Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 22
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 22
Orin 54 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 8, ìpínrọ̀ 8 sí 16 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 106-109 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 109:1-20 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ṣé Àwa Èèyàn Lè Bá Àwọn Mọ̀lẹ́bí Wa Tó Ti Kú Sọ̀rọ̀?—td 24D (5 min.)
No. 3: Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù Nípa Híhùwà Ọmọlúwàbí (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Fi Hàn Pé Ire Ẹni Tí Ò Ń Wàásù fún Jẹ Ọ́ Lógún. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 186 sí 187. Ní ṣókí ṣe àṣefihàn kan látinú àpá yìí.
10 min: Àwọn Ìrírí Tá A Ní Nígbà Tá A Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Gbóríyìn fún àwọn ará nítorí bí wọ́n ṣe kọ́wọ́ ti ìṣètò náà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọjọ́ Saturday àkọ́kọ́ nínú oṣù. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní. Ẹ lè ṣe àṣefihàn ìrírí kan tàbí méjì tó ta yọ.
10 min: “Máa Lò Ó Nígbà Gbogbo.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣe àṣefihàn ọ̀kan lára àwọn àbá tó wà níbẹ̀.
Orin 112 àti Àdúrà