaye. (1 Peteru 2:12) Ṣugbọn olu-ilu nla, tabi aarin gbungbun kan, nibi ti a ti lè lọ bá Jesu ha wà bi? Jesu dahun eyi nipa sisọ asọtẹlẹ pe ni ifojusọna fun wíwàníhìn-ín rẹ̀, awọn èké Kristi yoo dide. O kilọ pe: “Nitori naa bi wọn ba wi fun yin pe, Wò ó, ó [Kristi] wa ni aginju; ẹ má lọ sibẹ: Wò ó, ó wà ní ìyẹ̀wù; ẹ maṣe gbagbọ. Nitori gẹgẹ bi manamana tii kọ lati ila-oorun, tii sii mọlẹ dé iwọ-oorun; bẹẹ ni [wíwàníhìn-ín, NW] [pa·rou·siʹa] Ọmọ eniyan yoo rí pẹlu.”—Matteu 24:24, 26, 27.

9 Ju ẹnikẹni miiran lọ lori ilẹ̀-ayé, Jesu, “Ọmọ eniyan,” mọ̀ ibi ti oun yoo wà nigba ti wíwàníhìn-ín rẹ̀ ba bẹrẹ niti gidi. Oun kì yoo fi araarẹ̀ si boya ìhín tabi ọ̀hún tabi ni ibi pato kan lori ilẹ̀-ayé. Oun kò ní ní ifarahan kankan ni ibi adado kan, “ni aginju,” ki awọn ti wọn bá fẹ́ wá Messia le tọ̀ ọ́ lọ ki awọn alaṣẹ ijọba ilẹ naa ma baa rí wọn, ibikan nibi ti awọn ọmọlẹhin ti lè gba idanilẹkọọ labẹ ipo aṣiwaju rẹ̀, ni mimurasilẹ lati da eto oṣelu lágbo nù ki wọn sì fi i joye gẹgẹ bi Messia Oluṣakoso ayé. Siwaju sii, oun kò ni fi araarẹ̀ pamọ́ ni “iyẹwu” kan, ni jijẹ ki ibi ti o wà jẹ eyi ti kiki awọn kereje ti a yàn mọ̀, ki o lè jẹ pe nibẹ, laiṣakiyesi ati laiṣawari rẹ̀, oun lè gbimọ ki o sì ṣe awọn iwewee bonkẹlẹ pẹlu awọn abaniṣebi fun didoju ijọba ayé délẹ̀ ki o sì fi ami ororo yan araarẹ̀ gẹgẹ bi Messia ti a ṣeleri naa. Bẹẹkọ!

10. Bawo ni ìmọ́lẹ̀ otitọ Bibeli ṣe ń tàn kaakiri agbaye?

10 Kaka bẹẹ, kì yoo si ohun kan lati fi pamọ nipa ti dídé Jesu gẹgẹ bi Ọba, ni ibẹrẹ wíwàníhìn-ín rẹ̀ bi ọba. Gẹgẹ bi Jesu ti sọtẹlẹ, ni ọ̀nà kari-aye, awọn ìmọ́lẹ̀ otitọ Bibeli ń baa lọ lati maa tàn yika agbegbe ti o gbooro lati ayika ila-oorun de ayika iwọ-oorun. Loootọ, gẹgẹ bi awọn olùtan ìmọ́lẹ̀ ode-oni, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti fi araawọn hàn bi “ìmọ́lẹ̀ awọn keferi, ki [Jehofa] lè ṣe igbala . . . titi de opin ayé.”—Isaiah 49:6.

Igbokegbodo Angẹli

11. (a) Ni ọ̀nà wo ni a gba ń lo agbajọ awọn angẹli ninu titan ìmọ́lẹ̀ Ijọba? (b) Nigba wo ati sinu awujọ wo ni a ti kó awọn mẹmba ẹgbẹ́ alikama jọ sí?

11 Awọn ẹsẹ iwe mimọ miiran ti o niiṣe pẹlu wíwàníhìn-ín Jesu ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi ẹni ti agbajọ awọn angẹli wà pẹlu rẹ, tabi ‘ti o ń rán wọn jade.’ (Matteu 16:27; 24:31) Ninu akawe alikama ati èpò, Jesu sọ pe “oko ni ayé” ati pe “igbẹhin ayé ni ikore; awọn angẹli sì ni awọn olukore.” Bi o ti wu ki o ri, eyi kò tumọsi pe, nigba wíwàníhìn-ín rẹ̀ ninu agbara ati ògo Ijọba, oun ń lo kiki awọn iranṣẹ ti wọn jẹ́ angẹli fun ijihin-iṣẹ ilẹ̀-ayé. Bẹrẹ ni 1919, awọn angẹli labẹ idari Jesu ya awọn ẹgbẹ́ alikama ti awọn ti a fi ami ororo yàn lori ilẹ̀-ayé, ti a ti fọnkaakiri nipa awọn iṣẹlẹ Ogun Agbaye I sọtọ, awọn wọnyi ni a sì murasilẹ fun igbokegbodo siwaju sii ni orukọ Ọba naa. (Matteu 13:38-43) Ni awọn ọdun 1920 ẹgbẹẹgbẹrun eniyan miiran mu ipo wọn fun Ijọba Ọlọrun ti a ti gbekalẹ ti a sì fi ẹmi Ọlọrun yan wọn. Awọn ẹni-ami-ororo wọnyi ni a fikun awọn aṣẹku ipilẹsẹ naa lọna gbigbeṣẹ. Lapapọ, wọn parapọ di ẹgbẹ́ ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu fun ọjọ wa.

12. Ninu isọdimimọ wo ni awọn angẹli ti kópa, pẹlu abajade wo sì ni fun ori ilẹ̀-ayé?

12 Apẹẹrẹ miiran nipa ilọwọsi angẹli nigba wíwàníhìn-ín Jesu tẹle ìgbégoríìtẹ́ rẹ̀ ni 1914 ni a kọsilẹ ninu Ìfihàn 12:7-9 pe: “Mikaeli [Jesu Kristi] ati awọn angẹli rẹ̀ ba dragoni naa jagun; dragoni si jagun ati awọn angẹli rẹ̀. Wọn kò sì lè ṣẹgun; bẹẹ ni a kò sì rí ipò wọn mọ́ ni ọrun. A sì lé dragoni nla naa jade, ejo laelae nì, ti a ń pe ni Eṣu, ati Satani, ti ń tan gbogbo ayé jẹ, a sì lé e jù si ilẹ̀-ayé, a sì lé awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀.” Nipa bayii, awọn ọrun loke lọhun-un ni a ti sọ di mímọ́ nisinsinyi, ni fifi kiki ilẹ-ọba Ijọba naa ti ori ilẹ̀-ayé silẹ lati di eyi ti a wẹ̀ mọ́ patapata fun ìsọdimímọ́ orukọ Jehofa. Ni ọdun 1993 yii, ikilọ atọrunwa naa ń baa lọ lati ni ifisilo pe: “Ègbé ni fun ayé . . . nitori Eṣu sọkalẹ tọ yin wa ni ibinu nla, nitori ó mọ̀ pe ìgbà kukuru ṣa ni oun ni.”—Ìfihàn 12:12.

Ajinde ti Ọ̀run

13, 14. (a) Ki ni Iwe Mimọ fihàn pe o ti ń tẹsiwaju lati 1918 wá? (b) Ki ni Paulu ati Johannu ṣipaya nipa aṣẹku ẹni-ami-ororo lonii?

13 Iṣẹlẹ yiyanilẹnu miiran nigba wíwàníhìn-ín Kristi ni ibẹrẹ ajinde ti ọrun. Aposteli Paulu fihàn pe awọn Kristian ẹni-ami-ororo ti wọn ti sùn fun ìgbà pipẹ ninu iboji wọn ni a óò kọkọ sọ di ààyè ti wọn yoo sì gbé pẹlu Kristi Jesu ninu ilẹ-ọba ẹmi. Ẹ̀rí ni a ti gbejade jalẹ ọpọlọpọ ọdun lati fihàn pe eyi ni o farahan pe o ṣẹlẹ lati 1918 siwaju. Paulu kọwe pe: “A o sọ gbogbo eniyan di alaaye ninu Kristi. Ṣugbọn olukuluku ni ipo tirẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹhin naa awọn wọnni ti wọn jẹ́ ti Kristi nigba wíwàníhìn-ín [pa·rou·siʹa] rẹ̀.” (1 Korinti 15:22, 23, NW) Ajinde awọn ẹni-ami-ororo nigba wíwàníhìn-ín Kristi ni a jẹrii si ninu 1 Tessalonika 4:15-17 (NW), pe: “Eyi ni ohun ti awa sọ fun un yin nipa ọ̀rọ̀ Jehofa, pe awa alaaye ti a walaaye di [ìgbà] wíwàníhìn-ín [pa·rou·siʹa] Oluwa kì yoo ṣaaju awọn wọnni ti wọn ti sùn ninu iku lọnakọna . . . Awọn wọnni ti wọn ti ku ni irẹpọ pẹlu Kristi ni wọn yoo kọkọ dide. Lẹhin ìgbà naa awa alaaye ti a walaaye, ni a o mú lọ papọ pẹlu wọn, ninu awọsanmọ lati pade Oluwa ninu atẹ́gùn.” Awọn 144,000 wà ti wọn jẹ́ ti Kristi gẹgẹ bi awọn ẹni-ami-ororo ti wọn gba èrè agbayanu yii lẹhin-ọ-rẹhin.—Ìfihàn 14:1.

14 Gẹgẹ bi Paulu ṣe fihàn, awọn wọnni ti wọn jẹ́ ti aṣẹku ẹni-ami-ororo ti wọn walaaye lonii kò ni wọnu Ijọba naa ṣaaju awọn wọnni ti wọn jẹ́ Kristian ẹni-ami-ororo aduroṣinṣin ajẹ́rìíkú ati ọmọ-ẹhin akọkọbẹrẹ. Siwaju sii, aposteli Johannu tun ṣapejuwe awọn wọnni ti wọn jẹ ẹni-ami-ororo ti wọn kú lonii gẹgẹ bi o ti tẹlee: “Alabukunfun ni awọn òkú ti o kú nipa ti Oluwa lati ìhín lọ: bẹẹni, ni ẹmi wí: ki wọn ki o lè sinmi kuro ninu laalaa wọn, nitori iṣẹ wọn ń tọ̀ wọn lẹhin,” iyẹn ni pe, nigba iwalaaye wọn lẹhin ajinde. (Ìfihàn 14:13) Paulu si sọ pe: “Kiyesi i, ohun ijinlẹ ni mo sọ fun yin; gbogbo wa kì yoo sùn, ṣugbọn gbogbo wa ni a o palarada, lọ́gán, ni iṣẹju, nigba ìpè ikẹhin: nitori ìpè yoo dún, a o sì jí awọn òkú dide ni aidibajẹ, a o sì pa wá láradà.” (1 Korinti 15:51, 52) Ẹ wo iru iṣẹ iyanu aṣeninikayeefi ti iyẹn jẹ́!

15, 16. (a) Akawe wo ni Jesu fifunni ninu Luku 19:11-15, fun idi wo sì ni? (b) Bawo ni asọtẹlẹ yii ti ṣe ń ni imuṣẹ lonii?

15 Nigba kan nigba ti Jesu ń waasu fun awujọ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ nipa Ijọba Ọlọrun, o lo akawe kan lati ràn wọn lọwọ lati ṣatunṣe awọn ero òdì wọn. Akọsilẹ naa kà pe: “Wọn ń ro pe ijọba Ọlọrun yoo farahan nisinsinyi. O si wi pe, Ọkunrin ọlọ́lá kan re ilu okeere lọ ígba ijọba fun araarẹ̀ ki o sì pada. O sì pe awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ mẹwaa, o fi mina mẹwaa fun wọn, o sì wi fun wọn pe, Ẹ maa ṣòwò titi emi o fi de. . . . O sì ṣe, nigba ti o gba ijọba tan, ti o pada dé, o paṣẹ pe, ki a pe awọn ọmọ-ọdọ wọnni wa sọdọ rẹ̀, ti oun ti fi owó fun nitori ki o lè mọ iye èrè ti olukuluku fi iṣowo jẹ.”—Luku 19:11-15.

16 Jesu ni “ọkunrin” yẹn ẹni ti o lọ si ọrun, “ilu okeere” nibi ti oun ti nilati gba ijọba kan. Ijọba yẹn ni o gbà ni 1914. Laipẹ lẹhin naa, Kristi gẹgẹ bi Ọba ṣe iṣiro kan pẹlu awọn ti wọn fẹnu jẹwọ jíjẹ́ ọmọlẹhin rẹ̀ lati ri ohun ti wọn ti ṣe ni bibojuto ire Ijọba ti a ti fi si ìkáwọ́ wọn. Awọn diẹ ti wọn jẹ́ oluṣotitọ ni a yàn lati gba igboriyin ọ̀gá naa pe: “O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere: nitoriti iwọ ṣe oloootọ ni ohun kín-ń-kín-ní, gba aṣẹ lori ilu mẹwaa.” (Luku 19:17) Akoko wíwàníhìn-ín Kristi yii ni ninu igbokegbodo iṣẹ iwaasu Ijọba kan ti ń baa lọ kíkankíkan, eyi ti o ni ninu ikede idajọ Ọlọrun lodisi awọn ẹni buburu, ọla-aṣẹ ti a fifun “ọmọ-ọdọ rere” naa sì ni ninu ṣiṣabojuto iṣẹ yii.

Iwaasu Kárí-Ayé

17. Idunnu-ayọ wo ni o sami si pa·rou·siʹa?

17 Ki ni ohun miiran ti yoo ṣẹlẹ nigba pa·rou·siʹa yii? Yoo jẹ́ akoko ayọ ribiribi ninu iṣẹ wiwaasu ati ninu riran awọn ẹni titun lọwọ lati murasilẹ fun lila ipọnju nla ti ń bọ̀ já. Awọn wọnyi ti wọn jẹ́ ti “ogunlọgọ nla” naa, ti wọn ran àṣẹ́kù lọwọ di “iwe ìyìn.” (Ìfihàn 7:9; 2 Korinti 3:1-3) Paulu mẹnukan ayọ iṣẹ ikore yii nigba ti o sọ pe: “Ki ni ireti tabi idunnu-ayọ tabi adé ayọ-aṣeyọri wa—họwu, kìí ha ṣe ẹyin ni niti gidi bi?—niwaju Jesu Oluwa wa nigba wíwàníhìn-ín [pa·rou·siʹa] rẹ̀?”—1 Tessalonika 2:19, NW.

Wà ni Mímọ́ ati ni Ailaleebu

18. (a) Adura Paulu wo ni o tọkasi pa·rou·siʹa? (b) Ẹmi wo ni gbogbo wa gbọdọ fihàn ni akoko yii, ni awọn ọ̀nà wo sì ni?

18 Paulu tun gbadura fun iyasimimọ awọn wọnni ti wọn walaaye ni akoko wíwàníhìn-ín Kristi yii pe: “Ki Ọlọrun alaafia gan-an sọ yin di mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà. Ki o sì pa ẹmi ati ọkàn ati ara ẹyin ará mọ́ ní yiyekooro lọna gbogbo ní alailẹgan nigba wíwàníhìn-ín [pa·rou·siʹa] Oluwa wa Jesu Kristi.” (1 Tessalonika 5:23, NW) Bẹẹni, lonii, yala a jẹ́ ara àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo tabi ti ọpọ rẹpẹtẹ awọn agutan miiran, ẹmi ifọwọsowọpọ ń so wa papọ pẹlu iduroṣinṣin ki a baa lè maa baa lọ lati jẹ́ mímọ́ ati alailaleebu ni akoko alailẹgbẹ yii. Bakan naa, a nilati ni suuru. Jakọbu kọwe pe: “Nitori naa, ẹ ni suuru, ẹyin ara, titi di [ìgbà] wíwàníhìn-ín [pa·rou·siʹa] Oluwa. . . . Ẹ mu ọkan-aya yin le gbọnyin, nitori wíwàníhìn-ín [pa·rou·siʹa] Oluwa ti sunmọle.”—Jakọbu 5:7, 8, NW.

19. Ikilọ wo ni Peteru fifunni nipa pa·rou·siʹa, bawo ni a sì ṣe gbọdọ dahunpada?

19 Aposteli Peteru pẹlu tun ni ohun kan lati sọ fun awa ti a walaaye ni akoko isinsinyi. O kilọ fun wa lodisi awọn ẹlẹgan, awọn ẹni ti wọn pọ̀ ni gbogbo apá ilẹ̀-ayé. Peteru sọ pe: “Ki ẹ kọ́ mọ eyi pe, nigba ọjọ ikẹhin, awọn ẹlẹ́gàn yoo de pẹlu ẹ̀gàn wọn, wọn o maa rin nipa ifẹ araawọn, wọn o si maa wi pe: Nibo ni ileri [wíwàníhìn-ín, NW] [pa·rou·siʹa] rẹ̀ gbe wa? Lati ìgbà ti awọn baba ti sùn, ohun gbogbo ń lọ bi wọn ti wà rí lati ìgbà ọjọ ìwà.” (2 Peteru 3:3, 4) Laika igbodekan awọn ẹlẹgan si nigba wíwàníhìn-ín Kristi, awọn eniyan Jehofa ń baa lọ lati maa tan gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ ayé, fun igbala ọpọlọpọ.

Awọn Ibeere fun Atunyẹwo

◻ Bawo ni a ṣe ń la awọn eniyan Jehofa loye lọna ti ń tẹsiwaju nipa pa·rou·siʹa?

◻ Bawo ni Matteu 24:4-8 ti ṣe ń ni imuṣẹ?

◻ Bawo ni awọn angẹli ti ṣe ń fọwọsowọpọ pẹlu Kristi ti a ti gbé gori ìtẹ́ naa?

◻ Iṣẹ iyanu aṣeninikayeefi wo ni o farahan bi eyi ti o bá pa·rou·siʹa rìn?

◻ Ayọ wo ni a ń nírìírí rẹ̀ ni akoko yii, ta ni o si ń nipin in ninu rẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́