ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/97 ojú ìwé 7
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Ibi Ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
  • Bí A Ṣe Lè Ṣètò Àkójọ-Ìwé Ti Ìṣàkóso Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Máa Lo Àwọ́n Ìtẹ̀jáde Tí Ọjọ́ Wọn Ti Pẹ́ Tí Ìjọ Ní Lọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Ìṣètò Tuntun fún Àwọn Ibi Ìkówèésí Tó Wà Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 4/97 ojú ìwé 7

Àpótí Ìbéèrè

◼ Àwọn ìtẹ̀jáde wo ni ó yẹ kí a kó sí ibi àkójọ ìwé kíkà ti Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run?

A ti pèsè ọ̀pọ̀ yanturu ìtẹ̀jáde fún àǹfààní àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ akéde kò ti ní gbogbo ìwọ̀nyí fúnra wọn, ibi àkójọ ìwé kíkà ti Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ń pèsè ọ̀nà fún ìṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ì bá tí sí lárọ̀ọ́wọ́tó. Nípa báyìí, ó yẹ kí a kó onírúurú ìtumọ̀ Bíbélì, àwọn ìtẹ̀jáde Society ti lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn ẹ̀dà Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ìdìpọ̀ Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, àti àwọn ìwé atọ́ka náà, Watch Tower Publications Index, sí ibẹ̀. Ní àfikún sí i, ó yẹ kí a fi ìwé atúmọ̀ èdè ti òde òní tí ó dára kún un. Bí wọ́n bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó, tí agbára bá sì gbé e, àwọn ìwé gbédègbẹ́yọ̀, ìwé àwòrán ilẹ̀ (atlas), tàbí ìwé ìtọ́ka lórí gírámà àti ìtàn lè wúlò. Ṣùgbọ́n, àníyàn wa pàtàkì jù lọ gbọ́dọ̀ jẹ́ nípa àwọn ìtẹ̀jáde tí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” pèsè.—Mát. 24:45.

Nínú àwọn ọ̀ràn kan, a ròyìn pé àwọn ìwé tí a lè gbé ìbéèrè dìde sí ni a ti kó sí ibi àkójọ ìwé kíkà ti Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Kì yóò bójú mu láti fi àwọn ìwé ìtàn àròsọ, àwọn àlàyé lórí Bíbélì tí ń tẹnu mọ́ ṣíṣe lámèyítọ́ Bíbélì, tàbí àwọn ìwé ọgbọ́n èrò orí tàbí ìbẹ́mìílò kún un. Ibi àkójọ ìwé kíkà ti Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ní kìkì àwọn ìwé tí yóò jẹ́ kí àwọn tí ń lò ó máa ní ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí tí ń bá a nìṣó.—1 Tím. 4:15.

Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ni ó ni ẹrù iṣẹ́ bíbójútó ibi àkójọ ìwé kíkà náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè yan arákùnrin mìíràn láti ràn án lọ́wọ́ láti bójú tó o. Ó gbọ́dọ̀ rí sí i pé ibi àkójọ ìwé kíkà náà ni a mú bágbà mu nípa fífi àwọn ìtẹ̀jáde tuntun kún un gbàrà tí wọ́n bá ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó. A gbọ́dọ̀ kọ orúkọ ìjọ tí ó ni ìwé kọ̀ọ̀kan sí inú ẹ̀yìn ìwé náà. Lọ́dọọdún, a gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé náà láti rí i bóyá èyíkéyìí nílò àtúnṣe tàbí nílò fífi òmíràn rọ́pò.

Olúkúlùkù ènìyàn lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti bójú tó ibi àkójọ ìwé kíkà náà. A gbọ́dọ̀ lo ìṣọ́ra nínú ọ̀nà tí a ń gbà lo ìwé náà. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ọmọdé fi wọ́n ṣeré, ẹnikẹ́ni kò sì gbọ́dọ̀ kọ ohunkóhun sínú wọn. A lè kọ ìsọfúnni kékeré kan síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí pé a kò gbọ́dọ̀ mú àwọn ìwé náà kúrò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Bí a ti ń dá àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀ láti ìgbà dé ìgbà, ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ ibi àkójọ ìwé kíkà máà tóbi. Àwọn akéde kan tí wọ́n ní àwọn ìtẹ̀jáde wa tí ó ti pẹ́ lọ́wọ́ lè ronú nípa fífi wọ́n ta ìjọ lọ́rẹ. Àwọn alàgbà lè fẹ́ láti béèrè fún àwọn ìdìpọ̀ Ilé Ìṣọ́ tí Society tún tẹ̀. Ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí, ibi àkójọ ìwé kíkà ti Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run yóò wúlò gidigidi ní ríran gbogbo ènìyàn lọ́wọ́ láti ṣàwárí àwọn ìṣúra fífara sin ti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ń fúnni ní ìmọ̀, ọgbọ́n, àti òye.—Òwe 2:4-6.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́