ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/07 ojú ìwé 24-25
  • Ṣó Burú Kéèyàn Máa Mutí Líle?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó Burú Kéèyàn Máa Mutí Líle?
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Bíbélì Wí?
  • Kí Ni Jésù Ṣe?
  • Èwo Ló Yẹ Káwa Ṣe?
  • Ọtí Líle
    Jí!—2013
  • Ìwọ Ha Ní Ojú Ìwòye Ọlọ́run Nípa Ọtí Líle Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ṣọ́ra Fún Ọtí Àmujù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ṣé Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọtí Àmujù Burú Tó Ni?
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 1/07 ojú ìwé 24-25

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣó Burú Kéèyàn Máa Mutí Líle?

“AFINIṢẸ̀SÍN ni wáìnì, aláriwo líle ni ọtí tí ń pani, olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣáko lọ kò gbọ́n.” Ǹjẹ́ gbólóhùn yìí tó wà nínú Òwe 20:1 sọ pé ó burú kéèyàn máa mutí líle? Àwọn kan rò bẹ́ẹ̀. Ẹ̀rí míì tí wọ́n ń fúnka mọ́ ni àkọsílẹ̀ Bíbélì to sọ nípa ìwàkiwà táwọn tó mutí líle nímukúmu hù.—Jẹ́nẹ́sísì 9:20-25.

Yàtọ̀ síyẹn, àmujù ọtí líle máa ń wu ẹ̀mí léwu, ó máa ń fa àìsàn mẹ́dọ̀wú, jàǹbá tó lè la ẹ̀mí lọ, ó ń sọ èèyàn di tálákà, ó ń mú kéèyàn máa han àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ̀ léèmọ̀ tàbí kó máa fòòró ẹ̀mí wọn, ó sì ń ṣèpalára fóyún inú. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí àwọn jàǹbá tó ń fà yìí ni “ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn pé kò tọ́ láti máa mutí líle” gẹ́gẹ́ bi gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia ṣe sọ. Ṣùgbọ́n ṣé lóòótọ́ ló burú láti mutí líle? Ǹjẹ́ ṣe ni Bíbélì sọ pé kéèyàn má fẹnu kan ọtí líle rárá, bó ti wù kó mọ?

Kí Ni Bíbélì Wí?

Bíbélì kìlọ̀ nípa ohun tó máa ń tìdí mímu ọtí líle lámujù yọ. Éfésù 5:18 gbà wá níyànjú pé: “Ẹ má ṣe máa mu wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí ìwà wọ̀bìà wà.” Bákan náà, Òwe 23:20, 21 ṣí wa létí pé: “Má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri, lára àwọn tí ń jẹ ẹran ní àjẹkì. Nítorí ọ̀mùtípara àti alájẹkì yóò di òtòṣì.” Aísáyà 5:11 sọ pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ kí wọ́n lè máa wá kìkì ọtí tí ń pani kiri, àwọn tí ń dúró pẹ́ títí di òkùnkùn alẹ́ tí ó fi jẹ́ pé wáìnì mú wọn gbiná!”

Bíbélì tún mẹ́nu ba ìgbádùn àti àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa mutí níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 104:15 sọ pé ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni “wáìnì tí ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀.” Oníwàásù 9:7 sì sọ pé èrè fún ṣíṣe iṣẹ́ rere ni pé kéèyàn ‘máa fi ayọ̀ yíyọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ̀ kí o sì máa fi ọkàn-àyà tí ó yá gágá mu wáìnì rẹ̀.’ Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ọtí líle lè ṣiṣẹ́ bí egbòogi ló ṣe sọ fún Tímótì pé kó “má mu omi mọ́” ṣùgbọ́n kó ‘máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí àpòlúkù rẹ̀ àti ọ̀ràn àìsàn rẹ̀ tí ó ṣe lemọ́lemọ́.’ (1 Tímótì 5:23) Bíbélì jẹ́ kà mọ̀ pé ọtí líle lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti fara da àníyàn.—Òwe 31:6, 7.

Ó ṣe kedere pé Bíbélì ò ka mímutí líle léèwọ̀. Ohun tí Bíbélì kà léèwọ̀ ni mímu àmujù tàbí àmupara. Ìdí nìyí tí Pọ́ọ̀lù fi gba àwọn Kristẹni alábòójútó, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àtàwọn àgbà obìnrin níyànjú pé kí wọ́n má ṣe fi ara wọn “fún ọ̀pọ̀ wáìnì,” ó sì gba Tímótì nímọ̀ràn pé kó máa mu “wáìnì díẹ̀.” (1 Tímótì 3:2, 3, 8; Títù 2:2, 3) Bíbélì jẹ́ kí gbogbo Kristẹni mọ̀ pé “àwọn ọ̀mùtípara” ò ní “jogún ìjọba Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.

Ohun tá ò tún gbọ́dọ̀ gbójú fò dá ni pé Bíbélì so ìmutípara mọ́ àjẹkì, ó sì gbà wá níyànjú pé ká yẹra fún méjèèjì. (Diutarónómì 21:20) Bó bá wá jẹ́ pé rárá la ò gbọ́dọ̀ mutí líle, ǹjẹ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó lòdì láti jẹun kódà kó tiẹ̀ jẹ́ níwọ̀nba? Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ pó lòdì ni mímutí lámupara àti jíjẹ àjẹkì—kò sọ pé ká má ṣe jẹun tàbí ká má ṣe mutí níwọ̀ntúnwọ̀nsì.

Kí Ni Jésù Ṣe?

Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Kristi ‘fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún wa ká lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.’ Ó tún fi kún un pé, “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” (1 Pétérù 2:21, 22) Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ojú wo ni Jésù fi wo ọtí líle? Ó dára, àkọ́kọ́ lára iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe ni èyí tó fi sọ omi di wáìnì. Irú wáìnì wo ni Jésù sọ omi dà? “Olùdarí àsè” tiẹ̀ gbóṣùbà fún ọkọ ìyàwó nítorí wáìnì tí Jésù fi iṣẹ́ ìyanu pèsè. Ó ní: “Olúkúlùkù ènìyàn mìíràn a kọ́kọ́ gbé wáìnì àtàtà jáde, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì ti mutí yó tán, yóò sì kan gbàrọgùdù. Ìwọ ti fi wáìnì àtàtà pa mọ́ títí di ìsinsìnyí.”—Jòhánù 2:9, 10.

Níbi ayẹyẹ Ìrékọjá, wáìnì wà lára ohun tí wọ́n máa ń lò, bákan náà, wáìnì wà lára ohun tí Jésù lò nígbà tó ń fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀. Nígbà tó gbé ife tí wáìnì wà nínú ẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín.” Nígbà tó rí i pé àtikú òun kù sí dẹ̀dẹ̀, ó wá fi kún un pé: “Mo sọ fún yín, dájúdájú, èmi kì yóò mu èyíkéyìí nínú àmújáde àjàrà yìí lọ́nàkọnà láti ìsinsìnyí lọ títí di ọjọ́ yẹn nígbà tí èmi yóò mu ún ní tuntun pẹ̀lú yín nínú ìjọba Baba mi.” (Mátíù 26:27, 29) Kò sí àní àní, aráyé mọ̀ pé Jésù mu wáìnì.—Lúùkù 7:34.

Èwo Ló Yẹ Káwa Ṣe?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò ka mímutí líle léèwọ̀, ìyẹn ò fi hàn pé ó di dandan ká máa mu ún. Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tá a fi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ọtí líle. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó bá ti jẹ́ ọ̀mùtípara rí á mọ̀ pé ìfẹ̀mí wewu ni láti mutí kódà kó jẹ́ tọ́ńbìlà kan ṣoṣo. Nítorí ewu tí ọtí líle lè fà fóyún inú, aboyún lè fẹ́ láti má ṣe fẹnu kàn án. Àti nítorí bí ọtí líle ṣe máa ń mú kó ṣòro fún awakọ̀ láti fi làákàyè wakọ̀ lójú pópó, ṣe ló yẹ káwọn awakọ̀ jìnnà sí ohunkóhun tó bá máa fi ẹ̀mí wọn tàbí tàwọn ẹlòmíì sínú ewu.

Kristẹni kan ò ní fẹ́ jẹ́ okùnfà ìkọ̀sẹ̀ fẹ́nikẹ́ni tí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ bá dá ọtí mímu lẹ́bi. (Róòmù 14:21) Ó bọ́gbọ́n pé kó má ṣe mutí líle nígbà tó bá ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá. Kókó kan tá ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ni pé Òfin tí Ọlọ́run fáwọn ọmọ Íṣírẹ́lì ìgbàanì kà á léèwọ̀ fáwọn àlùfáà láti “mu wáìnì tàbí ọtí tí ń pani,” bí wọ́n bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn. (Léfítíkù 10:9) Bákan náà, láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti ka mímutí líle léèwọ̀ tàbí tí òfin ti wà lórí ìwọ̀n téèyàn gbọ́dọ̀ mu, dandan ni káwọn Kristẹni tẹ̀ lé òfin náà.—Róòmù 13:1.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kálukú ló máa pinnu bóyá kóun mutí tàbí kóun má mú un tàbí ìwọ̀n tó yẹ kóun mu, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ó gbọ́dọ̀ jẹ́ níwọ̀ntúnwọ̀nsí nígbà tó sọ pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 10:31.

ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?

◼ Ìkìlọ̀ wo nípa mímu ọtí líle ló wà nínú Ìwé Mímọ́?—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.

◼ Ǹjẹ́ Jésù Kristi mutí líle?—Lúùkù 7:34.

◼ Kí ló ń tọ́ àwọn Kristẹni sọ́nà tó bá dọ̀rọ̀ oúnjẹ àti ọtí?—1 Kọ́ríńtì 10:31.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́