ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 1/8 ojú ìwé 26-27
  • Ṣé “Ìyá Ọlọrun” Ni Maria?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé “Ìyá Ọlọrun” Ni Maria?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Maria—‘Ẹni Tí Ó Rí Ojú Rere Ọlọrun Jù Lọ’
  • ‘Jọ́sìn Lọ́nà Tí Ó Yẹ Ẹ̀dá Amọnúúrò’
  • Ṣé Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • “Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • “Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìwọ́ Ha Ti Ṣe Kàyéfì Rí Bí?
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 1/8 ojú ìwé 26-27

Ojú-ìwòye Bibeli

Ṣé “Ìyá Ọlọrun” Ni Maria?

“A Ń WÁ ÌSÁDI LÁBẸ́ ÀÀBÒ ÀÁNÚ RẸ, ÌYÁ ỌLỌRUN; MÁ ṢE KỌ ÌRAWỌ́ Ẹ̀BẸ̀ WA NÍGBÀ ÀÌNÍ ṢÙGBỌ́N GBÀ WÁ LỌ́WỌ́ ÌPARUN, ÌWỌ ẸNÌ KAN ṢOṢO TÍ A BÙ KÚN.”

IRÚ àdúrà yẹn ṣàkópọ̀ ìmọ̀lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ń jọ́sìn Maria, ìya Jesu Kristi. Lójú wọn, òun ni ìṣàpẹẹrẹ ìyá onínúure, tí ó lè bá wọn bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun, tí ó sì lè dẹwọ́ ìdájọ́ rẹ̀ lórí wọn.

Bí ó ti wù kí ó rí, ṣé “Ìyá Ọlọrun” ni Maria ní tòótọ́?

Maria—‘Ẹni Tí Ó Rí Ojú Rere Ọlọrun Jù Lọ’

Láìsí àníàní, Maria ni “ẹni tí ó rí ojú rere jù lọ”—tí a ṣojúure púpọ̀ sí, ní ti gidi, ju obìnrin èyíkéyìí mìíràn tí ó tí ì gbé ayé rí lọ. (Luku 1:28, The Jerusalem Bible) Áńgẹ́lì Gabrieli fara hàn án, ó sì ṣàlàyé bí yóò ti láǹfààní tó. Ó wí pé: “Tẹ́tí sílẹ̀! Ìwọ yóò lóyún, ìwọ óò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ sì gbọ́dọ̀ sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu. Yóò di ẹni ńlá, a óò sì pè é ní Ọmọkùnrin Ẹni Gíga Jù Lọ.” Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó kún fún ìyanu yìí ṣe ṣeé ṣe? Gabrieli ń bá a lọ pé: “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò bà lé ọ, . . . agbára Ọ̀gá Ògo Jù Lọ yóò ṣíji bò ọ́. Nítorí náà, ọmọ náà yóò jẹ́ ẹni mímọ́, a óò sì pè é ní Ọmọkùnrin Ọlọrun.”—Luku 1:31, 32, 35, JB.

Maria sọ pé: “‘Ẹrúbìnrin Oluwa ni mí, ǹjẹ́ kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.’” (Luku 1:38, JB) Nípa bẹ́ẹ̀, Maria fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tẹ́wọ́ gba ìdarí àtọ̀runwá yìí, nígbà tí ó sì yá, ó bí Jesu.

Bí ó ti wù kí ó rí, láàárín àwọn ọ̀rúndún tí ó tẹ̀ lé e, àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ gbé e ga láti ipò rírẹlẹ̀ ti jíjẹ́ “ẹrúbìnrin Oluwa” sí ipò “ayaba ìyá” tí ó ní ìdarí kíkàmàmà ní ọ̀run. Àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì pòkìkí rẹ̀ nínú ìjọsìn, gẹ́gẹ́ bí “Ìyá Ọlọrun” ní ọdún 431 Ṣáájú Sànmánì Tiwa níbi Àpérò Efesu. Kí ló ṣokùnfà ìyípadà yìí? Póòpù John Paul Kejì ṣàlàyé okùnfà kan: “Ìfọkànsìn tòótọ́ sí Ìyá Ọlọrun . . . ní ìpìlẹ̀ fífìdí múlẹ̀ nínú Ohun Ìjìnlẹ̀ Mẹ́talọ́kan Tí A Bù Kún.”—Crossing the Threshold of Hope.

Nítorí náà, gbígbà pé, “Ìyá Ọlọrun” ni Maria sinmi lórí gbígba Mẹ́talọ́kan gbọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli ha fi Mẹ́talọ́kan kọ́ni bí?a Jọ̀wọ́ gbé ohun tí aposteli Paulu kọ nínú Bibeli yẹ̀ wò. Ó kìlọ̀ pé, “àwọn olùkọ́ èké . . . yóò yọ́ kẹ́lẹ́ mú àdámọ̀ tí ń pani run wọ agbo, wọn óò [sì] gbìyànjú láti fi àwọn àríyànjiyàn ayédèrú kó o yín nífà pẹ̀lú.” (2 Peteru 2:1, 3, The New Testament in Modern English, láti ọwọ́ J. B. Phillips) Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan jẹ́ ọ̀kan lára irú àwọn àdámọ̀ bẹ́ẹ̀. Gbàrà tí wọ́n bá ti tẹ́wọ́ gbà á, èrò pé, “Ìya Ọlọrun” ni Maria (Gíríìkì: Theotokos, tí ó túmọ̀ sí “Ẹni tí ó bí Ọlọrun”) ti bójú mu. Geoffrey Ashe sọ nínú ìwé rẹ̀, The Virgin, pé, “bí Kristi bá jẹ́ Ọlọrun, Ẹnì Kejì nínú Mẹ́talọ́kan,” gẹ́gẹ́ bí àwọn onígbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan ṣe ń ronú, “nígbà náà ìyá rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ènìyàn jẹ́ Ìyá Ọlọrun.”

Bí Jesu bá jẹ́ “Ọlọrun ní pátápátá àti ní porongodo,” gẹ́gẹ́ bí Catechism of the Catholic Church tuntun ti sọ, nígbà náà, a lè fi ẹ̀tọ́ pe Maria ní “Ìyá Ọlọrun.” Bí ó ti wù kí ó rí, a gbọ́dọ̀ mẹ́nu kàn án pé, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ lára àwọn onígbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan látètèkọ́ṣe láti gba ẹ̀kọ́ yìí nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ dábàá rẹ̀—gẹ́gẹ́ bí àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì onígbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan ti ṣe lónìí. Wọ́n máa ń pè é ní “ẹnà onífọkànsìn, ‘ẹni tí ọ̀run kò gbà, ikùn rẹ̀ gbà á.’” (The Virgin)—Fi wé 1 Àwọn Ọba 8:27.

Ṣùgbọ́n Jesu Kristi ha jẹ́ “Ọlọrun ní pátápátá àti ní porongodo” ní tòótọ́ bí? Rárá, kò sọ pé òún jẹ́ bẹ́ẹ̀ rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń fìgbà gbogbo sọ nípa ipò wíwà tí òún wà lábẹ́ Bàbá òun.—Wo Matteu 26:39; Marku 13:32; Johannu 14:28; 1 Korinti 15:27, 28.

‘Jọ́sìn Lọ́nà Tí Ó Yẹ Ẹ̀dá Amọnúúrò’

Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli fún àwọn Kristian níṣìírí láti lo agbára ìrònú wọn nínú ìjọsìn. A kò ní kí á gbà gbọ́ bí afọ́jú nínú ohun tí a fi irọ́ pọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ìjìnlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, aposteli Paulu sọ pé, a gbọ́dọ̀ ‘jọ́sìn lọ́nà tí ó yẹ ẹ̀dá amọnúúrò.’—Romu 12:1, JB.

Anne, tí a tọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bíi Kátólíìkì, sọ pé: “Wọn kò fìgbà kan rí fún wa níṣìírí láti ronú nípa rẹ̀. A kò gbé ìbéèrè dìde nípa rẹ̀ rí. A ṣáà wulẹ̀ gbà gbọ́ pé Jesu ni Ọlọrun, nítorí náà, ‘Ìyá Ọlọrun’ ni Maria—ó ṣòroó gbà gbọ́!” Rántí pé, Catechism of the Catholic Church sọ pé, ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn “Ìsopọ̀ àtọ̀runwá” náà jẹ́ “Ọlọrun ní pátápátá àti ní porongodo.” Ó wí pé, kò sí ọlọrun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mẹ́ta. Nígbà náà, ó ha yẹ kí á gbà gbọ́ pé, bí àwọn sẹ́ẹ̀lì abẹ̀mí tí ó wà ní ikùn Maria ṣe ń pín sí kéékèèké, ẹni tí ó jẹ́ “Ọlọrun ní pátápátá àti ní porongodo” wà nínú ọlẹ̀ kan tí ó fi jẹ́ pé láàárín oṣù àkọ́kọ́ tí ó lóyún, ó dàgbà di ohun tí kò ju ìdámẹ́rin íǹṣì kan ní gígùn, tí ó sì ní àwọn ojú àti etí kògbókògbó bí?

Fi sọ́kàn pé áńgẹ́lì Gabrieli wí fún Maria pé, a óò máa pe ọmọ rẹ̀ ní “Ọmọkùnrin Ẹni Gíga Jù Lọ” àti “Ọmọkùnrin Ọlọrun,” kì í ṣe “Ọlọrun Ọmọ.” Ní tòótọ́, bí ó bá jẹ́ pé, Jesu ni Ọlọrun Olódùmarè, kí ló dé tí áńgẹ́lì Gabrieli kò fi lo èdè ọ̀rọ̀ kan náà tí àwọn onígbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan ń lò lónìí—“Ọlọrun Ọmọ”? Gabrieli kò lo èdè ọ̀rọ̀ náà, nítorí pé a kò rí ẹ̀kọ́ náà nínú Bibeli.

Dájúdájú, a kò lóye gbogbo àwọn iṣẹ́ Ọlọrun tán. Ṣùgbọ́n òye títọ́ nípa Ìwé Mímọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbà gbọ́ pé Ọlọrun Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá gbogbo ohun alààyè, ní agbára láti fi ìyanu tàtaré ìwàláàyè Ọmọkùnrin rẹ̀ àyànfẹ́, Jesu Kristi, sínú ikùn Maria, kí ó sì dáàbò bò ó bí ó ti ń dàgbà nípasẹ̀ ipá ìṣiṣẹ́, tàbí ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀, títi di ìgbà tí Maria wá di ìyá Jesu—Ọmọkùnrin Ọlọrun.

Bẹ́ẹ̀ ni, a bù kún Maria lọ́nà gíga jù lọ gẹ́gẹ́ bí ìyá ẹni tí ó wá di Kristi. Kì yóò já sí àìfọ̀wọ̀ fún un bí a bá gbà pé, ẹ̀kọ́ Bibeli ṣíṣe kedere—títí kan àkọsílẹ̀ nípa ìrẹ̀lẹ̀ Maria fúnra rẹ̀—fagi lé pípè é ní “Ìyá Ọlọrun.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jọ̀wọ́ wo Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí? tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Museo del Prado, Madrid

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́