ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/14 ojú ìwé 1
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 11

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 11
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 11
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 8/14 ojú ìwé 1

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 11

Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 11

Orin 71 àti Àdúrà

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:

cl orí 11 ìpínrọ̀ 9 sí 16 (30 min.)

Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:

Bíbélì kíkà: Númérì 7-9 (10 min.)

No. 1: Númérì 9:9-23 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

No. 2: Ìsapá Èèyàn Kọ́ Ló Máa Mú Ìjọba Ọlọ́run Wá—td 21D (5 min.)

No. 3: Ǹjẹ́ Gbogbo Àpèjẹ Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí?—lr orí 29 (5 min.)

Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:

Orin 107

5 min: “Ọdún 1914 sí Ọdún 2014: Ọgọ́rùn-ún Ọdún tí Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!” Ìjíròrò. Ẹ ka ìpínrọ̀ tó wà lókè ojú ìwé yìí, kí ẹ sì jíròrò rẹ̀. A máa tẹnu mọ́ Ìjọba Ọlọ́run nínú àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn oṣù yìí. Sọ ètò tí ìjọ ṣe fún iṣẹ́ ìsìn pápá.

10 min: “Máa Lo Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Tuntun Tó Sọ̀rọ̀ Nípa Ìkànnì.“ Ẹ jíròrò ohun tó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Ṣe àṣefihàn bí akéde kan ṣe ń fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà lọ ẹnìkan. Lẹ́yìn náà, ó fi ìkànnì jw.org han ẹni náà lórí ẹ̀rọ tó ń lo íńtánẹ́ẹ̀tì tó ní lọ́wọ́.

15 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Ìgboyà Sọ̀rọ̀ Nípa Ìjọba Ọlọ́run.” Ìjíròrò. Ní kí àwọn akéde méjì ṣe àṣefihàn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Akéde kan wà nínú ọkọ̀ èrò, ó ń rìnrìn àjò. Ẹnì kejì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ka kókó kan nínú ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ rẹ̀, ló bá sọ pé: “Ayé yìí ò tiẹ̀ dáa mọ́! Gbogbo èèyàn ló ń wá bí wọ́n á ṣe yanjú ìṣòro ayé yìí, síbẹ̀ agbára wọn ò ká a.” Akéde náà wá ń dá sọ̀rọ̀, ó ní: ‘Ó sì yẹ kí n bá ẹni yìí sọ̀rọ̀ o. Mo gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run!’ Ni akéde náà bá sọ pé: “Mo mọ̀ pé ohun tẹ́ ẹ kà yẹn kì í ṣe ìròyìn ayọ̀. Àmọ́ ṣé mo lè fún yín ní ìwé yìí? Ó sọ̀rọ̀ nípa Ìkànnì kan tó jẹ́ kí n rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí ayé.” Akéde náà wá mẹ́nu kan kókó kan nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀ sì nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Orin 92 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́