Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tó wà nísàlẹ̀ yìí la óò gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 30, 2007. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ March 5 sí April 30, 2007. [Àkíyèsí: Níbi tá ò bá ti sọ ibi tá a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, kó o ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìlapa èrò àsọyé tá a fẹ́ lò mọ níwọ̀n? [be-YR ojú ìwé 168 ìpínrọ̀ 4]
2. Ọ̀nà mẹ́rin wo la lè gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ wa lẹ́sẹẹsẹ? [be-YR ojú ìwé 170 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 172 ìpínrọ̀ 4]
3. Kí làwọn nǹkan tó yẹ ká fi sọ́kàn nígbà tá a bá ń pinnu àwọn kókó tá a máa sọ̀rọ̀ lé lórí nínú àsọyé? [be-YR ojú ìwé 173 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
4. Kí nìdí tó fi dáa kéèyàn sọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀? [be-YR ojú ìwé 175 ìpínrọ̀ 2 sí 4]
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa sọ̀rọ̀ bí ẹni ń fọ̀rọ̀ wérọ̀, báwo la sì ṣe lè máa sọ̀rọ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀? [be-YR ojú ìwé 179 ìpínrọ̀ 4 àti àpótí; àpótí tó wà ní ojú ìwé 180]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Báwo ló ṣe yẹ kí arákùnrin kan múra sílẹ̀ bí wọ́n bá ní kó bójú tó àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀? [be-YR ojú ìwé 47 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
7. Àǹfààní tí ò láfiwé wo ni rírà tí Kristi rà wá padà mú wá tó ju àǹfààní táwa èèyàn ń rí jẹ látinú ẹ̀? [w05-YR 11/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 1]
8. Báwo ló ṣe yẹ ká máa lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ nínú ìlapa èrò? [be-YR ojú ìwé 53 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
9. Torí kí ni Jésù ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? [be-YR ojú ìwé 57 ìpínrọ̀ 1]
10. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo àfiwé nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? [be-YR ojú ìwé 57 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Báwo la ṣe lè rí i pé à ń fi àmọ̀ràn tó wà nínú Jeremáyà 6:16 sílò, èyí tó sọ pé ká máa rìn ní “òpópónà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, ibi tí ọ̀nà tí ó dára wà nísinsìnyí”?
12. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé káwọn Júù aláìṣòótọ́ wọ̀nyẹn kọ́gbọ́n lára ẹyẹ àkọ̀, ẹ̀kọ́ wo nìyẹn sì kọ́ wa? (Jer. 8:7)
13. Ẹ̀kọ́ wo ni Jeremáyà 15:17 kọ́ wa nípa ojú tó yẹ ká máa fi wo fàájì ṣíṣe lónìí?
14. Ọ̀nà wo làwọn èèyàn gbà dà bí amọ̀ lọ́wọ́ Amọ̀kòkò Gíga Jù Lọ Náà, Jèhófà? (Jer. 18:5-11)
15. Báwo ni ọ̀nà tí Jeremáyà 25:17-26 gbà to àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́sẹẹsẹ ṣe jẹ́ ohun tó yẹ ká fiyè sí lónìí?