Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní November: Pípín Ìròyìn Ìjọba No. 35 káàkiri yóò máa bá a nìṣó. Àwọn ìjọ tí ó bá ti kárí ìpínlẹ̀ wọn nípa mímú ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba No. 35 dé ọ̀dọ̀ àwọn onílé ní ilé tàbí ibùgbé kọ̀ọ̀kan lè fi ìwé Ìmọ̀ lọni fún ₦55. December: Gẹ̀ẹ́sì—New World Translation pẹ̀lú ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s? Ìfilọni àfidípò: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí Iwe Itan Bibeli Mi. Yorùbá—Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun. Ìfilọni àfidípò: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. Àwọn èdè yòó kù—Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí Iwe Itan Bibeli Mi. Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí a tẹ̀ sórí bébà tí ó máa ń di yẹ́lò tàbí tí ó máa ń di ràkọ̀ràkọ̀ tàbí èyíkéyìí tí a tẹ̀ ṣáájú 1985 ni a lè fi lọni ní ẹ̀dínwó. Bí ìjọ èyíkéyìí bá ní Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ lọ́wọ́, wọ́n lè fi ìtẹ̀jáde yìí lọni ní ẹ̀dínwó pẹ̀lú. Àwọn ìwé olójú ewé 192 yòó kù tí a tẹ̀ jáde ṣáájú 1985 tí a tẹ̀ sórí bébà tí kì í ṣá tàbí tí kì í di ràkọ̀ràkọ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ fi kún ìfilọni ẹlẹ́dìn-ínwó yìí. Ìfilọni àfidípò: Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia,” Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa, Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun, tàbí True Peace and Security—How Can You Find It? February: Revelation—Its Grand Climax At Hand! Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ó ti pẹ́ tí ó wà lọ́wọ́. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yí béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.