Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé?
Lẹ́yìn tó o bá ti kí onílé, fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà kó bàa lè rí àkọlé rẹ̀, kó o wá sọ pé: “Ibi gbogbo kárí ayé la ti ń pín ìwé yìí, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣe pàtàkì. Tiyín rèé.”
Tí ẹ bá fẹ́ fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà sí ẹnu ọ̀nà àwọn tí kò sí nílé, ẹ fi síbi tí àwọn tó ń kọjá lọ kò ti ní rí, ẹ má sì ká a lọ́nà tí kò bójú mu.
Tí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa tàbí tó fẹ́ kó o bá òun jíròrò, o lè ní kó sọ èrò rẹ̀ lórí ìbéèrè tó wà níwájú ìwé àṣàrò kúkúrú náà tó máa jẹ́ kó sọ èyí tó yàn nínú ìdáhùn tó wà níbẹ̀. Ṣí ìwé àṣàrò kúkúrú náà kó o sì fi ohun tí Sáàmù 119:144, 160 sọ hàn-án. Sọ fún un pé ìwé àṣàrò kúkúrú náà ní àwọn ìsọfúnni nípa Ìkànnì kan tó máa jẹ́ kó rí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn nínú Bíbélì. O lè fi àpẹẹrẹ kan hàn-án nínú fídíò náà, Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Kó o tó fi ibẹ̀ sílẹ̀, fi àwọn ìbéèrè mẹ́ta tó wà lẹ́yìn ìwé àṣàrò kúkúrú náà hàn-án, kó o wá béèrè pé, èwo lára àwọn ìbéèrè náà ló ń jẹ ẹ́ lọ́kàn jù lọ. Sọ fún onílé pé wàá pa dà wá fi bó ṣe máa rí ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè náà hàn-án lórí ìkànnì jw.org. Tó o bá pa dà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti jíròrò ìdáhùn sáwọn ìbéèrè náà, wo abala Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ.
Tí ẹ bá tún ń pín ìwé ìkésíni sí àpéjọ àgbègbè, ẹ fún onílé ní ìwé ìkésíni àti ìwé àṣàrò kúkúrú náà pa pọ̀, kí ẹ wá sọ pé: “A tún ń fi ìwé ìkésíni yìí pè yín síbi àpéjọ kan tá a pe gbogbo èèyàn sí lọ́fẹ̀ẹ́.”
Ilé Ìṣọ́ August 1
Tó o bá fẹ́ fi Ilé Ìṣọ́ lọni ní òpin ọ̀sẹ̀ nígbà tó o bá rí i pé ó yẹ, o lè sọ pé: “A fẹ́ fún yín ní ìwé ìròyìn wa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé. Ìwé ìròyìn yìí dáhùn ìbéèrè náà, Ǹjẹ́ Ọlọ́run bìkítà nípa rẹ?”
Ji! July–August
Tó o bá fẹ́ fi Jí! lọni ní òpin ọ̀sẹ̀ nígbà tó o bá rí i pé ó yẹ, o lè sọ pé: “A fẹ́ fún yín ní ìwé ìròyìn wa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé. Ìwé ìròyìn yìí máa ran ìdílé lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe lè máa ṣúnwó ná.”