Ìkànnì Wa Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì—Máa Fi Ṣe Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti Ìjọsìn Ìdílé
Lọ Ka Ìwé Ìròyìn Wa Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé Níbẹ̀: Lọ ka àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lórí ìkànnì wa ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú kẹ́ ẹ tó rí ẹ̀dà tá a tẹ̀ sórí ìwé gbà nínú ìjọ. O tún lè tẹ́tí sí àwọn ìwé ìròyìn wa tá a ti kà, tá a sì gbé síbẹ̀.—Lọ sí abala “Àwọn Ìtẹ̀jáde,” kó o tẹ ìlujá tá a pè ní “Àwọn Ìwé Ìròyìn.”
Lọ Ka Àwọn Àpilẹ̀kọ Tá A Gbé Sórí Ìkànnì Nìkan: Ní báyìí, orí Ìkànnì wa nìkan lẹ ó ti máa rí àwọn àpilẹ̀kọ bí “Abala Àwọn Ọ̀dọ́,” “Ẹ̀kọ́ Bíbélì,” “Àtúnyẹ̀wò Fún Ìdílé” àti “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé.” A rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ lọ sórí Ìkànnì wa láti lọ ka àwọn àpilẹ̀kọ yìí nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti Ìjọsìn ìdílé yín.—Ẹ lọ sí abala “Ẹ̀kọ́ Bíbélì,” kẹ́ ẹ tẹ ìlujá tá a pè ní “Àwọn Ọmọdé” tàbí “Àwọn Ọ̀dọ́.”
Lọ Ka Àwọn Ìròyìn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé Níbẹ̀: Ka àwọn ìròyìn àtàwọn ìrírí tó ń fúnni níṣìírí lórí Ìkànnì náà. O sì tún lè wo àwọn fídíò kékeré tó ń jẹ́ ká mọ bí iṣẹ́ wa ṣe ń lọ sí kárí ayé. Ìròyìn nípa àjálù àti inúnibíni tó wà níbẹ̀ á jẹ́ ká lè dìídì máa rántí àwọn ará wa kan pàtó nínú àdúrà wa. (Ják. 5:16)—Lọ sí abala “Ìròyìn.”
Ṣe Ìwádìí Nínú Àká Ìwé Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì: Bí Àká Ìwé Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì (ìyẹn Online Library) bá wà ní èdè rẹ, fi kọ̀ǹpútà tàbí ẹ̀rọ alágbèéká rẹ tó ṣeé lo Íńtánẹ́ẹ̀tì ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ tàbí kó o fi ṣe ìwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tọ́jọ́ wọn kò tíì pẹ́.—Lọ sí abala “Àwọn Ìtẹ̀jáde,” kó o sì tẹ ìlujá tá a pè ní “Àká Ìwé Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì.” Tàbí kó o tẹ www.wol.jw.org síbi tí wọ́n ń kọ àdírẹ́sì Ìkànnì téèyàn bá fẹ́ lọ sí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Bó O Ṣe Máa Lò Ó
1 Yan àwòrán tó o bá fẹ́ tàbí ìlujá tá a pè ní “Wà Á Jáde.” Àwòrán náà máa rí bí èyí tá a tẹ̀ sórí ìwé. Fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tẹ̀ ẹ́, kó o sì lò ó láti fi kọ́ ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́.
2 Tẹ àmì “Play” láti wo fídíò.