Bí A Ṣe Ń Ṣe Ìwádìí
SÓLÓMỌ́NÌ ỌBA “fẹ̀sọ̀ ronú, ó sì ṣe àyẹ̀wò fínnífínní, kí ó lè ṣètò ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe lọ́nà gígún régé.” Kí nìdí rẹ̀? Nítorí ó fẹ́ láti kọ “àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́.” (Oníw. 12:9, 10) Lúùkù “tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye” kí ó lè sọ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Kristi bí ó ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra gẹ́lẹ́. (Lúùkù 1:3) Ìwádìí ni ohun tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run méjèèjì yìí ń ṣe.
Kí ni ìwádìí? Ìwádìí jẹ́ fífẹ̀sọ̀ wá ìsọfúnni nípa ohun kan. Ó kan ìwé kíkà, ó sì gba kéèyàn fi àwọn ìlànà tó rọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ kíkọ́ sílò. Ó tún lè mú fífi ọ̀rọ̀ wáni lẹ́nu wò lọ́wọ́.
Kí làwọn nǹkan tó lè mú kí ìwádìí yẹ ní ṣíṣe? Àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan rèé. Àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì lójú rẹ lè jẹ yọ nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ tàbí bí o bá ń ka Bíbélì. Ẹni tí o wàásù fún lè béèrè ìbéèrè kan tí wàá fẹ́ ní ìsọfúnni pàtó láti fi dáhùn ìbéèrè yẹn. Ó sì lè jẹ́ pé a yan ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti sọ ni.
Wo àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀ tí a yàn fún ọ láti sọ. Ó lè jẹ́ kókó kan tó kó ohun púpọ̀ mọ́ra ni wọ́n ní kí o sọ̀rọ̀ lé lórí. Báwo ni wàá ṣe mú un bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ mu? Ńṣe ni kí o ṣe ìwádìí nípa rẹ̀ láti mú kí ó túbọ̀ kún fún ẹ̀kọ́. Bí o bá fi ìsọfúnni oníṣirò bíi mélòó kan, tàbí àpẹẹrẹ kan tó bá ọ̀rọ̀ rẹ mu tó sì tún wọ àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn, ṣàlàyé kókó kan tó dà bíi pé àwọn èèyàn ti mọ̀ bí ẹní mowó, kókó yẹn á di èyí tó kún fún ẹ̀kọ́, yóò tiẹ̀ tún tani jí pàápàá. Àpilẹ̀kọ tí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ kà lè jẹ́ èyí tí a kọ fún ìlò àwọn òǹkàwé jákèjádò ayé, bẹ́ẹ̀ sì rèé, o ní láti ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà, kí o fi àpèjúwe tì í lẹ́yìn, kí o sì mú àwọn kókó inú rẹ̀ bá ìjọ tàbí ẹnì kan pàtó mu. Ọ̀nà wo lo máa wá gbé e gbà?
Kí o tó bẹ̀rẹ̀ ìwádìí rẹ rárá, kọ́kọ́ ronú nípa àwùjọ tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Kí ni wọ́n á ti mọ̀ nípa kókó yẹn? Kí ló yẹ kí wọ́n mọ̀? Lẹ́yìn náà, wá pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe. Ṣé o fẹ́ ṣàlàyé nǹkan kan ni? tàbí o fẹ́ mú nǹkan kan dáni lójú? tàbí o fẹ́ já ohun kan ní koro? tàbí o fẹ́ rọni láti ṣe nǹkan kan? Àlàyé ṣíṣe ń béèrè pé kéèyàn pèsè ìsọfúnni síwájú sí i láti mú kí ọ̀ràn kan yéni yékéyéké. Àwọn kókó inú ọ̀rọ̀ yẹn lè yé wọn o, ṣùgbọ́n ó lè jẹ́ pé wàá túbọ̀ ṣàlàyé nípa ìgbà tí wọ́n máa ṣe ohun tí wọ́n gbọ́ tàbí bí wọ́n ṣe máa ṣe é. Mímú nǹkan dáni lójú ń béèrè pé kéèyàn ṣàlàyé àwọn ìdí tí ohun tá à ń sọ fi rí bẹ́ẹ̀, títí kan mímú ẹ̀rí wá. Jíjá nǹkan ní koro ń béèrè pé kéèyàn mọwá kó sì mẹ̀yìn ọ̀ràn ọ̀hún, kó sì tún ṣàlàyé àwọn ẹ̀rí tó bá lò yéni yékéyéké. Ó dájú ṣá o, pé ète wa kì í ṣe láti kàn wá àwọn gbankọgbì ẹ̀rí láti fi bi ọ̀rọ̀ ṣubú, bí kò ṣe láti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé òótọ́ ọ̀rọ̀. Rírọni láti ṣe nǹkan kan wé mọ́ sísọ̀rọ̀ lọ́nà tó wọni lọ́kàn. Ó túmọ̀ sí pé a óò bá àwùjọ sọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò ta wọ́n jí, a ó sì gbin èrò tí yóò mú kí wọ́n tara ṣàṣà láti ṣe ohun tí a ń wí sí wọn lọ́kàn. Mímú àpẹẹrẹ àwọn tó ti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, àní lójú ìnira pàápàá wá, lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà wọni lọ́kàn ṣinṣin.
O ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìwádìí wàyí, àbí? Ṣì ní sùúrù ná. Ronú nípa ìwọ̀n ìsọfúnni tó o nílò. Àkókò tí o máa fi sọ ọ́ tún ṣe pàtàkì. Bó bá ṣe pé o fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ ọ̀hún fún àwọn kan ni, báwo ni àkókò tó o ní láti fi sọ ọ́ ṣe pọ̀ tó? Ṣé ìṣẹ́jú márùn-ún ni? Ṣé ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta ni? Ṣé ó ti ní àkókò pàtó tó wà fún un, bíi ti ìpàdé ìjọ tàbí kò níye àkókò kan pàtó, bíi ti ìgbà tí a bá lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn?
Lákòótán, àwọn ohun èlò ìṣèwádìí wo lo lè rí lò? Láfikún sí àwọn tó o ní nílé, ṣé ó tún ku àwọn mìíràn tó o lè rí nínú ibi ìkówèésí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yín? Ṣé àwọn ará tó ti ń sin Jèhófà láti ọ̀pọ̀ ọdún wá yóò jẹ́ kí o lo àwọn ohun èlò ìṣèwádìí tiwọn? Ṣé ibi ìkówèésí ti ìlú wà lágbègbè rẹ, níbi tó o ti lè rí àwọn ìwé ìṣèwádìí lò bí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀?
Lílo Bíbélì—Ohun Èlò Ìṣèwádìí Wa Tó Gba Iwájú Jù Lọ
Bí ohun tó ò ń ṣèwádìí nípa rẹ̀ bá kan mímọ ìtumọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, kúkú bẹ̀rẹ̀ látinú Bíbélì fúnra rẹ̀.
Gbé Ohun Tó Fa Ọ̀rọ̀ Yẹn Yẹ̀ Wò. Bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ta ni ẹsẹ yìí ń bá sọ̀rọ̀? Kí ni àwọn ẹsẹ tó yí i ká fi hàn nípa ohun tó fà á tí wọ́n fi sọ ọ̀rọ̀ yẹn, tàbí ìwá àwọn èèyàn tí ẹsẹ yẹn ń sọ?’ Irú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ bí ìwọ̀nyí sábà máa ń jẹ́ ká lè lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, wọ́n sì tún lè mú kí ọ̀rọ̀ tí o sọ nígbà tó o lò wọ́n túbọ̀ lárinrin.
Bí àpẹẹrẹ, a sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ Hébérù 4:12 láti fi sọ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lágbára láti gún ọkàn ní kẹ́ṣẹ́ kí ó sì nípa lórí ìgbésí ayé ẹni. Ohun tó fa ọ̀rọ̀ yẹn túbọ̀ jẹ́ kí a mọyì bí ó ṣe lè rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ nípa ìrírí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ogójì ọdún tí wọ́n lò nínú aginjù kí wọ́n tó wọnú ilẹ̀ tí Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù ló ti ń sọ bọ̀. (Héb. 3:7–4:13) “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” ìyẹn ìlérí tó ṣe láti mú wọn wá sí ibi ìsinmi ní ìbámu pẹ̀lú májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá, kì í ṣe òkú ọ̀rọ̀; ààyè ọ̀rọ̀ tó ń báṣẹ́ lọ síbi tí yóò ti ní ìmúṣẹ ni. Kò sì sídìí tí kò fi yẹ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà á gbọ́. Àmọ́ o, bí Jèhófà ṣe ń ṣamọ̀nà wọn lọ láti Íjíbítì sí Òkè Sínáì, àti sí ọ̀nà Ilẹ̀ Ìlérí, léraléra ni wọ́n hùwà àìnígbàgbọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ìhùwàsí wọn nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń mú ọ̀rọ̀ ṣẹ wá fi ohun tó wà nínú ọkàn wọn hàn gbangba. Lọ́nà kan náà, láyé ìgbà tiwa yìí, ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ ìlérí Ọlọ́run máa ń fi ohun tó wà nínú ọkàn àwọn èèyàn hàn.
Yẹ Àwọn Atọ́ka Etí Ìwé Wò. Àwọn Bíbélì kan ní àwọn atọ́ka etí ìwé. Ṣé tìrẹ ní? Bí ó bá ní, ìyẹn lé ṣèrànwọ́. Wo àpẹẹrẹ kan látinú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ìwé 1 Pétérù 3:6 sọ nípa Sárà pé ó jẹ́ ẹni àwòkọ́ṣe fún àwọn Kristẹni aya. Atọ́ka etí ìwé ibẹ̀ tó tọ́ka sí Jẹ́nẹ́sísì 18:12 ti ọ̀rọ̀ yẹn lẹ́yìn nípa fífi hàn pé ńṣe ni Sárà sọ ọ́ “nínú ara rẹ̀” pé Ábúráhámù jẹ́ olúwa òun. Nípa bẹ́ẹ̀, ìtẹríba àtọkànwá ló ní. Láfikún sí àwọn ìjìnlẹ̀ òye bí èyí, atọ́ka etí ìwé tún lè tọ́ka rẹ sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ká mọ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan tàbí àpẹẹrẹ májẹ̀mú Òfin kan. Àmọ́ ṣá o, kí ó yé ọ pé àwọn atọ́ka etí ìwé kan kò wà fún ṣíṣe irú àwọn àlàyé yẹn o. Ó kàn lè jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó jọra wọn ni wọ́n ń tọ́ka sí, tàbí ìtàn ìgbésí ayé ẹnì kan, tàbí ìsọfúnni nípa ìlú tàbí ilẹ̀ ibì kan.
Fi Atọ́ka Ọ̀rọ̀ Bíbélì Wá A. Atọ́ka ọ̀rọ̀ Bíbélì jẹ́ ìwé atọ́ka kan tí a to àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú Bíbélì sí lọ́nà A, B, D. Ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàwárí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ mọ́ kókó tí ò ń ṣèwádìí nípa rẹ̀. Bí o bá ṣe ń yẹ̀ wọ́n wò, wàá tún mọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé mìíràn tó lè ṣèrànwọ́ síwájú sí i. Ìwọ yóò rí ẹ̀rí nípa “àpẹẹrẹ” òtítọ́ tí a là lẹ́sẹẹsẹ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Tím. 1:13) Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ṣókí fún “Atọ́ka Àṣàyàn Ọ̀rọ̀ Bíbélì.” Ìwé atọ́ka Comprehensive Concordance kún jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bí ó bá wà ní èdè rẹ, yóò tọ́ka rẹ sí gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ti lo àwọn lájorí ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan nínú Bíbélì.
Kíkọ́ Láti Lo Àwọn Ohun Èlò Ìṣèwádìí Yòókù
Àpótí tó wà lójú ewé 33 tọ́ka sí àwọn ohun ìṣèwádìí mélòó kan tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti pèsè. (Mát. 24:45-47) Ọ̀pọ̀ nínú wọn ní àtẹ kókó ẹ̀kọ́, púpọ̀ nínú wọn sì ní atọ́ka lápá ẹ̀yìn wọn, èyí tí a ṣe lọ́nà tí yóò fi lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wá ìsọfúnni pàtó rí. Ní ìparí ọdún kọ̀ọ̀kan, a máa ń tẹ atọ́ka kókó àpilẹ̀kọ sínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! láti tọ́ka ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ ti ọdún náà.
Béèyàn bá mọ irú ìsọfúnni tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì yìí, ìyẹn lè mú kí ìwádìí yá kíákíá láti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń fẹ́ mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀, ẹ̀kọ́ ohun tá a gbà gbọ́, ìwà Kristẹni, tàbí ìlò àwọn ìlànà Bíbélì. Inú Ilé Ìṣọ́ ló ṣeé ṣe kí o ti rí ohun tí ò ń wá. Jí! máa ń jíròrò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn ìṣòro, ẹ̀sìn, sáyẹ́ǹsì, àti àwọn èèyàn ní onírúurú ilẹ̀ òde òní. Àlàyé lórí bí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìtàn inú àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣe ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, wà nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Ìjíròrò odindi ìwé Bíbélì kan lẹ́sẹẹsẹ wà nínú irú ìtẹ̀jáde bí ìwé Ìṣípayá-Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! àti apá méjèèjì ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé. Nínú ìwé Reasoning From the Scriptures, ìwọ yóò rí àwọn ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìbéèrè lórí Bíbélì, èyí tí wọ́n sábà máa ń béèrè tí a bá wà lóde ẹ̀rí. Bí o bá fẹ́ túbọ̀ mọ̀ sí i nípa àwọn ẹ̀sìn yòókù, nípa àwọn ẹ̀kọ́ wọn, àti ìtàn nípa bí wọ́n ṣe ti ń bá ẹ̀sìn wọn bọ̀ látẹ̀yìnwá, wo ìwé Mankind’s Search for God. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn díẹ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Awọn Ẹlẹríi Jehofah—Nfi Pẹlu Iṣopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inú Ọlọrun Yíká Ayé. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tí a ti gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere jákèjádò ayé, wo Ilé Ìṣọ́ tí déètì rẹ̀ jẹ́ January 1 tó dé kẹ́yìn. Ìwé Insight on the Scriptures jẹ́ ìwé tó ń fúnni ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa Bíbélì àti àwòrán àwọn ilẹ̀ tó sọ̀rọ̀ lé lórí. Bí o bá ń fẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa àwọn èèyàn, ilẹ̀, nǹkan, èdè, tàbí ìtàn àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Bíbélì, inú ìwé yẹn lo ti lè rí i.
Ìwé Atọ́ka “Watch Tower Publications Index.” Ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index tí a tẹ̀ jáde ní èyí tó ju ogún èdè lọ yìí, yóò tọ́ka rẹ sí ìsọfúnni tó wà nínú onírúurú ìtẹ̀jáde wa. A pín in sí ẹ̀ka atọ́ka kókó ẹ̀kọ́ àti ẹ̀ka atọ́ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Tó o bá fẹ́ lo ẹ̀ka atọ́ka kókó ẹ̀kọ́, wá ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ kókó ẹ̀kọ́ tó o fẹ́ ṣèwádìí nípa rẹ̀ níbẹ̀. Tó o bá fẹ́ lo ẹ̀ka ti atọ́ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́, wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o fẹ́ kó túbọ̀ yé ọ sí i lára àwọn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ síbẹ̀. Bí a bá ti tẹ ohunkóhun jáde nípa kókó ẹ̀kọ́ kan tàbí nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o ní lọ́kàn, nínú àwọn ọdún tí ìwé Index yẹn wà fún, ìwọ yóò rí àwọn ìwé tí o ti lè rí i níbẹ̀. Lo àlàyé àwọn àmì ìkékúrú orúkọ ìwé tó wà lápá ìbẹ̀rẹ̀ ìwé Index láti fi mọ orúkọ ìwé tí àwọn àmì ìkékúrú tí a tọ́ka sí wà fún. (Bí àpẹẹrẹ, tí o bá lo ìyẹn, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé w99 3/1 15 tọ́ka sí Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) tí a tẹ̀ lọ́dún 1999, ẹ̀dà ti March 1, ojú ewé 15.) Àwọn lájorí àkòrí bíi “Field Ministry Experiences” [Àwọn Ìrírí Látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní Pápá] àti “Life Stories of Jehovah’s Witnesses” [Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà], lè wúlò gan-an nígbà tó o bá ń múra láti sọ ọ̀rọ̀ láti fi ta ìjọ jí.
Bó ṣe jẹ́ pé ìwádìí máa ń gbani láfiyèsí gan-an, ṣọ́ra kó o má bàa yà bàrá kúrò lórí ohun tó ò ń wá. Jẹ́ kí ọkàn rẹ wà lórí ète rẹ láti wá ìsọfúnni tó o fẹ́ lò fún iṣẹ́ tó wà lọ́wọ́ rẹ báyìí. Bí ìwé Index bá tọ́ka rẹ sí ìwé kan, ṣí ìwé yẹn sí ojú ìwé tí ó sọ, kí o wá lo àwọn àkòrí kéékèèké àti àwọn gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ àwọn ìpínrọ̀ ibẹ̀ gẹ́gẹ́ bí atọ́nà láti fi rí ìsọfúnni tó o nílò. Bí o bá ń wá ìtumọ̀ ẹsẹ Bíbélì kan ní pàtó, kọ́kọ́ wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn lójú ewé tí Index tọ́ka rẹ sí ná. Lẹ́yìn náà, kí o wá wo àlàyé tí a ṣe nípa rẹ̀ níbẹ̀.
“Watchtower Library” on CD-ROM [Àkójọ Ìtẹ̀jáde Society Tá A Ṣe Sórí Ike Pẹlẹbẹ Tá À Ń Fi Kọ̀ǹpútà Lò]. Bí o bá ń rí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà lò, o lè jàǹfààní lílo Watchtower Library on CD-ROM, èyí tó jẹ́ pé ó ní àkójọ àwọn ìtẹ̀jáde wa púpọ̀ rẹpẹtẹ nínú. Ètò tí a fi ń wá nǹkan rí tó wà nínú rẹ̀, tó rọrùn láti lò, yóò jẹ́ kí o lè wá ẹyọ ọ̀rọ̀ kan, gbólóhùn ọ̀rọ̀, tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nínú èyíkéyìí nínú ìtẹ̀jáde tó wà nínú ètò Watchtower Library ọ̀hún. Ká tiẹ̀ sọ pé ohun èlò ìṣèwádìí yìí kò sí ní èdè rẹ, o ṣì lè jàǹfààní rẹ̀ bí o bá lo èyí tó wà ní èdè ilẹ̀ òkèèrè tó o bá mọ̀.
Àwọn Ibi Ìkówèésí Ìjọba Ọlọ́run Yòókù
Nínú lẹ́tà kejì onímìísí tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin yẹn pé kí ó kó “àwọn àkájọ ìwé, ní pàtàkì àwọn ìwé awọ,” wá fún òun ní ìlú Róòmù. (2 Tím. 4:13) Pọ́ọ̀lù ka àwọn ìwé kan sí ohun ribiribi, ó sì pa wọ́n mọ́. Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ o máa ń tọ́jú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́, Jí!, àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tìrẹ pa mọ́ àní lẹ́yìn tí a bá tiẹ̀ ti kà wọ́n tán ní àwọn ìpàdé ìjọ? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lè rí wọn lò fún ìwádìí ṣíṣe, pa pọ̀ mọ́ àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni wa mìíràn tó o ti ní. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ ló ní àkójọ àwọn ìtẹ̀jáde ti ìjọba Ọlọ́run nínú ibi ìkówèésí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Ìwọ̀nyí wà fún àǹfààní ìjọ látòkèdélẹ̀, kí wọ́n lè lò wọ́n nígbà tí wọ́n bá wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Ní Àkójọ Ìsọfúnni Tìrẹ Fúnra Rẹ
Máa kíyè sí àwọn ìsọfúnni tó wuni, tó jẹ́ pé o lè lò nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀ àti nígbà tó o bá ń kọ́ni. Bí o bá rí ìròyìn kan, ìsọfúnni oníṣirò tàbí àpẹẹrẹ kan nínú ìwé ìròyìn, èyí tí o lè lò nínú iṣẹ́ ìsìn, gé ìsọfúnni náà pa mọ́ tàbí kí o dà á kọ. Kọ ọjọ́ tí wọ́n tẹ̀ ẹ́, orúkọ ìwé ìròyìn yẹn, àti orúkọ òǹkọ̀wé tàbí ti òǹtẹ̀wé náà sí i bí ó bá ṣeé ṣe. Ní àwọn ìpàdé ìjọ, kọ àwọn kókó ọ̀rọ̀ àti àwọn àpèjúwe tó o lè fi ṣàlàyé òtítọ́ fún àwọn ẹlòmíràn sílẹ̀. Ǹjẹ́ àpèjúwe tó dára kan tíì wá sí ọ lọ́kàn rí, ṣùgbọ́n tí o kò láǹfààní láti lò ó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? Kọ ọ́ sílẹ̀, kí o sì fi í sínú àkójọ ìsọfúnni kan. Tó bá fi pẹ́ díẹ̀ tó o ti ń wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, wàá ti sọ ọ̀rọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ bíi mélòó kan sẹ́yìn. Dípò tí wàá fi kó àwọn ìwé tí o kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí dà nù, tọ́jú wọn pa mọ́. Ìwádìí tó o ti ṣe lè padà wá wúlò tó bá yá.
Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀
Rántí pé àwọn èèyàn jẹ́ orísun pàtàkì tí a ti lè rí ìsọfúnni. Nígbà tí Lúùkù ń kọ ìtàn ìwé Ìhìn Rere tirẹ̀, ó dájú pé ó rí ìsọfúnni púpọ̀ gbà nípa fífi ọ̀rọ̀ wá àwọn tí ọ̀ràn ṣojú wọn lẹ́nu wò. (Lúùkù 1:1-4) Ó ṣeé ṣe kí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ kan lè túbọ̀ là ọ́ lóye nípa ohun kan tó o ti ń ṣèwádìí nípa rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Éfésù 4:8, 11-16 ṣe wí, Kristi ń lo “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” láti fi ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nínú “ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run.” Fífi ọ̀rọ̀ wá àwọn tó ti nírìírí nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lẹ́nu wò lè jẹ́ kí o gbọ́ àwọn àlàyé tó wúlò gan-an ni. Bíbá àwọn èèyàn fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ tún lè jẹ́ kó o mọ ohun tí wọ́n ń rò, èyí sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti múra ọ̀rọ̀ tó gbéṣẹ́ ní ti gidi.
Díwọ̀n Àbájáde Ìwádìí Rẹ
Tí a bá kórè àlìkámà tán, a ní láti gbọn hóró àlìkámà yẹn yọ kúró nínú háhá tó bò ó. Bí ohun tó o rí kó jọ látinú ìwádìí rẹ ṣe rí nìyẹn. Kí ó tó ṣeé lò, o ní láti yọ ohun tó wúlò kúrò lára èyí tí kò ní láárí.
Bí ó bá jẹ́ pé inú ọ̀rọ̀ kan tó o máa sọ lo ti fẹ́ lo ìsọfúnni náà, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ kókó tí mo ń ronú láti lò yìí kó ipá kankan tó ní láárí nínú ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ? Tàbí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsọfúnni tó dára ni, ṣé kò ní mú ọkàn ẹni kúrò lórí kókó tó yẹ kí ọ̀rọ̀ mi dá lé?’ Bí o bá ń rò ó pé o fẹ́ lo ìsọfúnni nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ tàbí pé o fẹ́ mú ìsọfúnni látinú àwọn ẹ̀ka sáyẹ́ǹsì tàbí ti ìṣègùn, tó jẹ́ pé ó máa ń yí padà látìgbàdégbà, rí i dájú pé ìsọfúnni yẹn bóde mu. Sì tún mọ̀ dájú pé, àtúnṣe lè ti bá àwọn kókó ọ̀rọ̀ kan tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa tó ti pẹ́ díẹ̀ sẹ́yìn, nítorí náà, ṣàyẹ̀wò ohun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ jáde láìpẹ́ lórí kókó ẹ̀kọ́ yẹn.
Ó ṣe pàtàkì pé kí o kíyè sára gidigidi bí o bá yàn láti lo ìsọfúnni látinú ìwé àwọn èèyàn ayé. Má ṣe gbàgbé pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni òtítọ́. (Jòh. 17:17) Ipò pàtàkì ni Jésù wà nínú ìmúṣẹ ète Ọlọ́run. Nítorí náà, Kólósè 2:3 sọ pé: “Inú rẹ̀ ni a rọra fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ti ìmọ̀ pa mọ́ sí.” Ìyẹn ni kó o fi máa díwọ̀n àbájáde ìwádìí rẹ. Nípa ti lílo ìwádìí àwọn ẹni ayé, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ àsọdùn, ìméfò, tàbí àìní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye wà nínú ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé ẹ̀mí ìmọtara ẹni nìkan ló sún wọn kọ ọ́ ni, tàbí torí kí wọ́n ṣáà ti rí nǹkan tà? Ǹjẹ́ àwọn ìwé yòókù tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ gbà pẹ̀lú rẹ̀? Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ǹjẹ́ ó bá òtítọ́ Bíbélì mu?’
Òwe 2:1-5 fún wa níṣìírí pé kí a wá ìmọ̀, òye, àti ìfòyemọ̀ bí ẹní wá ‘fàdákà, àti bí ẹní wá àwọn ìṣúra fífarasin.’ Ìyẹn túmọ̀ sí pé èèyàn á ṣakitiyan, á sì jèrè rẹpẹtẹ. Ìwádìí ṣíṣe gba ìsapá, àmọ́ bí o bá ń ṣe é yóò mú kí o lè mọ èrò Ọlọ́run lórí àwọn nǹkan, kí o lè ṣàtúnṣe sí àwọn èrò òdì, kí o sì lè di òtítọ́ mú ṣinṣin. Yóò tún jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kún fún ẹ̀kọ́ kí ó sì tani jí, tí yóò mú kí wọ́n dùn mọ́ ọ láti sọ, kí wọ̀n sì wuni láti gbọ́.