Bí A Ṣe Lè Ṣètò Àkójọ-Ìwé Ti Ìṣàkóso Ọlọrun
SHEREZADE, ọmọdébìnrin kékeré kan tí ó lóye tí ó sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Spania, jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin nígbà tí olùkọ́ rẹ̀ sọ fún kíláàsì pé wọn yóò kún àwọn àwòrán “Bàbá Kérésìmesì.” Ní kíámọ́sá, Sherezade sọ pé kí a yọ̀ọ̀da òun. Ó ṣàlàyé pé ẹ̀rí-ọkàn òun kí yóò yọ̀ọ̀da fún òun láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Bí ìkọ̀jálẹ̀ yìí ti yà á lẹ́nu, olùkọ́ náà sọ fún un pé ṣe ni ó wulẹ̀ dàbí kíkun àwòrán ọmọlangidi kan àti pé kò sí ohun tí ó burú nínú ìyẹn. Sherezade fèsì pé: “Bí ó bá jẹ́ pé ọmọlangidi kan lásán ni, èmi yóò kúkú yàn láti ya ọmọlangidi kan fúnraami bí ẹ bá gbà bẹ́ẹ̀.”
Ní àkókò mìíràn a sọ fún kíláàsì náà láti kun àsíá orílẹ̀-èdè. Lẹ́ẹ̀kan síi Sherezade béèrè bí ohun bá lè ṣe ohun mìíràn tí ó yàtọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àlàyé, ó sọ ìtàn Ṣadraki, Meṣaki, àti Abednego fún olùkọ́ náà.—Danieli 3:1-28.
Láìpẹ́ lẹ́yìn náà olùkọ́ náà késí ìyá Sherezade lórí tẹlifóònù láti sọ fún un nípa ìyàlẹ́nu tí ó ní. Ó wí pé: “Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọmọbìnrin rẹ ti ń sọ fún mi nípa ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀. Ìwọ ha lè fojú-inú wo ìyẹn bí? Ọmọdébìnrin kan ní iye ọjọ́-orí yẹn tí ń ṣàlàyé fún mi nípa ìdí ti ẹ̀rí-ọkàn òun fi ń da òun láàmú! Ṣe ó ríi, èmi kò faramọ́ ohun tí o fi ń kọ́ ọ, ṣùgbọ́n mo mú un dá ọ́ lójú pé o ti ń kẹ́sẹjárí. Mo sì fẹ́ kí o mọ̀ pé mo gbóṣùbà fún ọmọbìnrin rẹ.”
Báwo ni ọmọdébìnrin ọlọ́dún-mẹ́rin ṣe lè jèrè ẹ̀rí-ọkàn kan tí a fi Bibeli kọ́? Ìyá rẹ̀, Marina, ṣàlàyé pé Sherezade ní àkójọ-ìwé tirẹ̀ nínú iyàrá tirẹ̀. Àkójọ-ìwé náà ni ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà tirẹ̀ nínú, tí ó ti fa ìlà sí nídìí, ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ tirẹ̀ fún wíwàásù, àti gbogbo ìtẹ̀jáde Watchtower Society tí a ti mújáde láti ìgbà tí a ti bí i. Ohun àyànláàyò jùlọ tí ó wà nínú ibi àkójọ-ìwé rẹ̀ ni téèpù àgbohùnsí ti Iwe Itan Bibeli Mi, tí ó máa ń tẹ́tísí ní alaalẹ́ bí ó ti ń fojú bá a nìṣó nínú ẹ̀dà tirẹ̀. Ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bibeli yìí ni ó ti mú kí ó ṣeéṣe fún un láti ṣe àwọn ìpinnu tí a mẹ́nukàn lókè.
Àkójọ-ìwé ti ìṣàkóso Ọlọrun tí ó wà létòlétò dáradára ha lè ran ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ bí? Èéṣe ti ibi àkójọ-ìwé kan nínú ilé fi pọndandan?
“Àkójọ-Ìwé kan Kìí Ṣe Ọ̀ṣọ́ Àfitolé”
Henry Ward Beecher sọ pé, “Àkójọ-ìwé kan kìí ṣe ọ̀ṣọ́ àfitolé, bíkòṣe ọ̀kan lára àwọn ohun kòṣeémánìí nínú ìgbésí-ayé.” Láìsí iyèméjì, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa ni a ní ọ̀kan lára “àwọn ohun kòṣeémánìí nínú ìgbésí-ayé” wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má mọ̀. Báwo ni ó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Nítorí pé bí gbogbo ohun tí a ní kò bá ju Bibeli lọ, a ti ní oríṣi àkójọ-ìwé kan.
Níti tòótọ́ ni Bibeli jẹ́ àkójọ-ìwé ti ìṣàkóso Ọlọrun tí ó dára jùlọ. Ní ọ̀rúndún kẹrin, Jerome hùmọ̀ àpólà-ọ̀rọ̀ Latin náà Bibliotheca Divina (Àkójọ-Ìwé Àtọ̀runwá) láti ṣàpèjúwe gbogbo àkópọ̀ àwọn ìwé onímìísí tí a ń pè ní Bibeli. Jehofa pèsè àkójọ-ìwé mímọ́-ọlọ́wọ̀ yìí fún wa láti fún wa ní ìrànlọ́wọ́, ìtọ́ni, àti ìtọ́sọ́nà gbígbéṣẹ́. Ó jẹ́ ohun kan tí a kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ mú. Wíwulẹ̀ ní odidi Bibeli lọ́wọ́ túmọ̀sí pé a ní àkójọ-ìwé kan tí ó gbòòrò ju èyí tí ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní ní àwọn ìgbà àtijọ́.
Nígbà tí ó jẹ́ pé kìkì àwọn ìwé-àfọwọ́kọ gbígbówólórí ni ó ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ìwọ̀nba àwọn ilé àdáni, bí ó bá wà rárá, ni a ti lè rí odidi Bibeli. Nígbà tí Paulu fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ nígbà ìfisẹ́wọ̀n rẹ̀ tí ó gbẹ̀yìn ní Romu, ó níláti sọ pé kí Timoteu kó àwọn àkájọ-ìwé díẹ̀ wá fún òun láti Asia Minor—bóyá ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ apákan àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. (2 Timoteu 4:13) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn sinagọgu máa ń ní ìkójọpọ̀ àwọn àkájọ-ìwé, Jesu Kristi àti aposteli Paulu sì ló àǹfààní àwọn àkójọ-ìwé wọ̀nyí nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn. (Luku 4:15-17; Iṣe 17:1-3) A láyọ̀ pé, Ìwé Mímọ́ ti túbọ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó nísinsìnyí ju bí ó ti rí ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní lọ.
Ọpẹ́lọpẹ́ ìhùmọ̀ ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, lónìí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun—ohun yòówù kí èdè wọn jẹ́—lè rí odidi Bibeli rà ní iye owó tí ó mọníwọ̀n. Àwa pẹ̀lú ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ti fífikún “àkójọ-ìwé” mímọ́-ọlọ́wọ̀ yìí. Fún ohun tí ó ti ju ọ̀rúndún kan lọ báyìí, “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” náà ti ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu.—Matteu 24:45-47, NW.
Ṣùgbọ́n kò dàbí ẹni pé àwa yóò lo àǹfààní ṣíṣeyebíye yìí ní kíkún bí a kò bá ṣètò àkójọ-ìwé ti ìṣàkóso Ọlọrun kan tí ó jẹ́ tiwa. Báwo ni a ṣe lè ṣe ìyẹn? Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́, gẹ́gẹ́ bi a ti lè retí, ni láti ní àwọn ìwé tí ó yẹ kí ó wà nínú irúfẹ́ àkójọ-ìwé bẹ́ẹ̀. Ó yẹ gidigidi fún ìsapá náà, níwọ̀n bí yóò ti mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti ní àwọn ìsọfúnni pàtó tí a nílò lárọ̀ọ́wọ́tó láti bójútó àwọn ìṣòro kí a sì dáhùn àwọn ìbéèrè Bibeli.
Àwọn Ìwé Wo Ni Mo Nílò?
Ó ha ti ṣe kàyéfì rí nípa bí o ṣe lè yanjú ìṣòro ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nínú ìgbéyàwó rẹ tàbí bí o ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti sọ pé bẹ́ẹ̀kọ́ sí lílo oògùn ní ìlòkulò? Báwo ni o ṣe lè ran ọ̀rẹ́ kan tí ń jìyà ìsoríkọ́ lọ́wọ́? O ha lè ṣàlàyé ẹ̀rí tí a ní pé Ọlọrun wà àti ìdí tí ó fi fàyègba ìwà-burúkú ní kedere bí? Kí ni ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò inú ìwé Ìṣípayá orí 17 dúró fún?
Ìwọ̀nyí àti àìníye àwọn ìbéèrè mìíràn ni o lè dáhùn bí o bá ní àkójọ-ìwé ti ìṣàkóso Ọlọrun tí ó péye tó. Watchtower Society ti tẹ àwọn ìwé, àwọn ìwé-pẹlẹbẹ, àti àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ìwé ìròyìn tí ó jíròrò ẹ̀kúnwọ́ àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́. Síwájú síi, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí ń jíròrò àwọn ọ̀ràn ìdílé, wọ́n ń gbé ìgbàgbọ́ wa ró nínú Ọlọrun àti Bibeli, wọ́n ń mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti mú òye ìwàásù wa sunwọ̀n síi, wọ́n sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli.
Ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn ìtẹ̀jáde náà ti Society tẹ̀ ní 20 ọdún tí ó ti kọjá sẹ́yìn ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wà sínú òtítọ́ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, yóò jẹ́ ohun tí ó yẹ fún ọ láti ra gbogbo irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ tí ó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè rẹ. Ó lè jẹ́ pé àwọn ìdìpọ̀ Ilé-Ìṣọ́nà ti àwọn ọdún tí ó ti kọjá wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè rẹ. Àwọn ìwé ìtọ́kasí títayọ, bí Insight on the Scriptures àti Comprehensive Concordance, ni a tún ti tẹ̀ jáde ní onírúurú èdè. Bí ó ti wù kí ó rí, kìkì ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni níní àwọn ìwé wọ̀nyí jẹ́.
Ṣètò Àkójọ-Ìwé Rẹ!
Ohun kan ni ó jẹ́ láti mọ̀ pé o ní àwọn ìwé náà, ṣùgbọ́n ohun mìíràn ni pé kí o rí èyí tí o nílò. Bí a bá níláti fi ọ̀pọ̀ àkókò ṣòfò ní wíwá àwọn ìwé ìtọ́kasí tí a nílò kiri, ṣíṣeéṣe náà wà pé kí a pàdánù ọkàn-ìfẹ́ tí a ní nínú ọ̀ràn náà. Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, bí a bá ṣètò àwọn ìwé wa dáradára, sí ibìkan tí ó rọrùn, àwa yóò ní ìtẹ̀sí tí ó túbọ̀ pọ̀ síi láti ṣe ìwádìí jinlẹ̀ fúnraawa.
Bí ó bá ṣeéṣe, ó máa ń ṣèrànwọ́ pé kí a kó gbogbo ìwé ìṣàkóso Ọlọrun sí ojú kan náà. A lè ṣe àwọn àpótí ìkówèésí, ní ọ̀pọ̀ ìgbà pẹ̀lú owó pọ́ọ́kú, bí a kò bá lè ra èyí tí wọ́n ń ṣe tà, kò sì pọndandan kí wọ́n gba àyè tí ó pọ̀ jù. Mímú kí àkójọ-ìwé wà ní ibi tí ọwọ́ ti lè tètè tó o tún ṣe pàtàkì. Àwọn ìwé tí a kó pamọ́ sábẹ́ àjà wulẹ̀ máa ń kún fún eruku ni.
Ìgbésẹ̀ tí ó tẹ̀lé e ni láti ṣètò àwọn ìwé náà. Ìwọ̀nba àkókò kúkúrú tí a bá lò láti ṣètò àwọn ìwé lọ́nà tí ó bọ́gbọ́nmu máa ń mú èrè wá.
Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn tí ó pọ̀ jùlọ nínú ìdílé rẹ kìí ṣe Ẹlẹ́rìí Jehofa ńkọ́? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má ṣeéṣe fún ọ láti ṣètò àkójọ-ìwé gẹ́gẹ́ bí ìwọ yóò ti fẹ́ láti ṣe, nínú yàrá tìrẹ o lè ní ibi ìkówèésí kan nínú èyí tí ó kérétán àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbékarí Ìwé Mímọ́ wà.
Àkójọ-Ìwé kan Lè Ṣèrànwọ́ Láti Gbé Ipò Tẹ̀mí Ró
Lẹ́yìn tí a bá ti ṣètò àwọn ìwé wa tán, a nílò ìṣètò kan láti ràn wá lọ́wọ́ láti wá ìsọfúnni rí. Agbára ìrántí wa lè kùnà, àwa fúnraawa sì lè ṣàìmọ ohun tí ó wà nínú gbogbo ìwé ti ń bẹ lára àkójọ-ìwé ti ìṣàkóso Ọlọrun wa. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ìsọfúnni tí ń bẹ́ nínú àkójọ-ìwé náà ni ọwọ́ lè tètè tó. Bí ó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè wa, ìwé Watch Tower Publications Index lè mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti wá àwọn ìsọfúnni pàtó rí lórí èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo kókó ẹ̀kọ́ ní àárín àkókò kúkúrú.
Julián, tí ó ti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti alàgbà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ṣàlàyé pé Index náà ṣeyebíye gidigidi fún kíkọ́ ọmọkùnrin òun tí ó kéré jùlọ láti dákẹ́kọ̀ọ́. “Jairo, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún méje, ti ilé-ẹ̀kọ́ dé láìpẹ́ yìí ó sì bi mí pé, ‘Dádì, kí ni Society ti sọ nípa àwọn ẹranko dinosaur?’ Ní tààràtà ni a lọ sínú Index tí a sì wo ọ̀rọ̀ náà ‘dinosaurs.’ A fẹ́rẹ̀ má tíì ṣí i nígbà tí a rí ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ Jí! kan tí ó sọ̀rọ̀ nípa kókó-ẹ̀kọ́ náà. [August 8, 1990] Ní ọjọ́ yẹn kan náà, Jairo bẹ̀rẹ̀ síí kà á. Ó ti mọ̀ pé àkójọ-ìwé wa ní àwọn ìsọfúnni wíwúlò lórí èyí tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo kókó ẹ̀kọ́. Ní tèmi, ó dá mi lójú pé nígbà tí àwọn ọmọ wa bá kọ́ láti lo àkójọ-ìwé ti ìṣàkóso Ọlọrun lọ́nà rere, ó máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí. Wọ́n á kọ́ láti ronú, àti síwájú síi, wọ́n a rí i pé ìdákẹ́kọ̀ọ́ lè gbádùnmọ́ni.”
Fausto, bàbá Sherezade tí a mẹ́nukàn ní ìbẹ̀rẹ̀, gbàgbọ́ pé kíkọ́ àwọn ọmọ láti lo àkójọ-ìwé ti ìṣàkóso Ọlọrun ni a níláti bẹ̀rẹ̀ bí ó bá ti lè ṣeéṣe kí ó yá tó. Ó ṣàlàyé pé, “A ti ń fihàn Sherezade, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà nísinsìnyí, bí ó ṣe lè lo Index. Níwọ̀n bí ìrètí nípa Paradise ilẹ̀-ayé ti fà á mọ́ra, a bẹ̀rẹ̀ síí fi ọ̀rọ̀ náà ‘paradise’ hàn án nínú Index tí a sì bẹ̀rẹ̀ síí wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà nínú Ilé-Ìṣọ́nà tí a mẹ́nukàn. Lọ́pọ̀ ìgbà a wulẹ̀ ń fi àwọn àwòrán náà hàn án. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní ọ̀nà tí a gbé e gbà yìí ó kẹ́kọ̀ọ́ pé Index ni kọ́kọ́rọ́ náà sí wíwá ìsọfúnni rí láti inú àkójọ-ìwé wa ní ilé. A mọ̀ pé ó ti lóye kókó náà nígbà tí ó dárí dé láti ilé-ẹ̀kọ́ ní ọjọ́ kan pẹ̀lú ìbéèrè nípa ayẹyẹ Easter. Ó béèrè lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ pé, ‘Èéṣe tí a kò kúkú wò ó nínú Index?’”
Ohun yòówù kí ọjọ́ orí wa jẹ́, Bibeli fún wa níṣìírí láti “wádìí ohun gbogbo dájú; . . . di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.” (1 Tessalonika 5:21, NW) Èyí béèrè pé kí a ṣàyẹ̀wò ohun ti Ìwé Mímọ́ sọ. (Iṣe 17:11) Bí a bá ni àkójọ-ìwé kan tí a ṣètò dáradára, irú ìwádìí jinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ohun tí ó gbádùnmọ́ni. Ní ìgbà kọ̀ọ̀kan tí a bá ti lò àkójọ-ìwé wa lọ́nà yíyọrísírere láti múra ọ̀rọ̀-àsọyé kan sílẹ̀, láti wá ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ kan rí lórí ọ̀nà tí a lè gbà bójútó ìṣòro kan, tàbí láti wo àwọn ìsọfúnni fífanimọ́ra, yóò tẹ ìníyelórí ìgbéṣẹ́ àkójọ-ìwé wa mọ́ wa lọ́kàn.
Àwọn òbí Sherezade ṣàlàyé pé: “Nínú agboolé Kristian kan, ó dájú pé àkójọ-ìwé kan kìí ṣe ọ̀ṣọ́ àfitolé!”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]
BÁWO NI O ṢE LÈ ṢÈTÒ ÀWỌN ÌWÉ RẸ?
Kò sí ìlànà kan tí kò ṣeé yípadà lórí bí ó ṣe yẹ kí o ṣètò àwọn ìwé rẹ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìṣètò bíbọ́gbọ́nmu tí ó tẹ̀lé e yìí jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà kan tí o lè gbà ṣètò àwọn ìwé rẹ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ń bẹ nínú wọn.
1. Àwọn ìwé tí wọ́n ní kúlẹ̀kúlẹ̀ ìjíròrò ẹlẹ́sẹẹsẹ ti àwọn apákan nínu Bibeli
(Àpẹẹrẹ: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, Revelation—Its Grand Climax At Hand!, “The Nations Shall Know That I Am Jehovah”—How?, “Ifẹ Tirẹ Ni Ki A Ṣe Li Aiye”)
2. Àwọn ìwé tí wọ́n jẹmọ́ ìgbésí-ayé ìdílé
(Àpẹẹrẹ: Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ; Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Iwe Itan Bibeli Mi)
3. Bibeli àti àwọn ìwé ìtọ́kasí
(Àpẹẹrẹ: New World Translation of the Holy Scriptures—With References, àwọn Bibeli mìíràn, àwọn Watch Tower Publications Index, Comprehensive Concordance, Insight on the Scriptures, The Kingdom Interlinear Translation of the Greek Scriptures, ìwé atúmọ̀-èdè tí ó dára)
4. Àwọn ìwé tí a ń lò lọ́wọ́ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun
5. Àwọn kásẹ́ẹ̀tì tí a gbohùnsí àti àwọn fídíò
6. Àwọn ìdìpọ̀ Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!
7. Ọ̀rọ̀-ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa
(Àpẹẹrẹ: Àwọn Yearbook of Jehovah’s Witnesses, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom)
8. Àwọn ìwé àti ìwé-pẹlẹbẹ tí a ń lò déédéé nínú iṣẹ́-òjísẹ́ wa
(Àpẹẹrẹ: Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, Reasoning From the Scriptures, Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?, Mankind’s Search for God, Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Sherezade ti di akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli dáradára báyìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Bí ó tilẹ̀ kéré lọ́jọ́ orí, ọmọdékùnrin yìí ń lo àkójọ-ìwé ti ìṣàkóso Ọlọrun