Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 25
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 25
Orin 108 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 3 ìpínrọ̀ 1 sí 3, àpótí tó wà lójú ìwé 23 sí 27 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóòbù 33-37 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀. “Máa Lo Àwọ́n Ìtẹ̀jáde Tí Ọjọ́ Wọn Ti Pẹ́ Tí Ìjọ Ní Lọ́wọ́.” Àsọyé. Sọ àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́ fún àwọn ará.
15 min: Ǹjẹ́ Ò Ń Jàǹfààní Nínú Ìwé Ìròyìn Jí!? Ìjíròrò. Ìdí pàtàkì tá a fi ń tẹ ìwé ìròyìn Jí! jádé ni pé kó bàa lè mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú Bíbélì lágbára. A máa ń jíròrò àwọn àkòrí tí ọ̀pọ̀ èèyàn lè nífẹ̀ẹ́ sí, tó fi mọ́ ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn tá a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. (O lè lo àwọn àpilẹ̀kọ yìí tó jáde nínú Jí! April–June 2011, ojú ìwé 3 sí 9 àti ojú ìwé 13 sí 15; Jí! July–September 2010, ojú ìwé 16 sí 18; Jí! October–December 2010, ojú ìwé 12 sí 14, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, láti jẹ́ kí àwọn ará mọ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà níbẹ̀, kó o sì fún wọn ní ìṣírí láti máa kà á.) Ní kí àwọn ará sọ àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní tí wọ́n ti rí kọ́ látinú ìwé ìròyìn Jí!
15 min: Máa Ṣé Àṣàrò Lórí Ohun tí Jèhófà Ti Ṣe. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ January 15, 2011, ojú ìwé 31 àti 32.
Orin 119 and Àdúrà