ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/07 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 4/07 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá ó lò lóṣù April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó lò. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn títí kan àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ wa mìíràn àmọ́ tí wọn kì í ṣe déédéé nínú ìjọ, ẹ sapá láti fún wọn ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, kẹ́ ẹ lè fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. June: Ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà tàbí ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.

◼ A máa gbé àwọn ibi tá a ti máa ṣe Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!” tọdún 2007 jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ń bọ̀ lọ́nà.

◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ máa rí i pé Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé (S-205-YR) àti Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ (S-205b-YR) tó pọ̀ tó wà lọ́wọ́. Ẹ lè béèrè fún àwọn fọ́ọ̀mù yìí nípa lílo fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, Literature Request Form (S-14). Kẹ́ ẹ rí i pé èyí tí ìjọ ní lọ́wọ́ máa tó lò fún ọdún kan, ó kéré tán. Ẹ máa ṣàyẹ̀wò gbogbo fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé láti rí i dájú pé ìsọfúnni inú wọn pé pérépéré kẹ́ ẹ tó fi wọ́n ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì.

◼ Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí ní àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù tí gbogbo alága àwọn alábòójútó àti akọ̀wé ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́. Bí ìyípadà bá wà nígbàkigbà, kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ kọ àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù tí wọ́n ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ sínú fọ́ọ̀mù tá a máa ń kọ ìsọfúnni sí nípa ìyípadà àdírẹ́sì alága àwọn alábòójútó àti akọ̀wé, ìyẹn Presiding Overseer/Secretary Change of Address (S-29), kí wọ́n buwọ́ lù ú, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lọ́gán. Èyí kan ìyípadà tó bá wà nínú nọ́ńbà tẹlifóònù tí gbogbo àwọn tó wà ládùúgbò wọn gbọ́dọ̀ tẹ̀ kí wọ́n tó tẹ nọ́ńbà tí wọ́n fẹ́ pè.

◼ Nígbàkigbà tó o bá ń ṣètò fúnra rẹ láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tó o sì fẹ́ lọ sí ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àgbègbè níbẹ̀, ọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè náà ni kó o ti béèrè déètì, àkókò àti ibi tí wọ́n á ti ṣe ìpàdé ọ̀hún. Àdírẹ́sì àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wà ní ojú ìwé tó kẹ́yìn nínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook tọdún yìí.

◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2007 ni, “O Lè Nífọ̀kànbalẹ̀ Nínú Ayé Tó Kún fún Ìdààmú Yìí!” Ẹ wo ìfilọ̀ tó jọ èyí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2006.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́