Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 1
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 1
Orin 48 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 16 ìpínrọ̀ 18 sí 22 àti àpótí tó wà lójú ìwé 167 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 32-34 (10 min.)
No. 1: Diutarónómì 32:22-35 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Ohun Tó Ń Mú Kí Èèyàn Tóótun fún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Náà—td 37B (5 min.)
No. 3: Àwọn Ọmọdé Tó Mú Inú Ọlọ́run Dùn—lr orí 41 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Lóṣù December. Ìjíròrò. Ṣe àṣefihàn àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mẹ́ta tó wà lójú ìwé yìí. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, ní kí àwọn ará sọ ìdí tí àkòrí àwọn ìwé ìròyìn náà yóò fi fa àwọn èèyàn kan ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mọ́ra.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún.” Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní.
Orin 119 àti Àdúrà