Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní April àti May: Gbogbo èdè—àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́. Àwọn ìwé ìròyìn ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún ọdún kan, ₦280. Ẹlẹ́ẹ̀kan lóṣù fún ọdún kan tàbí ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún oṣù mẹ́fà, ₦140. Fún iṣẹ́ ìsìn àárín ọ̀sẹ̀ àti ní àwọn ìpínlẹ̀ ti a sábà máa ń kárí, a lè lo ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? June: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Pọkàn pọ̀ sórí bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. July àti August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tí ó tẹ̀ lé e yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Àwọn tí ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ gbọ́dọ̀ fi gbogbo àsansílẹ̀ owó tuntun àti ìsọdituntun fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, títí kan àsansílẹ̀ owó tiwọn fúnra wọn, ránṣẹ́ nípasẹ̀ ìjọ.
◼ Ní April 26 àti May 31, a óò ti ilé Bẹ́tẹ́lì pa. Nítorí náà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe wá ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe wá ra ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn déètì wọ̀nyí.
◼ Ìtẹ̀jáde tuntun tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó:
Kọrin Ìyìn sí Jehofah (Kékeré)—Ísókó