ORÍ 11
Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Máa Ṣọ̀rẹ́ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
Ọ̀nà wo ló wù ẹ́ pé káwọn èèyàn máa gbà bá ẹ sọ̀rọ̀?
□ Lójúkojú
□ Lórí fóònù
□ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì
Àwọn wo ló máa ń wù ẹ́ jù láti bá sọ̀rọ̀?
□ Àwọn ọmọ kíláàsì ẹ
□ Àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ
□ Àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni
Ibo lo rò pé ó ti máa ń yá ẹ lára láti sọ̀rọ̀?
□ Níléèwé
□ Nílé
□ Nípàdé ìjọ
WO ÌDÁHÙN tó o mú ní ìbéèrè àkọ́kọ́. Ṣóhun tó o sọ ni pé o fẹ́ràn láti máa sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ju kó o sọ̀rọ̀ lójúkojú lọ? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ lọ̀ràn ẹ rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa ń wá ọ̀rẹ́, tí wọ́n sì máa ń ṣọ̀rẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Elaine sọ pé: “Ó máa ń dùn mọ́ni nínú láti mọ̀ pé o lè mọ àwọn èèyàn tó jẹ́ pé tí kì í bá ṣe ti Íńtánẹ́ẹ̀tì ni, o ò bá máà bá wọn pàdé láéláé.” Tammy, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] náà tún sọ ohun kan tó mú káwọn èèyàn fẹ́ràn láti máa sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó ní: “Bó o bá ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìwọ lo máa sọ ojú tí wọ́n á máa fi wò ẹ́, àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹ̀ ń ríra yín lójúkojú, tí wọn ò bá gba tìẹ, kò sí nǹkan tó o lè ṣe sí i.”
Wá wo ìdáhùn tó o mú sí ìbéèrè kejì àti ìkẹta báyìí. Máà jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu pé ó rọ̀ ẹ́ lọ́rùn láti bá ọmọ kíláàsì ẹ sọ̀rọ̀ ju kó o bá Kristẹni bíi tìẹ sọ̀rọ̀ nípàdé lọ. Ọmọbìnrin ọlọ́dún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Jasmine sọ pé: “Ó máa ń rọrùn láti ráwọn ọmọ iléèwé ẹ tó jẹ́ pé bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ náà ló ṣe ń ṣàwọn náà, ìyẹn sì lè jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti bá wọn sọ̀rọ̀.”
Bó o bá gbé gbogbo àwọn kókó tá a ti jíròrò yẹ̀ wò dáadáa, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa bá àwọn ọmọ iléèwé èèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Tammy ò jiyàn pé òun ti ṣerú ẹ̀ rí, ó ní: “Gbogbo ìgbà làwọn ọmọ iléèwé mi máa ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, mi ò sì fẹ́ kẹ̀yìn síbi táyé kọjú sí.”a Ọmọbìnrin ẹni ogún [20] ọdún kan tó ń jẹ́ Natalie ṣe ìkànnì kan fún ara rẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kó lè máa gbabẹ̀ bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: “Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti sún síwájú. Ọ̀nà tuntun téèyàn lè gbà máa báwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ sì ti pọ̀ gan-an. Ọ̀kan lára ẹ̀ ni Íńtánẹ́ẹ̀tì, mo sì fẹ́ràn ẹ̀ gan-an.”
Gbé Ewu Tó Wà Níbẹ̀ Yẹ̀ Wò
Òótọ́ ni pé, ó rọrùn fáwọn kan láti máa ṣọ̀rẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Natalie sọ pé: “Àyà rẹ á ki tó o bá ń béèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ju kó o máa sọ̀rọ̀ lójúkojú lọ.” Tammy ní kò sírọ́ ńbẹ̀, ó sọ pé: “Bó o bá ń tijú láti báwọn èèyàn sọ̀rọ̀, kúkú máa bá wọn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, torí ìyẹn á jẹ́ kó o lè wéwèé ohun tó o máa sọ.”
Àmọ́, ewu wà nínú bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìwà òmùgọ̀ sì ni béèyàn ò bá ronú lórí àwọn ewu wọ̀nyẹn kó tó kọrùn bọ̀ ọ́. Àpèjúwe kan rèé: Ṣé wàá faṣọ bojú tó o bá ń rìn ládùúgbò táwọn ọmọ-ìta ti ń ṣayé? Bó o bá mọ̀ pé o ò lè ṣe bẹ́ẹ̀, kí ló wá dé tó ò ń yan ọ̀rẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nígbà tó o mọ̀ pé ó léwu?
Ìwọ ronú lórí ewu tó wà nínú yíyan ọ̀rẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Elaine tó ti fìgbà kan gbádùn bíbá àwọn tí kò mọ̀ rí sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sọ pé: “Ó máa ń rọrùn láti báwọn ọ̀bàyéjẹ́ èèyàn pàdé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Nígbà míì, ẹ ò tíì ní sọ̀rọ̀ jìnnà tí wọ́n á ti máa sọ̀rọ̀ rírùn sí ẹ, wọ́n tiẹ̀ lè bi ẹ́ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣó o ti mọ ọkùnrin? Ṣó o máa ń fẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ àwọn ẹlòmíì?’ Àwọn míì tiẹ̀ lè ní kẹ́ ẹ jọ máa sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”
Bó bá wá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ tó o mọ̀ dáadáa, tó o sì gbẹ̀rí ẹ̀ jẹ́ lò ń bá sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ńkọ́? Ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ o, kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ o, o ṣì ní láti ṣọ́ra. Joan sọ pé: “O lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò tó pọ̀ jù láti bá ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kódà ó lè jẹ́ ‘ọ̀rẹ́ lásán’ pàápàá. Bó o ṣe ń lo àkókò láti bá ẹni yẹn sọ̀rọ̀ tó, ni ọ̀rẹ́ yín á túbọ̀ máa wọ̀ sí i, tó bá sì yá, ẹ máa bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò yẹ kẹ́ ẹ bára yín sọ.”
“Àwọn Tí Ń Fi Ohun Tí Wọ́n Jẹ́ Pa Mọ́”
Dáfídì Ọba mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti gbara èèyàn lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́. Ó kọ̀wé pé: “Èmi kò bá àwọn tí kì í sọ òtítọ́ jókòó; àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ ni èmi kì í sì í bá wọlé.”—Sáàmù 26:4.
Ṣó o ti bá irú àwọn tí Dáfídì sọ̀rọ̀ rẹ̀ pàdé rí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Ìgbà wo làwọn téèyàn ń bá pàdé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń “fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́”? ․․․․․
Tàbí kẹ̀, bóyá ìwọ alára lo máa ń fi irú ẹni tó o jẹ́ pa mọ́ nígbà tó o bá ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Abigail máa ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó sọ pé: “Mo lè bẹ̀rẹ̀ sí í báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí màá sì máa sọ̀rọ̀ bí ẹni tó láwọn ànímọ́ tí onítọ̀hún ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.”
Ọ̀nà míì ni ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Leanne máa ń gbà tan àwọn èèyàn jẹ. Ó ní: “Mo máa ń bá ọmọkùnrin kan tó wà ní ìjọ kejì sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kò pẹ́ kò jìnnà, a bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé a ‘nífẹ̀ẹ́’ ara wa. Táwọn òbí mi bá ti ń kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, mo máa ń pa ojú ìkànnì yẹn dé, kí wọ́n má bàa mọ ohun tí mò ń ṣe. Mi ò rò pé wọ́n lè ronú láé pé ọmọbìnrin wọn tí ò ju ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13] lọ á máa kọ lẹ́tà ìfẹ́ sí ọmọkùnrin kan tí ò ju ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] lọ. Kò wá sí wọn lọ́kàn rí.”
Ṣọ́ra Ẹ!
Òótọ́ ni pé, àwọn ìgbà kan wà tí ò sóhun tó burú nínú kéèyàn bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan àwọn àgbàlagbà ló máa ń bá àwọn ọ̀rẹ́ wọn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí lèèyàn gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ẹ̀ fún? Àwọn kan rèé:
● Máa wo iye àkókò tó ò ń lò nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì, má sì jẹ́ kó gba àkókò tó yẹ kó o fi ṣe àwọn nǹkan pàtàkì mọ́ ẹ lọ́wọ́, títí kan oorun pàápàá. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Brian sọ pé: “Àwọn ọmọ kan níléèwé máa ń sọ pé aago mẹ́ta òru làwọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”—Éfésù 5:15, 16.
● Àwọn tó o mọ̀ dáadáa tàbí àwọn tí o lè wádìí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ ni kó o máa bá sọ̀rọ̀. Àwọn oníṣekúṣe máa ń rìn gbéregbère lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wọ́n ń wá àwọn ọ̀dọ́ tí ò tíì dákan mọ̀ tí wọ́n máa tàn jẹ.—Róòmù 16:18.
● Bó o bá ń ṣòwò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, máa fọgbọ́n ṣe é. Máa fura sáwọn èèyàn kó o tó sọ ohunkóhun fún wọn nípa ara rẹ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n lè lù ẹ́ ní jìbìtì tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.—Mátíù 10:16.
● Bó o bá fẹ́ fi fọ́tò ẹ ránṣẹ́ sáwọn ọ̀rẹ́ ẹ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé fọ́tò yìí jọ tẹni tó ń sin Ọlọ́run?’—Títù 2:7, 8.
● Bíi tìgbà téèyàn bá ń bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀ lójúkojú, tí ọ̀rọ̀ tíwọ àtẹnì kan jọ ń sọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì bá ti ń dà bí “ohun tí kò yẹ,” tètè fòpin sí i.—Éfésù 5:3, 4.
● Má fohun kóhun bò tó o bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bó o bá ti ń fi ‘irú ẹni tó o jẹ́ pa mọ́’ fáwọn òbí ẹ, nǹkan míì ti wọ̀ ọ́ nìyẹn o. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Kari sọ pé: “Mi ò kí ń fọ̀rọ̀ bò fún mọ́mì mi. Gbogbo nǹkan tí mo bá ń ṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni mo máa ń fi hàn wọ́n.”—Hébérù 13:18.
“Ìkánjú Òun Pẹ̀lẹ́, Ọgbọọgba Ni!”
O fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́ àbí? Kò sóhun tó burú ńbẹ̀. Ọlọ́run ti dá àwa èèyàn ká lè máa bára wa ṣọ̀rẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Torí náà tó bá ń ṣe ẹ́ bíi kó o lọ́rẹ̀ẹ́, má yọ ara ẹ lẹ́nu, bí Ọlọ́run ṣe dá ẹ nìyẹn! Ṣáà ṣọ́ra tó o bá fẹ́ yàn wọ́n.
Mọ̀ dájú pé bó o bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti fi yan ọ̀rẹ́, ọ̀rẹ́ gidi lo máa yàn. Bí ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] kan ṣe sọ ọ́ rèé: “Kò rọrùn láti rí ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ rẹ, tó sì fẹ́ràn Jèhófà. Àmọ́ nígbà tó o bá rí wọn tán ni wàá tó gbà pé ìkánjú òun pẹ̀lẹ́, ọgbọọgba ni!”
Ta ló sọ pé ọ̀rọ̀ kì í dunni? Òfófó a máa gúnni bí idà. Àmọ́, báwo lo ṣe lè fòpin sí i?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Èmi kò bá àwọn tí kì í sọ òtítọ́ jókòó; àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ ni èmi kì í sì í bá wọlé.”—Sáàmù 26:4.
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 103]
“Mi ò kì í bá àwọn tí mi ò mọ̀ tàbí tí mi ò lè bá ṣọ̀rẹ́ lójú ayé sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”—Joan
ÌMỌ̀RÀN
Àkókò kì í pẹ́ lọ tó o bá wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì! Torí náà, ní aago pàtó kan lọ́kàn tó o fẹ́ kúrò nídìí ẹ̀, kó o sì rí i pé o kúrò níbẹ̀ tí aago yẹn bá ti lù. Bó bá ṣeé ṣe pàápàá, tẹ aago tó o fẹ́ kúrò nídìí ẹ̀ yẹn sórí àláàmù, kó lè rán ẹ létí.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Gbogbo ohun tí ọ̀bàyéjẹ́ èèyàn kan nílò láti rí ẹ mú ò ju kó mọ orúkọ ẹ, iléèwé ẹ àti nọ́ńbà tẹlifóònù ẹ lọ.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Màá fẹ́ sọ àkókò tí mò ń lò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì di lọ́sẹ̀ ․․․․․, kí n sì lè tẹ̀ lé ìpinnu yìí, màá ․․․․․
Tí mo bá rí i pé àjèjì kan ni mò ń bá sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, màá ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Àǹfààní àti ewu wo ló wà nínú bíbá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tá a bá fi wé bíbáni sọ̀rọ̀ lójúkojú?
● Kí nìdí tó fi rọrùn láti parọ́ nípa irú ẹni tó o jẹ́ bó o bá ń sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
● Báwo lo ṣe lè díwọ̀n àkókò tó ò ń lò nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
● Àwọn ọ̀nà tó ṣàǹfààní wo lèèyàn lè gbà lo Íńtánẹ́ẹ̀tì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 100, 101]
Ṣé wàá faṣọ bojú tó o bá ń rìn ládùúgbò táwọn ọmọ-ìta ti ń ṣayé? Bó o bá mọ̀ pé o ò lè ṣe bẹ́ẹ̀, kí ló wá dé tó ò ń yan ọ̀rẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nígbà tó o mọ̀ pé ó léwu?