Ìwé Ìwádìí Tuntun
Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn akéde kárí ayé ti fi ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index ṣe ìwádìí dáadáa. Àmọ́, iye èdè tó wà kò tó nǹkan torí pé ìsọfúnni inú rẹ̀ pọ̀. Fún ìdí èyí, Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà ní àádọ́sàn-án [170] èdè. Àwọn ìwé tá a tẹ̀ jáde lọ́dún 2000 síwájú la tọ́ka sí ní pàtàkì nínú Ìwé Ìwádìí yìí. A kò tí ì tẹ Ìwé Ìwádìí ní àwọn èdè tí a fi tẹ ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index jáde, àmọ́ a ti gbé ẹ̀dà rẹ̀ tó ṣeé kà lórí ẹ̀rọ sórí Watchtower Library àti ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower. Ìwé Ìwádìí yìí máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàwárí ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè rẹ, wàá rí ìsọfúnni lórí àwọn ọ̀rọ̀ ara ẹni, o sì lè fi múra àwọn ìpàdé ìjọ àti ìjọsìn ìdílé sílẹ̀.