Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 25, 2011. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ March 7 sí April 25, 2011, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.
1. Ọ̀nà wo ni ‘púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà gbà polongo ara wọn ní Júù’? (Ẹ́sítérì 8:17) [w06 3/1 ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 3]
2. Kí nìdí tí Jèhófà fi gba Sátánì láyè láti wá síwájú rẹ̀? (Jóòbù 1:6; 2:1) [w06 3/15 ojú ìwé 13, ìpínrọ̀ 6]
3. Kí ni Sátánì ní lọ́kàn pẹ̀lú ìbéèrè tó bi Ọlọ́run pé, “Lásán ha ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run bí?” (Jóòbù 1:9) [w94 11/15 ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 6]
4. Báwo ni mímọ̀ tá a bá mọ̀ pé Jèhófà “jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ọkàn-àyà, ó sì le ní agbára” ṣe lè mú ká fọkàn tán an? (Jóòbù 9:4) [w07 5/15 ojú ìwé 25, ìpínrọ̀ 16]
5. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Élífásì sọ pé, èèyàn tí ń mu “àìṣòdodo bí ẹní mu omi” ṣe fi èrò Sátánì hàn? (Jóòbù 15:16) [w10 2/15 ojú ìwé 20, ìpínrọ̀ 1 sí 2]
6. Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ látinú bí Jóòbù ṣe ké jáde, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Jóòbù 19:2? [[w94 10/1 ojú ìwé 32, ìpínrọ̀ 1 sí 5]
7. Kí ló ran Jóòbù lọ́wọ́ tó fi lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́? (Jóòbù 27:5) [w09 4/15 ojú ìwé 6, ìpínrọ̀ 17]
8. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jóòbù nígbà tí àwọn ẹlòmíì bá ṣaláìní ohun kan? (Jóòbù 29:12, 13) [w02 5/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 19; w94 9/15 ojú ìwé 24, ìpínrọ̀ 2]
9. Ọ̀nà wo ni ìmọ̀ràn Élíhù gbà yàtọ̀ sí ti àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta yòókù? (Jóòbù 33:1, 6) [w95 2/15 ojú ìwé 29, ìpínrọ̀ 3]
10. Báwo ni ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà ṣe lè nípa lórí wa? (Jóòbù 37:14) [w06 3/15 ojú ìwé 16, ìpínrọ̀ 4]