Máa Lo Àwọ́n Ìtẹ̀jáde Tí Ọjọ́ Wọn Ti Pẹ́ Tí Ìjọ Ní Lọ́wọ́
Ọ̀pọ̀ ìjọ ló ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìtẹ̀jáde tí ọjọ́ wọn ti pẹ́. O lè gbà lára wọn kó o sì fi wọ́n sí ibi tó ò ń kó àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run sí. Ó sì ṣeé ṣe kó o ní àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe sórí àwo CD-ROM, ìyẹn Watchtower Library. Àmọ́, àǹfààní wà nínú kéèyàn ní ẹ̀dà àwọn ìwé náà lọ́wọ́. Ǹjẹ́ ò ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí ẹni náà sì ń tẹ̀ síwájú? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, fún un ní ìṣírí láti gba àwọn ìwé tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ yìí fún ìlò ara rẹ̀. Kí alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run rí i dájú pé àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́ wà ní ibi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn ìwé wọ̀nyí ṣì wúlò gan-an. Ó dára gan-an pé ká máa lo àwọn ìtẹ̀jáde yìí dípò tí a ó fi fi wọ́n sílẹ̀ lórí káńtà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba!