ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 18-19
  • Wọ́n Mọyì ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Mọyì ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìkànnì Wa Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì—Máa Fi Ṣe Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti Ìjọsìn Ìdílé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Báwo Ni Ibi Ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
  • Ìwé Ìwádìí Tuntun
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Lo Ètò Ìṣiṣẹ́ JW Library?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 18-19
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Wọ́n Mọyì ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower

Ní June 28, 2013, ìfilọ̀ kan jáde lórí ìkànnì pé ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower ti wà ní ọgọ́rùn-ún [100] èdè báyìí, ìtẹ̀síwájú ńlá lèyí jẹ́ nínú ìtàn ìkànnì wa. ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ yìí wúlò fún ṣíṣe ìwádìí bíi ti àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe sórí àwo CD-ROM, ìyẹn Watchtower Library on CD-ROM. Oríṣiríṣi ẹ̀rọ tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì ni ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ lè bá ṣiṣẹ́, irú bí kọ̀ǹpútà ńlá àti ti alágbèéká tàbí àwọn fóònù àtàwọn ohun èlò alágbèéká míì tó ń ṣiṣẹ́ bíi kọ̀ǹpútà. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà lórí rẹ̀ jẹ́ láti ọdún 2000 sísàlẹ̀. Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun àti ìwé Insight on the Scriptures tún wà níbẹ̀ ní oríṣiríṣi èdè. Ó tún ṣeé fi wá ọ̀rọ̀, gbólóhùn tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tá a pa pọ̀ bíi ti àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lórí ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ yìí, o lè wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tàbí ìsọfúnni jáde ní èdè kan, kó o sì ní kó tún gbé e jáde ní èdè míì. Díẹ̀ rèé lára ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ tí àwọn kan sọ nípa ohun èlò ìwádìí tó wúlò gan-an yìí:

“Ẹ ṣeun gan-an fún àká ìwé yìí. Ayọ̀ mi kún nígbà tí mo rí ohun èlò tí mo lè máa fi kẹ́kọ̀ọ́ yìí, mi ò tiẹ̀ mọ bí ǹ bá ṣe dúpẹ́. Mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn ètò táwọn èèyàn ń lò lórí kọ̀ǹpútà, mi ò sì mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì, ṣùgbọ́n mo gbà pé baba ńlá iṣẹ́ lẹ ṣe sínú ètò ìwádìí yìí. Ìfẹ́ tí ẹ ní sí àwọn èèyàn, àwọn ará àti fún Jèhófà ta yọ gan-an. Ọ̀nà tẹ́ ẹ gbà ṣe ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ yìí fi hàn kedere pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ yín lógún. Mi ò rò pé nǹkan míì wà tó tún dáa ju èyí lọ tí ǹ bá béèrè lọ́wọ́ Jèhófà Baba mi ọ̀run nítorí ìfẹ́ tó ní sí mi àti bó ṣe jẹ́ ọ̀làwọ́. Ẹ ṣeun gan-an ni.”—A., láti orílẹ̀-èdè Ajẹntínà.

“Ṣe ló dà bíi pé mò ń lálàá! Ní ọ̀sán yìí tí mo wo ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ, mo rí i pé èdè Creole ti orílẹ̀-èdè Haiti wà lára àwọn èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé síbẹ̀. Mi ò ní in lọ́kàn láé pé èyí lè ṣẹlẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀yin náà kíyè sí i nínú lẹ́tà yìí pé mi ò tiẹ̀ mohun tí ǹ bá sọ. Àdúrà mi ni pé kí Jèhófà bù kún gbogbo ìsapá yín, kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sì túbọ̀ máa darí yín.”—D.C., láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

[Graph tó wà ní ojú ìwé 19]
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́