ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb22 March ojú ìwé 9
  • Àwọn Wo Lò Ń Bá Ṣọ̀rẹ́ Lórí Ìkànnì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Wo Lò Ń Bá Ṣọ̀rẹ́ Lórí Ìkànnì?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Máa Ṣọ̀rẹ́ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ṣọ́ra fún Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Ìkànnì Àjọlò
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìkànnì Àjọlò Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Apá 2
    Jí!—2012
  • Ìkànnì Wa Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì—Máa Fi Ṣe Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti Ìjọsìn Ìdílé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
mwb22 March ojú ìwé 9

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Wo Lò Ń Bá Ṣọ̀rẹ́ Lórí Ìkànnì?

Ká tó lè pe ẹnì kan ní ọ̀rẹ́ wa, á jẹ́ pé ẹni náà sún mọ́ wa gan-an, a sì jọ nífẹ̀ẹ́ ara wa. Bí àpẹẹrẹ, Jónátánì àti Dáfídì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì. (1Sa 18:1) Àwọn méjèèjì níwà tó dáa, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n sún mọ́ra. Torí náà, ká tó lè di ọ̀rẹ́ ẹnì kan a gbọ́dọ̀ mọ ẹni náà dáadáa. Ká tó lè mọ ẹnì kan dáadáa, a gbọ́dọ̀ sapá láti sún mọ́ ọn, ìyẹn sì máa ń gba àkókò. Àmọ́ lórí ìkànnì àjọlò, àwọn èèyàn lè di “ọ̀rẹ́” ara wọn láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan. Ó rọrùn fẹ́nì kan láti fi irú ẹni tó jẹ́ pa mọ́ lórí ìkànnì, torí pé ẹni náà ló máa pinnu ohun tó máa sọ àtohun tó fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa òun. Torí náà, o gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ronú dáadáa kó o tó di ọ̀rẹ́ ẹnì kan lórí ìkànnì. Tí ẹnì kan tó ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ dáadáa bá sọ pé òun fẹ́ di ọ̀rẹ́ rẹ lórí ìkànnì àjọlò, má jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́ láti kọ̀, kó o wá máa ronú pé tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀ ẹni náà máa bínú. Àwọn kan tiẹ̀ pinnu pé àwọn ò ní lo ìkànnì àjọlò rárá torí ewu tó wà níbẹ̀. Àmọ́ tó o bá pinnu pé wàá lò ó, kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn?

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA FỌGBỌ́N LO ÌKÀNNÌ ÀJỌLÒ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Apá kan nínú fídíò “Máa Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò.” Ó ya ọmọbìnrin kan lẹ́nu nígbà tó rí fọ́tò ara ẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n.

    Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn kó o tó gbé àwòrán tàbí kọ ọ̀rọ̀ sórí ìkànnì àjọlò?

  • Apá kan nínú fídíò ‘Máa Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò.’ Àwọn ọkùnrin méjì tó rí wúruwùru ń fi ohun tó wà lórí ìkànnì àjọlò han ọmọ kan, ọmọ náà sì fọwọ́ bo ojú rẹ̀.

    Kí nìdí tó fi yẹ kó o fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lórí ìkànnì àjọlò?

  • Apá kan nínú fídíò “Máa Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò.” Ọmọkùnrin kan sùn lọ nídìí kọ̀ǹpútà torí gbogbo òru ló fi tẹ̀ ẹ́.

    Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ìkànnì àjọlò?​—Ef 5:15, 16

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́