ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/97 ojú ìwé 5-6
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 4/97 ojú ìwé 5-6

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun

Àtúnyẹ̀wò pípa ìwé dé lórí àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún àwọn ọ̀sẹ̀ January 6 sí April 21, 1997. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.

[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bibeli nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ḿbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́ka tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]

Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

1. Àwọn Kristẹni ní ìdí rere láti yà sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé. (1 Jòh. 5:19) [5, kl-YR ojú ìwé 60 ìpínrọ̀ 18]

2. Kò sí ọlá àṣẹ kankan lórí ilẹ̀ ayé tí ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, títí di ìgbà tí Jésù kú, tí ó sì pèsè ìràpadà. [8, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 4/15 ojú ìwé 29.]

3. Jèhófà lo wòlíì Sekaráyà àti Hágáì láti sọ ìtara àwọn ènìyàn Rẹ̀ jí fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì. [1, w89-YR 6/15 ojú ìwé 30]

4. Ìbatisí jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú ìgbàlà. [15, uw-YR ojú ìwé 100 ìpínrọ̀ 12]

5. Gbogbo ènìyàn ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, níwọ̀n bí Ádámù àti Éfà ti lóyún gbogbo àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀? [4, kl-YR ojú ìwé 58 ìpínrọ̀ 13]

6. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn aláìpé ni ìràpadà bò mọ́lẹ̀. [10, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 12/15 ojú ìwé 29.]

7. Àwọn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà Bábílónì Ńlá lójú méjèèjì àti àwọn aṣáájú ìsìn wọn wà lára “àwọn ewúrẹ́” tí a mẹ́nu kàn nínú Mátíù 25:31-46, tí yóò jìyà ìkékúrò àìnípẹ̀kun. [16, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 10/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 13 sí 15.]

8. Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù, tí a kọ sílẹ̀ nínú Mátíù 23:33, fi hàn pé àwọn akọ̀wé àti Farisí, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, jẹ́ apá kan irú ọmọ Ejò náà. [15, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 6/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 11.]

9. Dídárí ji àwọn ẹlòmíràn ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún Ọlọ́run láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. [7, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w94-YR 9/15 ojú ìwé 7.]

10. Ìbatisí Jésù sínú ikú bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa, kò sì parí títí di ìgbà tí ó kú, tí a sì jí i dìde. [13, uw-YR ojú ìwé 97 ìpínrọ̀ 6]

Dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí:

11. Ní èrò wo ni a kì yóò fi lè pa Ìjọba Jésù run? (Dán. 7:14) [8, uw-YR ojú ìwé 86 ìpínrọ̀ 15]

12. Àwọn ipa iṣẹ́ méjì tí Jésù Kristi mú ṣẹ wo ni a ṣàpèjúwe nínú Sekaráyà 6:12, 13? [3, w89-YR 6/15 ojú ìwé 31]

13. Dípò ṣíṣe lámèyítọ́ àwọn tí a rò pé wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba, kí ni ó yẹ kí a ṣe lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? (Gál. 6:4) [11, uw-YR ojú ìwé 93 ìpínrọ̀ 13]

14. Kí ni ṣíṣẹ́ tí Sekaráyà ṣẹ́ ọ̀pá tí ó pè ní Ẹwà túmọ̀ sí? (Sek. 11:7-11) [3, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 6/15 ojú ìwé 31.]

15. Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn ènìyàn gbà ń jàǹfààní nínú ẹbọ Jésù ní àkókò yí? [10, kl-YR ojú ìwé 68, 69 ìpínrọ̀ 17 sí 19]

16. Ní èrò wo ni “wòlíì Èlíjà” gbà fara hàn ní ọ̀rúndún kìíní, ní ìmúṣẹ Málákì 4:5? [4, w89-YR 7/1 ojú ìwé 30]

17. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè ja Ọlọ́run lólè? (Mál. 3:8) [4, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 4/15 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 15.]

18. Níbo nínú ìwé Mátíù ni a ti rí ìmọ̀ràn yíyè kooro tí Jésù fúnni lórí yíyanjú àwọn ìṣòro líle koko? [13, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 7/15 ojú ìwé 22.]

19. Kí ni “owó dínárì” tí a dárúkọ nínú àkàwé Jésù, tí a kọ sílẹ̀ nínú Mátíù 20:1-16? [14, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo gt-YR 97 ìpínrọ̀ 6.]

20. Dárúkọ ohun méjì tí àyè tí Ọlọ́run fi gba ìwà ibi fẹ̀rí rẹ̀ hàn. [14, 15, kl-YR ojú ìwé 77, 78 ìpínrọ̀ 18 sí 20]

Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tí a nílò láti parí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

21. Ìwé Mátíù inú Bíbélì ni a pè ní _________________________. [5, w89-YR 7/15 ojú ìwé 24]

22. _________________________ kọ́ ni okùnfà ọ̀pọ̀ _________________________ tí ń dààmú _________________________ (Ják. 1:13) [11, kl-YR ojú ìwé 71 ìpínrọ̀ 3]

23. A óò ṣèdájọ́ àwọn òkú tí a tọ́ka sí nínú Ìṣípayá 20:12 ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí wọ́n ṣe _________________________ àjíǹde wọn. Èyí ràn wá lọ́wọ́ láti lóye pé kì í ṣe dandan ni kí àjíǹde wọ́n jẹ àjíǹde _________________________ (Jòh. 5:28, 29) [2, uw-YR ojú ìwé 75 ìpínrọ̀ 12]

24. Bí a kò tilẹ̀ fún Jésù ní orúkọ náà, _________________________ ní ti gidi, ipa iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn mú _________________________ orúkọ náà ṣẹ. (Aísá. 7:14; Mát. 1:22, 23) [5, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w92-YR 1/15 ojú ìwé 22.]

25. “Ẹ̀mí” tí ó fi ara ẹ̀dá ènìyàn sílẹ̀ nígbà ikú ni _________________________ tí ó pilẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Orin Dá. 146:4) [16, kl-YR ojú ìwé 81, 82 ìpínrọ̀ 5, 6]

Mú ìdáhùn tí ó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

26. Ẹ̀rí wà pé Mátíù kọ Ìhìn Rere rẹ̀ ní èdè (Hébérù; Árámáíkì; Gíríìkì) tí ó sì tú u lẹ́yìn náà sí èdè (Hébérù; Árámáíkì; Gíríìkì). [5, w89-YR 7/15 ojú ìwé 24]

27. Èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú (àṣẹ́kù; 144,000) ti wà ní ọ̀run, (àṣẹ́kù; 144,000), tí ó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé, ni ó sì para pọ̀ jẹ́ (Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso; ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú). [6, uw-YR ojú ìwé 80 ìpínrọ̀ 7]

28. Jésù di Mèsáyà nígbà (ìbí; ìbatisí; àjíǹde) rẹ̀, tí ó wáyé ní ọdún (2 ṣááju Sànmánì Tiwa; 29 Sànmánì Tiwa; 33 Sànmánì Tiwa). [9, kl-YR ojú ìwé 65 ìpínrọ̀ 12]

29. Ìbatisí “ní orúkọ Bàbá àti ti Ọmọkùnrin àti ti ẹ̀mí mímọ́” bẹ̀rẹ̀ ní (29 Sànmánì Tiwa; 33 Sànmánì Tiwa; 36 Sànmánì Tiwa). (Mát. 28:19) [14, uw-YR ojú ìwé 98 ìpínrọ̀ 9]

30. Èrè tí Jésù ṣèlérí fún àwọn tí ń gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sínú ilé wọn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú Mátíù 10:41, ni (ìyè àìnípẹ̀kun; ààbò àtọ̀runwá; gbígbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba). [9, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 1/1 ojú ìwé 24.]

So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó tẹ̀ lé e yìí mọ́ àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yí:

Sek. 4:6; Mát. 4:8-10; Mát. 16:19; Fílíp. 1:9-11; Héb. 13:5, 6

31. Ó yẹ kí a lo ìgbésí ayé wa ní ọ̀nà tí ń fi hàn pé a lóye àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù ní tòótọ́. [10, uw-YR ojú ìwé 91 ìpínrọ̀ 9]

32. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tòótọ́ kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú àwọn àlámọ̀rí ìṣèlú ayé yìí. [6, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 5/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 9.]

33. Ìmọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣí ọ̀nà ọ̀run sílẹ̀ fún àwọn Júù, àwọn ará Samáríà, àti àwọn Kèfèrí. [12, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 3/15 ojú ìwé 5.]

34. A ti ṣẹ́gun àtakò kárí ayé sí iṣẹ́ ìwàásù wa, kì í ṣe nípa ìsapá ènìyàn, bí kò ṣe nípasẹ̀ ìdarí àti ààbò Jèhófà. [1, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w94-YR 8/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 4.]

35. Láìka iye owó ọjà tí ń ga sókè àti àìríṣẹ́ṣe tí ó tàn kálẹ̀ sí, Jèhófà yóò rí i dájú pé a ní àwọn ohun tí a nílò ní ti gidi. [9, uw-YR ojú ìwé 89 ìpínrọ̀ 6]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́