Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọtí Àmujù Burú Tó Ni?
LÁTI ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn làwọn tó máa ń ṣe bí ọlọ́tí láti pa àwọn èèyàn lẹ́rìn-ín ti máa ń wà nínú eré orí ìtàgé àti sinimá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé eré lásán làwọn tó ń ṣeré yẹn á sọ pé àwọn ń ṣe, irú eré tí wọ́n ń ṣe yẹn fi oríṣiríṣi èrò táwọn èèyàn ní nípa ọtí àmujù hàn, wọ́n gbà pé ohun tó kù díẹ̀ káàtó ni àmọ́ kò léwu.
Ká sòótọ́, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀rín rárá o. Àjọ Ìlera Àgbáyé gbà pé ọtí àmujù wà lára ohun tó gba ipò iwájú nínú àwọn ohun tó máa ń ṣàkóbá fún ìlera karí ayé. Wọ́n sọ pé bá a bá yọwọ́ sísọ tábà di bárakú, ọtí àmujù ló tún ń fa ikú àti àìsàn tó pọ̀ ju èyí táwọn àtẹnujẹ mìíràn tó ń mú kéèyàn ṣe tinú ẹni ń fà, owó tó sì máa ń gbọ́n lọ lọ́dún nínú ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lé ní bílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gọ́sàn-án owó dọ́là.
Láìfi bí gbogbo nǹkan ṣe rí yìí pè, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò ka ọtí àmujù sí ohun bàbàrà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n gbà pé tó bá pẹ́ tẹ́nìkan ti ń mutí àmujù, ó lè ṣàkóbá fún onítọ̀hún, wọn kò rí ohun tó burú nínú kéèyàn máa mutí yó bìnàkò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Láàárín àwọn ọ̀dọ́, láwọn apá ibì kan nínú ayé, wọ́n ka ọtí àmujù sí ohun tẹ́nì kan gbọ́dọ̀ ṣe láti fi hàn pé ó ti ń gòkè àgbà. Láìka àwọn ìkìlọ̀ táwọn àjọ ìlera ń ṣe sí, àwọn kan sọ pé ó dìgbà téèyàn bá mu ọtí márùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan kó tó di alámujù, ńṣe lèrò yìí ṣì ń gbilẹ̀ sí i láàárín àtàgbà àtọmọdé. Abájọ nígbà náà tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì nípa bóyá ọtí àmujù tiẹ̀ burú lóòótọ́. Kí ni Bíbélì sọ?
Wáìnì àti Ọtí Líle Jẹ́ Ẹ̀bùn Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
Níbi tó pọ̀ ni Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa wáìnì àti ọtí líle. Sólómọ́nì ọba kọ̀wé pé: “Máa lọ, máa fi ayọ̀ yíyọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ kí o sì máa fi ọkàn-àyà tí ó yá gágá mu wáìnì rẹ, nítorí pé Ọlọ́run tòótọ́ ti ní ìdùnnú sí àwọn iṣẹ́ rẹ ná.” (Oníwàásù 9:7) Onísáàmù náà sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ni Olùpèsè “wáìnì tí ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀.” (Sáàmù 104:14, 15) Nígbà náà, ó hàn kedere pé wáìnì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn tí Jèhófà fi bù kún ìran èèyàn.
Ó dájú pé Jésù náà fara mọ́ mímu wáìnì. Kódà, sísọ omi di ògidì ọtí wáìnì ni iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tó ṣe níbi àsè ìgbéyàwó kan. (Jòhánù 2:3-10) Ó tún lo wáìnì gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣàpẹẹrẹ tó bá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mu gẹ́lẹ́ nígbà tó ń fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀. (Mátíù 26:27-29) Kódà Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa bí wáìnì ṣe lè ṣiṣẹ́ bí egbòogi, nítorí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú láti “máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí àpòlúkù [rẹ̀].”—1 Tímótì 5:23; Lúùkù 10:34.
Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Ló Gbà
Ṣàkíyèsí pé “wáìnì díẹ̀” ni Pọ́ọ̀lù dámọ̀ràn. Kedere ni Bíbélì dẹ́bi fún ọtí àmujù lọ́nà èyíkéyìí. Àwọn àlùfáà Júù lómìnira láti mu ọtí níwọ̀nba bí wọn kò bá sí lẹ́nu iṣẹ́. Àmọ́ ṣá o, èèwọ̀ ni fún wọn láti mu ọtí líle èyíkéyìí nígbà tí wọ́n bá wà lẹ́nu iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. (Léfítíkù 10:8-11) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, a kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní pé àwọn ọ̀mùtípara kì “yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.
Láfikún sí i, nínú ìtọ́ni tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì, ó sọ pé àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ kò lè jẹ́ “aláriwo ọ̀mùtípara” bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe àwọn tó “fi ara wọn fún ọ̀pọ̀ wáìnì.”a (1 Tímótì 3:3, 8) Àní, Bíbélì tiẹ̀ pa á láṣẹ pé kí a yọ àwọn ọ̀mùtípara tí kò ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ Kristẹni. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13) Lọ́nà yíyẹ wẹ́kú, Ìwé Mímọ́ sọ pé “afiniṣẹ̀sín ni wáìnì.” (Òwe 20:1) Fífi ọtí kẹ́ ara ẹni bà jẹ́ lè sọ ẹnì kan dẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu mọ́ tàbí kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ má lè ronú jinlẹ̀ mọ́.
Ohun Tó Mú Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Dẹ́bi fún Ọtí Àmujù
Jèhófà, ‘Ẹni tí ń kọ́ wa kí a lè ṣe ara wa láǹfààní’ mọ̀ pé nígbà tí a bá ṣe ohun kan láṣejù, ó máa ń yọrí sí ìpalára fún wa àti fún àwọn ẹlòmíràn. (Aísáyà 48:17, 18) Òótọ́ pọ́ńbélé lèyí tó bá di ọ̀rọ̀ mímu ọtí líle. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run béèrè pé: “Ta ni ó ni ègbé? Ta ni ó ni àìnírọ̀rùn? Ta ni ó ni asọ̀? Ta ni ó ni ìdàníyàn? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí? Ta ni ó ni ojú ṣíṣe bàìbàì?” Ó wá dáhùn pé: “Àwọn tí ó máa ń dúró fún àkókò gígùn nídìí wáìnì ni, àwọn tí ń wọlé láti wá àdàlù wáìnì kàn.”—Òwe 23:29, 30.
Nígbà táwọn èèyàn bá ti mu ọtí lámujù, wọ́n máa ń ṣe ọ̀pọ̀ ohun tí kò mọ́gbọ́n dání tó sì léwu: wọ́n lè máa wa ọkọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti mu ọ̀tí yó tan, kí wọ́n wá tipa bẹ́ẹ̀ wu ìwàláàyè tiwọn àti tàwọn mìíràn léwu, ọkàn wọn lè fà sí ìyàwó tàbí ọkọ ẹlòmíràn jù bó ti yẹ lọ, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ba àjọṣe rere jẹ́, wọ́n lè sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n hùwà òmùgọ̀, wọ́n tiẹ̀ lè hùwà àyídáyidà pàápàá. (Òwe 23:23) Wọ́n sọ pé ọtí àmujù ni ìwà ìbàjẹ́ tó gbòde kan, tó sì ń ṣe ìran èèyàn lọ́ṣẹ́ jù lọ lónìí. Abájọ tí Ọlọ́run fi rọ̀ wá pé: “[Ẹ] má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri”!—Òwe 23:20.
Nínú Gálátíà 5:19-21, Pọ́ọ̀lù ka mímu àmuyíràá àti àwọn àríyá aláriwo kún “àwọn iṣẹ́ ti ara,” wọ́n sì lòdì sí àwọn èso tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń so. Ọtí àmujù yóò ṣàkóbá fún àjọṣe tó wà láàárín ẹnì kan àti Ọlọ́run. Nígbà náà, ó ṣe kedere pé Kristẹni kan gbọ́dọ̀ yẹra fún àṣìlò ọtí lọ́nàkọnà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé àwọn alábòójútó àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo nínú èrò àti ìwà wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ máa gbìyànjú láti fi àwọn ìlànà àtàtà Jèhófà sílò débi tí agbára wọn bá gbé e dé, ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé kí gbogbo àwọn Kristẹni máa ṣe bákan náà.