Ìṣètò Tuntun fún Àwọn Ibi Ìkówèésí Tó Wà Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba
Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún báyìí, àwọn ìjọ jákèjádò ayé ti ń jàǹfààní látinú lílo àwọn ibi ìkówèésí tó wà nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, èyí tá a mọ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ sí ibi ìkówèésí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Láwọn àkókò tó ti kọjá, a ronú pé ó pọn dandan kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ibi ìkówèésí tirẹ̀. Àmọ́, ní báyìí tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba ni àwọn ìjọ tó ń lò wọ́n ti ju ẹyọ kan lọ, tí díẹ̀ lára wọn sì jẹ́ àwọn ìjọ tó ń sọ èdè òkèèrè, ó jọ pé ohun tó máa dára jù lọ ni pé kí a ní ibi ìkówèésí kan ṣoṣo péré nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ̀ọ̀kan fún àwọn ìjọ tó ń sọ èdè kan náà, tí gbogbo ìwé tó yẹ yóò sì wà nínú rẹ̀. Láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bá ní àwọn gbọ̀ngàn ìpàdé tó ju ẹyọ kan lọ, kí gbọ̀ngàn kọ̀ọ̀kan ní ibi ìkówèésí kan fún àwùjọ kọ̀ọ̀kan tó ń sọ èdè kan náà tó ń pàdé níbẹ̀.
A ronú pé ìṣètò yìí yóò ṣèrànwọ́ láti dín àyè àti ìnáwó kù. Ìyẹn nìkan kọ́ o, dída ibi ìkówèésí ìjọ méjì tàbí mẹ́ta pọ̀ yóò túbọ̀ mú kí ó ṣeé ṣe pé kí àwọn ibi ìkówèésí wa túbọ̀ ní àwọn ìwé tó yẹ nínú. Bí a bá dà wọ́n pọ̀, a lè kó àwọn ẹ̀dà ìwé tó ṣẹ́ kù pa mọ́ kí a sì lò wọ́n lẹ́yìn náà nígbà tí a bá kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun. Bí Gbọ̀ngàn Ìjọba yín bá ní ètò ìsọfúnni orí kọ̀ǹpútà tó ń jẹ́ Watchtower Library on CD-ROM [Àkójọ Ìtẹ̀jáde Society Tá A Ṣe Sórí Ike Pẹlẹbẹ Tá À Ń Fi Kọ̀ǹpútà Lò], àwọn kan yóò jàǹfààní gan-an nínú lílo irinṣẹ́ yìí.
Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ̀ọ̀kan, arákùnrin kan yóò máa bójú tó ibi ìkówèésí náà. Ó dára kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ó ní láti máa fi àwọn ìtẹ̀jáde tó bá yẹ kún àwọn tó ti wà níbẹ̀ nígbà gbogbo, yóò sì máa sàmì sínú ìwé kọ̀ọ̀kan ní nigín-nigín láti fi hàn pé ibi ìkówèésí inú Gbọ̀ngàn Ìjọba ló wà fún. Ó kéré tán lọ́dún kan, ó ní láti máa ṣàyẹ̀wò àwọn ìtẹ̀jáde inú ibi ìkówèésí náà láti rí i pé wọ́n pé pérépéré, kó sì máa rí i dájú pé wọ́n wà nípò tó bójú mu. Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ mú àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú àwọn ibi ìkówèésí yìí jáde kúrò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Gbogbo àwọn tó ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ ló ń fi ìmọrírì hàn gan-an fún ibi ìkówèésí inú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ǹjẹ́ kí a máa fi hàn pé àwa gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan mọrírì ìṣètò yìí nípa fífi ọwọ́ pàtàkì mú un àti lílò ó láti fi ṣe àwárí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.”—Òwe 2:5.